Olúwa pe Samuẹli
1Samuẹli ọmọkùnrin náà ṣe òjíṣẹ́ níwájú Olúwa ní abẹ́ Eli. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì ọ̀rọ̀ Olúwa ṣọ̀wọ́n: kò sì sí ìran púpọ̀.
2Ní alẹ́ ọjọ́ kan Eli ẹni tí ojú rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí di aláìlágbára, tí kò sì ríran dáradára, ó dùbúlẹ̀ ní ipò rẹ̀ bi ti àtẹ̀yìnwá. 3Nígbà tí iná kò tí ì kú Samuẹli dùbúlẹ̀ nínú tẹmpili Olúwa, níbi tí àpótí Olúwa gbé wà. 4Nígbà náà ni Olúwa pe Samuẹli.
Samuẹli sì dáhùn “Èmi nìyí” 5Ó sì sáré lọ sí ọ̀dọ̀ Eli ó sì wí pé, “Èmi nìyí nítorí pé ìwọ pè mí.”
Ṣùgbọ́n Eli wí fún un pé, “Èmi kò pè ọ́; padà lọ dùbúlẹ̀.” Nítorí náà ó lọ ó sì lọ dùbúlẹ̀.
6Olúwa sì tún pè é, “Samuẹli!” Samuẹli tún dìde ó tọ Eli lọ, ó sì wí pé, “Èmi nìyìí, nítorí tí ìwọ pè mí.”
“Ọmọ mi, èmi kò pè ọ́, padà lọ dùbúlẹ̀.”
7Ní àkókò yìí Samuẹli kò tí ì mọ̀ Olúwa: bẹ́ẹ̀ ni a kò sì tí ì fi ọ̀rọ̀ Olúwa hàn án.
8Olúwa pe Samuẹli ní ìgbà kẹta, Samuẹli sì tún dìde, ó sì lọ sọ́dọ̀ Eli ó sì wí pé, “Èmi nìyìí; nítorí tí ìwọ pè mí.”
Nígbà náà ni Eli wá mọ̀ pé Olúwa ni ó ń pe ọmọ náà. 9Nítorí náà Eli sọ fún Samuẹli, “Lọ kí o lọ dùbúlẹ̀. Tí o bá sì pè ọ́, sọ wí pé, ‘máa wí, Olúwa nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbọ́.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni Samuẹli lọ, ó sì lọ dùbúlẹ̀ ní ààyè rẹ̀.
10Olúwa wá, ó sì dúró níbẹ̀, ó pè é bí ó ṣe pè é ní ìgbà tí ó kọjá, “Samuẹli! Samuẹli!”
Nígbà náà ni Samuẹli dáhùn pé, “Máa wí nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbọ́.”
11Olúwa sọ fún Samuẹli pé, “Wò ó, èmi ṣetán láti ṣe ohun kan ní Israẹli tí yóò jẹ́ kí etí gbogbo ènìyàn tí ó gbọ́ ọ já gooro. 12Ní ìgbà náà ni èmi yóò mú ohun gbogbo tí mo ti sọ sí ilé Eli ṣẹ láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. 13Nítorí èmi sọ fún un pé, Èmi yóò ṣe ìdájọ́ fún ilé rẹ̀ títí láé nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn tí òun mọ̀ nípa rẹ̀ nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀-òdì, òun kò sì dá wọn lẹ́kun. 14Nítorí náà, mo búra sí ilé Eli, ‘Ìwà ẹ̀ṣẹ̀ ilé Eli ni a kì yóò fi ẹbọ tàbí ọrẹ mú kúrò láéláé.’ ”
15Samuẹli dùbúlẹ̀ títí di òwúrọ̀ nígbà náà ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ilé Olúwa, ó sì bẹ̀rù láti sọ ìran náà fún Eli. 16Ṣùgbọ́n Eli pè é, ó sì wí pé, “Samuẹli, ọmọ mi.”
Samuẹli sì dáhùn pé, “Èmi nìyìí.”
17Eli béèrè pé, “Kín ni ohun tí ó sọ fún ọ?” “Má ṣe fi pamọ́ fún mi. Kí Ọlọ́run mi ṣe bẹ́ẹ̀ sí ọ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí ìwọ bá fi ohunkóhun tí ó wí fún ọ pamọ́ fún mi.” 18Samuẹli sọ gbogbo rẹ̀ fún un, kò sì fi ohun kankan pamọ́ fún un. Nígbà náà Eli wí pé, “Òun ni Olúwa; jẹ́ kí ó ṣe ohun tí ó dára ní ojú rẹ̀.”
19Olúwa wà pẹ̀lú Samuẹli bí ó ṣe ń dàgbà, kò sì jẹ́ kí ọ̀kan nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ kùnà. 20Gbogbo Israẹli láti Dani títí dé Beerṣeba mọ̀ pé a ti fa Samuẹli kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wòlíì Olúwa. 21Olúwa sì bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ara hàn án ní Ṣilo, nítorí Olúwa ti fi ará hàn án fún Samuẹli ní Ṣilo nípa ọ̀rọ̀ Olúwa.
Herren kallar den unge Samuel
1Den unge pojken Samuel fortsatte att tjäna Herren hos Eli. Vid den här tiden var budskap från Herren mycket sällsynta. Det var också ovanligt att någon såg en syn.
2Då hände en gång följande när Eli låg på sin plats. Hans ögon hade nu försvagats så att han inte längre kunde se. 3Guds lampa var ännu inte släckt och Samuel låg och sov i Herrens tempel där Guds ark3:3 Guds ark var den guldöverdragna kista där stentavlorna med förbundstexten, tio Guds bud, fanns. fanns.
4Herren kallade då på Samuel. ”Ja”, svarade Samuel, ”här är jag!” 5Sedan sprang han till Eli. ”Här är jag”, sa han. ”Du ropade på mig.” ”Jag ropade inte på dig”, svarade Eli, ”gå tillbaka och lägg dig!” Och Samuel lydde.
6Herren ropade på Samuel en gång till och, som förut, steg Samuel upp och gick till Eli. ”Ja”, svarade han, ”här är jag. Du ropade på mig.” ”Jag har inte ropat på dig, min son”, sa Eli. ”Gå tillbaka och lägg dig!”
7Samuel kände ännu inte Herren och hade aldrig tidigare fått ett budskap från honom. 8När Herren nu för tredje gången ropade på honom, steg Samuel än en gång upp och gick till Eli. ”Ja”, sa han. ”Här är jag! Du ropade på mig.”
Då förstod Eli att det var Herren som hade ropat på pojken, 9och han sa till Samuel: ”Gå och lägg dig igen och om han ropar på dig en gång till, så ska du svara: ’Tala, Herre, din tjänare hör!’ ” Och så gick Samuel tillbaka och lade sig.
10Då kom Herren och ställde sig där och ropade som förut: ”Samuel! Samuel!” Och nu svarade Samuel: ”Tala, din tjänare hör!”
11Herren sa då till Samuel: ”Jag ska göra något i Israel som kommer att ringa i öronen på alla som hör det. 12Då ska jag låta allt det hända som jag har varnat Eli och hans familj för, från början till slut. 13Jag har talat om för honom att jag ska döma hela hans familj för alltid på grund av den synd han känt till, att hans söner hädar mig utan att han ingriper. 14Därför har jag svurit en ed att de synder som Eli och hans söner har begått aldrig kan sonas vare sig genom slaktoffer eller genom några andra offer.”
15Samuel låg sedan kvar ända till morgonen då han öppnade dörrarna till Herrens hus. Han var rädd att berätta för Eli om synen. 16Men Eli ropade på honom: ”Samuel, min son!” ”Här är jag,” svarade Samuel. 17Sedan frågade Eli: ”Vad sa han till dig? Tala om alltihop! Må Gud straffa dig både nu och i framtiden om du döljer något för mig!” 18Och då berättade Samuel exakt utan att dölja någonting vad Herren hade sagt.
”Han är Herren, låt honom göra vad han vill”, svarade Eli.
19Samuel växte upp och Herren var med honom och lät allt vad han sagt gå i uppfyllelse. 20Hela Israel från Dan till Beer Sheva förstod att Samuel verkligen var en Herrens profet.
21Herren fortsatte sedan att visa sig i Shilo. Där uppenbarade han sig för Samuel genom sitt ord.