1 Kronika 18 – YCB & CCBT

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Kronika 18:1-17

Àwọn ìṣẹ́gun Dafidi

118.1-13: 2Sa 8.1-14.Ní àkókò kan, Dafidi kọlu àwọn ará Filistini, ó sì ṣẹ́gun wọn. Ó sì mú Gati àti àwọn ìletò agbègbè rẹ̀ kúrò lábẹ́ ìdarí àwọn ará Filistini.

2Dafidi borí àwọn ará Moabu, wọ́n sì di ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n sì mú owó òde wá.

3Síbẹ̀, Dafidi sì kọlu Hadadeseri ọba Soba ní Hamati, bí ó ti ń lọ láti fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ létí odò Eufurate. 4Dafidi fi agbára gba ẹgbẹ̀rún (1,000) kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) agun-kẹ̀kẹ́ àti ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) ológun ilẹ̀. Ó sì já gbogbo ọgọ́rùn-ún iṣan ẹsẹ̀ àwọn kẹ̀kẹ́-ẹṣin náà.

5Nígbà ti àwọn ará Siria ti Damasku wá láti ran Hadadeseri ọba Soba lọ́wọ́, Dafidi lu ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) wọn bọ lẹ̀. 6Ó sì fi àwọn ọ̀wọ́ ọmọ-ogun rẹ sínú ìjọba Siria ti Damasku, àwọn ará Siria sì ń sìn ní abẹ́ rẹ̀, wọ́n sì mú owó ìṣákọ́lẹ̀ wá. Olúwa sì ń fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní ibi gbogbo tí ó bá lọ.

7Dafidi mú àpáta wúrà tí àwọn ìjòyè Hadadeseri gbé, ó sì gbé wọn wá sí Jerusalẹmu. 8Láti Tibhati àti Kuni, àwọn ìlú Hadadeseri, Dafidi kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ idẹ tí Solomoni lò láti fi ṣe okùn idẹ, àwọn òpó àti oríṣìí ohun èlò idẹ.

9Nígbà tí Tou ọba Hamati gbọ́ pé Dafidi ti borí gbogbo ọmọ-ogun Hadadeseri ọba Soba. 10Ó rán ọmọ rẹ̀ Hadoramu sí ọba Dafidi láti kí i àti láti lọ bá a yọ̀ lórí ìṣẹ́gun rẹ̀ nínú ogun lórí Hadadeseri, tí ó wà lójú ogun pẹ̀lú Tou. Hadoramu mú oríṣìíríṣìí ohun èlò ti wúrà àti fàdákà àti idẹ wá.

11Ọba Dafidi ya ohun èlò wọ́n yí sí mímọ́ fún Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe pẹ̀lú fàdákà àti wúrà tí ó ti mú láti gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí: Edomu àti Moabu, ará Ammoni àti àwọn ará Filistini àti Amaleki.

12Abiṣai ọmọ Seruiah lu ẹgbàá mẹ́sàn (18,000) ará Edomu bolẹ̀ ní àfonífojì Iyọ̀. 13Ó fi ẹgbẹ́ ogun sí Edomu, gbogbo àwọn ará Edomu sì ń sìn ní abẹ́ Dafidi. Olúwa fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní gbogbo ibí tí ó bá lọ.

Àwọn oníṣẹ́ Dafidi

1418.14-17: 2Sa 8.15-18.Dafidi jẹ ọba lórí gbogbo Israẹli, ó sì ṣe òdodo àti ohun tí ó yẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀.

15Joabu ọmọ Seruiah jẹ́ olórí ẹgbẹ́ ọmọ-ogun;

Jehoṣafati ọmọ Ahiludi jẹ́ akọ̀wé ìrántí;

16Sadoku ọmọ Ahitubu àti Abimeleki ọmọ Abiatari jẹ́ àwọn àlùfáà;

Ṣafṣa jẹ́ akọ̀wé;

17Benaiah ọmọ Jehoiada jẹ́ olórí àwọn Kereti àti Peleti;

àwọn ọmọ Dafidi sì ni àwọn olóyè oníṣẹ́ ní ọ̀dọ̀ ọba.

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

歷代志上 18:1-17

大衛的勝利

1後來,大衛打敗並征服了非利士人,奪取了迦特及其周圍的村莊。 2他又打敗了摩押人,使他們稱臣、進貢。 3瑣巴哈大底謝出來要鞏固他在幼發拉底河一帶的權勢,大衛打敗了他,一直攻到哈馬4俘獲一千輛戰車、七千騎兵、兩萬步兵,砍斷拉戰車的馬匹的蹄筋,只留下夠拉一百輛戰車的馬匹。 5大馬士革亞蘭人前來支援瑣巴哈大底謝大衛殺了他們兩萬二千人, 6還派軍駐守亞蘭國的大馬士革亞蘭人臣服大衛,向他進貢。耶和華使大衛無往而不勝。 7大衛奪走哈大底謝侍從的金盾牌,帶回耶路撒冷8又從哈大底謝統治的提巴兩座城中奪走大量的銅。後來所羅門用這些銅製造銅海、銅柱及各種銅器。

9哈馬陀烏聽說大衛打敗瑣巴哈大底謝全軍, 10就派兒子哈多蘭帶著許多金銀銅器去朝見大衛王,向他請安,祝賀他打敗了哈大底謝。因為陀烏常常和哈大底謝交戰。 11於是,大衛把這些器皿和他從以東摩押亞捫非利士亞瑪力各國奪來的金銀都分別出來,奉獻給耶和華。

12洗魯雅的兒子亞比篩在鹽谷擊殺了一萬八千名以東人。 13大衛以東駐兵,以東人都臣服他。耶和華使他無往而不勝。

14大衛在全以色列秉公行義,治理百姓。 15那時,洗魯雅的兒子約押做元帥,亞希律的兒子約沙法做史官, 16亞希突的兒子撒督亞比亞他的兒子亞希米勒做祭司長,沙威沙做書記, 17耶何耶大的兒子比拿雅統管基利提人和比利提人。大衛王的眾子都在他左右做首領。