Ìṣe àwọn Aposteli 6 – YCB & TNCV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Ìṣe àwọn Aposteli 6:1-15

Yíyan àwọn méje

1Ǹjẹ́ ní ọjọ́ wọ̀nyí, nígbà tí iye àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ń pọ̀ sí i, ìkùnsínú wà ní àárín àwọn Helleni tí ṣe Júù àti àwọn Heberu tí ṣe Júù, nítorí tí a gbàgbé nípa ti àwọn opó wọn nínú ìpín fún ni ojoojúmọ́. 2Àwọn méjìlá sì pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn jọ sọ́dọ̀, wọn wí pé, “Kò yẹ kí àwa ó fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílẹ̀, kí a sì máa ṣe ìránṣẹ́ tábìlì. 3Nítorí náà, ará, ẹ wo ọkùnrin méje nínú yín, olórúkọ rere, tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti fún ọgbọ́n, tí àwa lè yàn sí iṣẹ́ yìí. 4Ṣùgbọ́n àwa yóò dúró ṣinṣin nínú àdúrà gbígbà, àti nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà.”

5Ọ̀rọ̀ náà sì tọ́ lójú gbogbo ìjọ; wọ́n sì yan Stefanu, ọkùnrin tí ó kún fún ìgbàgbọ́ àti fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti Filipi, àti Prokoru, àti Nikanoru, àti Timoni, àti Parimena, àti Nikolasi aláwọ̀ṣe Júù ará Antioku. 6Ẹni tí wọ́n mú dúró níwájú àwọn Aposteli; nígbà tí wọ́n sì gbàdúrà, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn.

7Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì gbilẹ̀, iye àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì pọ̀ sí i gidigidi ni Jerusalẹmu, ọ̀pọ̀ nínú ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà sí fetí sí tí ìgbàgbọ́ náà.

A mú Stefanu

8Stefanu tí ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ àti agbára, ó ṣe iṣẹ́ ìyanu, àti iṣẹ́ àmì ńlá láàrín àwọn ènìyàn. 9Ṣùgbọ́n àwọn kan dìde nínú àwọn ti ń ṣe ara Sinagọgu, tí a ń pè ní Libataini. Àwọn Júù Kirene àti ti Alekisandiria àti ti Kilikia, àti ti Asia wá, wọ́n ń bá Stefanu jiyàn, 10ṣùgbọ́n wọn kò sí lè ko ọgbọ́n àti Ẹ̀mí tí ó fi ń sọ̀rọ̀ lójú.

11Nígbà náà ni wọ́n fún àwọn ọkùnrin kan ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀, kí wọn ń wí pé, “Àwa gbọ́ tí Stefanu ń sọ ọ̀rọ̀-òdì sí Mose àti sí Ọlọ́run.”

12Wọ́n sí ru àwọn ènìyàn sókè, àti àwọn alàgbà, àti àwọn olùkọ́ni ní òfin. Wọ́n dìde sí i, wọ́n gbá a mú, wọ́n sì mú un wá sí iwájú àjọ ìgbìmọ̀. 13Wọ́n sí mú àwọn ẹlẹ́rìí èké wá, tiwọn wí pé, “Ọkùnrin yìí kò sinmi láti sọ ọ̀rọ̀-òdì sí ibi mímọ́ yìí, àti sí òfin. 14Nítorí àwa gbọ́ o wí pé Jesu ti Nasareti yìí yóò fọ́ ibí yìí, yóò sì yí àṣà ti Mose fi fún wa padà.”

15Gbogbo àwọn tí ó sì jókòó ni àjọ ìgbìmọ̀ tẹjúmọ́ Stefanu, wọ́n sì rí ojú rẹ̀ dàbí ojú angẹli.

Thai New Contemporary Bible

กิจการของอัครทูต 6:1-15

การเลือกคนทั้งเจ็ด

1ครั้งนั้นเมื่อสาวกเพิ่มจำนวนขึ้นชาวยิวผู้ถือธรรมเนียมกรีกบ่นไม่พอใจชาวยิวผู้ถือธรรมเนียมยิวเพราะแม่ม่ายในหมู่พวกตนถูกละเลยในการแจกจ่ายอาหารประจำวัน 2ดังนั้นอัครทูตทั้งสิบสองคนจึงเรียกสาวกทั้งปวงมาประชุมพร้อมหน้ากันและกล่าวว่า “เป็นการไม่ถูกต้องที่เราจะละเลยพันธกิจแห่งพระวจนะของพระเจ้าเพื่อไปรับใช้ที่โต๊ะอาหาร 3พี่น้องทั้งหลาย จงเลือกคนเจ็ดคนในพวกท่านซึ่งเป็นที่ทราบกันว่าเต็มด้วยพระวิญญาณและสติปัญญา เราจะได้มอบความรับผิดชอบนี้แก่พวกเขา 4ส่วนเราจะได้เอาใจใส่ในการอธิษฐานและพันธกิจแห่งพระวจนะ”

5ที่ประชุมทั้งหมดเห็นชอบกับข้อเสนอนี้จึงเลือกสเทเฟน ชายผู้เปี่ยมด้วยความเชื่อและพระวิญญาณบริสุทธิ์ พร้อมทั้งฟีลิป โปรโครัส นิคาโนร์ ทิโมน ปารเมนัส และนิโคลัสจากเมืองอันทิโอกซึ่งมาเข้าจารีตยิว 6พวกเขานำทั้งเจ็ดคนนี้มาหาอัครทูต อัครทูตก็อธิษฐานและวางมือให้

7ดังนั้นพระวจนะของพระเจ้าจึงแพร่ออกไปจำนวนสาวกในกรุงเยรูซาเล็มเพิ่มขึ้นอย่างรวดเร็วและมีปุโรหิตจำนวนมากมารับเชื่อ

สเทเฟนถูกจับ

8ฝ่ายสเทเฟนผู้เปี่ยมด้วยพระคุณและฤทธิ์เดชของพระเจ้าได้ทำหมายสำคัญและปาฏิหาริย์ที่ยิ่งใหญ่หลายอย่างในหมู่ประชาชน 9แต่ถูกต่อต้านโดยสมาชิกของธรรมศาลาแห่งทาสที่ได้รับอิสรภาพ (ตามที่เขาเรียกกัน) คือพวกยิวจากเมืองไซรีน เมืองอเล็กซานเดรีย ทั้งจากแคว้นซิลีเซียและเอเชีย คนเหล่านี้โต้เถียงกับสเทเฟน 10แต่ไม่สามารถเอาชนะสติปัญญาของเขาหรือพระวิญญาณผู้ตรัสผ่านเขา

11พวกเขาจึงลอบยุบางคนให้พูดว่า “เราได้ยินสเทเฟนกล่าวลบหลู่โมเสสและพระเจ้า”

12ดังนั้นพวกเขาได้ปลุกปั่นประชาชนตลอดจนเหล่าผู้อาวุโสและพวกธรรมาจารย์ให้ลุกฮือขึ้น พวกเขาจับสเทเฟนและนำตัวมาต่อหน้าสภาแซนเฮดริน 13พวกเขาสร้างพยานเท็จมาให้การว่า “ชายคนนี้พูดลบหลู่สถานบริสุทธิ์และบทบัญญัติไม่หยุดเลย 14เพราะเราได้ยินเขาพูดว่าพระเยซูแห่งนาซาเร็ธนั้นจะทำลายสถานที่นี้และเปลี่ยนธรรมเนียมซึ่งโมเสสได้ให้สืบทอดมาจนถึงเรา”

15คนทั้งปวงที่นั่งอยู่ในสภาแซนเฮดรินก็จ้องมองสเทเฟนเห็นใบหน้าของเขาเหมือนใบหน้าของทูตสวรรค์