Ìpín ti àwọn ọmọ-ogun
1Wọ̀nyí ni ìwé àkójọ orúkọ àwọn ọmọ Israẹli, àwọn olórí àwọn ìdílé, àwọn balógun ẹgbẹgbẹ̀rún àti àwọn balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún àti àwọn ìjòyè wọn. Tí ó n sin ọba nínú gbogbo ohun tí ó kan ìpín àwọn ọmọ-ogun tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ní oṣooṣù ní gbogbo ọdún. Ìpín kọ̀ọ̀kan jẹ́ ẹgbàá-méjìlá (24,000) ọkùnrin.
2Ní ti alákòóso lórí ìpín kìn-ín-ní fún oṣù kìn-ín-ní jẹ́ Jaṣobeamu ọmọ Sabdieli àwọn ọkùnrin ẹgbàá-méjìlá (24,000) ní ó wà ní abẹ́ ìpín tirẹ̀. 3Ó jẹ́ ìran ọmọ Peresi àti olóyè fún gbogbo àwọn ìjòyè ológun fún oṣù kìn-ín-ní.
4Alákòóso fún ìpín àwọn ọmọ-ogun fún oṣù kejì jẹ́ Dodai ará Ahohi; Mikloti jẹ́ olórí ìpín tirẹ̀. Ọkùnrin ẹgbàá-méjìlá ni ó wà ní ìpín tirẹ̀. (24,000).
5Olórí àwọn ọmọ-ogun ẹlẹ́kẹta fún oṣù kẹta jẹ́ Benaiah ọmọ Jehoiada àlùfáà. Ó jẹ́ olóyè, àwọn ọkùnrin ẹgbàá-méjìlá ní ó wà ní ìpín tirẹ̀. (24,000). 6Èyí ni Benaiah náà tí ó jẹ́ ọkùnrin ńlá láàrín àwọn ọgbọ̀n àti lórí àwọn ọgbọ̀n. Ọmọ rẹ̀ Amisabadi jẹ́ alákòóso lórí ìpín tirẹ̀.
7Ẹlẹ́kẹrin fún oṣù kẹrin, jẹ́ Asaheli arákùnrin Joabu: ọmọ rẹ̀ Sebadiah jẹ́ arọ́pò rẹ̀. Ẹgbàá-méjìlá ọkùnrin (24,000) ni ó wà ní ìpín rẹ̀.
8Ẹ̀karùnún fún oṣù karùn-ún, jẹ́ olórí Ṣamhuti ará Israhi. Ẹgbàá-méjìlá ọkùnrin (24,000) ní ó wà ní ìpín tirẹ̀.
9Ẹ̀kẹfà fún oṣù kẹfà jẹ́ Ira ọmọ Ikẹsi, ará Tekoi. Ọkùnrin ẹgbàá-méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín rẹ̀.
10Èkeje fún oṣù keje jẹ́ Helesi ará Peloni, ará Efraimu. Ọkùnrin ẹgbàá-méjìlá (24,000) ni o wà ní ìpín rẹ̀.
11Ẹ̀kẹjọ fún oṣù kẹjọ jẹ́ Sibekai ará Huṣati, ará Sera ọkùnrin ẹgbàá-méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín rẹ̀.
12Ẹ̀kẹsànán fún oṣù kẹsànán jẹ́. Abieseri ará Anatoti, ará Benjamini ọkùnrin ẹgbàá-méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín rẹ̀.
13Ẹ̀kẹwàá fún oṣù kẹwàá jẹ́ Maharai ará Netofa, ará Sera ọkùnrin ẹgbàá-méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín rẹ̀.
14Ìkọkànlá fún oṣù kọkànlá jẹ́ Benaiah ará Piratoni ará Efraimu ọkùnrin ẹgbàá-méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín tirẹ̀.
15Èkejìlá fún oṣù kejìlá jẹ́ Heldai ará Netofa láti ìdílé Otnieli. Ẹgbàá-méjìlá ọkùnrin (24,000) ni ó wà ní ìpín tirẹ̀.
Àwọn ìjòyè ti ẹ̀yà náà
16Àwọn ìjòyè lórí àwọn ẹ̀yà tí Israẹli:
lórí àwọn ará Reubeni: Elieseri ọmọ Sikri;
lórí àwọn ọmọ Simeoni: Ṣefatia ọmọ Maaka;
17lórí Lefi: Haṣabiah ọmọ Kemueli;
lórí Aaroni: Sadoku;
18lórí Juda: Elihu arákùnrin Dafidi;
lórí Isakari: Omri ọmọ Mikaeli;
19lórí Sebuluni: Iṣmaiah ọmọ Ọbadiah;
lórí Naftali: Jerimoti ọmọ Asrieli;
20lórí àwọn ará Efraimu: Hosea ọmọ Asasiah;
lórí ààbọ̀ ẹ̀yà Manase: Joeli ọmọ Pedaiah;
21lórí ààbọ̀ ẹ̀yà Manase ní Gileadi: Iddo ọmọ Sekariah;
lórí Benjamini: Jaasieli ọmọ Abneri;
22lórí Dani: Asareeli ọmọ Jerohamu.
Wọ̀nyí ni àwọn ìjòyè lórí ẹ̀yà Israẹli.
23Dafidi kò kọ iye àwọn ọkùnrin náà ní ogún ọdún sẹ́yìn tàbí dín nítorí Olúwa ti ṣe ìlérí láti ṣe Israẹli gẹ́gẹ́ bí iye ìràwọ̀ ojú ọ̀run. 24Joabu ọmọ Seruiah bẹ̀rẹ̀ sí ní kà wọ́n, ṣùgbọ́n kò parí kíkà wọ́n nítorí, ìbínú dé sórí àwọn Israẹli nípasẹ̀ kíka iye àti iye náà, a kò kọ ọ́ sínú ìwé ìtàn ayé ti ọba Dafidi.
Àwọn alábojútó ọba
25Asmafeti ọmọ Adieli wà ní ìdí ilé ìṣúra ti ọba.
Jonatani ọmọ Ussiah wà ní ìdí ilé ìṣúra ní iwájú agbègbè nínú àwọn ìlú, àwọn ìletò àti àwọn ilé ìṣọ́.
26Esri ọmọ Kelubu wà ní ìdí àwọn òṣìṣẹ́ lórí pápá, tí wọ́n ń ko ilẹ̀ náà.
27Ṣimei ará Ramoti wà ní ìdí àwọn ọgbà àjàrà.
Sabdi ará Sifmi wà ní ìdí mímú jáde ti èso àjàrà fún ọpọ́n ńlá tí a ń fi ọ̀tún èso àjàrà sí.
28Baali-Hanani ará Gederi wà ní ìdí olifi àti àwọn igi sikamore ní apá ìhà ìwọ̀-oòrùn àwọn ní ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀.
Joaṣi wà ní ìdí fífún ni ní òróró olifi.
29Ṣitrai ará Ṣaroni wà ní ìdí fífi ọwọ́ ẹran jẹ oko ní Ṣaroni.
Ṣafati ọmọ Adlai wà ní ìdí àwọn ọ̀wọ́ ẹran ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀.
30Obili ará Iṣmaeli wà ní ìdí àwọn ìbákasẹ.
Jehdeiah ará Meronoti wà ní ìdí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.
31Jasisi ará Hagari wà ní ìdí àwọn agbo ẹran.
Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn oníṣẹ́ tí wọ́n wà ní ìdí ẹrù ọba Dafidi.
32Jonatani, arákùnrin Dafidi jẹ́ olùdámọ̀ràn, ọkùnrin onímọ̀ àti akọ̀wé.
Jehieli ọmọ Hakmoni bojútó àwọn ọmọ ọba.
33Ahitofeli jẹ́ olùdámọ̀ràn ọba.
Huṣai ará Arki jẹ́ ọ̀rẹ́ ọba.
34(Jehoiada ọmọ Benaiah àti nípasẹ̀ Abiatari jẹ ọba rọ́pò Ahitofeli.)
Joabu jẹ́ olórí ọmọ-ogun ọba.
Войсковое деление
1Вот перечень израильтян — глав семейств, тысячников, и сотников, и их чиновников, которые служили царю во всем, что относилось к войсковым отделениям, несшим службу по месяцу в течение года. В каждом отделении было 24 000 воинов.
2Во главе первого отделения для первого месяца стоял Иашовеам, сын Завдиила. В его отделении было 24 000 воинов. 3Он был потомком Пареца и главой всех военачальников в первый месяц.
4Во главе отделения для второго месяца стоял ахохитянин Додай, его главным воеводой был Миклот. В его отделении было 24 000 воинов.
5Третьим военачальником для третьего месяца был Беная, сын священника Иодая. Он был вождем, и в его отделении было 24 000 воинов. 6Это тот Беная, который был могучим воином среди тех тридцати и начальником над ними. Его сын Аммизавад стоял над его отделением.
7Четвертым для четвертого месяца был Асаил, брат Иоава; его сын Зевадия был его преемником. В его отделении было 24 000 воинов.
8Пятым для пятого месяца был военачальник Шамгут27:8 Вариант имени Шамма (см. 11:27 и 2 Цар. 23:25). израхитянин. В его отделении было 24 000 воинов.
9Шестым для шестого месяца был Ира, сын текоитянина Иккеша. В его отделении было 24 000 воинов.
10Седьмым для седьмого месяца был пелонитянин Хелец из потомков Ефрема. В его отделении было 24 000 воинов.
11Восьмым для восьмого месяца был хушатянин Сивхай, потомок Зераха. В его отделении было 24 000 воинов.
12Девятым для девятого месяца был анатотянин Авиезер из потомков Вениамина. В его отделении было 24 000 воинов.
13Десятым для десятого месяца был нетофитянин Магарай, потомок Зераха. В его отделении было 24 000 воинов.
14Одиннадцатым для одиннадцатого месяца был пирафонянин Беная из потомков Ефрема. В его отделении было 24 000 воинов.
15Двенадцатым для двенадцатого месяца был нетофитянин Хелдай, потомок Отниила. В его отделении было 24 000 воинов.
Вожди израильских родов
16Вождями родов Израиля были:
у Рувима: Элиезер, сын Зихрия;
у Симеона: Шефатия, сын Маахи;
17у Левия: Хашавия, сын Кемуила;
у Аарона: Цадок;
18у Иуды: Элигу, брат Давида;
у Иссахара: Омри, сын Михаила;
19у Завулона: Ишмая, сын Авдия;
у Неффалима: Иеримот, сын Азриила;
20у Ефрема: Осия, сын Азазии;
у половины рода Манассии: Иоиль, сын Педаи;
21у половины рода Манассии в Галааде: Иддо, сын Захарии;
у Вениамина: Иаасиил, сын Авнера;
22у Дана: Азариил, сын Иерохама.
Это вожди родов Израиля.
23Давид не считал тех, кому было двадцать лет или меньше, потому что Господь обещал сделать Израиль многочисленным, как звезды на небе. 24Иоав, сын Саруи, начал пересчитывать народ, но не закончил: гнев за эту перепись постиг Израиль, и ее результат не был вписан в «Летопись царя Давида».
Царские сановники
25Азмавету, сыну Адиила, было поручено смотреть за царскими кладовыми.
Ионафану, сыну Уззии, за кладовыми в провинции: в городах, поселениях и сторожевых башнях.
26Езрию, сыну Хелува, за работниками на поле, которые возделывали землю.
27Раматитянину Шимею — за виноградниками.
Шифмитянину Завдию — за запасами вина в винных погребах.
28Гедеритянину Баал-Ханану — за оливковыми деревьями и сикоморами в западных предгорьях.
Иоашу — за запасами оливкового масла.
29Шаронитянину Шитраю — за крупным скотом, пасущимся в районе Шарон, а Шафату, сыну Адлая, за крупным скотом в долинах.
30Измаильтянину Овилу — за верблюдами.
Меронофянину Иехдии — за ослицами.
31Агарянину Иазизу — за мелким скотом.
Это сановники, которым было поручено смотреть за добром царя Давида.
Советники Давида
32Ионафан, дядя Давида, проницательный человек и писарь, был советником.
Иехиил, сын Хахмония, воспитывал царских сыновей.
33Ахитофел был царским советником.
Аркитянин Хусий был другом царя.
34Преемниками Ахитофела были Иодай, сын Бенаи, и Авиатар.
Иоав стоял во главе царского войска.