1 Kọrinti 2 – YCB & CARST

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Kọrinti 2:1-16

12.1: 1Kọ 1.17.Nígbà tí èmí tọ̀ yín wá, ẹ̀yin ará, kì í ṣe nípa ọ̀rọ̀ gíga àti ọgbọ́n gíga ni mo fi bá yín sọ̀rọ̀, nígbà tí èmi ń sọ̀rọ̀ ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run fún un yín. 22.2: Ga 6.14; 1Kọ 1.23.Èmi ti pinnu láti má mọ ohunkóhun nígbà ti mo wà láàrín yín bí kò ṣe Jesu Kristi, ẹni tí a kàn mọ́ àgbélébùú. 32.3: Ap 18.1,6,12; 1Kọ 4.10; 2Kọ 11.30.Èmi sì tọ̀ yín wá ni àìlera, àti ní ẹ̀rù, àti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwárìrì. 42.4: Ro 15.19; 1Kọ 4.20.Ìwàásù mi àti ẹ̀kọ́ mi, kì í ṣe nípa ọgbọ́n ènìyàn àti ọ̀rọ̀ tí a fi ń yí ènìyàn lọ́kàn padà, bí kò ṣe nípa ìfihàn agbára Ẹ̀mí. 52.5: 2Kọ 4.7; 6.7; 1Kọ 12.9.Kí ìgbàgbọ́ yín kí ó má ṣe dúró lórí ọgbọ́n ènìyàn, ṣùgbọ́n kí ó dúró lórí agbára Ọlọ́run.

Ọgbọ́n láti ọ̀dọ̀ ẹ̀mí wá

62.6: Ef 4.13.Ṣùgbọ́n àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n láàrín àwọn tí a pè, ṣùgbọ́n kì í ṣe ọgbọ́n ti ayé yìí tàbí ti àwọn olórí ayé yìí, èyí tí yóò di asán. 72.7: Ro 8.29-30.Bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n ti Ọlọ́run tó fi ara sin, ọgbọ́n tí ó ti fi ara pamọ́, èyí tí Ọlọ́run ti lànà sílẹ̀ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé fún ògo wa. 82.8: Ap 7.2; Jk 2.1.Èyí ti ẹnikẹ́ni nínú àwọn aláṣẹ ayé yìí kò mọ̀. Ìbá ṣe pé wọ́n mọ̀ ọ́n, wọn kì bá tún kan Olúwa ògo mọ́ àgbélébùú. 92.9: Isa 64.4; 65.17.Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:

“Ojú kò tí ì rí,

etí kò tí í gbọ́,

kò sì ọkàn ènìyàn tí ó tí í mọ̀

ohun tí Ọlọ́run tí pèsè sílẹ̀ fún àwọn tí o fẹ́ ẹ.”

102.10: Mt 11.25; 13.11; 16.17; Ef 3.3,5.Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi í hàn fún wa nípasẹ̀ Ẹ̀mí rẹ̀.

Ẹ̀mí á máa wádìí ohun gbogbo, kódà àwọn àṣírí Ọlọ́run tó jinlẹ̀ jùlọ. 11Ta ni nínú ènìyàn tí ó mọ èrò ọkàn ènìyàn kan, bí kò ṣe ẹ̀mí ènìyàn tí ó wà nínú rẹ̀? Bákan náà, kò sí ẹni ti ó mọ àwọn èrò Ọlọ́run, bí kò ṣe Ẹ̀mí Ọlọ́run fúnra rẹ̀. 122.12: Ro 8.15.Àwa kò gbà ẹ̀mí ti ayé yìí, bí kò ṣe Ẹ̀mí ẹni tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa, kí a lè ní òye ohun tí Ọlọ́run fi fún wa lọ́fẹ̀ẹ́. 132.13: 1Kọ 1.17.Èyí ni àwa ń wí, kì í ṣe èyí tí a ń kọ nípa ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ènìyàn, ṣùgbọ́n èyí tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi ń kọ ènìyàn, èyí tí a ń fi ohun Ẹ̀mí wé ohun Ẹ̀mí. 142.14: 1Kọ 1.18; Jk 3.15.Ṣùgbọ́n ènìyàn nípa ti ara kò gba ohun ti Ẹ̀mí Ọlọ́run wọ̀n-ọn-nì, nítorí pé wèrè ni wọ́n jásí fún un, òun kò sì le mọ̀ wọ́n, nítorí nípa tí Ẹ̀mí ní a fi ń wádìí wọn. 152.15: 1Kọ 3.1; 14.37; Ga 6.1.Ṣùgbọ́n ẹni tí ó wà nípa ti ẹ̀mí ń wádìí ohun gbogbo, ṣùgbọ́n kò sí ẹnikẹ́ni tí í wádìí rẹ̀.

162.16: Isa 40.13; Ro 11.34.“Nítorí ta ni ó mọ ọkàn Olúwa,

ti yóò fi máa kọ́ Ọ?”

Ṣùgbọ́n àwa ní inú Kristi.

Священное Писание (Восточный перевод), версия для Таджикистана

1 Коринфянам 2:1-16

Проповедь в силе Духа

1Братья, когда я пришёл к вам, чтобы возвещать о тайне Всевышнего2:1 Или: «чтобы возвещать свидетельство Всевышнего»., то мои слова не отличались ни красноречием, ни особой мудростью. 2Находясь среди вас, я решил не знать ничего, кроме Исо Масеха, и притом распятого. 3Будучи у вас, я был слаб, полон страха и трепета. 4И моя весть и моя проповедь были не в убедительных словах человеческой мудрости, но в проявлении силы Духа, 5чтобы ваша вера основывалась не на мудрости человеческой, а на силе Всевышнего.

Мудрость от Духа

6Мудрость же мы возвещаем среди людей духовно зрелых, но это не мудрость этого мира и не мудрость властителей этого мира, которые обречены стать ничем. 7Нет, мы говорим о тайной мудрости Всевышнего, которая до сих пор была скрыта, но ещё до сотворения мира предназначена Им для нашей славы. 8Те, кому принадлежит власть в этом мире, не поняли её, иначе они не распяли бы Повелителя славы. 9Но, как написано:

«Не видел глаз,

не слышало ухо,

и не приходило на сердце человеку то,

что Всевышний приготовил любящим Его»2:9 См. Ис. 64:4..

10Нам же Всевышний открыл это Духом Своим, потому что Духу известно всё. Он проникает во все глубины премудрости Всевышнего. 11Кто может знать мысли человека, кроме его собственного духа, живущего в нём? Так же и замыслов Всевышнего никто не знает, кроме Духа Всевышнего. 12Мы же получили не дух этого мира, но Духа от Всевышнего, чтобы мы могли понять всё дарованное нам Всевышним. 13Об этом мы возвещаем не словами человеческой мудрости, но словами, которым нас научил Дух. Мы объясняем духовные истины словами, которые нам даёт Дух2:13 Или: «Мы духовные истины объясняем людям духовным».. 14Человек, не знающий Всевышнего, не принимает того, что приходит от Духа Всевышнего. Он считает это глупостью и не может понять, потому что об этом можно судить только духовно. 15Духовный же человек может судить обо всём, тогда как о нём никакой человек судить не может, 16потому что

«кто постиг разум Вечного Повелителя,

чтобы советовать Ему?»2:16 Ис. 40:13.

Мы же имеем разум Масеха.