1 Kronika 24 – YCB & NIV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Kronika 24:1-31

Pínpín àwọn àlùfáà

1Àwọn wọ̀nyí sì ni pínpín àwọn ọmọ Aaroni.

Àwọn ọmọ Aaroni ni Nadabu, Abihu, Eleasari àti Itamari. 2Ṣùgbọ́n Nadabu àti Abihu kú kí ó tó di wí pé baba wọn kú, wọn kò sì ní àwọn ọmọ; bẹ́ẹ̀ ni Eleasari àti Itamari sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àlùfáà. 3Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Sadoku ọmọ Eleasari àti Ahimeleki ọmọ Itamari, Dafidi sì yà wọ́n nípa nínú ìpín fún ìyàsọ́tọ̀ àwọn iṣẹ́ ìsìn wọn. 4A rí ọ̀pọ̀ àwọn olórí lára àwọn ọmọ Eleasari ju lára àwọn ọmọ Itamari lọ, wọ́n sì pín wọn lẹ́sẹ lẹ́sẹ: mẹ́rìndínlógún olórí láti ìdílé ọmọ Eleasari ìran wọn àti olórí méjọ ìdílé láti ara àwọn ọmọ Itamari. 5Wọ́n sì pín wọn láìṣègbè nípa yíya ìpín, nítorí àwọn olórí ibi mímọ́ àti àwọn olórí ilé Ọlọ́run wà láàrín àwọn ọmọ méjèèjì Eleasari àti Itamari.

6Ṣemaiah ọmọ Netaneli, akọ̀wé ọ̀kan lára àwọn ọmọ Lefi sì kọ orúkọ wọn níwájú ọba àti àwọn ìjòyè: Sadoku àlùfáà, Ahimeleki ọmọ Abiatari àti olórí ìdílé àwọn àlùfáà tí a mú láti ọ̀dọ̀ Eleasari àti ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ Itamari.

7Ìpín èkínní jáde sí Jehoiaribu,

èkejì sí Jedaiah,

8ẹlẹ́ẹ̀kẹta sì ni Harimu,

ẹ̀kẹrin sì ní Seorimu,

9ẹ̀karùnún sì ni Malkiah,

ẹlẹ́ẹ̀kẹfà sì ni Mijamini,

10èkeje sì ni Hakosi,

ẹlẹ́ẹ̀kẹjọ sí ni Abijah,

11ẹ̀kẹsànán sì ni Jeṣua,

ẹ̀kẹwàá sì ni Ṣekaniah,

12ẹ̀kọkànlá sì ni Eliaṣibu,

ẹlẹ́ẹ̀kẹjìlá sì ni Jakimu,

13ẹ̀kẹtàlá sì ni Hupa,

ẹlẹ́ẹ̀kẹrìnlá sì ni Jeṣebeabu,

14ẹ̀kẹdógún sì ni Bilgah,

ẹ̀kẹrìndínlógún sì ni Immeri,

15ẹ̀kẹtàdínlógún sì ni Hesiri,

èkejìdínlógún sì ni Hafisesi,

16ẹ̀kọkàndínlógún sì ni Petahiah,

ogún sì ni Jeheskeli,

17ẹ̀kọkànlélógún sì ni Jakini,

ẹ̀kẹrìnlélógún sì ni Gamuli,

18ẹ̀kẹtàlélógún sì ni Delaiah,

ẹ̀kẹrìnlélógún sì ni Maasiah.

19Àwọn wọ̀nyí ni a yàn fún iṣẹ́ ìsìn nígbà tí wọ́n wọ ilé Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìlànà àti àṣẹ tí a ti fi fún wọn láti ọwọ́ baba ńlá wọn Aaroni gẹ́gẹ́ bí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, tí pàṣẹ fun un.

Ìyókù nínú àwọn ọmọ Lefi

20Ìyókù àwọn ọmọ Lefi.

Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Amramu: Ṣubaeli

láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ṣubaeli; Jehdeiah.

21Àti gẹ́gẹ́ bí Rehabiah, láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Rehabiah, Iṣiah sì ni alákọ́kọ́.

22Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Isari: Ṣelomiti;

láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ṣelomoti: Jahati.

23Àwọn ọmọ Hebroni:

Jeriah alákọ́kọ́, Amariah ẹlẹ́ẹ̀kejì, Jahasieli ẹlẹ́ẹ̀kẹta àti Jekameamu ẹlẹ́ẹ̀kẹrin.

24Àwọn ọmọ Usieli: Mika;

nínú àwọn ọmọ Mika: Ṣamiri.

25Àwọn arákùnrin Mika: Iṣi;

nínú àwọn ọmọ Iṣiah: Sekariah.

26Àwọn ọmọ Merari: Mahili àti Muṣi.

Àwọn ọmọ Jaasiah: Beno.

27Àwọn ọmọ Merari.

Láti Jaasiah: Beno, Ṣohamu, Sakkuri àti Ibri.

28Láti Mahili: Eleasari, ẹni tí kò ni àwọn ọmọ.

29Láti Kiṣi. Àwọn ọmọ Kiṣi: Jerahmeeli.

30Àti àwọn ọmọ Muṣi: Mahili, Ederi àti Jerimoti.

Èyí ni àwọn ọmọ Lefi, gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.

31Wọ́n sì ṣé kèké gẹ́gẹ́ bí àwọn arákùnrin wọn àwọn ọmọ Aaroni ṣe ṣẹ́, níwájú ọba Dafidi àti Sadoku, Ahimeleki, àti olórí ìdílé àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi. Àwọn ìdílé àgbàgbà arákùnrin wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ lórí àwọn arákùnrin wọn kéékèèké.

New International Version

1 Chronicles 24:1-31

The Divisions of Priests

1These were the divisions of the descendants of Aaron:

The sons of Aaron were Nadab, Abihu, Eleazar and Ithamar. 2But Nadab and Abihu died before their father did, and they had no sons; so Eleazar and Ithamar served as the priests. 3With the help of Zadok a descendant of Eleazar and Ahimelek a descendant of Ithamar, David separated them into divisions for their appointed order of ministering. 4A larger number of leaders were found among Eleazar’s descendants than among Ithamar’s, and they were divided accordingly: sixteen heads of families from Eleazar’s descendants and eight heads of families from Ithamar’s descendants. 5They divided them impartially by casting lots, for there were officials of the sanctuary and officials of God among the descendants of both Eleazar and Ithamar.

6The scribe Shemaiah son of Nethanel, a Levite, recorded their names in the presence of the king and of the officials: Zadok the priest, Ahimelek son of Abiathar and the heads of families of the priests and of the Levites—one family being taken from Eleazar and then one from Ithamar.

7The first lot fell to Jehoiarib,

the second to Jedaiah,

8the third to Harim,

the fourth to Seorim,

9the fifth to Malkijah,

the sixth to Mijamin,

10the seventh to Hakkoz,

the eighth to Abijah,

11the ninth to Jeshua,

the tenth to Shekaniah,

12the eleventh to Eliashib,

the twelfth to Jakim,

13the thirteenth to Huppah,

the fourteenth to Jeshebeab,

14the fifteenth to Bilgah,

the sixteenth to Immer,

15the seventeenth to Hezir,

the eighteenth to Happizzez,

16the nineteenth to Pethahiah,

the twentieth to Jehezkel,

17the twenty-first to Jakin,

the twenty-second to Gamul,

18the twenty-third to Delaiah

and the twenty-fourth to Maaziah.

19This was their appointed order of ministering when they entered the temple of the Lord, according to the regulations prescribed for them by their ancestor Aaron, as the Lord, the God of Israel, had commanded him.

The Rest of the Levites

20As for the rest of the descendants of Levi:

from the sons of Amram: Shubael;

from the sons of Shubael: Jehdeiah.

21As for Rehabiah, from his sons:

Ishiah was the first.

22From the Izharites: Shelomoth;

from the sons of Shelomoth: Jahath.

23The sons of Hebron: Jeriah the first,24:23 Two Hebrew manuscripts and some Septuagint manuscripts (see also 23:19); most Hebrew manuscripts The sons of Jeriah: Amariah the second, Jahaziel the third and Jekameam the fourth.

24The son of Uzziel: Micah;

from the sons of Micah: Shamir.

25The brother of Micah: Ishiah;

from the sons of Ishiah: Zechariah.

26The sons of Merari: Mahli and Mushi.

The son of Jaaziah: Beno.

27The sons of Merari:

from Jaaziah: Beno, Shoham, Zakkur and Ibri.

28From Mahli: Eleazar, who had no sons.

29From Kish: the son of Kish:

Jerahmeel.

30And the sons of Mushi: Mahli, Eder and Jerimoth.

These were the Levites, according to their families. 31They also cast lots, just as their relatives the descendants of Aaron did, in the presence of King David and of Zadok, Ahimelek, and the heads of families of the priests and of the Levites. The families of the oldest brother were treated the same as those of the youngest.