1 Ọba 1 – YCB & BPH

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Ọba 1:1-53

Adonijah fi ara rẹ̀ jẹ Ọba

1Nígbà tí Dafidi ọba di arúgbó, ọjọ́ rẹ̀ sì pọ̀, ara rẹ̀ kò le è móoru bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n da ọ̀pọ̀lọpọ̀ aṣọ bò ó. 2Nígbà náà ni àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wí fún un pé, “Ẹ jẹ́ kí a wá ọ̀dọ́mọbìnrin wúńdíá kan kí ó dúró ti ọba, kì ó sì máa tọ́jú rẹ̀. Kí ó dùbúlẹ̀ ní àyà rẹ̀ kí ara ọba olúwa wa lè móoru.”

3Nígbà náà ni wọ́n lọ jákèjádò ilẹ̀ Israẹli láti wá ọ̀dọ́mọbìnrin arẹwà, wọ́n sì rí Abiṣagi, ará Ṣunemu, wọ́n sì mú un wá sí ọ̀dọ̀ ọba. 4Ọmọbìnrin náà rẹwà gidigidi; ó sì ń ṣe ìtọ́jú ọba, ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún un, ṣùgbọ́n ọba kò sì bá a lòpọ̀.

5Adonijah ẹni tí ìyá rẹ̀ ń ṣe Haggiti sì gbé ara rẹ̀ ga, ó sì wí pé, “Èmi yóò jẹ ọba.” Ó sì ṣètò kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin, pẹ̀lú àádọ́ta ọkùnrin láti máa sáré níwájú rẹ̀. 6(Baba rẹ̀ kò bà á nínú jẹ́ rí nípa bíbéèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Èéṣe tí ìwọ fi hùwà báyìí?” Ó sì jẹ́ arẹwà ọkùnrin, òun ni a bí lé Absalomu.)

7Adonijah sì gbèrò pẹ̀lú Joabu, ọmọ Seruiah àti Abiatari àlùfáà, wọ́n sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún un. 8Ṣùgbọ́n Sadoku àlùfáà, Benaiah ọmọ Jehoiada, Natani wòlíì, Ṣimei àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ Rei àti olórí ogun Dafidi ni kò darapọ̀ mọ́ Adonijah.

9Nígbà náà ni Adonijah fi àgùntàn àti màlúù àti ẹran ọ̀sìn tí ó sanra rú ẹbọ níbi Òkúta Soheleti tí ń bẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ En-Rogeli. Ó sì pe gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn ọmọ ọba, àti gbogbo àwọn ọkùnrin Juda tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ ọba. 10Ṣùgbọ́n kò pe Natani wòlíì tàbí Benaiah tàbí àwọn olórí tàbí Solomoni arákùnrin rẹ̀.

11Nígbà náà ni Natani béèrè lọ́wọ́ Batṣeba, ìyá Solomoni pé, “Ǹjẹ́ ìwọ kò gbọ́ pé Adonijah, ọmọ Haggiti ti jẹ ọba láìjẹ́ pé Dafidi olúwa wa mọ̀ sí i? 12Ǹjẹ́ nísinsin yìí, jẹ́ kí èmi gbà ọ́ ní ìmọ̀ràn bí ìwọ ṣe lè gba ẹ̀mí rẹ là àti ẹ̀mí ọmọ rẹ Solomoni. 13Lọ sọ́dọ̀ Dafidi ọba, kí o sì wí fún un pé, ‘Olúwa mi ọba, ǹjẹ́ ìwọ kò búra fún ìránṣẹ́ rẹ pé, “Dájúdájú Solomoni ọmọ rẹ ni yóò jọba lẹ́yìn mi, yóò sì jókòó lórí ìtẹ́ mi?” Èéṣe nígbà náà tí Adonijah fi jẹ ọba?’ 14Níwọ́n ìgbà tí ìwọ sì wà níbẹ̀, tí o sì ń bá ọba sọ̀rọ̀ èmi yóò wá, láti wádìí ohun tí o ti sọ.”

15Bẹ́ẹ̀ ni Batṣeba lọ rí ọba ní inú yàrá rẹ̀, ọba sì gbó gidigidi níbi tí Abiṣagi ará Ṣunemu ti ń ṣe ìránṣẹ́ fún ọba. 16Batṣeba sì tẹríba, ó sì kúnlẹ̀ níwájú ọba.

Ọba sì béèrè pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́?”

17Ó sì wí fún ọba pé, “Olúwa mi; ìwọ fúnra rẹ̀ fi Olúwa Ọlọ́run rẹ búra fún ìránṣẹ́ rẹ pé, ‘Solomoni ọmọ rẹ yóò jẹ ọba lẹ́yìn mi, yóò sì jókòó lórí ìtẹ́ mi.’ 18Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, Adonijah ti di ọba, ìwọ, ọba olúwa mi kò sì mọ̀ nípa rẹ̀. 19Òun sì ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ màlúù, àti ẹran tí ó ní ọ̀rá, àti àgùntàn rú ẹbọ, ó sì pe gbogbo àwọn ọmọ ọba, àti Abiatari àlùfáà àti Joabu balógun, ṣùgbọ́n kò sì pe Solomoni ìránṣẹ́ rẹ. 20Olúwa mi ọba, ojú gbogbo Israẹli ń bẹ lára rẹ, láti mọ ẹni tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ olúwa mi ọba lẹ́yìn rẹ. 21Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí olúwa mi ọba bá sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, wọn yóò sì ka èmi àti Solomoni sí ẹlẹ́ṣẹ̀.”

22Bí ó sì ti ń bá ọba sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Natani wòlíì sì wọlé. 23Wọ́n sì sọ fún ọba pé, “Natani wòlíì wà níbí.” Ó sì lọ síwájú ọba, ó wólẹ̀, ó sì dojúbolẹ̀.

24Natani sì wí pé, “Ǹjẹ́ ìwọ, olúwa mi ọba, ti sọ pé Adonijah ni yóò jẹ ọba lẹ́yìn rẹ àti pé òun ni yóò jókòó lórí ìtẹ́ rẹ? 25Ó sì ti sọ̀kalẹ̀ lọ ní òní, ó sì ti rú ẹbọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ màlúù, àti ẹran ọlọ́ràá àti àgùntàn. Ó sì ti pe gbogbo àwọn ọmọ ọba, balógun àti Abiatari àlùfáà. Nísìnsinyìí, wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì wí pé, ‘Kí Adonijah ọba kí ó pẹ́!’ 26Ṣùgbọ́n èmi ìránṣẹ́ rẹ, àti Sadoku àlùfáà, àti Benaiah ọmọ Jehoiada, àti Solomoni ìránṣẹ́ rẹ ni kò pè. 27Ṣé nǹkan yìí ni olúwa mi ọba ti ṣe láìjẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ mọ ẹni tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ olúwa mi ọba lẹ́yìn rẹ?”

Dafidi fi Solomoni jẹ ọba

28Nígbà náà ni Dafidi ọba wí pé, “Pe Batṣeba wọlé wá.” Ó sì wá síwájú ọba, ó sì dúró níwájú rẹ̀.

29Ọba sì búra pé, “Dájúdájú bí Olúwa ti wà ẹni tí ó ti gbà mí kúrò nínú gbogbo wàhálà 30Lónìí dandan ni èmi yóò gbé ohun tí mo ti fi Olúwa Ọlọ́run Israẹli búra fún yọ pé, Solomoni ọmọ rẹ ni yóò jẹ ọba lẹ́yìn mi, àti pé yóò jókòó lórí ìtẹ́ mi ní ipò mi.”

31Nígbà náà ni Batṣeba tẹríba, ó sì kúnlẹ̀ níwájú ọba pé, “Kí olúwa mi Dafidi ọba kí ó pẹ́!”

32Dafidi ọba sì wí pé, “Ẹ pe Sadoku àlùfáà wọlé fún mi àti Natani wòlíì àti Benaiah ọmọ Jehoiada.” Nígbà tí wọ́n wá síwájú ọba, 33ọba sì wí fún wọn pé, “Ẹ mú àwọn ìránṣẹ́ olúwa yín pẹ̀lú yín kí ẹ sì mú kí Solomoni ọmọ mi kí ó gun ìbáaka mi, kí ẹ sì mú un sọ̀kalẹ̀ wá sí Gihoni. 34Níbẹ̀ ni Sadoku àlùfáà àti Natani wòlíì yóò ti fi òróró yàn án ní ọba lórí Israẹli. Ẹ fọn fèrè, kí ẹ sì ké pé, ‘Kí Solomoni ọba kí ó pẹ́!’ 35Nígbà náà ni kí ẹ sì gòkè pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì wá, kí ó sì jókòó sórí ìtẹ́ mi, kí ó sì jẹ ọba ní ipò mi. Èmi ti yàn án ní ọba lórí gbogbo Israẹli àti Juda.”

36Benaiah ọmọ Jehoiada sì dá ọba lóhùn pé, “Àmín! Kí Olúwa Ọlọ́run olúwa mi ọba, kéde rẹ̀ bẹ́ẹ̀. 37Olúwa ti wà pẹ̀lú olúwa mi ọba, bẹ́ẹ̀ ni kí ó wà pẹ̀lú Solomoni kí ó lè mú kí ìjọba rẹ̀ pẹ́ ju ìtẹ́ olúwa mi Dafidi ọba lọ!”

38Nígbà náà ni Sadoku àlùfáà, Natani wòlíì, Benaiah ọmọ Jehoiada, àwọn ará Kereti àti Peleti sì sọ̀kalẹ̀ wá wọ́n sì gbé Solomoni gun ìbáaka Dafidi ọba wá sí Gihoni. 39Sadoku àlùfáà sì mú ìwo òróró láti inú àgọ́, ó sì dà á sí Solomoni lórí. Nígbà náà ni wọ́n sì fọn fèrè, gbogbo àwọn ènìyàn sì ké pé, “Kí Solomoni ọba kí ó pẹ́!” 40Gbogbo ènìyàn sì gòkè tọ̀ ọ́ lẹ́yìn wọ́n ń fọn ìpè, wọ́n sì ń yọ ayọ̀ ńlá, tó bẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ mì fún ìró wọn.

41Adonijah àti gbogbo àwọn àlejò tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ gbọ́ ọ́ bí wọ́n ti ń jẹun tán, wọ́n ń gbọ́ ìpè, Joabu sì wí pé, “Kí ní ìtumọ̀ gbogbo ariwo nínú ìlú yìí?”

42Bí ó sì ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Jonatani ọmọ Abiatari àlùfáà sì dé, Adonijah sì wí pé, “Wọlé wá, ọkùnrin yíyẹ ìwọ gbọdọ̀ mú ìròyìn rere wá.”

43Jonatani sì dáhùn, ó sì wí fún Adonijah pé, “Lóòótọ́ ni olúwa wa Dafidi ọba, fi Solomoni jẹ ọba. 44Ọba sì ti rán Sadoku àlùfáà, Natani wòlíì, Benaiah ọmọ Jehoiada àti àwọn ará Kereti àti Peleti pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì ti gbé e gun ìbáaka ọba, 45Sadoku àlùfáà àti Natani wòlíì ti fi òróró yàn án ní ọba ní Gihoni. Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti gòkè wá pẹ̀lú ayọ̀, ìlú sì ń hó pẹ̀lú rẹ̀. Èyí ni ariwo tí ẹ̀yin ń gbọ́. 46Solomoni sì ti jókòó lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀. 47Àwọn ìránṣẹ́ ọba sì ti tún wá láti bá olúwa wa Dafidi ọba yọ̀, wí pé, ‘Kí Ọlọ́run rẹ̀ mú orúkọ Solomoni lókìkí ju tirẹ̀ lọ àti kí ìtẹ́ rẹ̀ kí ó pọ̀ ju tirẹ̀ lọ!’ Ọba sì tẹ ara rẹ̀ ba lórí ibùsùn rẹ̀, 48ọba sì wí pé, ‘Ògo ni fún Olúwa Ọlọ́run Israẹli, ẹni tí ó ti jẹ́ kí ojú mi rí ẹnìkan tí ó jókòó lórí ìtẹ́ mi lónìí.’ ”

49Nígbà náà ni gbogbo àwọn àlejò tí ó wà lọ́dọ̀ Adonijah dìde ní ìdágìrì, wọ́n sì túká. 50Ṣùgbọ́n Adonijah sì bẹ̀rù Solomoni, ó lọ, ó sì di ìwo pẹpẹ mú. 51Nígbà náà ni a sì sọ fún Solomoni pé, “Adonijah bẹ̀rù Solomoni ọba, ó sì di ìwo pẹpẹ mú, Ó wí pé, ‘Jẹ́ kí ọba Solomoni búra fún mi lónìí pé, òun kì yóò fi idà pa ìránṣẹ́ rẹ̀.’ ”

52Solomoni sì dáhùn pé, “Bí ó bá fi ara rẹ̀ hàn láti jẹ́ ẹni ọ̀wọ̀, irun orí rẹ̀ kan kì yóò sì bọ́ sílẹ̀; ṣùgbọ́n bí a bá rí búburú kan ní ọwọ́ rẹ̀ òun yóò kú.” 53Nígbà náà ni Solomoni ọba rán àwọn ènìyàn, wọ́n sì mú un sọ̀kalẹ̀ láti ibi pẹpẹ wá. Adonijah sì wá, ó sì foríbalẹ̀ fún Solomoni ọba, Solomoni sì wí pé, “Lọ ilé rẹ.”

Bibelen på hverdagsdansk

1. Kongebog 1:1-53

David som en gammel mand

1På sine gamle dage døjede kong David med at holde varmen. Uanset hvor mange tæpper man lagde over ham, frøs han altid.

2Hans rådgivere sagde da til ham: „Lad os lede efter en ung pige, som kan ligge i din favn og hjælpe dig til at holde varmen.” Det syntes David var en god idé.

3-4Så gennemsøgte de landet på kryds og tværs i håb om at finde den rigtige pige, og de fandt Abishag, en smuk ung pige fra Shunem. Hende førte de til kongen, og hun tog sig kærligt af ham, men der var ikke tale om noget seksuelt forhold.

Adonija gør krav på tronen

5Adonija, som var søn af kong David og Haggit, havde store tanker om sig selv, og han ville gerne være konge efter sin far. Derfor anskaffede han sig vogn, ryttere og en livgarde på 50 mand, der skulle løbe foran ham gennem byen. 6David hverken irettesatte ham eller satte spørgsmålstegn ved, hvad han gjorde. Adonija var en flot ung mand, og nummer to i tronfølgerækken efter Absalom. 7Han allierede sig med hærføreren Joab og præsten Ebjatar, som begge lovede at hjælpe ham til magten. 8Men præsten Zadok, profeten Natan, samt Benaja, Shimi, Rei og Davids livgarde svigtede ikke kongen. De nægtede at give Adonija tilsagn om støtte.

9En dag tog Adonija af sted til den såkaldte Slangesten ved Rogelkilden lidt uden for Jerusalem, hvor han ofrede småkvæg, hornkvæg og fedekalve. Til denne selvbestaltede kroningsfest inviterede han alle sine halvbrødre undtagen Salomon, og alle de kongelige embedsmænd i Juda 10med undtagelse af profeten Natan, Benaja og kongens livgarde.

11Da gik profeten Natan til Batsheba, Salomons mor, og sagde: „Har du hørt, at Adonija har udråbt sig selv til konge, uden at David aner noget om det? 12Hvis du har dit eget og din søn Salomons liv kært, så gør som jeg siger: 13Gå straks til kong David og sig til ham: ‚Herre, lovede du mig ikke, at Salomon skulle overtage tronen efter dig? Hvorfor er Adonija så blevet udråbt til konge?’ ” 14Og Natan tilføjede: „Mens du er hos kongen, kommer jeg og bekræfter hvert eneste ord, du siger.”

15Derpå gik Batsheba ind i kongens soveværelse. David var jo meget gammel, og Abishag var hos ham. 16Batsheba bøjede sig dybt for kongen, og han spurgte: „Hvad vil du?”

17„Min herre,” svarede hun. „Du aflagde det løfte over for Herren, din Gud, at min søn Salomon skulle afløse dig på tronen. 18Men i stedet er Adonija blevet udråbt til konge uden dit vidende. 19Han har kronet sig selv og ofret en masse hornkvæg, småkvæg og fedekalve. Både Ebjatar og Joab og alle dine sønner på nær Salomon er med til festen. 20Og nu, min herre konge, venter hele Israel på at få at vide, om du virkelig har udpeget Adonija som din efterfølger. 21Hvis du ikke griber ind nu, vil Salomon og jeg blive henrettet, så snart du er død.”

22-23Mens Batsheba talte med David, ankom Natan til paladset, og tjenerne meddelte kongen: „Profeten Natan er her for at tale med dig,” Batsheba blev bedt om at gå ud, så kongen kunne høre, hvad Natan havde at sige.

Da Natan kom ind i soveværelset, bøjede han sig dybt for kongen 24og spurgte: „Herre, er det rigtigt, at du har udpeget Adonija til at blive din efterfølger? Er det ham, der skal sidde på tronen efter dig? 25I dag fejrede han kroningsfest ved at ofre en masse hornkvæg, småkvæg og fedekalve, og han inviterede dine sønner til festen sammen med Joab og Ebjatar. I dette øjeblik fester og drikker de og råber: ‚Længe leve kong Adonija!’ 26Men Zadok, Benaja, Salomon og jeg blev ikke inviteret. 27Sker det efter din befaling? Har du virkelig udpeget Adonija til tronfølger uden at sige et ord om det til dine betroede embedsmænd?”

David gør Salomon til konge

28„Kald på Batsheba!” befalede kong David sine tjenere, da Natan var gået. Så kom hun tilbage og stod foran kongen. 29Da sagde David: „Jeg lover ved den levende Gud, som trofast har hjulpet mig gennem alle farer, 30at jeg i dag vil indfri det løfte, jeg gav dig ind for Guds ansigt: Din søn Salomon skal være min efterfølger på tronen!”

31Da bøjede Batsheba sig dybt for ham og udbrød: „Gid min herre og konge må leve for evigt!”

32„Kald Zadok ind,” beordrede kongen, „også Natan og Benaja!”

Da de var kommet, 33sagde han til dem: „Tag Salomon og mine mænd med jer til Gihon, og giv Salomon mit eget muldyr at ride på. 34Dér ved Gihonkilden skal Zadok i sin egenskab af præst og Natan som profet salve ham til konge over Israels folk. Efter salvningen skal I lade blæse i vædderhornet og udråbe et længe leve for kong Salomon. 35Og når I kommer tilbage, skal I sætte ham på min kongetrone, for jeg har udpeget ham til at være konge over Israel og Juda.”

36„Amen!” svarede Benaja. „Herren, min konges Gud, vil føre det igennem! 37Gid Herren må velsigne Salomon, som han har velsignet dig—ja, må Salomons kongedømme blive endnu mægtigere end dit!”

38Så fik Zadok, Natan og Benaja fat på Salomon og lod ham ride på kongens private muldyr, og de tog alle af sted til Gihon sammen med den kongelige livgarde. 39Zadok havde hentet hornet med den hellige salveolie fra teltet, hvor arken stod, og da de kom til Gihon, hældte han olien ud over Salomons hoved. Salomon var dermed salvet til konge. Der blev blæst i vædderhornet, og folket råbte: „Længe leve kong Salomon!” 40Derpå fulgte de Salomon tilbage til Jerusalem. Undervejs spillede folk på fløjte og jublede så højt, at jorden gyngede under dem.

41I mellemtiden var Adonijas kroningsfest ved at være til ende. Gæsterne var netop ved at bryde op, da de hørte lyden af vædderhornet inde fra byen.

„Hvad sker der?” udbrød Joab. „Hvad er der på færde i byen?” 42I det samme ankom præsten Ebjatars søn, Jonatan.

„Velkommen!” sagde Adonija til Jonatan. „En mand som du kommer sikkert med gode nyheder!”

43„Desværre!” råbte Jonatan. „Kong David har netop udråbt Salomon til konge! 44-45Han gav ham sit eget private muldyr og sendte ham til Gihon sammen med Zadok, Natan og Benaja, eskorteret af den kongelige livgarde. Der salvede Zadok og Natan ham til konge. De er netop vendt tilbage fra Gihon, og byen er på den anden ende af begejstring. Det er grunden til al den larm. 46Salomon er nu indsat som konge, 47-48og hele hoffet lykønsker kong David og siger: ‚Gid din Gud må gøre Salomon endnu mere berømt end dig—og hans kongedømme endnu mægtigere end dit!’ Kongen har fra sin seng udtrykt sin taknemmelighed til Gud og sagt: ‚Lovet være Herren, Israels Gud, som i dag har gjort mig den glæde at udvælge en af mine sønner til konge efter mig!’ ”

49-50Ved de ord sprang Adonija og hans gæster panikslagne op fra bordet og flygtede for livet. Adonija skyndte sig til helligdommen og greb fat i de horn, der sad på hjørnerne af alteret.

51Salomon fik besked om, at Adonija havde søgt tilflugt ved alterets horn, og at han sagde: „Jeg bliver her, indtil Salomon sværger på, at han ikke vil slå mig ihjel.” 52Salomons reaktion var: „Hvis han vil være loyal over for mig, skal jeg ikke krumme et hår på hans hoved, men hvis han pønser på at undergrave mit kongedømme, skal han dø.” 53Så sendte kong Salomon sine mænd af sted for at hente Adonija ved alteret. Han blev ført frem for kongen og kastede sig ned foran ham med ansigtet mod jorden. Men Salomon nøjedes med at sige til ham: „Du har frihed til at gå hjem.”