Ìfihàn 11 – YCB & NIRV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Ìfihàn 11:1-19

Àwọn ẹlẹ́rìí méjì

111.1: El 40.3.A sì fi ìfèéfèé kan fún mi tí o dàbí ọ̀pá-ìwọ̀n: ẹnìkan sì wí pé, “Dìde, wọn tẹmpili Ọlọ́run, àti pẹpẹ, àti àwọn tí ń sìn nínú rẹ̀. 211.2: Sk 12.3; Isa 63.18; Lk 21.24.Sì fi àgbàlá tí ń bẹ lóde tẹmpili sílẹ̀, má sì ṣe wọ́n ọ́n; nítorí tí a fi fún àwọn aláìkọlà: ìlú mímọ́ náà ni wọn ó sì tẹ̀ mọ́lẹ̀ ní oṣù méjìlélógójì (42). 3Èmi ó sì yọ̀ǹda fún àwọn ẹlẹ́rìí mi méjèèje, wọn ó sì sọtẹ́lẹ̀ fún ẹgbẹ̀fà ọjọ́ ó lé ọgọ́ta (1,260) nínú aṣọ ọ̀fọ̀.” 411.4: Sk 4.3,11-14.Wọ̀nyí ni igi olifi méjì náà, àti ọ̀pá fìtílà méjì náà tí ń dúró níwájú Olúwa ayé. 511.5: 2Ọb 1.10; Jr 5.14.Bí ẹnikẹ́ni bá sì fẹ́ pa wọn lára, iná ó ti ẹnu wọn jáde, a sì pa àwọn ọ̀tá wọn run, báyìí ni a ó sì pa ẹnikẹ́ni tí ó ba ń fẹ́ pa wọn lára run. 611.6: 1Ọb 17.1; Ek 7.17,19.Àwọn wọ̀nyí ni ó ni agbára láti sé ọ̀run, tí òjò kò fi lè rọ̀ ni ọjọ́ àsọtẹ́lẹ̀ wọn. Wọ́n sì ní agbára lórí omi láti sọ wọn di ẹ̀jẹ̀, àti láti fi onírúurú àjàkálẹ̀-ààrùn kọlu ayé, nígbàkígbà tí wọ́n bá fẹ́.

711.7: Da 7.3,7,21.Nígbà tí wọn bá sì ti parí ẹ̀rí wọn, ẹranko tí o ń tí inú ọ̀gbun gòkè wá yóò bá wọn jagun, yóò sì ṣẹ́gun wọn, yóò sì pa wọ́n. 811.8: Isa 1.9.Òkú wọn yóò sì wà ni ìgboro ìlú ńlá náà tí a ń pè ní Sodomu àti Ejibiti nípa ti ẹ̀mí, níbi tí a gbé kan Olúwa wọ́n mọ́ àgbélébùú. 9Fún ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀ ni àwọn ènìyàn nínú ènìyàn gbogbo àti ẹ̀yà, àti èdè, àti orílẹ̀, wo òkú wọn, wọn kò si jẹ kì a gbé òkú wọn sínú ibojì. 10Àti àwọn tí o ń gbé orí ilẹ̀ ayé yóò sì yọ̀ lé wọn lórí, wọn yóò sì ṣe àríyá, wọn ó sì ta ara wọn lọ́rẹ; nítorí tí àwọn wòlíì méjèèjì yìí dá àwọn tí o ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé lóró.

1111.11: El 37.5,10.Àti lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀ náà, ẹ̀mí ìyè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá wọ inú wọn, wọn sì dìde dúró ni ẹsẹ̀ wọn; ẹ̀rù ńlá sì ba àwọn tí o rí wọn. 1211.12: 2Ọb 2.11.Wọn sì gbọ́ ohùn ńlá kan láti ọ̀run wá ń wí fún wọn pé, “Ẹ gòkè wá ìhín!” Wọn sì gòkè lọ sí ọ̀run nínú ìkùùkuu àwọsánmọ̀; lójú àwọn ọ̀tá wọn.

13Ní wákàtí náà omìmì-ilẹ̀ ńlá kan sì mì, ìdámẹ́wàá ìlú náà sì wó, àti nínú omìmì-ilẹ̀ náà ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) ènìyàn ní a pa; ẹ̀rù sì ba àwọn ìyókù, wọn sì fi ògo fún Ọlọ́run ọ̀run.

14Ègbé kejì kọjá; sì kíyèsi i, ègbé kẹta sì ń bọ̀ wá kánkán.

Ìpè méje

1511.15: Sm 22.28; Da 7.14,27.Angẹli keje sì fọn ìpè; a sì gbọ́ ohùn ńlá láti ọ̀run, wí pé,

“Ìjọba ayé di ti Olúwa wá, àti tí Kristi rẹ̀;

òun yóò sì jẹ ọba láé àti láéláé!”

16Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà tí wọn jókòó níwájú Ọlọ́run lórí ìtẹ́ wọn, dojúbolẹ̀, wọn sì sin Ọlọ́run, 17wí pé:

“Àwa fi ọpẹ́ fún ọ, Olúwa Ọlọ́run, Olódùmarè,

tí ń bẹ, tí ó sì ti wà,

nítorí pé ìwọ ti gba agbára ńlá rẹ̀,

ìwọ sì ti jẹ ọba.

1811.18: Sm 2.1.Inú bí àwọn orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú rẹ̀ ti dé,

àti àkókò láti dá àwọn òkú lẹ́jọ́,

àti láti fi èrè fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì,

àti àwọn ènìyàn mímọ́, àti àwọn tí o bẹ̀rù orúkọ rẹ̀,

àti ẹni kékeré àti ẹni ńlá;

àti láti run àwọn tí ń pa ayé run.”

1911.19: 1Ọb 8.1-6; 2.A sì ṣí tẹmpili Ọlọ́run sílẹ̀ ní ọ̀run, a sì ri àpótí májẹ̀mú nínú tẹmpili rẹ̀. Mọ̀nàmọ́ná sì kọ, a sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, ilẹ̀ sì mi, yìnyín ńlá sì bọ́.

New International Reader’s Version

Revelation 11:1-19

The Two Witnesses

1I was given a long stick that looked like a measuring rod. I was told, “Go and measure the temple of God. And measure the altar where the people are worshiping. 2But do not measure the outer courtyard. That’s because it has been given to the Gentiles. They will take over the holy city for 42 months. 3I will appoint my two witnesses. And they will prophesy for 1,260 days. They will be dressed in the rough clothes people wear when they’re sad.” 4The witnesses are “the two olive trees” and the two lampstands. And “they stand in front of the Lord of the earth.” (Zechariah 4:3,11,14) 5If anyone tries to harm them, fire comes from their mouths and eats up their enemies. This is how anyone who wants to harm them must die. 6These witnesses have power to close up the sky. Then it will not rain while they are prophesying. They also have power to turn the waters into blood. And they can strike the earth with every kind of plague. They can do this as often as they want to.

7When they have finished speaking, the beast that comes up from the Abyss will attack them. He will overpower them and kill them. 8Their bodies will lie in the main street of the great city. It is also the city where their Lord was nailed to a cross. The city is sometimes compared to Sodom or Egypt. 9For three and a half days, people will stare at their bodies. These people will be from every tribe and nation, no matter what language they speak. They will refuse to bury them. 10Those who live on the earth will be happy about this. That’s because those two prophets had made them suffer. The people will celebrate by sending one another gifts.

11But after the three and a half days, the breath of life from God entered the witnesses. They both stood up. Terror struck those who saw them. 12Then the two witnesses heard a loud voice from heaven. It said to them, “Come up here.” They went up to heaven in a cloud. Their enemies watched it happen.

13At that same time there was a powerful earthquake. A tenth of the city crumbled and fell. In the earthquake, 7,000 people were killed. Those who lived through it were terrified. They gave glory to the God of heaven.

14The second terrible judgment has passed. The third is coming soon.

The Seventh Trumpet

15The seventh angel blew his trumpet. There were loud voices in heaven. They said,

“The kingdom of the world has become

the kingdom of our Lord and of his Messiah.

He will rule for ever and ever.”

16The 24 elders were sitting on their thrones in front of God. They fell on their faces and worshiped God. 17They said,

“Lord God who rules over all, we give thanks to you.

You are the God who is and who was.

We give you thanks.

That’s because you have begun to rule with your great power.

18The nations were angry,

and the time for your anger has come.

The time has come to judge the dead.

It is time to reward your servants the prophets

and your people who honor you.

There is a reward for all your people,

both great and small.

It is time to destroy those who destroy the earth.”

19Then God’s temple in heaven was opened. Inside it the wooden chest called the ark of his covenant could be seen. There were flashes of lightning, rumblings and thunder, an earthquake and a severe hailstorm.