1 Johanu 1 – YCB & CCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Johanu 1:1-10

Ọ̀rọ̀ Ìyè

11.1-2: Lk 24.39; Jh 1.1; 4.14; 15.27; 20.20,25; Ap 4.20; 1Jh 2.13.Èyí tí ó wà láti àtètèkọ́ṣe, tí àwa ti gbọ́, tí àwa ti fi ojú wa rí, tí àwa sì ti tẹjúmọ́, tí ọwọ́ wa sì ti dì mú; èyí tí a kéde; ní ti ọ̀rọ̀ ìyè; 2iyè náà sì ti farahàn, àwa sì ti rí i, àwa sì ń jẹ́rìí, àwa sì ń sọ ti ìyè àìnípẹ̀kun náà fún yín, tí ó ti ń bẹ lọ́dọ̀ Baba, tí ó sì farahàn fún wa. 3Àwa ń sọ fún yín, èyí tí àwa ti rí, tí àwa sì ti gbọ́, kí ẹ̀yin pẹ̀lú kí ó lè ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú wa. Nítòótọ́ ìdàpọ̀ wa sì ń bẹ pẹ̀lú Baba àti pẹ̀lú ọmọ rẹ̀, Jesu Kristi. 41.4: Jh 15.11; 2Jh 12.Àwa sì kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí sí yín, kí ayọ̀ yín kí ó lè di kíkún.

Rírìn nínú ìmọ́lẹ̀

51.5: 1Jh 3.11.Èyí sì ni iṣẹ́ tí àwa ti gbọ́ lẹ́nu rẹ̀, tí àwa sì ń jẹ́ fún yín pé, ìmọ́lẹ̀ ni Ọlọ́run; ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ kò sì òkùnkùn rárá. 61.6-8: Jh 3.2; 1Jh 2.4,11.Bí àwa bá wí pé àwa ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, tí àwa sì ń rìn nínú òkùnkùn, àwa ń ṣèké, àwa kò sì gbé nínú òtítọ́. 71.7: If 1.5.Ṣùgbọ́n bí àwa bá ń rìn nínú ìmọ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òun ti ń wà nínú ìmọ́lẹ̀, àwa ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú ara wa, àti pé ẹ̀jẹ̀ Jesu Kristi, Ọmọ rẹ̀, wẹ̀ wá nù kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo.

8Bí àwa bá wí pé àwa kò ní ẹ̀ṣẹ̀, àwa ń tan ara wa jẹ, òtítọ́ kan kò sì ṣí nínú wa. 9Bí àwa bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa, olóòtítọ́ àti olódodo ni òun láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, àti láti wẹ̀ wá nù kúrò nínú àìṣòdodo gbogbo. 101.10: 1Jh 5.10.Bí àwa bá wí pé àwa kò dẹ́ṣẹ̀, àwa mú un ní èké, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì ṣí nínú wa.

Chinese Contemporary Bible

约翰一书 1:1-10

生命之道

1论到从太初就已经存在的生命之道,我们曾经耳闻目睹,亲眼看过,亲手摸过。 2这生命曾显现过,我们看见了,现在做见证,向你们传扬这原本与父同在、曾向我们显现的永恒生命。 3我们把所见所闻传给你们,使你们可以与我们相交。诚然,我们是与父和祂儿子耶稣基督相交。 4我们将这些话写给你们,是要让大家都充满喜乐。

要活在光中

5我们从耶稣那里听见、现在传给你们的信息就是:上帝是光,在祂里面毫无黑暗。 6如果我们说与祂相交,却仍过着黑暗的生活,就是撒谎,没有遵行真理。 7如果我们生活在光明之中,像上帝在光明中一样,就能够彼此相交,上帝儿子耶稣的血能洗净我们一切的罪。

8如果我们说自己没有罪,便是自欺,真理就不在我们心中。 9如果我们承认自己的罪,上帝是信实公义的,必赦免我们的罪,洗净我们一切的不义。 10我们如果说自己没有犯过罪,就是把上帝看作说谎的,祂的道也不在我们心中。