1 Samuẹli 10 – YCB & NTLR

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Samuẹli 10:1-27

1Samuẹli sì mú ìgò kékeré tí òróró wà nínú rẹ̀, ó sì dà á sí orí Saulu. Ó sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu, wí pé, “Olúwa kò ha tí fi òróró yàn ọ ní olórí lórí ohun ìní rẹ̀? 2Bí ìwọ bá kúrò lọ́dọ̀ mi lónìí, ìwọ yóò bá ọkùnrin méjì pàdé lẹ́bàá ibojì Rakeli ní Selsa, ní agbègbè Benjamini. Wọ́n yóò sọ fún ọ pé, ‘Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ìwọ jáde lọ láti wá ní wọn tí rí. Nísinsin yìí, baba à rẹ tí dákẹ́ kò ronú nípa wọn mọ́, ó sì ń dààmú nípa à rẹ. Ó ń béèrè, “Kí ni èmi yóò ṣe nípa ọmọ mi?” ’

3“Nígbà náà, ìwọ yóò lọ láti ibẹ̀ títí yóò fi dé ibi igi ńlá Tabori. Ọkùnrin mẹ́ta tí wọ́n ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run ní Beteli yóò pàdé rẹ níbẹ̀. Ọ̀kan yóò mú ọmọ ewúrẹ́ mẹ́ta lọ́wọ́, èkejì, ìṣù àkàrà mẹ́ta àti ẹ̀kẹta yóò mú ìgò wáìnì. 4Wọ́n yóò kí ọ, wọn yóò sì fún ọ ní ìṣù àkàrà méjì, tí ìwọ yóò gbà lọ́wọ́ wọn.

5“Lẹ́yìn náà, ìwọ yóò lọ sí òkè Ọlọ́run, níbi tí ẹgbẹ́ ogun àwọn Filistini wà. Bí ìwọ ti ń súnmọ́ ìlú náà, ìwọ yóò bá àwọn wòlíì tí ó tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ bọ̀ láti ibi gíga, pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn, tambori àti fèrè àti haapu níwájú wọn, wọn yóò sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀. 6Ẹ̀mí Olúwa yóò sì bà lé ọ, ìwọ yóò sì sọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú wọn, ìwọ yóò sì di ẹni ọ̀tọ̀. 7Bí ìwọ bá ti rí àmì wọ̀nyí, ṣe ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá bà láti ṣe, nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ.

8“Lọ ṣáájú mi sí Gilgali. Èmi yóò sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ wá láti rú ẹbọ sísun àti láti rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀, ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ dúró fún ọjọ́ méje títí èmi yóò fi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ láti sọ fún ọ ohun tí ó yẹ tí ìwọ yóò ṣe.”

A fi Saulu jẹ ọba

9Bí Saulu ti yípadà láti fi Samuẹli sílẹ̀, Ọlọ́run yí ọkàn Saulu padà àti pé gbogbo àmì wọ̀nyí sì wá sí ìmúṣẹ ní ọjọ́ náà. 10Nígbà tí wọ́n dé òkè Gibeah náà, àwọn wòlíì tí ó ń tò ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ pàdé rẹ̀, Ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé e nínú agbára, ó sì darapọ̀ bá wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀. 11Nígbà tí gbogbo àwọn tí ó ti mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀ rí i tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú àwọn wòlíì, wọ́n bi ara wọn, “Kí ni ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí ọmọ Kiṣi yìí. Ṣé Saulu wà lára àwọn wòlíì ni?”

12Ọkùnrin kan tí ó ń gbé níbẹ̀ dáhùn pé, “Ta ni baba wọn?” Ó ti di ohun tí a fi ń pa òwe pé, ǹjẹ́ Saulu náà wà lára àwọn wòlíì bí? 13Lẹ́yìn tí Saulu dákẹ́ sísọ àsọtẹ́lẹ̀, ó lọ sí ibi gíga.

14Nísinsin yìí, arákùnrin baba Saulu béèrè lọ́wọ́ Saulu àti ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Níbo ni ẹ lọ?”

Ó wí pé, “À ń wá àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,” ṣùgbọ́n nígbà tí a kò rí wọn, a lọ sí ọ̀dọ̀ Samuẹli.

15Arákùnrin baba Saulu wí pé, “Sọ fún mi ohun tí Samuẹli wí fún un yín.”

16Saulu dáhùn pé, “Ó fi dá wa lójú pé wọ́n ti rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.” Ṣùgbọ́n kò sọ fún arákùnrin baba a rẹ̀ ohun tí Samuẹli sọ nípa ọba jíjẹ.

17Samuẹli pé àwọn ọmọ Israẹli jọ sí iwájú Olúwa ní Mispa. 18Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli sọ, ‘Èmi mú Israẹli jáde wá láti Ejibiti, Èmi sì gbà yín kúrò lọ́wọ́ agbára Ejibiti àti gbogbo ìjọba tí ó ń pọ́n ọn yín lójú.’ 19Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti kọ Ọlọ́run yín, tí ó gbà yín kúrò nínú gbogbo wàhálà àti ìpọ́njú yín. Ẹ̀yin sì ti sọ pé, ‘Rárá, yan ọba kan fún wa.’ Báyìí, ẹ kó ara yín jọ níwájú Olúwa ní ẹ̀yà àti ìdílé yín.”

20Nígbà tí Samuẹli mú gbogbo ẹ̀yà Israẹli súnmọ́ tòsí, ó yan ẹ̀yà Benjamini. 21Ó kó ẹ̀yà Benjamini síwájú ní ìdílé ìdílé, a sì yan ìdílé Matiri. Ní ìparí a sì yan Saulu ọmọ Kiṣi. Ṣùgbọ́n ní ìgbà tí wọ́n wá a, a kò rí i, 22bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Olúwa pé, “Ṣé ọkùnrin náà ti wá sí bí ni?”

Olúwa sì sọ pé, “Bẹ́ẹ̀ ni ó ti fi ara rẹ̀ pamọ́ láàrín àwọn ẹrù.”

23Wọ́n sáré, wọ́n sì mú un jáde wá. Bí ó ti dúró láàrín àwọn ènìyàn, ó sì ga ju gbogbo àwọn tí ó kù lọ láti èjìká rẹ̀ sókè. 24Samuẹli sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn pé, “Ṣé ẹ ti ri ọkùnrin tí Olúwa ti yàn? Kò sí ẹnìkan bí i rẹ̀ láàrín gbogbo àwọn ènìyàn.”

Nígbà náà àwọn ènìyàn kígbe pé, “Kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn!”

25Samuẹli ṣàlàyé fún àwọn ènìyàn àwọn ìlànà ìjọba. Ó kọ wọ́n sínú ìwé, ó sì fi lélẹ̀ níwájú Olúwa. Lẹ́yìn náà, Samuẹli tú àwọn ènìyàn ká olúkúlùkù sí ilé e rẹ̀.

26Saulu náà padà sí ilé e rẹ̀ ní Gibeah. Àwọn akọni ọkùnrin tí Ọlọ́run ti fi ọwọ́ tọ́ ọkàn wọ́n sì sìn ín. 27Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Beliali wí pé, “Báwo ni ọkùnrin yìí yóò ti ṣe gbà wá?” Wọ́n kẹ́gàn rẹ̀, wọn kò sì mú ẹ̀bùn wá fún un, ṣùgbọ́n Saulu fọwọ́ lérán.

Nouă Traducere În Limba Română

1 Samuel 10:1-27

1Samuel a luat sticluța cu untdelemn, l‑a turnat pe capul lui Saul și i‑a dat sărutare, zicând:

– Nu te‑a uns Domnul să fii conducător peste moștenirea Lui? 2După ce vei pleca de la mine, vei întâlni doi bărbați lângă mormântul Rahelei, în teritoriul lui Beniamin, la Țelțah. Ei îți vor spune: „Măgărițele, pe care te‑ai dus să le cauți, au fost găsite. Tatăl tău însă nu mai este îngrijorat pentru măgărițe, ci este îngrijorat pentru voi. El întreabă: «Ce să fac pentru fiul meu?»“ 3Treci de locul acela și mergi mai departe până la stejarul din Tabor. Acolo te vor întâlni trei bărbați care se suie la Dumnezeu, la Betel. Unul dintre ei duce cu el trei iezi, altul trei pâini, iar altul un burduf cu vin. 4Ei te vor saluta și îți vor dărui două pâini pe care le vei lua din mâna lor.

5După aceea vei merge la Ghiva lui Dumnezeu unde se află o garnizoană de‑a filistenilor. Cum vei intra în cetate, vei întâlni un grup de profeți coborând de pe înălțime cu harfe, tamburine, flaute și lire înaintea lor, iar ei profețind. 6Duhul Domnului va veni peste tine, vei profeți împreună cu ei și vei fi preschimbat într‑un alt om. 7Când ți se vor împlini aceste semne, fă ceea ce mâinile tale vor găsi potrivit să facă, pentru că Domnul este cu tine.

8Coboară înaintea mea la Ghilgal. După aceea voi coborî și eu la tine ca să aduc arderi‑de‑tot și jertfe de pace8 Adesea tradus prin jertfe de comuniune sau jertfe de mulțumire, deoarece poartă și aceste sensuri.. Vei aștepta șapte zile până voi veni la tine ca să‑ți fac cunoscut ce vei avea de făcut.

9De îndată ce Saul s‑a întors cu spatele ca să se despartă de Samuel, Dumnezeu i‑a dat o altă inimă și toate semnele acestea s‑au împlinit în acea zi. 10Au ajuns la Ghiva și iată că un grup de profeți i‑a ieșit în întâmpinare. Duhul lui Dumnezeu a venit peste el și el a profețit în mijlocul lor. 11Când toți cei care‑l cunoșteau înainte au văzut că profețea împreună cu ei, au zis unul către celălalt: „Ce i s‑a întâmplat fiului lui Chiș? Este oare și Saul printre profeți?“ 12Iar un localnic a zis: „Și cine este tatăl lor?“ Astfel s‑a ajuns la următoarea zicere: „Este oare și Saul printre profeți?“

13Când a terminat de profețit, Saul a venit pe înălțime.

14Atunci unchiul său l‑a întrebat pe el și pe slujitorul său:

– Pe unde ați umblat?

Saul i‑a răspuns:

– În căutarea măgărițelor. Însă când am văzut că nu sunt de găsit ne‑am dus la Samuel.

15Unchiul lui l‑a întrebat:

– Spune‑mi, te rog, ce v‑a zis Samuel?

16Saul i‑a răspuns unchiului său:

– Ne‑a zis că măgărițele au fost găsite.

Însă nu i‑a spus nimic din ce i‑a vorbit Samuel cu privire la domnie.

Saul, desemnat oficial drept rege al lui Israel

17Samuel a chemat poporul înaintea Domnului, la Mițpa. 18El le‑a zis fiilor lui Israel: „Așa vorbește Domnul, Dumnezeul lui Israel: «Eu l‑am scos pe Israel din Egipt și v‑am eliberat din mâna egiptenilor și a tuturor regatelor care vă asupreau.» 19Voi însă Îl respingeți astăzi pe Dumnezeul vostru Care v‑a izbăvit din toate nenorocirile și necazurile voastre, zicându‑I: «Când vei pune un rege peste noi?» De aceea înfățișați‑vă acum înaintea Domnului, după semințiile și clanurile voastre.“

20Samuel a apropiat toate semințiile lui Israel, iar sorțul a căzut pe seminția lui Beniamin. 21Apoi a apropiat seminția lui Beniamin după clanuri, iar sorțul a căzut pe clanul lui Matri. În cele din urmă sorțul a căzut pe Saul, fiul lui Chiș. Când l‑au căutat însă, n‑a fost găsit.

22Ei l‑au întrebat în continuare pe Domnul:

– A sosit omul acesta aici?

Domnul a răspuns:

– Iată, s‑a ascuns printre bagaje.

23Ei au alergat și l‑au scos de acolo. Când a stat în picioare în mijlocul poporului, era mai înalt cu un cap decât toți ceilalți din popor. 24Atunci Samuel a zis întregului popor:

– Îl vedeți pe acela pe care l‑a ales Domnul? Nu este altul ca el în tot poporul.

Și toți au strigat:

– Trăiască regele!

25Samuel a făcut cunoscută poporului legea monarhiei și a scris‑o într‑un sul, pe care l‑a așezat înaintea Domnului. După aceea, Samuel a trimis întregul popor, pe fiecare în parte, la casa lui.

26Apoi și Saul a plecat acasă, în Ghiva, însoțit de vitejii ale căror inimi le atinsese Domnul. 27Au fost însă și niște oameni de nimic27 Lit.: fii ai lui Belial. Sensul literal al termenului Belial este fără folos(ință), fără utilitate (bun de nimic). În sens lărgit, termenul se poate traduce cu ticălos, netrebnic. Vezi și nota din 2 Cor. 6:15. care au zis: „Cum ar putea acesta să ne izbăvească?“ L‑au disprețuit și nu i‑au adus niciun dar. Saul însă s‑a făcut că nu‑i aude.