1 Samuẹli 1 – Yoruba Contemporary Bible YCB

Yoruba Contemporary Bible

1 Samuẹli 1:1-28

Ìbí Samuẹli

1Ọkùnrin kan wà, láti Ramataimu-Sofimu, láti ìlú olókè Efraimu, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Elkana, ọmọ Jerohamu, ọmọ Elihu, ọmọ Tohu, ọmọ Sufu, ará Efrata. 2Ó sì ní ìyàwó méjì: orúkọ wọn ni Hana àti Penina: Penina ní ọmọ, ṣùgbọ́n Hana kò ní.

3Ní ọdọọdún, ọkùnrin yìí máa ń gòkè láti ìlú rẹ̀ láti lọ sìn àti láti ṣe ìrúbọ sí Olúwa àwọn ọmọ-ogun jùlọ ní Ṣilo, níbi tí àwọn ọmọkùnrin Eli méjèèjì, Hofini àti Finehasi ti jẹ́ àlùfáà Olúwa. 4Nígbàkígbà tí ó bá kan Elkana láti ṣe ìrúbọ, òun yóò bù lára ẹran fún aya rẹ̀ Penina àti fún gbogbo àwọn ọmọ ọkùnrin àti obìnrin. 5Ṣùgbọ́n ó máa ń pín ìlọ́po fun Hana nítorí pé ó fẹ́ràn rẹ̀ àti pé Olúwa ti sé e nínú. 6Nítorí pé Olúwa ti sé e nínú, orogún rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní fín níràn láti lè mú kí ó bínú. 7Eléyìí sì máa ń ṣẹlẹ̀ ní ọdọọdún. Nígbàkígbà tí Hana bá gòkè lọ sí ilé Olúwa, orogún rẹ̀ a máa fín níràn títí tí yóò fi máa sọkún tí kò sì ní lè jẹun. 8Elkana ọkọ rẹ̀ yóò sọ fún un pé, “Hana èéṣe tí ìwọ fi ń sọkún? Èéṣe tí ìwọ kò fi jẹun? Èéṣe tí ìwọ fi ń ba ọkàn jẹ́? Èmi kò ha ju ọmọ mẹ́wàá lọ fún ọ bí?”

9Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti jẹ, tí wọ́n tún mu tán ní Ṣilo, Hana dìde wá síwájú Olúwa. Nígbà náà, Eli àlùfáà wà lórí àga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa ní ibi tí ó máa ń jókòó. 10Pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn Hana sọkún gidigidi, ó sì gbàdúrà sí Olúwa. 11Ó sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ wí pé, “Olúwa àwọn ọmọ-ogun, jùlọ tí ìwọ bá le bojú wo ìránṣẹ́bìnrin rẹ kí ìwọ sì rántí rẹ̀, tí ìwọ kò sì gbàgbé ìránṣẹ́ rẹ ṣùgbọ́n tí ìwọ yóò fún un ní ọmọkùnrin, nígbà náà èmi yóò sì fi fún Olúwa ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ a kì yóò sì fi abẹ kàn án ní orí.”

12Bí ó sì ṣe ń gbàdúrà sí Olúwa, Eli sì kíyèsi ẹnu rẹ̀. 13Hana ń gbàdúrà láti inú ọkàn rẹ̀, ṣùgbọ́n ètè rẹ̀ ni ó ń mì, a kò gbọ́ ohùn rẹ̀. Eli rò wí pé ó ti mu ọtí yó. 14Eli sì wí fún un pé, “Yóò ti pẹ́ fún ọ tó tí ìwọ yóò máa yó? Mú ọtí wáìnì rẹ̀ kúrò.”

15Hana dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, Olúwa mi,” “Èmi ni obìnrin oníròbìnújẹ́. Èmi kò mu ọtí wáìnì tàbí ọtí líle; Èmi ń tú ọkàn mi jáde sí Olúwa ni. 16Má ṣe mú ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí obìnrin búburú. Èmi ti ń gbàdúrà níhìn-ín nínú ìrora ọkàn àti ìbànújẹ́ mi.”

17Eli dáhùn pé, “Máa lọ ní àlàáfíà, kí Ọlọ́run Israẹli fi ohun tí ìwọ ti béèrè ní ọwọ́ rẹ̀ fún ọ.”

18Ó wí pé, “Kí ìránṣẹ́bìnrin rẹ rí oore-ọ̀fẹ́ lójú rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni obìnrin náà bá tirẹ̀ lọ, ó sì jẹun, kò sì fa ojú ro mọ́.

19Wọ́n sì dìde ni kùtùkùtù òwúrọ̀, wọn wólẹ̀ sìn níwájú Olúwa, wọn padà wa sí ilé wọn ni Rama: Elkana si mọ Hana aya rẹ̀: Olúwa sì rántí rẹ̀. 20Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ rẹ̀ pé, lẹ́yìn ìgbà tí Hana lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Samuẹli, pé, “Nítorí tí mo béèrè rẹ̀ lọ́wọ́ Olúwa.”

A ya Samuẹli sí mímọ́ fún Olúwa

21Ọkùnrin náà Elkana, àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, gòkè lọ láti rú ẹbọ ọdún sí Olúwa, àti láti sán ẹ̀jẹ́ rẹ̀. 22Ṣùgbọ́n Hana kò gòkè lọ; nítorí tí ó sọ fún ọkọ rẹ̀ pé, “Ó di ìgbà tí mo bá gba ọmú lẹ́nu ọmọ náà, nígbà náà ni èmi yóò mú un lọ, kí òun lè fi ara hàn níwájú Olúwa, kí ó sí máa gbé ibẹ̀ títí láé.”

23Elkana ọkọ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Ṣe èyí tí ó tọ́ lójú rẹ. Dúró títí ìwọ yóò fi gba ọmú lẹ́nu rẹ̀; ṣùgbọ́n kí Olúwa sá à mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni obìnrin náà sì jókòó, ó sì fi ọmú fún ọmọ rẹ̀ títí ó fi gbà á lẹ́nu rẹ̀.

24Nígbà tí ó sì gba ọmú lẹ́nu rẹ̀, ó sì mú un gòkè lọ pẹ̀lú ara rẹ̀. Pẹ̀lú ẹgbọrọ màlúù mẹ́ta, àti ìyẹ̀fun efa kan, àti ìgò ọtí wáìnì kan, ó sì mú un wá sí ilé Olúwa ní Ṣilo: ọmọ náà sì wà ní ọmọdé. 25Wọ́n pa ẹgbọrọ màlúù, wọ́n sì mú ọmọ náà tọ Eli wá. 26Hana sì wí pé, “Olúwa mi, bí ọkàn rẹ ti wà láààyè, Olúwa mi, èmi ni obìnrin náà tí ó dúró lẹ́bàá ọ̀dọ̀ rẹ níhìn-ín tí ń tọrọ lọ́dọ̀ Olúwa. 27Ọmọ yìí ni mo ń tọrọ; Olúwa sì fi ìdáhùn ìbéèrè tí mo béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ fún mi. 28Nítorí náà pẹ̀lú, èmi fi í fún Olúwa; ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀: nítorí tí mo ti béèrè rẹ̀ fún Olúwa.” Wọn si wólẹ̀ sin Olúwa níbẹ̀.