1 Kọrinti 13 – YCB & CCBT

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Kọrinti 13:1-13

Ìfẹ́

113.1: Sm 150.5.Bí èmi tilẹ̀ lè sọ oríṣìíríṣìí èdè tí ènìyàn àti ti angẹli, tí n kò bá sì ní ìfẹ́, mo kàn ń pariwo bí ago lásán ni tàbí bí i kimbali olóhùn gooro. 213.2: 1Kọ 14.2; Mt 17.20; 21.21.Bí mo bá ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀, tí mo sì ní òye gbogbo ohun ìjìnlẹ̀, àti gbogbo ìmọ̀, bí mo sì ni gbogbo ìgbàgbọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí mo lè ṣí àwọn òkè ńlá nídìí, tí èmi kò sì ní ìfẹ́, èmi kò jẹ nǹkan kan. 3Bí mo bá fi gbogbo nǹkan tí mo ní tọrẹ fún àwọn aláìní, tí mo sì fi ara mi fún ni láti sùn ṣùgbọ́n tí n kò ní ìfẹ́, kò ní èrè kan fún mi.

4Ìfẹ́ a máa mú sùúrù, ìfẹ́ a máa ṣeun, ìfẹ́ kì í ṣe ìlara, ìfẹ́ kì í fẹ̀, ìfẹ́ kì í sọ̀rọ̀ ìgbéraga. 513.5: 1Kọ 10.24.Ìfẹ́ kì í hùwà àìtọ́, kì í wá ohun ara rẹ̀ nìkan. Ìfẹ́ kì í bínú fùfù, ìfẹ́ kì í fi búburú ọmọ ẹnìkejì sínú. 6Inú ìfẹ́ kì í dùn sí àìṣòótọ́. Ṣùgbọ́n inú rẹ̀ a máa dùn nígbà gbogbo. 713.7: 1Kọ 9.12.A máa faradà ohun gbogbo sí òtítọ́, a máa gba ohun gbogbo gbọ́, a máa retí ohun gbogbo, a máa fàyàrán ohun gbogbo.

8Ìfẹ́ kì í kùnà láé, kì í sì í yẹ̀ ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ ni, wọn yóò dópin, bí ó bá ṣe ẹ̀bùn ahọ́n ni, wọn yóò dákẹ́, bí ó bá ṣe pé ìmọ̀ ni yóò di asán. 9Nítorí àwa mọ̀ ní apá kan, àwa sì sọtẹ́lẹ̀ ní apá kan. 10Ṣùgbọ́n nígbà tí èyí ti o pé bá dé, èyí tí í ṣe tí apá kan yóò dópin. 11Nígbà tí mó wà ni èwe, èmi á máa sọ̀rọ̀ bi èwe, èmi a máa mòye bí èwe, èmi a máa gbèrò bí èwe. Ṣùgbọ́n nígbà tí mó di ọkùnrin tán, mo fi ìwà èwe sílẹ̀. 12Nítorí pé nísinsin yìí àwa ń ríran bàìbàì nínú dígí; nígbà náà a ó rí í lójúkojú. Nísinsin yìí mò mọ̀ pé ní apá kan; nígbà náà èmi o mọ̀ lẹ́kùnrẹ́rẹ́, kódà bí mo ti dí mí mọ̀ pẹ̀lú.

13Ǹjẹ́ nísinsin yìí àwọn nǹkan mẹ́ta wọ̀nyí dúró: ìgbàgbọ́, ìrètí, àti ìfẹ́. Ṣùgbọ́n èyí tí o tóbi jù nínú wọn ni ìfẹ́.

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

哥林多前書 13:1-13

愛的真諦

1即使我能說人類和天使的各種語言,如果沒有愛,我不過像咣咣作響的鑼和鈸。 2即使我能作先知講道,又明白各樣的奧祕,而且學問淵博,甚至有移開山嶺的信心,如果沒有愛,我仍然算不了什麼。 3即使我傾家蕩產賙濟窮人,甚至捨己捐軀任人焚燒,如果沒有愛,對我也毫無益處。

4愛是恆久忍耐,又有恩慈。愛是不嫉妒,不自吹自擂,不驕傲自大, 5不輕浮無禮;不自私自利,不輕易動怒,不懷怨記恨; 6不喜愛不義,只喜愛真理。 7凡事能包容,凡事有信心,凡事有盼望,凡事能忍耐。

8愛永不止息。然而,先知講道的恩賜終會過去,說方言的恩賜也會停止,學問也將成為過去。 9我們現在知道的有限,講道的恩賜也有限, 10等那全備的來到,這一切有限的事都要被廢棄。

11當我是小孩子的時候,我的思想、言語和推理都像小孩子,長大後,我就把一切幼稚的事丟棄了。 12如今我們好像對著鏡子觀看影像,模糊不清,但將來會看得真真切切13·12 看得真真切切」希臘文是「面對面」。。現在我所知道的有限,但將來會完全知道,如同主知道我一樣。

13如今常存的有信、望、愛這三樣,其中最偉大的是愛。