1 Kronika 27 – YCB & BDS

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Kronika 27:1-34

Ìpín ti àwọn ọmọ-ogun

1Wọ̀nyí ni ìwé àkójọ orúkọ àwọn ọmọ Israẹli, àwọn olórí àwọn ìdílé, àwọn balógun ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún àti àwọn ìjòyè wọn. Tí ó n sin ọba nínú gbogbo ohun tí ó kan ìpín àwọn ọmọ-ogun tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ní oṣooṣù ní gbogbo ọdún. Ìpín kọ̀ọ̀kan jẹ́ ẹgbàá méjìlá (24,000) ọkùnrin.

2Ní ti alákòóso lórí ìpín kìn-ín-ní fún oṣù kìn-ín-ní jẹ́ Jaṣobeamu ọmọ Sabdieli àwọn ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ní ó wà ní abẹ́ ìpín tirẹ̀. 3Ó jẹ́ ìran ọmọ Peresi àti olóyè fún gbogbo àwọn ìjòyè ológun fún oṣù kìn-ín-ní.

4Alákòóso fún ìpín àwọn ọmọ-ogun fún oṣù kejì jẹ́ Dodai ará Ahohi; Mikloti jẹ́ olórí ìpín tirẹ̀. Ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín tirẹ̀.

5Olórí àwọn ọmọ-ogun ẹlẹ́ẹ̀kẹta fún oṣù kẹta jẹ́ Benaiah ọmọ Jehoiada àlùfáà. Ó jẹ́ olóyè, àwọn ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ní ó wà ní ìpín tirẹ̀. 6Èyí ni Benaiah náà tí ó jẹ́ ọkùnrin ńlá láàrín àwọn ọgbọ̀n àti lórí àwọn ọgbọ̀n. Ọmọ rẹ̀ Amisabadi jẹ́ alákòóso lórí ìpín tirẹ̀.

7Ẹlẹ́ẹ̀kẹrin fún oṣù kẹrin, jẹ́ Asaheli arákùnrin Joabu: ọmọ rẹ̀ Sebadiah jẹ́ arọ́pò rẹ̀. Ẹgbàá méjìlá (24,000) ọkùnrin ni ó wà ní ìpín rẹ̀.

8Ẹ̀karùnún fún oṣù karùn-ún, jẹ́ olórí Ṣamhuti ará Israhi. Ẹgbàá méjìlá (24,000) ọkùnrin ní ó wà ní ìpín tirẹ̀.

9Ẹ̀kẹfà fún oṣù kẹfà jẹ́ Ira ọmọ Ikẹsi, ará Tekoi. Ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín rẹ̀.

10Èkeje fún oṣù keje jẹ́ Helesi ará Peloni, ará Efraimu. Ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni o wà ní ìpín rẹ̀.

11Ẹ̀kẹjọ fún oṣù kẹjọ jẹ́ Sibekai ará Huṣati, ará Sera ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín rẹ̀.

12Ẹ̀kẹsànán fún oṣù kẹsànán jẹ́. Abieseri ará Anatoti, ará Benjamini ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín rẹ̀.

13Ẹ̀kẹwàá fún oṣù kẹwàá jẹ́ Maharai ará Netofa, ará Sera ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín rẹ̀.

14Ìkọkànlá fún oṣù kọkànlá jẹ́ Benaiah ará Piratoni ará Efraimu ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín tirẹ̀.

15Èkejìlá fún oṣù kejìlá jẹ́ Heldai ará Netofa láti ìdílé Otnieli. Ẹgbàá méjìlá (24,000) ọkùnrin ni ó wà ní ìpín tirẹ̀.

Àwọn ìjòyè ti ẹ̀yà náà

16Àwọn ìjòyè lórí àwọn ẹ̀yà tí Israẹli:

lórí àwọn ará Reubeni: Elieseri ọmọ Sikri;

lórí àwọn ọmọ Simeoni: Ṣefatia ọmọ Maaka;

17lórí Lefi: Haṣabiah ọmọ Kemueli;

lórí Aaroni: Sadoku;

18lórí Juda: Elihu arákùnrin Dafidi;

lórí Isakari: Omri ọmọ Mikaeli;

19lórí Sebuluni: Iṣmaiah ọmọ Obadiah;

lórí Naftali: Jerimoti ọmọ Asrieli;

20lórí àwọn ará Efraimu: Hosea ọmọ Asasiah;

lórí ààbọ̀ ẹ̀yà Manase: Joẹli ọmọ Pedaiah;

21lórí ààbọ̀ ẹ̀yà Manase ní Gileadi: Iddo ọmọ Sekariah;

lórí Benjamini: Jaasieli ọmọ Abneri;

22lórí Dani: Asareeli ọmọ Jerohamu.

Wọ̀nyí ni àwọn ìjòyè lórí ẹ̀yà Israẹli.

23Dafidi kò kọ iye àwọn ọkùnrin náà ní ogún ọdún sẹ́yìn tàbí dín nítorí Olúwa ti ṣe ìlérí láti ṣe Israẹli gẹ́gẹ́ bí iye ìràwọ̀ ojú ọ̀run. 24Joabu ọmọ Seruiah bẹ̀rẹ̀ sí ní kà wọ́n, ṣùgbọ́n kò parí kíkà wọ́n nítorí, ìbínú dé sórí àwọn Israẹli nípasẹ̀ kíka iye àti iye náà, a kò kọ ọ́ sínú ìwé ìtàn ayé ti ọba Dafidi.

Àwọn alábojútó ọba

25Asmafeti ọmọ Adieli wà ní ìdí ilé ìṣúra ti ọba.

Jonatani ọmọ Ussiah wà ní ìdí ilé ìṣúra ní iwájú agbègbè nínú àwọn ìlú, àwọn ìletò àti àwọn ilé ìṣọ́.

26Esri ọmọ Kelubu wà ní ìdí àwọn òṣìṣẹ́ lórí pápá, tí wọ́n ń ko ilẹ̀ náà.

27Ṣimei ará Ramoti wà ní ìdí àwọn ọgbà àjàrà.

Sabdi ará Sifmi wà ní ìdí mímú jáde ti èso àjàrà fún ọpọ́n ńlá tí a ń fi ọ̀tún èso àjàrà sí.

28Baali-Hanani ará Gederi wà ní ìdí olifi àti àwọn igi sikamore ní apá ìhà ìwọ̀-oòrùn àwọn ní ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀.

Joaṣi wà ní ìdí fífún ni ní òróró olifi.

29Ṣitrai ará Ṣaroni wà ní ìdí fífi ọwọ́ ẹran jẹ oko ní Ṣaroni.

Ṣafati ọmọ Adlai wà ní ìdí àwọn ọ̀wọ́ ẹran ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀.

30Obili ará Iṣmaeli wà ní ìdí àwọn ìbákasẹ.

Jehdeiah ará Meronoti wà ní ìdí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

31Jasisi ará Hagari wà ní ìdí àwọn agbo ẹran.

Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn oníṣẹ́ tí wọ́n wà ní ìdí ẹrù ọba Dafidi.

32Jonatani, arákùnrin Dafidi jẹ́ olùdámọ̀ràn, ọkùnrin onímọ̀ àti akọ̀wé.

Jehieli ọmọ Hakmoni bojútó àwọn ọmọ ọba.

33Ahitofeli jẹ́ olùdámọ̀ràn ọba.

Huṣai ará Arki jẹ́ ọ̀rẹ́ ọba.

34(Jehoiada ọmọ Benaiah àti nípasẹ̀ Abiatari jẹ ọba rọ́pò Ahitofeli.)

Joabu jẹ́ olórí ọmọ-ogun ọba.

La Bible du Semeur

1 Chroniques 27:1-34

L’organisation de l’armée

1Voici la liste des Israélites, chefs de groupe familial qui furent les commandants des « milliers » ou des « centaines » et les administrateurs qui assistaient le roi pour tout ce qui concernait les divisions militaires appelées tour à tour à prendre mensuellement leur service. Chaque division comptait 24 000 hommes27.1 Comme dans de nombreux autres textes, il pourrait s’agir de vingt-quatre « milliers » d’hommes. Un « millier » était peut-être un corps d’armée comprenant quelques centaines d’hommes..

2A la tête de la première division affectée au premier mois27.2 Mois de la Pâque (Ex 12.2 ; Esd 6.19). se trouvait Yashobeam, fils de Zabdiel. Sa division comptait 24 000 hommes. 3Il était de la lignée de Pérets et commandait tous les chefs d’armée du premier mois. 4A la tête de la division du second mois comprenant également 24 000 hommes se trouvait Dodaï l’Ahohite. Miqloth était le chef de sa division. 5Le commandant de la troisième armée pour le troisième mois était Benaya, fils du grand-prêtre Yehoyada. Il avait dans sa division 24 000 hommes. 6Ce Benaya était l’un des guerriers du groupe des trente, il était à sa tête. Son fils Ammizadab avait sa division sous ses ordres. 7Le quatrième commandant affecté au quatrième mois était Asaël, frère de Joab. Son fils Zebadia lui succéda. Sa division comprenait 24 000 hommes. 8Le cinquième, pour le cinquième mois, était le commandant Shamehouth de la famille d’Yizrah. Sa division comptait 24 000 hommes. 9Pour le sixième mois : Ira fils d’Iqqesh, le Teqoïte. Sa division comptait 24 000 hommes. 10Le septième, pour le septième mois : Hélets le Pelonite, des descendants d’Ephraïm. Sa division comptait 24 000 hommes. 11Le huitième, pour le huitième mois : Sibbekaï, le Houshatite, de la famille des Zérahites. Sa division comptait 24 000 hommes. 12Le neuvième, pour le neuvième mois : Abiézer, d’Anatoth, des Benjaminites. Sa division comptait 24 000 hommes. 13Le dixième, pour le dixième mois : Maharaï, de Netopha, de la famille des Zérahites. Sa division comptait 24 000 hommes. 14Le onzième, pour le onzième mois : Benaya, de Piratôn, des Ephraïmites. Sa division comptait 24 000 hommes. 15Le douzième, pour le douzième mois : Heldaï, de Netopha, descendant d’Otniel. Sa division comptait 24 000 hommes.

Les chefs des tribus

16Voici les chefs des tribus d’Israël : les Rubénites avaient comme chef Eliézer, fils de Zikri ; les Siméonites : Shephatia, fils de Maaka. 17Pour Lévi, c’était Hashabia, fils de Qemouel ; pour Aaron, Tsadoq ; 18pour Juda : Elihou, frère de David ; pour Issacar : Omri, fils de Michaël ; 19pour Zabulon : Yishmaya, fils d’Abdias ; pour Nephtali : Yerimoth, fils d’Azriel ; 20pour les descendants d’Ephraïm : Osée, fils d’Azazia ; pour la demi-tribu de Manassé : Joël, fils de Pedaya ; 21pour la demi-tribu de Manassé en Galaad : Yiddo, fils de Zacharie ; pour Benjamin : Yaasiel, fils d’Abner ; 22pour Dan : Azaréel, fils de Yeroham. Ce sont là les chefs des tribus d’Israël.

23David ne comptait pas dans le dénombrement les moins de vingt ans, car l’Eternel avait promis de rendre Israël aussi nombreux que les étoiles du ciel27.23 Voir Gn 15.5 ; 22.17 ; 26.4.. 24Joab, fils de Tserouya, avait commencé le recensement ; mais il ne l’acheva pas. D’ailleurs, à cause de ce recensement, l’Eternel se mit en colère contre Israël. C’est pourquoi les chiffres de ce recensement n’ont pas été reportés dans les Annales du roi David27.24 Voir 1 Ch 21..

Les administrateurs des biens du roi

25Le responsable des trésors du roi était Azmaveth, fils d’Adiel. Le responsable des trésors entreposés à la campagne, dans les villes, les villages, et les tours, était Jonathan, fils d’Ozias. 26Le responsable des ouvriers agricoles qui cultivaient la terre était Ezri, fils de Keloub. 27Le responsable des vignobles était Shimeï, de Rama ; celui des réserves de vin dans les vignes était Zabdi, de Shepham. 28Le responsable des plantations d’oliviers et de sycomores du Bas-Pays27.28 C’est-à-dire la plaine côtière du littoral méditerranéen, célèbre pour sa fertilité. Les sycomores ne doivent pas être confondus avec les arbres portant ce nom dans nos régions : ce sont des figuiers aux feuilles semblables à celle du mûrier qui croissent en abondance de l’Egypte à la Syrie (voir Lc 19.4). était Baal-Hanân, de Guéder ; celui des réserves d’huile était Joas. 29Le responsable des troupeaux de bétail qui avaient leur pâture dans la plaine du Saron27.29 Partie nord de la plaine côtière qui s’étend de Jaffa au pied du mont Carmel. était Shitraï, de Saron ; celui du bétail qui se trouvait dans les vallées était Shaphath, fils d’Adlaï. 30Le responsable des chameaux était Obil, l’Ismaélite27.30 Donc un descendant d’Ismaël (voir Gn 16.11-12 ; 25.12-18). ; celui des ânesses était Yéhdeya, de Méronoth. 31Le responsable des troupeaux de moutons et de chèvres était Yaziz, l’Agarénien. Tous ceux-là étaient les intendants des biens du roi David.

Les conseillers privés de David

32Jonathan, oncle de David, et son conseiller, un homme intelligent, qui était secrétaire, avait la charge, avec Yehiel, fils de Hakmoni, de l’éducation des fils du roi. 33Ahitophel était conseiller du roi. Houshaï, l’Arkien, était son confident. 34Après Ahitophel, il y eut Yehoyada, fils de Benaya, et Abiatar. Joab était chef des armées du roi.