Ìran Adamu títí de Abrahamu
Títí dé ọmọkùnrin Noa
11.1-53: Gẹ 5; 10; 11; 25; 36.Adamu, Seti, Enoṣi,
2Kenani, Mahalaleli, Jaredi,
3Enoku, Metusela, Lameki,
Noa.
4Àwọn ọmọ Noa: Ṣemu, Hamu àti Jafeti.
Àwọn Ọmọ Jafeti
5Àwọn ọmọ Jafeti ni:
Gomeri, Magogu, Madai; Jafani, Tubali, Meṣeki àti Tirasi.
6Àwọn ọmọ Gomeri ni:
Aṣkenasi, Rifàti àti Togarma.
7Àwọn ọmọ Jafani ni:
Eliṣa, Tarṣiṣi, Kittimu, àti Dodanimu.
Àwọn ọmọ Hamu
8Àwọn ọmọ Hamu ni:
Kuṣi, Misraimu, Puti, àti Kenaani.
9Àwọn ọmọ Kuṣi ni:
Seba, Hafila, Sabta, Raama, àti Ṣabteka.
Àwọn ọmọ Raama:
Ṣeba àti Dedani.
10Kuṣi sì bí Nimrodu:
Ẹni tí ó di alágbára jagunjagun ní ayé.
11Misraimu sì bí
Ludimu, Anamimu, Lehabimu, Naftuhimu, 12Patrusimu, Kasluhimu, (láti ọ̀dọ̀ ẹni tí àwọn ará Filistini ti wá) àti àwọn ará Kaftorimu.
13Kenaani sì bí Sidoni àkọ́bí rẹ̀,
àti Heti, 14Àti àwọn ará Jebusi, àti àwọn ará Amori, àti àwọn ará Girgaṣi, 15àti àwọn ará Hifi, àti àwọn ará Arki, àti àwọn ará Sini, 16àti àwọn ará Arfadi, àti àwọn ará Ṣemari, àti àwọn ará Hamati.
Àwọn ará Ṣemu.
17Àwọn ọmọ Ṣemu ni:
Elamu, Aṣuri, Arfakṣadi, Ludi àti Aramu.
Àwọn ọmọ Aramu:
Usi, Huli, Geteri, àti Meṣeki.
18Arfakṣadi sì bí Ṣela,
Ṣela sì bí Eberi.
19Eberi sì bí ọmọ méjì:
ọ̀kan ń jẹ́ Pelegi, nítorí ní ìgbà ọjọ́ rẹ̀ ni ilẹ̀ ya; orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Joktani.
20Joktani sì bí
Almodadi, Ṣelefi, Hasarmafeti, Jera. 21Hadoramu, Usali, Dikla, 22Ebali, Abimaeli, Ṣeba. 23Ofiri, Hafila, àti Jobabu. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Joktani.
24Ṣemu, Arfakṣadi, Ṣela,
25Eberi, Pelegi. Reu,
26Serugu, Nahori, Tẹra:
27Àti Abramu (tí ń ṣe Abrahamu).
Ìdílé Abrahamu
28Àwọn ọmọ Abrahamu: Isaaki àti Iṣmaeli.
Àwọn ọmọ Hagari
29Èyí ni àwọn ọmọ náà:
Nebaioti àkọ́bí Iṣmaeli: Kedari, Adbeeli, Mibsamu, 30Miṣima, Duma, Massa, Hadadi, Tema, 31Jeturi, Nafiṣi, àti Kedema.
Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Iṣmaeli.
Àwọn ọmọ Ketura
32Àwọn ọmọ Ketura, obìnrin Abrahamu:
Simrani, Jokṣani Medani, Midiani Iṣbaki àti Ṣua.
Àwọn ọmọ Jokṣani:
Ṣeba àti Dedani.
33Àwọn ọmọ Midiani:
Efani, Eferi, Hanoku, Abida àti Eldaa.
Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ìran Ketura.
Àwọn Ìran Sara
34Abrahamu sì jẹ́ baba Isaaki:
Àwọn ọmọ Isaaki:
Esau àti Israẹli.
Àwọn ọmọ Esau
35Àwọn ọmọ Esau:
Elifasi, Reueli, Jeuṣi, Jalamu, àti Kora.
36Àwọn ọmọ Elifasi:
Temani, Omari, Sefi, Gatamu àti Kenasi;
láti Timna: Amaleki.
37Àwọn ọmọ Reueli:
Nahati, Sera, Ṣamma àti Missa.
Àwọn ènìyàn Seiri ní Edomu
38Àwọn ọmọ Seiri:
Lotani, Ṣobali, Sibeoni, Ana, Diṣoni, Eseri àti Diṣani.
39Àwọn ọmọ Lotani:
Hori àti Homamu: Timna sì ni arábìnrin Lotani.
40Àwọn ọmọ Ṣobali:
Afiani, Manahati, Ebali, Ṣefo àti Onamu.
Àwọn ọmọ Sibeoni:
Aiah àti Ana.
41Àwọn ọmọ Ana:
Diṣoni.
Àwọn ọmọ Diṣoni:
Hemdani, Eṣbani, Itrani, àti Kerani.
42Àwọn ọmọ Eseri:
Bilhani, Saafani àti Akani.
Àwọn ọmọ Diṣani:
Usi àti Arani.
Àwọn alákòóso Edomu
43Àwọn wọ̀nyí ni ọba tí ó jẹ ní Edomu, kí ó tó di pé ọba kankan jẹ lórí Israẹli:
Bela ọmọ Beori, orúkọ ìlú rẹ̀ ni Dinhaba.
44Nígbà tí Bela kú, Jobabu ọmọ Sera ti Bosra sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
45Nígbà tí Jobabu kú, Huṣamu láti ilẹ̀ Temani sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
46Nígbà tí Huṣamu kú, Hadadi ọmọ Bedadi tí ó kọlu Midiani ní ìgbẹ́ Moabu, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Afiti.
47Nígbà tí Hadadi sì kú, Samla láti Masreka, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
48Samla sì kú, Saulu ti Rehoboti létí odò sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀
49Nígbà tí Saulu kú, Baali-Hanani, ọmọ Akbori jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
50Nígbà tí Baali-Hanani kú, Hadadi ni ó jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Pau; orúkọ ìyàwó sì ni Mehetabeeli ọmọbìnrin Matiredi, ọmọbìnrin Mesahabu. 51Hadadi sì kú pẹ̀lú.
Àwọn baálẹ̀ Edomu ni:
baálẹ̀ Timna, baálẹ̀ Alfa, baálẹ̀ Jeteti 52baálẹ̀ Oholibama, baálẹ̀ Ela, baálẹ̀ Pinoni. 53baálẹ̀ Kenasi, baálẹ̀ Temani, baálẹ̀ Mibsari, 54Magdieli àti Iramu.
Àwọn wọ̀nyí ni baálẹ̀ Edomu.