Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Kọrinti 1:1-31

11.1: Ro 1.1; Ap 18.17.Paulu, ẹni ti a pé láti jẹ́ aposteli Kristi Jesu nípa ìfẹ́ Ọlọ́run àti Sostene arákùnrin wa.

21.2: Ap 18.1.Sí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run ni Kọrinti, sí àwọn ti a sọ di mímọ́ nínú Kristi Jesu àti àwọn ti a pè láti jẹ́ mímọ́ pẹ̀lú gbogbo ènìyàn ni ibikíbi ti ń pe orúkọ Olúwa wa Jesu Kristi ẹni ti ń ṣe Olúwa tiwọn àti ti àwa náà.

31.3: Ro 1.7.Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti Olúwa wa tí í ṣe Jesu Kristi.

Ìdúpẹ́

41.4: Ro 1.8.Nígbà gbogbo ni mo ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tó fi fún un yín nínú Kristi Jesu. 5Nítorí nínú rẹ̀ ni a ti sọ yín di ọlọ́rọ̀ nínú ọ̀rọ̀ sísọ yín gbogbo àti nínú ìmọ̀ yín gbogbo. 6Nítorí ẹ̀rí wa nínú Kristi ni a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nínú yín. 7Nítorí náà ẹ̀yin kò ṣe aláìní nínú èyíkéyìí ẹ̀bùn ẹ̀mí, bí ẹ̀yin ṣe ń retí ìfarahàn Olúwa wa Jesu Kristi. 81.8: 1Kọ 5.5; 2Kọ 1.14.Òun yóò sì mú yín dúró títí dé òpin, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ́ aláìlábùkù ní ọjọ́ Olúwa wa Jesu Kristi. 91.9: Ro 8.28; 1Jh 1.3.Ọlọ́run, nípasẹ̀ ẹni ti a pè yín sínú ìdàpọ̀ pẹ̀lú Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi Olúwa wa, jẹ́ Olóòtítọ́.

Ìyapa nínú ìjọ Ọlọ́run

10Mo bẹ̀ yín ẹ̀yin ara, ní orúkọ Olúwa wa Jesu Kristi, pé kí gbogbo yín fohùn ṣọ̀kan kí ó máa ṣe sí ìyapa láàrín yín, àti pé kí a lè ṣe yín pé ní inú àti ìmọ̀ kan náà. 11Ẹ̀yin ará mi, àwọn kan láti ilé Kloe sọ di mí mọ̀ fún mi pé ìjà ń bẹ́ láàrín yín. 121.12: 1Kọ 3.4; Ap 18.24; 1Kọ 3.22; Jh 1.42; 1Kọ 9.5; 15.5.Ohun tí mo ń sọ ní pé: Olúkúlùkù yín ń wí pé, “Èmí tẹ̀lé Paulu”; “Èmi tẹ̀lé Apollo” òmíràn wí pé “Èmi tẹ̀lé Kefa, Peteru”; àti ẹlòmíràn wí pé “Èmi tẹ̀lé Kristi.”

131.13: Mt 28.19; Ap 2.38.Ǹjẹ́ a ha pín Kristi bí? Ṣé a kan Paulu mọ́ àgbélébùú fún un yín bí? Ǹjẹ́ a tẹ̀ yín bọ omi ní orúkọ Paulu bí? 141.14: Ap 18.8; Ro 16.23.Inú mi dún púpọ̀ pé èmi kò tẹ ẹnikẹ́ni nínú yín bọ omi yàtọ̀ sí Krisipu àti Gaiu. 15Nítorí náà kò sí ẹni tí ó lè sọ pé òun ṣe ìtẹ̀bọmi ní orúkọ èmi fúnra ara mi. 161.16: 1Kọ 16.15.(Bẹ́ẹ̀ ni, mo tún tẹ ìdílé Stefana bọ omi; lẹ́yìn èyí, èmí kò rántí pé mo tẹ ẹnikẹ́ni bọ omi mọ́ níbikíbi). 171.17: Jh 4.2; Ap 10.48; 1Kọ 2.1; 4.13.Nítorí Kristi kò rán mi láti máa ṣe ìtẹ̀bọmi, ṣùgbọ́n ó rán mi láti máa wàásù ìhìnrere: kì í ṣe nípa ọgbọ́n ènìyàn, kí a máa ṣe sọ àgbélébùú Kristi dí aláìlágbára.

Kristi ní ọgbọ́n àti agbára Ọlọ́run

18Nítorí pé òmùgọ̀ ni ọ̀rọ̀ àgbélébùú jẹ́ sí àwọn tí ń ṣègbé, ṣùgbọ́n fún àwa tí a ń gbàlà ó jẹ́ agbára Ọlọ́run. 191.19: Isa 29.14.Nítorí a tí kọ ọ́ pé:

“Èmi yóò pa ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n run,

òye àwọn olóye ni Èmi yóò sọ di asán.”

20Àwọn ọlọ́gbọ́n náà ha dá? Àwọn akọ̀wé náà ha dà? Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ayé yìí ha dà? Ọlọ́run kò ha ti sọ ọgbọ́n ayé yìí di aṣiwèrè? 21Nítorí pé, nínú ọgbọ́n Ọlọ́run, ayé kò le mọ̀ òun nípa ọgbọ́n àti ìṣeféfé wọn. Ó sì gba gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́ là nípa ìwàásù tí àwọn aráyé pè ní òmùgọ̀ àti ọ̀rọ̀ ọ yẹ̀yẹ́. 221.22: Mt 12.38.Nítorí pé àwọn Júù ń béèrè ààmì, àwọn Helleni sí ń ṣàfẹ́rí ọgbọ́n, 231.23: 1Kọ 2.2; Ga 3.1; 5.11.ṣùgbọ́n àwa ń wàásù Kristi ti a kàn mọ́ àgbélébùú, òkúta ìkọ̀sẹ̀ àwọn Júù àti òmùgọ̀ fún àwọn kèfèrí. 24Ṣùgbọ́n sí àwọn tí Ọlọ́run tí pè, àti àwọn Júù àti àwọn Giriki, Kristi ni agbára Ọlọ́run, àti ọgbọ́n Ọlọ́run. 25Nítorí pé òmùgọ̀ Ọlọ́run jù ọgbọ́n ènìyàn lọ; àti aláìlera Ọlọ́run ni agbára jù ìlera ènìyàn lọ.

26Ará, ẹ kíyèsi ohun tí ẹ jẹ́ nígbà tí a pè yín. Kì í ṣe ọ̀pọ̀ yín jẹ ọlọ́gbọ́n nípa àgbékalẹ̀ ti ènìyàn, tàbí ọ̀pọ̀ nínú yín jẹ́ ènìyàn pàtàkì, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ọ̀pọ̀ nínú yín jẹ́ ọlọ́lá nípa ibi tí a gbé bí i. 271.27: Jk 2.5.Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tí yàn àwọn òmùgọ̀ ayé láti fi dààmú àwọn ọlọ́gbọ́n; Ọlọ́run sì ti yàn àwọn ohun aláìlera ayé láti fi dààmú àwọn ohun tí ó ni agbára. 281.28: Ro 4.17.Àti àwọn ohun tí ayé tí kò ní ìyìn, àti àwọn ohun tí a kẹ́gàn, ni Ọlọ́run sì ti yàn, àní àwọn ohun tí kò sí, láti sọ àwọn ohun tí ó wà di asán. 291.29: Ef 2.9.Nítorí kí ó má ba à sí ẹnìkan tí yóò ṣògo níwájú rẹ̀. 301.30: 1Kọ 4.15; Ro 8.1; 2Kọ 5.21; 1Kọ 6.11; 1Tẹ 5.23; Ef 1.7,14; Kl 1.14; Ro 3.24.Nítorí rẹ̀ ni ẹ̀yin ṣe wà nínú Kristi Jesu ẹni ti ó jásí ọgbọ́n fún wa láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run—èyí ń ni, òdodo, ìwà mímọ́ àti ìràpadà wa. 311.31: Jr 9.24; 2Kọ 10.17.Nítorí náà, bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹni ti ó bá ń ṣògo kí ó máa ṣògo nínú Olúwa.”

New Russian Translation

1 Коринфянам 1:1-31

Приветствия и благодарность

1От Павла, призванного быть апостолом Христа Иисуса по воле Божьей, и от брата Сосфена1:1 Сосфен – см. Деян. 18:17..

2Церкви Божьей в Коринфе, всем освященным во Христе Иисусе, призванным быть святыми, а также всем, кто в самых различных местах призывает имя нашего Господа Иисуса Христа – Господа их и нашего.

3Благодать и мир вам от Бога, нашего Отца, и от Господа Иисуса Христа.

Благодарность

4Я всегда благодарю моего Бога за вас, за ту благодать, которую вы получили от Него через Иисуса Христа, 5потому что благодаря Ему вы были обогащены во всем: и во всяком слове, и во всяком познании1:5 См. 12:8; 2 Кор. 8:7., 6так как наше свидетельство о Христе прочно утвердилось в вас. 7Поэтому у вас нет недостатка ни в каком духовном даре, пока вы ждете явления нашего Господа Иисуса Христа. 8Он утвердит вас в истине до конца, чтобы в День нашего Господа Иисуса Христа вам оказаться непорочными. 9Верен Бог, призвавший вас быть в общении с Его Сыном Иисусом Христом, нашим Господом!

Разделения в церкви

10Я умоляю вас, братья, во имя нашего Господа Иисуса Христа, быть в согласии друг с другом! Пусть между вами не будет разделений, но будьте едины в мыслях и в целях. 11Братья мои, от домашних Хлои я узнал о ваших спорах. 12Я имею в виду, что одни из вас говорят: «Я – сторонник Павлов», другие: «Я Аполлосов1:12 Аполлос – см. Деян. 18:24-28; Тит 3:13.», третьи: «Я Кифин1:12 Кифа – т. е. Петр. Арамейское имя Кифа и греческое Петрос переводятся как «камень, скала».», четвертые: «А я Христов». 13Неужели Христос разделился? Или, может, это Павел был распят за вас? Или вы были крещены во имя Павла? 14Слава Богу, я никого из вас не крестил, кроме Криспа1:14 Крисп – см. Деян. 18:8. и Гая1:14 Гай – см. Рим. 16:23., 15так что никто из вас не может сказать, что он крещен во имя мое. 16Да, еще я крестил и домашних Стефана1:16 Стефан – см. 16:15, 17., а больше не помню, чтобы я крестил кого-либо. 17Ведь Христос послал меня не крестить, а возвещать Радостную Весть, и возвещать не по человеческой мудрости, иначе крест Христа потерял бы свое значение.

«Мудрость» мира и «безумие» креста

18Те, кто идет к погибели, считают, что весть о кресте – это безумие, но для нас, спасаемых, – это сила Божья. 19Ведь написано:

«Я погублю мудрость мудрецов,

и разум разумных Я отвергну»1:19 Ис. 29:14..

20Где мудрец? Где ученый?1:20 Или: «книжник». Где искусный спорщик этого века? Разве Бог не показал, что вся мудрость этого мира на самом деле глупость? 21И так как по великой мудрости Божьей этот мир, несмотря на всю его мудрость, так и не смог познать Его, то Богу было угодно спасти тех, кто поверит через «безумие» возвещаемой вести. 22Иудеи требуют знамений, греки ищут мудрости, 23а мы возвещаем распятого Христа – для иудеев это камень преткновения, а для язычников – безумие. 24Для тех же, кого Бог призвал, будь то иудей или грек, Христос – это сила и мудрость Божья! 25Ведь то, что кажется глупостью Божьей, – куда мудрее человеческой мудрости, и что кажется слабостью Божьей – куда сильнее человеческой силы.

26Взгляните, братья, на то, какими вы были, когда вас призвал Бог. Много ли среди вас было мудрых, если судить по-человечески, много ли среди вас могущественных, много ли знатных? 27Но Бог избрал глупых мира, чтобы постыдить мудрых, и слабых – чтобы постыдить сильных. 28Он избрал низкое и презренное, то, что в мире не имеет никакой цены, чтобы сделать ничем то, что считается важным, 29так что теперь никто не может хвалиться перед Ним. 30Благодаря Ему вы находитесь во Христе Иисусе, Который стал для нас мудростью Божьей, нашей праведностью, святостью и искуплением. 31Поэтому, как написано: «Тот, кто хвалится, пусть хвалится Господом»1:31 Иер. 9:24..