Lórí ìyapa nínú ìjọ
13.1: Ro 7.14; Hb 5.13.Ará, èmí kò sí le bá yín sọ̀rọ̀ bí àwọn tí í ṣe ti Ẹ̀mí, bí kò ṣe bí àwọn ti í ṣe ti ara, àní bí àwọn ọmọ ọwọ́ nínú Kristi. 23.2: Hb 5.12-13; 1Pt 2.2.Wàrà ni mo ti fi bọ́ yín, kì í ṣe oúnjẹ; nítorí ẹ kò í tí le gbà á nísinsin yìí náà, ẹ kò í tí le gbà a. 3Nítorí ẹ̀yin jẹ́ ti ara síbẹ̀. Nítorí, níwọ̀n bí owú jíjẹ àti ìjà ṣe wà láàrín ara yín, ẹ̀yin kò ha ṣe ti ayé bí? Ẹ̀yin kò ha ṣe bí ènìyàn lásán bí? 43.4: 1Kọ 1.12.Ǹjẹ́ ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn lásán bí? Níwọ́n ìgbà tí ẹ ba ń sọ pé, “Èmi ń tẹ̀lé Paulu,” àti ti ẹlòmíràn tún wí pé, “Èmi ń tẹ̀lé Apollo.”
53.5: 2Kọ 6.4; Ef 3.7; Kl 1.25.Jú gbogbo rẹ̀ lọ, kí ni Apollo ha jẹ́, kín ni Paulu sì jẹ́, àwọn ìránṣẹ́ lásán, nípasẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin gbàgbọ́, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti fi fún olúkúlùkù. 63.6: Ap 18.4-11,24-27; 1Kọ 1.12.Èmi gbìn, Apollo ń bomirin; ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni ń mú ìbísí wá. 7Ǹjẹ́ kì í ṣe ẹni tí ó ń gbìn nǹkan kan, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ẹni tí ń bomirin; bí kò ṣe Ọlọ́run tí ó ń mú ìbísí wá. 8Ẹni tí ó ń gbìn àti ẹni tí ó ń bu omi rín ní ìrònú kan àti èrèdí kan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnìkọ̀ọ̀kan wa yóò gba èrè tirẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe é kárakára tó. 93.9: Isa 61.3; Ef 2.20-22; 1Pt 2.5.A ń bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́ pọ̀ ni, ẹ̀yin pàápàá sì jẹ́ ọgbà ohun ọ̀gbìn fún Ọlọ́run, kì í ṣe fún wa, ilé Ọlọ́run ni yín, kì í ṣe ilé tiwa.
103.10: Ro 12.3; 1Kọ 15.10.Nípa oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọ́run tí fi fún mi, gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n ọ̀mọ̀lé, mo ti fi ìpìlẹ̀ ilé lélẹ̀, ẹlòmíràn sì ń mọ lé e, ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù kíyèsára bí yóò ṣe mọ ọ́n lé e. 113.11: Ef 2.20.Nítorí kò sí ẹlòmíràn tó le fi ìpìlẹ̀ tòótọ́ mìíràn lélẹ̀ ju èyí tí a fi lélẹ̀ àní Jesu Kristi ni ìpìlẹ̀ náà. 12Ǹjẹ́ bí ẹnikẹ́ni bá fi wúrà, fàdákà, òkúta olówó-iyebiye, igi, koríko, àgékù koríko mọ lé orí ìpìlẹ̀ yìí. 133.13: 2Tẹ 1.7-10.Iṣẹ́ olúkúlùkù ènìyàn yóò hàn, nítorí ọjọ́ náà yóò fi í hàn, nítorí pé nínú iná ni a ó ti fihàn, iná náà yóò sì dán irú iṣẹ́ èyí tí olúkúlùkù ṣe wò. 14Bí iṣẹ́ tí ẹnikẹ́ni bá ṣe lórí rẹ̀ bá dúró, òun yóò sì gba èrè rẹ̀. 153.15: Jb 23.10.Bí iṣẹ́ ẹnikẹ́ni bá jóná, òun yóò pàdánù: Ṣùgbọ́n òun tìkára rẹ̀ ni a ó gbàlà, ṣùgbọ́n bí ìgbà tí ènìyàn bá la àárín iná kọjá.
163.16: 1Kọ 6.19; 2Kọ 6.16.Ṣé ẹ̀yin kò tilẹ̀ mọ̀ pé tẹmpili Ọlọ́run ni ẹ̀yin jẹ́? Àti pẹ̀lú pe Ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé inú yín? 17Bí ẹnikẹ́ni bá ba tẹmpili Ọlọ́run jẹ́, òun ni Ọlọ́run yóò parun; nítorí pé mímọ́ ni tẹmpili Ọlọ́run, èyí tí ẹ̀yin jẹ́.
183.18: Isa 5.21; 1Kọ 8.2; Ga 6.3.Kí ẹnikẹ́ni, má ṣe tan ara rẹ̀ jẹ mọ́. Bí ẹnikẹ́ni yín nínú ayé yìí ba rò pé òun gbọ́n, ẹ jẹ́ kí ó di òmùgọ̀ kí ó bá a le è gbọ́n. 193.19: Jb 5.13; 1Kọ 1.20.Nítorí ọgbọ́n ayé yìí jẹ́ òmùgọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú Ìwé Mímọ́ pé, “Ẹni ti tí ó mu àwọn ọlọ́gbọ́n nínú àrékérekè wọn”; 203.20: Sm 94.11.lẹ́ẹ̀kan sí i, “Olúwa mọ̀ èrò inú àwọn ọlọ́gbọ́n pé asán ní wọn.” 213.21: 1Kọ 4.6; Ro 8.32.Nítorí kí ẹnikẹ́ni má ṣe ṣògo nínú ènìyàn. Nítorí tí yín ni ohun gbogbo. 223.22: 1Kọ 1.12; Ro 8.38.Ìbá ṣe Paulu, tàbí Apollo, tàbí Kefa, tàbí ayé tàbí ìyè, tàbí ikú, tàbí ohun ìsinsin yìí, tàbí ohun ìgbà tí ń bọ̀; tiyín ni gbogbo wọn. 23Ẹ̀yin sì ni ti Kristi; Kristi sì ni ti Ọlọ́run.
Paulus vädjar om enhet i församlingen
1Syskon, jag kunde inte tala till er som till andliga människor, utan jag fick tala till er som till människor som fortfarande drivs av sin mänskliga natur, som till små barn i Kristus. 2Jag fick mata er med mjölk, inte med fast föda, för den klarade ni inte av. Och den klarar ni inte ens nu, 3eftersom ni fortfarande har kvar er gamla natur. Om ni är avundsjuka på varandra och bråkar, har ni väl fortfarande kvar er gamla natur och lever som de andra? 4Är ni inte som alla andra när ni säger: ”Jag följer Paulus” eller ”Jag följer Apollos”?
5Vad är då Apollos? Eller Paulus? Tjänare, som hjälpte er att börja tro. Var och en av oss har utfört det uppdrag vi fick från Herren.
6Jag planterade, Apollos vattnade, men det var Gud som gav växten. 7Varken den som planterar eller den som vattnar är något, utan bara Gud som ger växten. 8Den som planterar och den som vattnar är ett, och var och en får lön efter sitt arbete. 9Vi är ju medarbetare till Gud, och ni är Guds åker, hans bygge.
Församlingen är Guds bygge
10På grund av den nåd Gud gav mig lade jag, som en erfaren byggmästare, grunden, och sedan bygger någon annan vidare på den. Men var och en som bygger måste tänka på hur han bygger. 11Ingen kan lägga en annan grund än den som redan är lagd, och den grunden är Jesus Kristus själv. 12På den grunden kan man bygga med guld, silver och ädelstenar, eller med trä, gräs och halm, 13och det ska visa sig vad man har byggt, när den dagen kommer som ska avslöja det. Hur vars och ens verk är ska elden pröva. 14Den vars bygge består ska få lön för sitt arbete. 15Men den vars verk brinner ner blir utan lön. Själv ska han dock bli räddad, men som ur eld.
Förstör inte församlingen genom splittring
16Förstår ni inte att ni är Guds tempel och att Guds Ande bor i er? 17Om någon fördärvar Guds tempel, ska Gud fördärva honom. Guds tempel är ju heligt, och det är ni som är det templet. 18Bedra inte er själva. Den som anser sig vara vis enligt den här tidsålderns sätt att se, måste först bli en dåre för att kunna bli vis. 19Den här världens vishet är ju dårskap för Gud. Det står ju skrivet: ”Han fångar de kloka i deras slughet”,3:19 Se Job 5:13. 20och: ”Herren känner de visas tankar och vet att de är tomhet.”3:20 Se Ps 94:11. 21Skryt därför inte över människor. Allting tillhör er, 22Paulus, Apollos, Kefas och hela världen, liv och död, nutid och framtid, allting är ert. 23Ni tillhör Kristus, och Kristus tillhör Gud.