1 Kronika 26 – YCB & NSP

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Kronika 26:1-32

Àwọn olùtọ́jú ẹnu ọnà

1Àwọn ìpín tí àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà.

Láti ìran Kora:

Meṣelemiah ọmọ Kore, ọ̀kan lára àwọn ọmọ Asafu. 2Meṣelemiah ní àwọn ọmọkùnrin:

Sekariah àkọ́bí, Jediaeli ẹlẹ́ẹ̀kejì,

Sebadiah ẹlẹ́ẹ̀kẹta, Jatnieli ẹlẹ́ẹ̀kẹrin,

3Elamu ẹlẹ́ẹ̀karùnún, Jehohanani ẹlẹ́ẹ̀kẹfà

àti Elihoenai ẹlẹ́ẹ̀keje.

4Obedi-Edomu ni àwọn ọmọkùnrin pẹ̀lú:

Ṣemaiah àkọ́bí, Jehosabadi ẹlẹ́ẹ̀kejì,

Joah ẹlẹ́ẹ̀kẹta, Sakari ẹlẹ́ẹ̀kẹrin,

Netaneli ẹlẹ́ẹ̀karùnún, 5Ammieli ẹ̀kẹfà,

Isakari èkeje àti Peulltai ẹ̀kẹjọ.

(Nítorí tí Ọlọ́run ti bùkún Obedi-Edomu).

6Ọmọ rẹ̀ Ṣemaiah ní àwọn ọmọkùnrin pẹ̀lú tí wọ́n jẹ́ olórí ní ìdílé baba a wọn nítorí wọ́n jẹ́ ọkùnrin tó lágbára. 7Àwọn ọmọ Ṣemaiah:

Otni, Refaeli, Obedi àti Elsabadi;

àwọn ìbátan rẹ̀ Elihu àti Samakiah jẹ́ ọkùnrin alágbára.

8Gbogbo wọ̀nyí ní ìran ọmọ Obedi-Edomu; àwọn àti ọmọkùnrin àti ìbátan wọn jẹ́ alágbára ọkùnrin pẹ̀lú ipá láti ṣe ìsìn náà. Ìran Obedi-Edomu méjìlélọ́gọ́ta ni gbogbo rẹ̀.

9Meṣelemiah ní àwọn ọmọ àti àwọn ìbátan, tí ó jẹ́ alágbára méjìdínlógún ni gbogbo wọn.

10Hosa ará Merari ní àwọn ọmọkùnrin:

Ṣimri alákọ́kọ́ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé kì i ṣe àkọ́bí, baba a rẹ̀ ti yàn an ní àkọ́kọ́.

11Hilkiah ẹlẹ́ẹ̀kejì, Tabaliah ẹ̀kẹta

àti Sekariah ẹ̀kẹrin.

Àwọn ọmọ àti ìbátan Hosa jẹ́ mẹ́tàlá ni gbogbo rẹ̀.

12Ìpín wọ̀nyí ti àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà nípasẹ̀ olóyè ọkùnrin wọn, ní iṣẹ́ ìsìn fún jíjíṣẹ́ nínú ilé Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìbátan wọn ti ṣe. 13Wọ́n ṣẹ́ kèké fún ẹnu-ọ̀nà kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àwọn ìdílé wọn bí ọ̀dọ́ àti arúgbó.

14Kèké fún ẹnu-ọ̀nà ilà oòrùn bọ́ sí ọ̀dọ̀ Ṣelemiah.

Nígbà náà a dá kèké fún ọmọkùnrin rẹ̀ Sekariah, ọlọ́gbọ́n onímọ̀ràn, kèké fún ẹnu-ọ̀nà àríwá sì bọ́ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.

15Kèké fún ẹnu-ọ̀nà ìhà gúúsù bọ́ sí ọ̀dọ̀ Obedi-Edomu, kèké fún ilé ìṣúra sì bọ́ sí ọ̀dọ̀ ọmọ rẹ̀.

16Kèké fún ẹnu-ọ̀nà ìhà ìwọ̀-oòrùn àti Ṣaleketi ẹnu-ọ̀nà ní ọ̀nà apá òkè bọ́ sí ọ̀dọ̀ Ṣuppimu àti Hosa.

Olùṣọ́ wà ní ẹ̀bá olùṣọ́.

17Àwọn ará Lefi mẹ́fà ní ó wà ní ọjọ́ kan ní ìhà ìlà-oòrùn,

mẹ́rin ní ọjọ́ kan ní ìhà àríwá,

mẹ́rin ní ọjọ́ kan ní ìhà gúúsù

àti méjì ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ní ilé ìṣúra.

18Ní ti ilé ẹjọ́ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn, mẹ́rin sì wà ní ojú ọ̀nà àti méjì ní ilé ẹjọ́ fúnra rẹ̀.

19Wọ̀nyí ni ìpín ti àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà tí wọ́n jẹ́ àwọn ìran ọmọ Kora àti Merari.

Àwọn afowópamọ́ àti àwọn òṣìṣẹ́ ìyókù

20Láti inú àwọn ọmọ Lefi, Ahijah ni ó wà lórí ìṣúra ti ilé Ọlọ́run àti lórí ìṣúra nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí a yà sí mímọ́.

21Àwọn ìran ọmọ Laadani tí wọn jẹ́ ará Gerṣoni nípasẹ̀ Laadani àti tí wọn jẹ́ àwọn olórí àwọn ìdílé tí ó jẹ́ ti Laadani ará Gerṣoni ni Jehieli. 22Àwọn ọmọ Jehieli, Setamu àti arákùnrin rẹ̀ Joẹli. Wọ́n ṣalábojútó ilé ìṣúra ti ilé ìṣúra ti ilé Olúwa.

23Láti ọ̀dọ̀ àwọn ará Amramu, àwọn ará Isari, àwọn ará Hebroni àti àwọn ará Usieli.

24Ṣubaeli, ìran ọmọ Gerṣomu ọmọ Mose jẹ́ olórí tí ó bojútó ilé ìṣúra. 25Àwọn ìbátan rẹ̀ nípasẹ̀ Elieseri: Rehabiah ọmọ rẹ̀, Jeṣaiah ọmọ rẹ̀, Joramu ọmọ rẹ̀, Sikri ọmọ rẹ̀, Ṣelomiti ọmọ rẹ̀.

26Ṣelomiti àti àwọn ìbátan rẹ̀ jẹ́ alábojútó ilé ìṣúra fún àwọn ohun tí à ti yà sọ́tọ̀ nípa ọba Dafidi, nípasẹ̀ àwọn olórí àwọn ìdílé tí wọ́n jẹ́ alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún àti nípasẹ̀ alákòóso ọmọ-ogun mìíràn. 27Díẹ̀ nínú ìkógun tí wọ́n kó nínú ogun ni wọ́n yà sọ́tọ̀ fún títún ilé Olúwa ṣe. 28Pẹ̀lú gbogbo nǹkan tí a yà sọ́tọ̀ láti ọ̀dọ̀ Samuẹli aríran láti nípasẹ̀ Saulu ọmọ Kiṣi, Abneri ọmọ Neri àti Joabu ọmọ Seruiah gbogbo ohun tí a yà sọ́tọ̀ sì wà ní abẹ́ ìtọ́jú Ṣelomiti àti àwọn ìbátan rẹ̀.

29Láti ọ̀dọ̀ àwọn Isari:

Kenaniah àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni a pín iṣẹ́ ìsìn fún kúrò ní apá ilé Olúwa, gẹ́gẹ́ bí àwọn oníṣẹ́ àti àwọn adájọ́ lórí Israẹli.

30Láti ọ̀dọ̀ àwọn Hebroni:

Haṣabiah àti àwọn ìbátan rẹ̀ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán (17,000) ọkùnrin alágbára ní ó dúró ni Israẹli, ìhà ìwọ̀-oòrùn Jordani fún gbogbo iṣẹ́ Olúwa àti fún iṣẹ́ ọba. 31Ní ti àwọn ará Hebroni, Jeriah jẹ́ olóyè wọn gẹ́gẹ́ bí ìwé ìrántí ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, ní ti ìdílé wọn.

Ní ọdún kẹrin ìjọba Dafidi, a ṣe ìwádìí nínú ìwé ìrántí, àwọn ọkùnrin alágbára láàrín àwọn ará Hebroni ni a rí ní Jaseri ní Gileadi. 32Jeriah ní ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (2,700) ìbátan, tí wọn jẹ́ ọkùnrin alágbára àti olórí àwọn ìdílé ọba Dafidi sì fi wọ́n ṣe àkóso lórí àwọn ará Reubeni àwọn ará Gadi àti ààbọ̀ ẹ̀yà ti Manase fún gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó jọ mọ́ ti Ọlọ́run àti fún ọ̀ràn ti ọba.

New Serbian Translation

1. Књига дневника 26:1-32

Вратари

1А ово су били вратарски редови: Корејеви синови:

Корејев син Меселемија од Асафових синова.

2Меселемијини синови: Захарија првенац, Једиаило други, Зевадија трећи, Јатнило четврти, 3Елам пети, Јоанан шести, и Елиоинај седми.

4Овид-Едомови синови: Семаја првенац, Јозавад други, Јоах трећи, Сакар четврти, Натанаило пети, 5Амило шести, Исахар седми, Феултај осми; јер га је благословио Бог.

6Његовом сину Семаји су се родили синови, који су имали управу над својим отачким домовима, јер су били људи од угледа. 7Семајини синови: Готније, Рафаило, Овид, Елзавад и његова браћа, врсни људи, Елијуј и Семахија. 8Сви ови од Овид-Едомових синова, и они и њихови синови и њихова браћа, били су врсни људи, способни за службу. Било их је шездесет два од Овид-Едома.

9Меселемијиних синова и браће, храбрих људи, било је осамнаест.

10Од Мераријевих потомака: Осини синови: главар Симрије; иако није био првенац, отац га је поставио за главара, 11Хелкија други, Тевалија трећи и Захарија четврти. Свих Осиних синова и браће било је тринаест.

12Ово су редови вратара по њиховим главарима. Њихове дужности су биле да служе у Дому Господњем уз своју браћу. 13Бацали су жреб, како млади тако стари, по својим отачким домовима за свака врата.

14Жреб на исток је пао Селемији. Кад су бацили жреб за његовог сина Захарију, мудрог саветника, жреб је пао на север, 15Овид-Едому на југ, а његовим синовима код складишта. 16Суфејцима и Оси на западу код Салехетских врата, на путу који иде горе; стража је била до страже.

17С истока шест Левита, са севера четири на дан, с југа четири на дан, а код складишта по два. 18На трему, са запада, четири на путу и два код трема.

19То су вратарски редови међу Корејевим и Мераријевим синовима.

Ризничари и остали званичници

20Од Левита, Ахија је био над ризницама Дома Божијег и над ризницама посвећених ствари.

21Ладанови синови, Гирсонови потомци, који су били Ладанови, главари Ладанових отачких домова: Јехило. 22Јехилови синови: Зетам и његов брат Јоило, који су били над ризницама Дома Господњег.

23Од Амрамових, Исарових, Хевронових и Озилових синова, били су:

24Суваило, син Мојсијевог сина Гирсама, старешина над ризницама. 25Његова браћа по Елиезеру: његов син Реавија, његов син Јесаија, његов син Јорам, његов син Зихрије, и његов син Селомит. 26Овај Селомит и његова браћа су били над свим ризницама посвећених ствари, које је посветио цар Давид, главари отачких домова и заповедници над хиљаду и стотину, и војводе. 27Део плена од ратова су посветили да се поправи Дом Господњи. 28И што год је посветио виделац Самуило, Кисов син Саул, Неров син Авенир, и Серујин син Јоав, све посвећено, било је у надлештву Селомита и његове браће.

29Од Исарових синова: Хенанија и његови синови. Они су били надлежни за световне послове у Израиљу, као управитељи и судије.

30Од Хевронових синова: Асавија и његова браћа, хиљаду седам стотина способних људи. Они су били надлежни за Израиљ западно од Јордана за сваки посао Господњи и за царску службу. 31Међу Хевроновим синовима, Јерија је био главар Хевронових синова. Четрдесете године Давидовог царевања тражили су по њиховим родословљима, по њиховим породицама и отачким домовима, и нашли међу њима веома способне људе у Јазиру галадском. 32Његове браће, способних људи, било је две хиљаде седам стотина породичних главара. Цар Давид их је поставио над Рувимовим и Гадовим синовима и над половином Манасијиног племена за све Божије и царске послове.