Ìfihàn 14 – YCB & NSP

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Ìfihàn 14:1-20

Ọ̀dọ́-àgùntàn àti ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000)

114.1: El 9.4.Mo sì wo, si kíyèsi i, Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà dúró lórí òkè Sioni, àti pẹ̀lú rẹ̀ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) ènìyàn; wọ́n ní orúkọ rẹ̀, àti orúkọ baba rẹ̀ tí a kọ sí iwájú orí wọn. 2Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá, bí ariwo omi púpọ̀, àti bí sísán àrá ńlá, mo sì gbọ́ àwọn aludùùrù tí wọn ń lu dùùrù. 3Wọ́n sì ń kọ bí ẹni pé orin tuntun níwájú ìtẹ́ náà, àti níwájú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin n nì àti àwọn àgbà náà, kò sì ṣí ẹni tí o lè kọ orin náà, bí kò ṣe àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) ènìyàn, tí a tí rà padà láti inú ayé wá. 4Àwọn wọ̀nyí ni a kò fi obìnrin sọ di èérí, nítorí tí wọ́n jẹ́ wúńdíá. Àwọn wọ̀nyí ni o ń tọ Ọ̀dọ́-àgùntàn náà lẹ́yìn níbikíbi tí o bá ń lọ. Àwọn wọ̀nyí ni a rà padà láti inú àwọn ènìyàn wá, wọ́n jẹ́ àkọ́so fún Ọlọ́run àti fún Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà. 5A kò sì rí èké lẹ́nu wọn, wọn jẹ́ aláìlábùkù.

Àwọn angẹli mẹ́ta

6Mo sì rí angẹli mìíràn ń fò ní àárín méjì ọ̀run, pẹ̀lú ìyìnrere àìnípẹ̀kun láti wàásù fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀, àti ẹ̀yà, àti èdè, àti ènìyàn. 7Ó ń wí ni ohùn rara pé, “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí tí wákàtí ìdájọ́ rẹ̀ dé: ẹ sì foríbalẹ̀ fún ẹni tí o dá ọ̀run, àti ayé, àti Òkun, àti àwọn orísun omi!”

814.8: Isa 21.9.Angẹli mìíràn sì tẹ̀lé e, ó ń wí pé, “o ṣubú, Babeli ńlá ṣubú, èyí ti o tí ń mú gbogbo orílẹ̀-èdè mu nínú ọtí wáìnì àìmọ́ àgbèrè rẹ̀!”

9Angẹli mìíràn, ẹ̀kẹta, sì tẹ̀lé wọn, ó ń wí ni ohùn rara pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá ń foríbalẹ̀ fún ẹranko náà àti àwòrán rẹ̀, tí ó sì gba àmì sí iwájú orí rẹ̀ tàbí sí ọwọ́ rẹ̀. 1014.10: Jr 51.7; Gẹ 19.24.Òun pẹ̀lú yóò mú nínú ọtí wáìnì ìbínú Ọlọ́run, tí a dà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ sínú ago ìrunú rẹ̀; a ó sì fi iná sulfuru dá a lóró níwájú àwọn angẹli mímọ́, àti níwájú Ọ̀dọ́-àgùntàn. 1114.11: Isa 34.10.Èéfín ìdálóró wọn ń lọ sókè títí láéláé wọn kò sì ní ìsinmi ni ọ̀sán àti ní òru, àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún ẹranko náà àti fún àwòrán rẹ̀, àti ẹnikẹ́ni tí o ba sì gba àmì orúkọ rẹ̀.” 12Níhìn-ín ni sùúrù àwọn ènìyàn mímọ́ gbé wà: àwọn tí ń pa òfin Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ Jesu mọ́.

13Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá ń wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀, Alábùkún fún ni àwọn òkú tí o kú nínú Olúwa láti ìhín lọ.”

Alábùkún ni wọ́n nítòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni, Ẹ̀mí wí, “Nítorí tí wọn yóò sinmi kúrò nínú làálàá wọn, nítorí iṣẹ́ wọn ń tọ̀ wọn lẹ́yìn.”

Ìkórè ayé

1414.14: Da 7.13.Mo sì wo, sì kíyèsi i, ìkùùkuu àwọsánmọ̀ funfun kan, àti lórí ìkùùkuu àwọsánmọ̀ náà ẹnìkan jókòó tí o dàbí “ọmọ ènìyàn,” tí òun ti adé wúrà ní orí rẹ̀, àti dòjé mímú ni ọwọ́ rẹ̀. 1514.15: Jl 3.13; Mt 13.30.Angẹli mìíràn sì tí inú tẹmpili jáde wa tí ń ké lóhùn rara sí ẹni tí ó jókòó lórí ìkùùkuu àwọsánmọ̀ náà pé, “Tẹ dòjé rẹ bọ̀ ọ́, kí ó sì máa kórè; nítorí àkókò àti kórè dé, nítorí ìkórè ayé ti gbó tán.” 16Ẹni tí ó jókòó lórí ìkùùkuu àwọsánmọ̀ náà sì tẹ dòjé rẹ̀ bọ orí ilẹ̀ ayé; a sì ṣe ìkórè ilẹ̀ ayé.

17Angẹli mìíràn sì tí inú tẹmpili tí ń bẹ ni ọ̀run jáde wá, òun pẹ̀lú sì ní dòjé mímú, kan. 18Angẹli mìíràn sì tí ibi pẹpẹ jáde wá, tí ó ní agbára lórí iná; ó sì ké ni ohùn rara sí ẹni tí o ni dòjé mímú náà, wí pé, “Tẹ dòjé rẹ mímú bọ̀ ọ́, ki ó sì rẹ́ àwọn ìdì àjàrà ayé, nítorí àwọn èso rẹ̀ tí pọ́n.” 19Angẹli náà sì tẹ dòjé rẹ̀ bọ ilẹ̀ ayé, ó sì gé àjàrà ilẹ̀ ayé, ó sì kó o lọ sínú ìfúntí, ìfúntí ńlá ìbínú Ọlọ́run. 2014.20: Jl 3.13.A sì tẹ ìfúntí náà lẹ́yìn òde ìlú náà, ẹ̀jẹ̀ sì ti inú ìfúntí náà jáde, ó sì ga sókè dé okùn ìjánu ẹṣin, èyí tí ìnàsílẹ̀ rẹ to ẹ̀gbẹjọ̀ (1,600) ibùsọ̀.

New Serbian Translation

Откривење 14:1-20

Јагње и његов народ

1Затим сам видео Јагње како стоји на брду Сион, и са њим стотину четрдесет четири хиљаде, на чијим је челима било написано његово име и име његовога Оца. 2Зачуо сам глас са неба сличан хуку многих река и одјеку јаког грома. Глас је био сличан мелодији коју изводе свирачи харфе на својим харфама. 3Тих стотину четрдесет четири хиљаде певало је нову песму пред престолом, пред четири бића, и пред старешинама. Ту песму нико није могао да научи, осим њих, откупљених са земље. 4Они су очували себе чистима, не узимајући себи жена; то су, наиме, девственици. Они следе Јагње куд год оно иде. Они су откупљени од остатка човечанства као првина која припада Богу и Јагњету. 5Лаж никад нису изустили; они су непорочни.

Час Божијег суда

6Затим сам видео другог анђела како лети посред неба са вечном Радосном вешћу да је објави становницима земље: свакој народности, племену, језику и народу. 7Говорио је снажним гласом: „Бојте се Бога и дајте му славу, јер дошао је час његовог суда. Зато се поклоните Створитељу неба и земље, мора и водених извора.“

8Други анђео дође за њим и рече: „Паде, паде, велики Вавилон, јер је жестоким вином свога блудничења напојио све народе.“

9За њима је дошао трећи анђео и проговорио снажним гласом: „Ко год се клања Звери и њеном кипу, те прима жиг на своје чело или на своју руку, 10и сам ће пити вино Божијега гнева које је неразблажено наточено у чашу његовога гнева, па ће бити мучен у огњу и сумпору пред светим анђелима и пред Јагњетом. 11А дим од њиховог мучења дизаће се од сад и довека. Ти који се клањају Звери и њеном кипу и примају жиг са њеним именом, неће имати починка ни дању ни ноћу.“ 12Ово захтева постојаност светих, који држи Божије заповести и веру у Исуса.

13Тада сам чуо глас са неба како говори: „Напиши: благо онима који од сада умиру ради Господа! Да, говори Дух, они ће се одморити од свог мукотрпног рада, јер њихова дела сведоче за њих.“

Земаљска жетва

14Тада сам погледао, и гле, бели облак. На облаку је седео неко „као син човечији“, са златним венцем на глави и са оштрим српом у својој руци. 15Тада неки други анђео изађе из храма вичући громким гласом ономе што је седео на облаку: „Узми срп и жањи, јер је дошло време за жетву, дозрео је усев на земљи.“ 16Онај што је седео на облаку баци свој срп на земљу и земља би пожњевена.

17Из небеског храма изађе други анђео који је такође са собом носио оштар срп. 18Други, опет, анђео, који је имао власт над ватром, дође од жртвеника и повика громким гласом ономе са оштрим српом: „Замахни својим оштрим српом, па обери грожђе са земаљског чокота, јер је грожђе сазрело!“ 19Анђео баци свој срп на земљу, обере земаљски чокот, а грожђе стави у велику муљару Божијег гнева. 20Грожђе у муљари би изгажено изван града, те из муљаре потече крв коњима до узда, неких хиљаду шест стотина стадија14,20 Око 300 km. унаоколо.