1 Ọba 2 – YCB & BPH

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Ọba 2:1-46

Dafidi pàṣẹ fún Solomoni

1Nígbà tí ọjọ́ ikú Dafidi súnmọ́ etílé, ó pàṣẹ fún Solomoni ọmọ rẹ̀.

2Ó sì wí pé, “Èmi ti fẹ́ lọ sí ọ̀nà gbogbo ayé, nítorí náà jẹ́ alágbára kí o sì fi ara rẹ hàn bí ọkùnrin, 3kí o sì wòye ohun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ béèrè, rìn ní ọ̀nà rẹ̀, kí o sì pa àṣẹ àti òfin rẹ̀ mọ́, àti ìdájọ́ rẹ, àti ẹ̀rí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé òfin Mose, nítorí kí ìwọ kí ó le è máa ṣe rere ní ohun gbogbo tí ìwọ ṣe, àti ní ibikíbi tí ìwọ bá lọ, 4Olúwa kí ó lè pa ìlérí rẹ̀ tí ó sọ nípa tèmi mọ́ pé, ‘Bí àwọn ọmọ rẹ bá kíyèsi ọ̀nà wọn, tí wọ́n bá sì fi gbogbo àyà wọn àti ọkàn wọn rìn níwájú mi ní òtítọ́, o kì yóò sì kùnà láti ní ọkùnrin kan lórí ìtẹ́ Israẹli.’

5“Ìwọ pẹ̀lú sì mọ ohun tí Joabu ọmọ Seruiah ṣe sí mi àti ohun tí ó ṣe sí balógun méjì nínú àwọn ológun Israẹli, sí Abneri ọmọ Neri àti sí Amasa ọmọ Jeteri. Ó sì pa wọ́n, ó sì ta ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ ní ìgbà àlàáfíà bí í ti ojú ogun ó sì fi ẹ̀jẹ̀ náà sí ara àmùrè rẹ̀ tí ń bẹ ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, àti sí ara sálúbàtà rẹ̀ tí ń bẹ ní ẹsẹ̀ rẹ̀. 6Ṣe sí í gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n rẹ̀, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí ewú orí rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí isà òkú ní àlàáfíà.

7“Ṣùgbọ́n fi inú rere hàn sí àwọn ọmọ Barsillai, ti Gileadi, jẹ́ kí wọn wà lára àwọn tí ó ń jẹun lórí tábìlì rẹ̀. Wọ́n dúró tì mí nígbà tí mo sá kúrò níwájú Absalomu arákùnrin rẹ.

8“Àti kí o rántí, Ṣimei ọmọ Gera ẹ̀yà Benjamini tí Bahurimu wà pẹ̀lú rẹ̀, tí ó bú mi ní èébú tí ó korò ní ọjọ́ tí mo lọ sí Mahanaimu. Nígbà tí ó sọ̀kalẹ̀ wá pàdé mi ní Jordani, mo fi Olúwa búra fún un pé, ‘Èmi kì yóò fi idà pa ọ́.’ 9Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, má ṣe kíyèsi í gẹ́gẹ́ bí aláìlẹ́ṣẹ̀, ọkùnrin ọlọ́gbọ́n ni ìwọ ṣe; ìwọ yóò mọ ohun tí ìwọ yóò ṣe sí i. Mú ewú orí rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sínú isà òkú pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀.”

10Nígbà náà ni Dafidi sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dafidi. 11Dafidi ti jẹ ọba lórí Israẹli ní ogójì ọdún, ọdún méje ni Hebroni àti ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n ní Jerusalẹmu. 122.12: 1Ki 29.23.Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi baba rẹ̀, ìjọba rẹ̀ sì fi ìdí múlẹ̀ gidigidi.

Ìtẹ́ ọba Solomoni fìdímúlẹ̀

13Wàyí, Adonijah ọmọ Haggiti tọ Batṣeba, ìyá Solomoni wá. Batṣeba sì bi í pé, “Àlàáfíà ni o bá wa bí?”

Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àlàáfíà ni.” 14Nígbà náà ni ó sì fi kún un pé, “Mo ní ohun kan láti sọ fún ọ.”

Batṣeba sì wí pé, “Máa wí.”

15Ó wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí o ti mọ̀, ti tèmi ni ìjọba náà. Gbogbo Israẹli ti wò mí bí ọba wọn. Ṣùgbọ́n nǹkan yípadà, ìjọba náà sì ti lọ sí ọ̀dọ̀ arákùnrin mi, nítorí ó ti wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti ọwọ́ Olúwa wá. 16Nísinsin yìí mo ní ìbéèrè kan láti bi ọ́, má ṣe kọ̀ fún mi.”

Ó wí pé, “O lè wí.”

17Bẹ́ẹ̀ ni ó sì tẹ̀síwájú pé, “Mo bẹ̀ ọ́, jọ̀wọ́ sọ fún Solomoni ọba (òun kì yóò kọ̀ fún ọ́) kí ó fún mi ní Abiṣagi ará Ṣunemu ní aya.”

18Batṣeba sì dáhùn pé, “Ó dára èmi yóò bá ọba sọ̀rọ̀ nítorí rẹ̀.”

19Nígbà tí Batṣeba sì tọ Solomoni ọba lọ láti bá a sọ̀rọ̀ nítorí Adonijah, ọba sì dìde láti pàdé rẹ̀, ó sì tẹríba fún un, ó sì jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀. Ó sì tẹ́ ìtẹ́ kan fún ìyá ọba, ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀.

20Ó sì wí pé, “Mo ní ìbéèrè kékeré kan láti béèrè lọ́wọ́ rẹ, má ṣe kọ̀ fún mi.”

Ọba sì dáhùn wí pé, “Béèrè, ìyá mi; èmi kì yóò kọ̀ ọ́.”

21Nígbà náà ni ó wí pé, “Jẹ́ kí a fi Abiṣagi ará Ṣunemu fún Adonijah arákùnrin rẹ ní aya.”

22Solomoni ọba sì dá ìyá rẹ̀ lóhùn pé, “Èéṣe tí ìwọ fi béèrè Abiṣagi ará Ṣunemu fún Adonijah! Ìwọ ìbá sì béèrè ìjọba fún un pẹ̀lú nítorí ẹ̀gbọ́n mi ní í ṣe, fún òun pàápàá àti fún Abiatari àlùfáà àti fun Joabu ọmọ Seruiah!”

23Nígbà náà ni Solomoni ọba fi Olúwa búra pé, “Kí Ọlọ́run ki ó jẹ mí ní yà, àti jù bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, bí Adonijah kò bá ní fi ẹ̀mí rẹ̀ san ìbéèrè yìí! 24Àti nísinsin yìí, bí ó ti dájú pé Olúwa wà láààyè, ẹni tí ó ti mú mi jókòó lórí ìtẹ́ baba mi Dafidi, àti tí ó sì ti kọ́ ilé fún mi bí ó ti ṣèlérí, lónìí ni a ó pa Adonijah!” 25Solomoni ọba sì pàṣẹ fún Benaiah ọmọ Jehoiada, ó sì kọlu Adonijah, ó sì kú.

26Ọba sì wí fún Abiatari àlùfáà pé, “Padà lọ sí pápá rẹ ni Anatoti, ó yẹ fún ọ láti kú, ṣùgbọ́n èmi kì yóò pa ọ́ nísinsin yìí, nítorí o ti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa Olódùmarè níwájú Dafidi baba mi, o sì ti ní ìpín nínú gbogbo ìyà tí baba mi jẹ.” 27Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni yọ Abiatari kúrò nínú iṣẹ́ àlùfáà Olúwa, kí ó lè mú ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti sọ nípa ilé Eli ní Ṣilo ṣẹ.

28Nígbà tí ìròyìn sì dé ọ̀dọ̀ Joabu, ẹni tí ó ti dìtẹ̀ pẹ̀lú Adonijah bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò wà pẹ̀lú Absalomu, ó sì sálọ sínú àgọ́ Olúwa, ó sì di ìwo pẹpẹ mú. 29A sì sọ fún Solomoni ọba pé Joabu ti sálọ sínú àgọ́ Olúwa àti pé ó wà ní ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. Nígbà náà ni Solomoni pàṣẹ fún Benaiah ọmọ Jehoiada pé, “Lọ, kí o sì kọlù ú.”

30Benaiah sì wọ inú àgọ́ Olúwa, ó sì wí fún Joabu pé, “Ọba sọ wí pé, ‘Jáde wá.’ ”

Ṣùgbọ́n ó dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, èmi yóò kú níhìn-ín.”

Benaiah sì mú èsì fún ọba, “Báyìí ni Joabu ṣe dá mi lóhùn.”

31Ọba sì pàṣẹ fún Benaiah pé, “Ṣe bí ó ti wí. Kọlù ú, kí o sì sin ín, kí o sì mú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi àti kúrò lọ́dọ̀ ilé baba mi, tí Joabu ti ta sílẹ̀. 32Olúwa yóò sì san ẹ̀jẹ̀ tí ó ti ta sílẹ̀ padà fún un, nítorí tí ó kọlu ọkùnrin méjì, ó sì fi idà rẹ̀ pa wọ́n, Dafidi baba mi kò sì mọ̀. Àwọn méjèèjì ni Abneri ọmọ Neri olórí ogun Israẹli, àti Amasa ọmọ Jeteri olórí ogun Juda, wọ́n jẹ́ olódodo, wọ́n sì sàn ju òun fúnra rẹ̀ lọ. 33Kí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wọn wá sórí Joabu àti sórí irú-ọmọ rẹ̀ títí láé. Ṣùgbọ́n sórí Dafidi àti irú-ọmọ rẹ̀, sí ilé rẹ̀ àti sí ìtẹ́ rẹ̀, ni kí àlàáfíà Olúwa wà títí láé.”

34Bẹ́ẹ̀ ni Benaiah ọmọ Jehoiada sì gòkè lọ, ó sì kọlu Joabu, ó sì pa á, a sì sin ín ní ilẹ̀ ibojì ara rẹ̀ ní aginjù. 35Ọba sì fi Benaiah ọmọ Jehoiada jẹ olórí ogun ní ipò Joabu àti Sadoku àlùfáà ní ipò Abiatari.

36Nígbà náà ni ọba ránṣẹ́ sí Ṣimei, ó sì wí fún un pé, “Kọ́ ilé fún ara rẹ ní Jerusalẹmu, kí o sì máa gbé ibẹ̀, ṣùgbọ́n kí o má sì ṣe lọ sí ibòmíràn. 37Ọjọ́ tí ìwọ bá jáde, tí o sì kọjá àfonífojì Kidironi, kí ìwọ kí ó mọ̀ dájúdájú pé ìwọ yóò kú; ẹ̀jẹ̀ rẹ yóò sì wà lórí ara rẹ.”

38Ṣimei sì dá ọba lóhùn pé, “Ohun tí ìwọ sọ dára. Ìránṣẹ́ rẹ yóò ṣe bí olúwa mi ọba ti wí.” Ṣimei sì gbé ní Jerusalẹmu fún ìgbà pípẹ́.

39Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ Ṣimei méjì sì sálọ sọ́dọ̀ Akiṣi ọmọ Maaka, ọba Gati, a sì sọ fún Ṣimei pé, “Àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ méjì wà ní Gati.” 40Fún ìdí èyí, ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó sì lọ sọ́dọ̀ Akiṣi ní Gati láti wá àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni Ṣimei sì lọ, ó sì mú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ padà bọ̀ láti Gati.

41Nígbà tí a sì sọ fún Solomoni pé Ṣimei ti lọ láti Jerusalẹmu sí Gati, ó sì ti padà. 42Ọba pe Ṣimei lẹ́jọ́, ó wí fún un pé, “Ǹjẹ́ èmi kò ti mú ọ búra ní ti Olúwa, èmi sì ti kìlọ̀ fún ọ pé, ‘Ní ọjọ́ tí ìwọ bá kúrò láti lọ sí ibikíbi, kí o mọ̀ dájú pé ìwọ yóò kú.’ Nígbà náà ni ìwọ sì sọ fún mi pé, ‘Ohun tí ìwọ sọ dára. Èmi yóò ṣe ìgbọ́ràn.’ 43Èéṣe, nígbà náà tí ìwọ kò pa ìbúra Olúwa mọ́, àti kí o sì ṣe ìgbọ́ràn sí àṣẹ tí mo pa fún ọ?”

44Ọba sì tún wí fún Ṣimei pé, “Ìwọ mọ̀ ní ọkàn rẹ gbogbo búburú tí ìwọ ti ṣe sí Dafidi baba mi. Báyìí, Olúwa yóò san gbogbo ìṣe búburú rẹ padà fún ọ. 45Ṣùgbọ́n a ó sì bùkún fún Solomoni ọba, ìtẹ́ Dafidi yóò sì wà láìfòyà níwájú Olúwa títí láéláé.”

46Nígbà náà ni ọba pàṣẹ fún Benaiah ọmọ Jehoiada, ó sì jáde lọ, ó sì kọlu Ṣimei, ó sì pa á.

Ìjọba náà sì wá fi ìdí múlẹ̀ ní ọwọ́ Solomoni.

Bibelen på hverdagsdansk

1. Kongebog 2:1-46

Davids sidste formaning til Salomon

1Kort efter, da David lå for døden, kaldte han Salomon ind for at give ham sine sidste ord:

2„Alle skal jo dø, og nu er det snart min tur! Men Salomon, jeg har tillid til, at du vil blive en stærk og værdig efterfølger. 3Gør altid, som Gud siger! Adlyd omhyggeligt de love og forordninger, som han gav os gennem Moses, så vil dit liv lykkes. 4Hvis du altid er lydig, vil Herren opfylde det løfte, han gav mig, for han har lovet, at hvis mine børn og deres efterkommere tager sig i agt og viser helhjertet trofasthed imod ham, vil der i al fremtid være en af mine efterkommere på tronen i Israel.

5Hør nu efter! Du ved, at Joab myrdede mine to hærførere Abner og Amasa, da han i fredstid stak dem ned uden varsel som hævn for, hvad de havde gjort i en krigssituation. 6Du er en klog mand, Salomon, og du ved, hvad du bør gøre: Lad ikke Joab dø en fredelig død i sin alderdom. 7Men Barzillajs sønner fra Gilead skal du vise godhed, og du skal sørge for deres fornødenheder, for de tog sig af mig, dengang jeg flygtede fra din bror Absalom. 8Og husker du Shimi, Geras søn af Benjamins stamme fra Bahurim? Han forbandede mig groft, da jeg var på vej til Mahanajim. Men da han senere kom ned til Jordanfloden for at møde mig, lovede jeg, at jeg ikke ville slå ham ihjel. 9Men det betyder ikke, at han er uskyldig. Salomon, du er en klog mand; du finder nok på råd, så Shimi får en blodig død!”

10Derefter døde David, og han blev begravet i Davidsbyen.2,10 Davidsbyen blev efterhånden betegnelsen for et mindre område i Jerusalem syd for tempelpladsen, der hvor Davids palads var bygget. 11Han havde regeret i Israel i 40 år, de syv med hovedsæde i Hebron og de 33 med hovedsæde i Jerusalem. 12Salomon blev den nye konge efter sin far David, og hans kongedømme var stærkt fra starten.

Salomon befæster sit kongedømme

13En dag opsøgte Adonija Salomons mor, Batsheba.

„Kommer du i et fredeligt ærinde?” spurgte hun.

„Ja, det gør jeg,” svarede Adonija. 14„Faktisk kommer jeg for at bede dig gøre mig en tjeneste.”

„Hvilken tjeneste?” spurgte hun.

15„Jo, ser du,” begyndte Adonija. „Det var jo egentlig mig, der havde krav på tronen, for jeg var den ældste af Davids sønner, der er i live, og hele Israel forventede, at jeg blev konge. Men så overtog min bror som bekendt det hele—og det må vel være Herrens vilje. 16Nu beder jeg dig blot love mig, at du vil gøre mig en lille tjeneste.”

„Hvad drejer det sig om?” spurgte Batsheba.

17„At du taler til kong Salomon på mine vegne,” svarede Adonija. „Jeg ved jo, at han vil gøre, hvad du beder ham om. Bed ham om at give mig Abishag fra Shunem til kone.”

18„Jeg skal gøre, hvad jeg kan,” lovede hun.

19Så gik Batsheba til kong Salomons tronsal. Da hun kom ind, gik han hende i møde og bøjede sig dybt for hende, hvorefter han gav ordre til, at der skulle bæres en trone frem til hende. Den blev anbragt på hans højre side, og hun tog plads.

20„Jeg vil bede dig gøre mig en lille tjeneste,” begyndte hun. „Jeg håber ikke, du skuffer mig.”

„Hvad tænker du på, mor?” spurgte han. „Du ved, jeg ikke vil nægte dig noget!”

21„Så lad din bror Adonija få lov at gifte sig med Abishag,” svarede hun.

22„Er du vanvittig?” udbrød Salomon. „Hvorfor tror du, han beder om Abishag? Han kunne lige så godt bede om kongeværdigheden med det samme! Han er jo min ældste bror, og han har tilmed Ebjatar og Joab på sin side.” 23-24Da svor kong Salomon: „Måtte Herren straffe mig om ikke den listige anmodning kommer til at koste Adonija livet! Jeg sværger ved den levende Gud, han, der indsatte mig som konge efter min far og som lovede mig, at min slægt skulle være konger efter mig, at Adonija skal dø allerede i dag!”

25Salomon befalede Benaja, at han straks skulle hugge Adonija ned med sit sværd.

26Kongen sagde derefter til Ebjatar: „Tag hjem til din gård i Anatot. Jeg burde egentlig også lade dig henrette, men lad os nu se tiden an, for trods alt bar du Herren, den Almægtiges, Ark, dengang min far var konge, og du udholdt din del af de strabadser, min far måtte igennem.”

27Dermed blev Ebjatar afsat fra sin stilling som præst for Herren, og samtidig opfyldtes det ord, Herren havde talt i Shilo om Elis efterkommere.

28Da Joab hørte nyheden om Adonijas død, søgte han straks tilflugt i helligdommen og greb fat om alterets horn. Han var i fare, fordi han havde støttet Adonija i hans oprør, selv om han ikke havde støttet Absalom. 29Da kong Salomon fik at vide, hvor Joab gemte sig, sendte han Benaja af sted for at henrette ham.

30Benaja gik hen til helligdommen og sagde til Joab: „I kongens navn: Kom ud!”

„Nej,” svarede Joab, „jeg bliver her, til jeg dør!”

Så vendte Benaja tilbage til kongen med den besked.

31„Godt,” svarede kongen, „så lad ham dø der! Henret ham ved alteret og begrav ham. Så hviler skylden for de mord, han har begået på uskyldige mennesker, ikke længere på mig og min fars slægt. 32Herren vil holde ham personligt ansvarlig for at have myrdet to mænd, der var bedre end ham, for det var ikke med min fars samtykke, at de blev myrdet, hverken Abner, der var øverstkommanderende for Israels hær, eller Amasa, der var øverstkommanderende for Judas hær. 33Må skylden alene tilregnes Joab og hans efterkommere, og må Herren frifinde David og hans efterkommere i den sag.”

34Så gik Benaja tilbage og dræbte Joab, og han blev begravet uden for sit hus i ørkenen. 35Kongen udpegede derefter Benaja til sin nye hærfører og Zadok til præst ved helligdommen i Ebjatars sted.

36-37Kongen sendte nu bud efter Shimi og sagde: „Byg dig et hus her i Jerusalem. Du er under husarrest, og du må ikke forlade byen, uanset hvad der sker. I samme øjeblik du overskrider Kedrondalen, er du dødsens, og du er selv ude om det.”

38„Godt,” svarede Shimi. „Du er min herre og konge, og jeg vil gøre, som du siger.” Han blev derefter i Jerusalem i lang tid.

39Men tre år senere flygtede to af Shimis slaver til kong Akish i Gat. Da Shimi fik at vide, at hans slaver var i Gat, 40sadlede han sit æsel og opsøgte kong Akish. Efter at have fundet sine slaver vendte han tilbage til Jerusalem.

41Salomon fik imidlertid at vide, at Shimi havde forladt Jerusalem og var taget til Gat og hjem igen. 42Da sendte han bud efter ham og sagde: „Befalede jeg dig ikke i Guds navn at blive i Jerusalem, hvis du havde dit liv kært? Og svor du ikke på, at du ville blive i byen? 43Hvorfor har du da trodset min befaling og brudt din ed? 44Og hvad med alle de onde ting, du gjorde mod min far, David? Nu vil Herren straffe dig for din ondskab, 45men hans velsignelse vil fortsat hvile over Davids slægt, så de kan bevare kongemagten for evigt.” 46På kongens befaling henrettede Benaja så Shimi.

Med Adonijas og Joabs død blev Salomons kongedømme yderligere befæstet.