1 Kronika 15 – YCB & HTB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Kronika 15:1-29

Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí wá sí Jerusalẹmu

115.1–16.3: 2Sa 6.12-19.Lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi ti kọ́ ilé fún ara rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Ó sì fi ààyè sílẹ̀ fún àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ó sì pàgọ́ fún un. 2Nígbà náà Dafidi wí pé, kò sí ẹnìkan àyàfi àwọn ọmọ Lefi ni ó lè gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, nítorí Olúwa yàn wọ́n láti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa àti láti máa ṣe ìránṣẹ́ níwájú rẹ̀ títí láé.

3Dafidi kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ ní Jerusalẹmu láti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa wá sí ibi tí ó ti pèsè sílẹ̀ fún un.

4Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Aaroni àti àwọn ọmọ Lefi tí Dafidi péjọ papọ̀.

5Ọgọ́fà nínú àwọn ọmọ Kohati;

Urieli olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀.

6Igba ó lé ogún nínú àwọn ọmọ Merari;

Asaiah olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀.

7Àádóje nínú àwọn ọmọ Gerṣoni;

Joẹli olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀.

8Igba nínú àwọn ọmọ Elisafani;

Ṣemaiah olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀.

9Ọgọ́rin nínú àwọn ọmọ Hebroni;

Elieli olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀.

10Méjìléláàádọ́fà nínú àwọn ọmọ Usieli;

Amminadabu olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀.

11Dafidi sì ránṣẹ́ pe Sadoku, Abiatari tí wọ́n jẹ́ àlùfáà, àti Urieli, Asaiah. Joẹli, Ṣemaiah, Elieli àti Amminadabu tí wọ́n jẹ́ Lefi. 12Ó sì fi fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni olórí àwọn ìdílé Lefi; ẹ̀yin àti àwọn Lefi ènìyàn yín, ẹ ya ara yín sí mímọ́ kí ẹ lè gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, lọ sí ibi tí mó ti pèsè sílẹ̀ fún un. 13Nítorí tí ẹ̀yin ọmọ Lefi kò gbe gòkè wá ní ìgbà àkọ́kọ́ ti Olúwa Ọlọ́run fi ìbínú rẹ̀ ko lù wá. Àwa kò sì ṣe ìwádìí lọ́wọ́ rẹ̀ nípa bí a ti ń ṣe é gẹ́gẹ́ bí ọ́nà tí a là sílẹ̀.” 14Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà àti àwọn Lefi ya ara wọn sí mímọ́ láti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa gòkè wá, Ọlọ́run Israẹli. 15Nígbà náà ni àwọn Lefi gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run pẹ̀lú ọ̀pá ní èjìká wọn gẹ́gẹ́ bí Mose ti pa á láṣẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa.

16Dafidi sọ fún àwọn olórí àwọn Lefi láti yan àwọn arákùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí akọrin láti kọ orin ayọ̀, pẹ̀lú àwọn ohun èlò orin olókùn, dùùrù, àti símbálì.

17Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Lefi yan Hemani ọmọ Joẹli; àti nínú àwọn arákùnrin rẹ̀, Asafu ọmọ Berekiah, àti nínú àwọn ọmọ Merari arákùnrin wọn, Etani ọmọ Kuṣaiah; 18àti pẹ̀lú wọn àwọn arákùnrin wọn tí a yàn bí olùrànlọ́wọ́ wọn: Sekariah, Jaasieli, Ṣemiramotu, Jehieli, Unni, Eliabu, Benaiah, Maaseiah, Mattitiah, Elifelehu, Mikimeiah, àti Obedi-Edomu àti Jeieli, àwọn aṣọ́bodè.

19Àwọn akọrin sì ni Hemani, Asafu, àti Etani ti àwọn ti kimbali idẹ tí ń dún kíkan; 20Sekariah, Asieli, Ṣemiramotu, Jehieli, àti Unni, Eliabu, Maaseiah àti Benaiah àwọn tí ó gbọdọ̀ ta ohun èlò orin olókùn gẹ́gẹ́ bí alamoti, 21àti Mattitiah, Elifelehu, Mikneiah, Obedi-Edomu, Jeieli àti Asasiah ni ó ní láti ta ohun èlò olóhùn gooro, láti darí gẹ́gẹ́ bí ṣeminiti. 22Kenaniah olórí àwọn ará Lefi ni ó wà ní ìkáwọ́ orin èyí sì ni ojúṣe nítorí ó mòye nípa rẹ̀.

23Berekiah àti Elkana ni kí ó wà gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́nà fún àpótí ẹ̀rí. 24Ṣebaniah, Jehoṣafati, Netaneli, Amasai, Sekariah, Benaiah àti Elieseri ní àwọn àlùfáà, tí o ń fún ìpè níwájú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run. Obedi-Edomu àti Jehiah ni ó sì gbọdọ̀ jẹ́ olùṣọ́nà fún àpótí ẹ̀rí.

25Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi àti àwọn àgbàgbà Israẹli àti àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ láti gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú Olúwa láti ilé Obedi-Edomu, pẹ̀lú inú dídùn. 26Nítorí Ọlọ́run tì ràn wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Lefi ẹni tí ó gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú Olúwa, akọ màlúù méje pẹ̀lú àgbò méje láti fi ṣé ìrúbọ. 27Dafidi sì wọ efodu; aṣọ ìgúnwà ọ̀gbọ̀ dáradára, àti gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí ń ru àpótí ẹ̀rí náà, àti àwọn akọrin, àti Kenaniah olórí pẹ̀lú àwọn akọrin. Dafidi sì wọ aṣọ ìgúnwà funfun. 28Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Israẹli gbé àpótí ẹ̀rí àti májẹ̀mú Olúwa gòkè wá pẹ̀lú ariwo, pẹ̀lú àyíká ìhó ayọ̀ àti láti fọn fèrè ti ìpè, àti kimbali, àti láti ta ohun èlò orin olókùn àti dùùrù olóhùn gooro.

29Bí àpótí ẹ̀rí Olúwa ti ń wọ ìlú ńlá Dafidi, Mikali ọmọbìnrin Saulu ń wò láti ojú fèrèsé nígbà tí ó sì rí ọba Dafidi ń jó, ó sì ń ṣe àjọyọ̀, ó sì kẹ́gàn rẹ̀ ní ọkàn rẹ̀.

Het Boek

1 Kronieken 15:1-29

1Toen David voor zichzelf paleizen had gebouwd in de Davidstad, stelde hij een plaats vast voor de ark van God en spande haar een tent. 2Maar nu beval David, dat de ark van God alleen gedragen zou worden door de levieten, daar Jahweh hen had uitverkoren, om de ark van God te dragen en Hem voor altijd te dienen. 3Nu liet David heel Israël naar Jerusalem komen, om de ark van Jahweh over te brengen naar de plaats, die hij daarvoor had vastgesteld. 4Hij riep de zonen van Aäron en de levieten bijeen; 5van de afstammelingen van Kehat: Oeriël, het hoofd, met honderd twintig stamgenoten; 6van de afstammelingen van Merari: Asaja, het hoofd, met tweehonderd twintig stamgenoten; 7van de afstammelingen van Gersjom: Joël, het hoofd, met honderd dertig stamgenoten; 8van de afstammelingen van Elisafan: Sjemaja, het hoofd, met tweehonderd stamgenoten; 9van de afstammelingen van Chebron: Eliël, het hoofd, met tachtig stamgenoten; 10van de afstammelingen van Oezziël: Amminadab, het hoofd, met honderd twintig stamgenoten. 11Daarna ontbood David de priesters Sadok en Ebjatar, en de levieten Oeriël, Asaja, Joël, Sjemaja, Eliël en Amminadab, 12en zeide tot hen: Gij, de familiehoofden der levieten, moet uzelf en uw broeders heiligen, om de ark van Jahweh, den God van Israël, over te brengen naar de plaats, die ik daarvoor heb vastgesteld. 13Want de vorige keer, toen gij er niet waart, is Jahweh heftig tegen ons losgebroken, omdat wij niet voor Hem hadden gezorgd, zoals het behoort. 14De priesters en levieten heiligden zich dus, om de ark van Jahweh, den God van Israël, over te brengen. 15De levieten zouden nu de ark van God met stangen op hun schouders dragen, zoals Moses op Gods bevel had bepaald. 16Ook gaf David aan de hoofden der levieten het bevel, de zangers onder hun stamgenoten met de muziekinstrumenten, harpen, citers en cymbalen op te stellen, om feestelijke klanken te laten horen. 17De levieten wezen dus Heman aan, den zoon van Joël, met zijn stamgenoot Asaf, den zoon van Berekjáhoe, en van de Merarieten, hun ambtgenoten, Etan, den zoon van Koesjajáhoe. 18Verder hun ambtgenoten van de tweede rang: de poortwachters Zekarjáhoe, Jaäziël, Sjemiramot, Jechiël, Oenni, Eliab, Benajáhoe, Maäsejáhoe, Mattitjáhoe, Elifeléhoe, Miknejáhoe, Obed-Edom en Jeïël. 19Bovendien de zangers Heman, Asaf en Etan met koperen cymbalen voor de feestmuziek; 20Zekarja, Aziël, Sjemiramot, Jechiël, Oenni, Eliab, Maäsejáhoe, Benajáhoe met harpen, hooggestemd; 21Mattitjáhoe, Elifeléhoe, Miknejáhoe, Obed-Edom, Jeïël en Azazjáhoe met citers, om een octaaf lager te begeleiden. 22Kenanjáhoe had bij het vervoer het toezicht op de levieten, en daar hij deskundig was, de leiding bij het vervoer. 23Berekja en Elkana hielden de wacht bij de ark. 24De priesters Sjebanjáhoe, Josjafat, Netaneël, Amasai, Zekarjáhoe, Benajáhoe en Eliézer bliezen op de trompetten voor de ark van God, en Obed-Edom en Jechi-ja hielden de wacht bij de ark. 25Nu ging David met de oudsten van Israël en de bevelhebbers van duizend de verbondsark van Jahweh op feestelijke wijze uit het huis van Obed-Edom overbrengen. 26En toen bleek, dat God de levieten bijstond, die de verbondsark van Jahweh droegen, werden zeven stieren en zeven rammen geofferd. 27David was daarbij gekleed in een mantel van fijn lijnwaad, gelijk alle levieten, die de ark droegen, en zoals de zangers, Kenanja, de leider van het vervoer, en de muzikanten; verder was David slechts met een linnen borstkleed bedekt. 28Zo bracht Israël de verbondsark van Jahweh over, met gejubel en bazuingeschal, terwijl de trompetten, cymbalen, harpen en citers hun feestklanken lieten horen. 29Toen de verbondsark van Jahweh in de Davidstad aankwam, gluurde Mikal, de dochter van Saul, door het venster. Zij zag koning David dansend en springend, en verachtte hem in haar hart.