1 Kronika 10 – YCB & NSP

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Kronika 10:1-14

Saulu gba ẹ̀mí ara rẹ̀

110.1-12: 1Sa 31.1-13.Nísinsin yìí, àwọn ará Filistini dojú ìjà kọ Israẹli, àwọn ará Israẹli sì sálọ kúrò níwájú wọn, a sì pa ọ̀pọ̀ wọn sí orí òkè Gilboa. 2Àwọn ará Filistini sí lépa Saulu gidigidi àti àwọn ọmọ rẹ̀. Wọ́n sì pa àwọn ọmọ rẹ̀. Jonatani, Abinadabu àti Malikiṣua. 3Ogun náà sí gbóná janjan fún Saulu, nígbà tí àwọn tafàtafà sì lé e bá, wọ́n sì ṣá a lọ́gbẹ́.

4Saulu sì sọ fún ẹni tí ó gbé ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Fa idà rẹ yọ, kí o sì fi gún mi, kí àwọn aláìkọlà wọ̀nyí má wá láti bú mi.”

Ṣùgbọ́n ẹni tí ó ń gbé ìhámọ́ra rẹ̀ ń bẹ̀rù, kò sì le ṣe é, bẹ́ẹ̀ ni Saulu mú idà tirẹ̀ ó sì ṣubú lé e. 5Nígbà tí agbé-ìhámọ́ra rí pé Saulu ti kú, òhun pẹ̀lú ṣubú lórí idà tirẹ̀, ó sì kú. 6Bẹ́ẹ̀ ni Saulu àti ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kú, gbogbo ilé rẹ̀ sì kú ṣọ̀kan, lọ́jọ́ kan náà.

7Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rí wí pé àwọn ọmọ-ogun ti sálọ àti pé Saulu àti àwọn ọmọ rẹ̀ ti kú wọ́n kọ àwọn ìlú wọn sílẹ̀, wọ́n sì sálọ. Àwọn ará Filistini wá, wọ́n sì jókòó nínú wọn.

8Ní ọjọ́ kejì, nígbà tí àwọn ará Filistini wá láti kó òkú, wọ́n rí Saulu àti àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n ṣubú sórí òkè Gilboa. 9Wọ́n bọ́ ní aṣọ, wọ́n sì gbé orí rẹ̀ àti ìhámọ́ra rẹ̀, wọ́n sì rán ìránṣẹ́ lọ káàkiri ilẹ̀ àwọn ará Filistini láti kéde ìròyìn náà láàrín àwọn òrìṣà wọn àti àwọn ènìyàn wọn. 10Wọ́n gbé ìhámọ́ra rẹ̀ sí inú ilé tí wọ́n kọ́ fún òrìṣà wọn, wọ́n sì fi orí rẹ̀ kọ́ sí inú ilé Dagoni.

11Nígbà tí gbogbo àwọn olùgbé Jabesi—Gileadi gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn ará Filistini ṣe fún Saulu, 12gbogbo àwọn akọni ọkùnrin wọn lọ láti mú àwọn ará Saulu àti àwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n sì kó wọn wá sí Jabesi. Nígbà náà, wọ́n sin egungun wọn sábẹ́ igi óákù ní Jabesi, wọ́n sì gbààwẹ̀ fún ọjọ́ méje.

13Saulu kú nítorí kò ṣe òtítọ́ sí Olúwa, kò pa ọ̀rọ̀ Olúwa mọ́ pẹ̀lú, ó tọ abókùúsọ̀rọ̀ lọ fún ìtọ́sọ́nà. 14Kò sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa pa á, Ó sì yí ìjọba náà padà sọ́dọ̀ Dafidi ọmọ Jese.

New Serbian Translation

1. Књига дневника 10:1-14

Смрт Саула и његових синова

1Филистејци су ступили у бој против Израиљаца, али су Израиљци побегли пред Филистејцима, па су падали мртви на гори Гелвуји. 2Филистејци су притисли Саула и његове синове и убили Јонатана, Авинадава и Малхи-Сува, Саулове синове. 3Битка се жестоко водила око Саула. А онда су га стрелци погодили и ранили га.

4Тада Саул рече своме штитоноши: „Извади свој мач и прободи ме, да не дођу ови необрезани и наругају ми се.“

Али штитоноша није хтео, јер се веома уплашио. Тада је Саул узео мач и бацио се на њега. 5Кад је његов штитоноша видео да је Саул мртав, и он се бацио на мач и умро.

6Тако су погинули и Саул и његова три сина, и сав његов дом.

7Кад су Израиљци који су били у долини видели да су Израиљци побегли и да су погинули Саул и његови синови, напустили су своје градове и побегли. Тада су дошли Филистејци и населили се у њима.

8Сутрадан, кад су Филистејци дошли да опљачкају мртве, нашли су Саула и његове синове, који су погинули на гори Гелвуји. 9Тада су га свукли, одсекли му главу и скинули оружје с њега, и то су послали по филистејској земљи да разгласе радосну вест својим идолима и народу. 10Његово оружје су ставили у храм својих богова, а главу су му обесили у Дагоновом храму.

11Кад су сви мештани Јавис-Галада чули шта су Филистејци урадили Саулу, 12дигли су се сви храбри људи, па су скинули Саулово тело и тела његових синова и донели их у Јавис. Њихове кости су сахранили под тамариском у Јавису. Затим су постили седам дана.

13Тако је Саул умро због својег неверства које је починио против Господа, јер није држао реч Господњу, и још је тражио савет од призивача духова. 14И пошто није тражио савет од Господа, Господ га је убио и пренео царство на Давида, сина Јесејевог.