Ìfihàn 17 – YCB & CRO

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Ìfihàn 17:1-18

Obìnrin àti ẹranko

117.1: Jr 51.13.Ọ̀kan nínú àwọn angẹli méje náà tí ó ní ìgò méje wọ̀n-ọn-nì sì wá, ó sì ba mi sọ̀rọ̀ wí pé, “Wá níhìn-ín; èmi ó sì fi ìdájọ́ àgbèrè ńlá ní tí ó jókòó lórí omi púpọ̀ han ọ, 217.2: Isa 23.17; Jr 25.15-16.ẹni tí àwọn ọba ayé bá ṣe àgbèrè, tí a sì fi ọtí wáìnì àgbèrè rẹ̀ pa àwọn tí ń gbé inú ayé.”

3Ó sì gbé mi nínú ẹ̀mí lọ sí aginjù: mo sì rí obìnrin kan ó jókòó lórí ẹranko aláwọ̀ òdòdó kan tí ó kún fún orúkọ ọ̀rọ̀-òdì, ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá. 417.4: Jr 51.7.A sì fi aṣọ elése àlùkò àti aṣọ òdòdó wọ obìnrin náà, a sì fi wúrà àti òkúta iyebíye àti perli ṣe é ní ọ̀ṣọ́, ó ní ago wúrà kan ní ọwọ́ rẹ̀, tí ó kún fún ìríra àti fún ẹ̀gbin àgbèrè rẹ̀; 5àti níwájú rẹ̀ ni orúkọ kan tí a kọ:

Ohun ìjìnlẹ̀ Babeli ńlá

ìyá àwọn panṣágà

àti àwọn ohun ìríra ayé.

6Mo sì rí obìnrin náà mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́, àti ẹ̀jẹ̀ àwọn ajẹ́rìí ikú Jesu ní àmuyó.

Nígbà tí mo sì rí i, ẹnu yà mi gidigidi. 7Angẹli sì wí fún mi pé, “Nítorí kí ni ẹnu ṣe yà ọ́? Èmi ó sọ ti ìjìnlẹ̀ obìnrin náà fún ọ, àti ti ẹranko tí ó gùn, ti ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá. 817.8: Da 7.3; If 3.5.Ẹranko tí ìwọ ri nì, o ti wà, kò sì ṣí mọ́, yóò sì ti inú ọ̀gbun gòkè wá, yóò sì lọ sínú ìparun rẹ. Àwọn olùgbé ayé ti a kọ orúkọ wọn sínú ìwé iye láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, nígbà tí wọn ń wò ẹranko tí o ti wà, tí kò sì ṣí mọ́, tí ó sì ń bọ̀ wá, ẹnu si ya wọn.

9“Níhìn-ín ni ìtumọ̀ tí o ní ọgbọ́n wà. Orí méje ni òkè ńlá méje ni, lórí èyí tí obìnrin náà jókòó. 10Ọba méje sì ní wọn: àwọn márùn-ún ṣubú, ọ̀kan ń bẹ, ọ̀kan ìyókù kò sì tí ì dé; nígbà tí ó bá sì dé, yóò dúró fún ìgbà kúkúrú. 11Ẹranko tí ó sì ti wà, tí kò sì ṣí, òun náà sì ni ẹ̀kẹjọ, ó sì ti inú àwọn méje náà wá, ó sì lọ sí ìparun.

1217.12: Da 7.20-24.“Ìwo mẹ́wàá tí ìwọ sì rí ni ọba mẹ́wàá ni wọn, tí wọn kò ì ti gba ìjọba; ṣùgbọ́n wọn gba àṣẹ bí ọba pẹ̀lú ẹranko náà fún wákàtí kan. 13Àwọn wọ̀nyí ní inú kan, wọ́n yóò sì fi agbára àti ọlá wọn fún ẹranko náà. 1417.14: Da 2.47.Àwọn wọ̀nyí ni yóò si máa bá Ọ̀dọ́-Àgùntàn jagun, Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà yóò sì ṣẹ́gun wọn: nítorí òun ni Olúwa àwọn Olúwa, àti ọba àwọn ọba: àwọn tí ó sì wà pẹ̀lú rẹ̀, tí a pè, tí a yàn, tí wọ́n sì jẹ́ olóòtítọ́ yóò sì ṣẹ́gun pẹ̀lú.”

15Ó sì wí fún mi pé, “Àwọn omi tí ìwọ ti rí ni, níbi tí àgbèrè náà jókòó, àwọn ènìyàn àti ẹ̀yà àti orílẹ̀ àti onírúurú èdè ni wọ́n. 16Àti ìwo mẹ́wàá tí ìwọ rí, àti ẹranko náà, àwọn wọ̀nyí ni yóò kórìíra àgbèrè náà, wọn ó sì sọ ọ́ di ahoro àti ẹni ìhòhò, wọn ó sì jẹ ẹran-ara rẹ̀, wọn ó sì fi iná sun ún pátápátá. 17Nítorí Ọlọ́run ti fi sínú ọkàn wọn láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ, láti ní inú kan, àti láti fi ìjọba wọn fún ẹranko náà, títí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò fi ṣẹ. 18Obìnrin tí ìwọ rí ní ìlú ńlá ni, tí ń jẹ ọba lórí àwọn ọba ilẹ̀ ayé.”

Knijga O Kristu

Otkrivenje 17:1-18

Velika Bludnica

1Priđe mi jedan od sedmorice anđela koji su izlili sedam posuda i reče: “Dođi! Pokazat ću ti osudu koja će snaći veliku Bludnicu koja sjedi na mnogim vodama. 2S njome su zemaljski kraljevi bludničili a stanovnici zemlje se opijali vinom njezina bluda.”

3I anđeo me u duhu17:3 Ili: u Duhu. prenese u pustinju. Ondje ugledam ženu kako sjedi na skrletnoj Zvijeri sa sedam glava i s deset rogova, punoj bogohulnih imena. 4Žena je bila odjevena u grimiz i skrlet, sva u zlatu, dragome kamenju i biserju. U ruci je držala zlatnu čašu punu gnusobe i nečisti svojega bluda. 5Na čelu joj je pisalo tajnovito ime: “Veliki Babilon, majka svih bludnica i gadosti zemaljskih.” 6Vidio sam da je Žena pijana od krvi svetih ljudi i krvi Isusovih svjedoka. Silno sam se začudio.

7“Što se čudiš?” upita me anđeo. “Reći ću ti tajnu o toj ženi i o Zvijeri koja je nosi, sa sedam glava i s deset rogova.” 8Zvijer koju si vidio vladala je, ali više ne vlada. Uskoro će izići iz bezdana i otići u vječno prokletstvo. I stanovnici zemlje kojih imena nisu upisana u Knjigu života od postanka svijeta zaprepastit će se kad opet vide Zvijer koja je bila, i nije, i opet će biti.

9Da se ovo razumije, treba mudrosti: sedam Zvijerinih glava sedam su bregova na kojima žena sjedi. One također predstavljaju sedam kraljeva. 10Petorica su već pala, šesti vlada, a sedmi tek treba doći, ali njegova će vladavina kratko trajati. 11Skrletna Zvijer jest osmi kralj koji je prije vladao kao jedan od sedmorice. Nakon druge vladavine slijedi mu propast. 12Deset rogova deset su kraljeva koji još nisu došli na vlast. Oni će doći na vlast i samo nakratko17:12 U grčkome: samo jednu uru. vladati skupa sa Zvijeri. 13Složit će se da njoj predaju svoju silu i vlast. 14Zaratit će protiv Jaganjca, ali on će ih pobijediti skupa sa svojim vjernim izabranicima koje je pozvao jer je Gospodar gospodara i Kralj kraljeva.

15“Vode koje si vidio,” reče mi još anđeo, “na kojima Bludnica sjedi, mnoštvo su naroda i jezika. 16Skrletna Zvijer i njezinih deset rogova—desetorica kraljeva koji će skupa s njom vladati—zamrzit će Bludnicu. Opustošit će ju i ogoliti, najesti se njezina mesa a zatim ju spaliti. 17Jer Bog im je stavio u srca da izvrše njegov naum: da složno predaju vlast Zvijeri dok se ne ispune Božje riječi. 18Žena koju si vidio velik je grad koji vlada nad zemaljskim kraljevima.”