1 Samuẹli 2 – YCB & BPH

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Samuẹli 2:1-36

Àdúrà Hana

1Hana sì gbàdúrà pé,

“Ọkàn mi yọ̀ sí Olúwa;

ìwo agbára mi ni a sì gbé sókè sí Olúwa.

Ẹnu mi sì gbòòrò lórí àwọn ọ̀tá mi,

nítorí ti èmi yọ̀ ni ìgbàlà rẹ̀.

2“Kò sí ẹni tí ó mọ́ bi Olúwa;

kò sí ẹlòmíràn bí kò ṣe ìwọ;

kò sì sí àpáta bi Ọlọ́run wa.

3“Má ṣe halẹ̀;

má ṣe jẹ́ kí ìgbéraga ti ẹnu yín jáde

nítorí pé Ọlọ́run olùmọ̀ ni Olúwa,

láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá ni a ti ń wọn ìwà.

4“Ọ̀run àwọn alágbára ti ṣẹ́,

àwọn tí ó ṣe aláìlera ni a fi agbára dì ní àmùrè.

5Àwọn tí ó yọ̀ fún oúnjẹ ti fi ara wọn ṣe alágbàṣe,

àwọn tí ebi ń pa kò sì ṣe aláìní.

Tó bẹ́ẹ̀ tí àgàn fi bí méje.

Ẹni tí ó bímọ púpọ̀ sì di aláìlágbára.

6Olúwa pa ó sì sọ di ààyè;

ó mú sọ̀kalẹ̀ lọ sí isà òkú, ó sì gbé dìde.

7Olúwa sọ di tálákà; ó sì sọ di ọlọ́rọ̀;

ó rẹ̀ sílẹ̀, ó sì gbé sókè.

8Ó gbé tálákà sókè láti inú erùpẹ̀ wá,

ó gbé alágbe sókè láti orí òkìtì eérú wá,

láti mú wọn jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé,

láti mu wọn jogún ìtẹ́ ògo,

“Nítorí pé ọ̀wọ́n ayé ti Olúwa ni,

ó sì ti gbé ayé ka orí wọn.

9Yóò pa ẹsẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ mọ́,

àwọn ènìyàn búburú ni yóò dákẹ́ ní òkùnkùn.

“Nípa agbára kò sí ọkùnrin tí yóò borí.

10A ó fọ́ àwọn ọ̀tá Olúwa túútúú;

láti ọ̀run wá ni yóò sán àrá sí wọn;

Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ òpin ayé.

“Yóò fi agbára fún ọba rẹ̀,

yóò si gbé ìwo ẹni àmì òróró rẹ̀ sókè.”

11Elkana sì lọ sí Rama, sí ilé rẹ̀, ọmọ náà sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún Olúwa níwájú Eli àlùfáà.

Àwọn ọmọ Eli búburú

12Àwọn ọmọ Eli sì jẹ́ ọmọ Beliali; wọn kò mọ Olúwa. 13Iṣẹ́ àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwọn ènìyàn ni pé nígbà tí ẹnìkan bá ṣe ìrúbọ, ìránṣẹ́ àlùfáà á dé, nígbà tí ẹran náà bá ń hó lórí iná, pẹ̀lú ọ̀pá-ẹran náà oníga mẹ́ta ní ọwọ́ rẹ̀. 14Òun a sì fi gún inú apẹ, tàbí àgé tàbí ọpọ́n, tàbí ìkòkò, gbogbo èyí tí ọ̀pá-ẹran oníga náà bá mú wá sí òkè, àlùfáà á mú un fún ara rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe sí gbogbo Israẹli tí ó wá sí ibẹ̀ ní Ṣilo. 15Pẹ̀lú, kí wọn tó sun ọ̀rá náà, ìránṣẹ́ àlùfáà á dé, á sì wí fún ọkùnrin tí ó ń ṣe ìrúbọ pé, “Fi ẹran fún mi láti sun fún àlùfáà; nítorí tí kì yóò gba ẹran sísè lọ́wọ́ rẹ, bí kò ṣe tútù.”

16Bí ọkùnrin náà bá sì wí fún un pé, “Jẹ́ kí wọn ó sun ọ̀rá náà nísinsin yìí, kí o sì mú iyekíye tí ọkàn rẹ̀ bá fẹ́,” nígbà náà ni yóò dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n kí ìwọ ó fi í fún mi nísinsin yìí, bí kó ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó fi agbára gbà á.”

17Ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì tóbi gidigidi níwájú Olúwa: nítorí tí àwọn ènìyàn kórìíra ẹbọ Olúwa.

18Ṣùgbọ́n Samuẹli ń ṣe ìránṣẹ́ níwájú Olúwa, ọmọdé, ti a wọ̀ ní efodu ọ̀gbọ̀. 19Pẹ̀lúpẹ̀lú, ìyá rẹ̀ máa ń dá aṣọ ìlekè péńpé fún un, a sì máa mú wá fún un lọ́dọọdún, nígbà tí ó bá bá ọkọ rẹ̀ gòkè wá láti ṣe ìrúbọ ọdún. 20Eli súre fún Elkana àti aya rẹ̀ pé, “Kí Olúwa fún ọ ní irú-ọmọ láti ara obìnrin yìí wá, nítorí ẹ̀bùn tí ó béèrè tí ó sì tún fún Olúwa.” Wọ́n sì lọ sí ilé wọn. 21Olúwa si bojú wo Hana, ó sì lóyún, ó bí ọmọkùnrin mẹ́ta àti ọmọbìnrin méjì. Samuẹli ọmọ náà sì ń dàgbà níwájú Olúwa.

22Eli sì di arúgbó gidigidi, ó sì gbọ́ gbogbo èyí ti àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe sí gbogbo Israẹli; àti bi wọ́n ti máa ń bá àwọn obìnrin sùn, tí wọ́n máa ń péjọ ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ. 23Ó sì wí fún wọn pé, kí ni ó ti ri “Èétirí tí èmi fi ń gbọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sí yín? Nítorí tí èmi ń gbọ́ iṣẹ́ búburú yín láti ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn. 24Bẹ́ẹ̀ kọ́ ẹ̀yin ọmọ mi, nítorí kì ṣe ìròyìn rere èmi gbọ́; ẹ̀yin mú ènìyàn Olúwa dẹ́ṣẹ̀. 25Bí ẹnìkan bá ṣẹ̀ sí ẹnìkejì, onídàájọ́ yóò ṣe ìdájọ́ rẹ̀: ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ṣẹ̀ sí Olúwa, ta ni yóò bẹ̀bẹ̀ fún un?” Wọn kò sì fi etí sí ohùn baba wọn, nítorí tí Olúwa ń fẹ́ pa wọ́n.

26Ọmọ náà Samuẹli ń dàgbà, ó sì rí ojúrere lọ́dọ̀ Olúwa, àti ènìyàn pẹ̀lú.

Wòlíì sọtẹ́lẹ̀ nípa ilé Eli

27Ènìyàn Ọlọ́run kan tọ Eli wá, ó sì wí fún un pé, “Báyìí ni Olúwa wí, ‘Èmi fi ara mi hàn ní gbangba fún ilé baba rẹ, nígbà tí wọ́n ń bẹ ní Ejibiti nínú ilé Farao. 28Èmi sì yàn án kúrò láàrín gbogbo ẹ̀yà Israẹli láti jẹ́ àlùfáà mi, láti rú ẹbọ lórí pẹpẹ mi, láti fi tùràrí jóná, láti wọ efodu níwájú mi, èmi sì fi gbogbo ẹbọ tí ọmọ Israẹli máa ń fi iná sun fún ìdílé baba rẹ̀. 29Èéha ṣe tí ẹ̀yin fi tàpá sí ẹbọ àti ọrẹ mi, tí mo pàṣẹ ní ibùjókòó mi, ìwọ sì bu ọlá fún àwọn ọmọ rẹ jù mí lọ, tí ẹ sì fi gbogbo àṣàyàn ẹbọ Israẹli àwọn ènìyàn mi mú ara yín sanra.’

30“Nítorí náà Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí pé, ‘Èmi ti wí nítòótọ́ pé, ilé rẹ àti ilé baba rẹ, yóò máa rìn níwájú mi títí.’ Ṣùgbọ́n nísinsin yìí Olúwa wí pé, ‘Kí á má rí i! Àwọn tí ó bú ọlá fún mi ni èmi yóò bu ọlá fún, àti àwọn tí kò kà mí sí ni a ó sì ṣe aláìkàsí. 31Kíyèsi i, àwọn ọjọ́ ń bọ̀ tí èmi ó gé agbára rẹ kúrò, àti agbára baba rẹ, tí kì yóò sí arúgbó kan nínú ilé rẹ. 32Ìwọ yóò rí wàhálà ti Àgọ́, nínú gbogbo ọlá tí Ọlọ́run yóò fi fún Israẹli; kì yóò sí arúgbó kan nínú ilé rẹ láéláé. 33Ọkùnrin tí ó jẹ́ tìrẹ, tí èmi kì yóò gé kúrò ní ibi pẹpẹ mi ni a ó dá sí láti sọkún yọ lójú àti láti banújẹ́. Ṣùgbọ́n gbogbo irú-ọmọ ilé rẹ̀ ni a ó fi idà pa ní ààbọ̀ ọjọ́ wọn.

34“ ‘Kí ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ ọkùnrin rẹ̀ méjèèjì, Hofini àti Finehasi, yóò jẹ́ àmì fún ọ—àwọn méjèèjì yóò kú ní ọjọ́ kan náà. 35Èmi yóò dìde fún ara mi láti gbé àlùfáà olódodo dìde fún ara mi, ẹni tí yóò ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó wà ní ọkàn mi àti inú mi. Èmi yóò fi ẹsẹ̀ ilé rẹ̀ múlẹ̀ gbọningbọnin òun yóò sì ṣe òjíṣẹ́ níwájú ẹni òróró mi ní ọjọ́ gbogbo. 36Nígbà náà olúkúlùkù ẹnikẹ́ni tí ó bá kù ní ìdílé yín, yóò jáde wá yóò sì foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀ nítorí ẹyọ fàdákà àti nítorí èépá àkàrà àti ẹ̀bẹ̀ pé, “Jọ̀wọ́ yàn mí sí ọ̀kan nínú iṣẹ́ àwọn àlùfáà, kí èmi kí ó le máa rí oúnjẹ jẹ.” ’ ”

Bibelen på hverdagsdansk

1. Samuelsbog 2:1-36

Hannas lovprisning

1Da lovpriste Hanna Herren med følgende ord:

Jeg fryder mig over dig, Herre.

Du har gjort mig glad.

Nu kan jeg le ad mine fjender

og glæde mig over, at du har reddet mig.

2Ingen er hellig, som du er.

Du hjælper og beskytter os.

Din lige findes ikke.

3Intet menneske må være hovmodigt

eller bruge pralende ord,

for Herren er den alvidende Gud,

han dømmer vores handlinger.

4Den overlegne lider nederlag,

men den segnefærdige finder styrke.

5Den rige må arbejde for føden,

mens den sultende spiser sig mæt.

Den barnløse kvinde føder syv børn,

mens den børnerige sidder og sygner hen.

6Herren bringer død, og Herren giver liv.

Nogle lægges i graven, andre oprejses fra den.

7Herren gør nogle fattige og andre rige,

han ydmyger nogle og ophøjer andre.

8Han løfter de hjælpeløse op fra støvet,

han giver de fortvivlede nyt mod.

Han ærer dem som kongebørn,

bænker dem på hæderspladsen.

Jordens grundvold har Herren skabt,

på den byggede han hele verden.

9Herren beskytter sine trofaste tjenere,

men de onde omkommer i mørket.

Ingen kan klare sig i egen kraft.

10De, som kæmper mod Herren, kvæstes.

Han tordner imod dem fra Himlen.

Herren dømmer alle på jorden.

Han giver sin konge styrke

og stor magt til sin salvede.2,10 På dette tidspunkt havde Israel ingen konge, og kun præsterne var salvede med olivenolie som tegn på deres indvielse og tjeneste for Herren. Det hebraiske ord for „salvede” her i teksten er Mashiach (Messias), og den græske oversættelse af ordet „salvede” er Christos. Disse ord fra Hanna kan derfor opfattes profetisk om den senere åndelige konge, Jesus Messias, den salvede og udvalgte.

11Derefter rejste Elkana og Hanna hjem til Rama. Men drengen blev i Shilo, hvor han tjente Herren under Elis opsyn.

Elis sønner

12Selv om Elis sønner var præster, var de ugudelige og uden ærefrygt for Herren. 13Nu var det sådan, at præsterne havde ret til at få en vis del af, hvad der blev ofret. Så hver gang nogen bragte et slagtoffer, kom præsternes tjener, mens den del af offerkødet, som skulle spises, stod og kogte, og stak en tregrenet gaffel 14ned i gryden. Det kød, som sad på gaflen, når den blev trukket op, var præsternes del. Den fremgangsmåde brugte de over for alle, der kom til Shilo for at ofre. 15Men nu var det blevet sådan, at inden fedtet var brændt af den del af offerkødet, som tilhørte Herren, kom tjeneren og sagde til den, som ofrede: „Giv præsterne noget kød, de kan stege. De vil ikke have kogt kød, kun råt.” 16Hvis manden svarede: „Tag så meget, du vil, men lad mig først brænde fedtet af,” sagde tjeneren: „Nej, giv mig kødet nu, ellers tager jeg det med magt.” 17Elis sønners synd var stor i Herrens øjne, for de viste ringeagt for Herrens offergaver.

18Samuel derimod tjente Herren, selvom han endnu kun var et barn. Han havde en efod af linned på magen til præsternes. 19Hvert år lavede hans mor en kappe til ham. Den havde hun så med, når hun kom til Shilo for at ofre sammen med sin mand.

20Før Elkana og Hanna rejste hjem fra Shilo, velsignede Eli dem med ordene: „Må Gud give jer andre børn i stedet for Samuel, som er givet til Herren.” 21Og Gud velsignede Hanna, så hun blev gravid igen. Hun fødte i alt tre sønner og to døtre foruden Samuel, som voksede op hos Herren.

22Eli var efterhånden en gammel mand, men han vidste godt, hvad hans sønner foretog sig. Han hørte om, hvordan de behandlede folk, og at de gik i seng med de kvinder, som hjalp til ved indgangen til helligdommen. 23Derfor sagde han til dem: „Jeg har hørt om de skammelige ting, I gør. 24I bliver nødt til at holde op med det. I har fået et dårligt ry blandt Herrens folk. 25Når en mand gør noget forkert over for en anden person, kan Gud forsvare den ene eller den anden. Men når nogen gør oprør imod Gud selv, hvem kan så forsvare ham?” Men Elis sønner lyttede ikke til deres fars advarsel, for Herren havde allerede besluttet, at de skulle dø.

26I mellemtiden voksede Samuel op og var afholdt både af mennesker og Gud.

Dommen over Elis familie

27En dag kom en af Guds profeter til Eli og gav ham følgende budskab fra Herren: „Åbenbarede jeg mig ikke tydeligt, allerede dengang dine forfædre var Faraos slaver i Egypten? 28Af alle Israels stammer udvalgte jeg din slægt til at være mine præster, til at bringe ofre på mit alter, til at brænde røgelse og til at bære præstedragt og tjene mig. Og jeg gav jer ret til en vis del af offerkødet. 29Hvorfor er I da så grådige, at I forgriber jer på de øvrige ofre, som jeg har forordnet for min helligdom? Hvorfor tager du mere hensyn til dine sønner end til mig? I er jo blevet fede ved at tage den bedste del af mit folks offergaver til jer selv. 30Derfor siger Herren, Israels Gud: Jeg lovede engang, at dine efterkommere skulle være præster for mig altid, men sådan bliver det ikke nu. For jeg ærer den, som ærer mig; og jeg foragter den, som foragter mig. 31Derfor vil jeg straffe din familie og slægt, så at ingen mand i din familie bliver gammel. 32Med misundelse vil du se på, hvordan mit folk får fremgang, mens din egen slægt skrumper ind. Ingen fra din slægt bliver gamle. 33De, som ikke bliver dræbt, vil leve i sorg og skændsel, og deres børn vil blive dræbt i krig. 34Som et tegn på, at det vil ske, som jeg har sagt, skal dine to sønner Hofni og Pinehas dø på samme dag. 35I stedet vil jeg lade en trofast præst fremstå, en, som vil tjene mig og gøre, som jeg siger. Jeg vil velsigne hans slægt, og de skal altid tjene som præster for min udvalgte konge. 36Dine efterkommere skal bøje sig for ham og tigge ham om penge og mad. ‚Vær barmhjertig,’ vil de sige, ‚og giv os arbejde som præster, så vi kan få noget at spise.’ ”