Ìfihàn 2 – YCB & TCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Ìfihàn 2:1-29

Sí ìjọ Efesu

1“Sí angẹli ìjọ ní Efesu kọ̀wé:

Nǹkan wọ̀nyí ní ẹni tí ó mú ìràwọ̀ méje náà ni ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ wí, ẹni tí ń rìn ní àárín ọ̀pá wúrà fìtílà méje.

2Èmi mọ iṣẹ́ rẹ, àti làálàá rẹ, àti ìfaradà rẹ, àti bí ara rẹ kò ti gba àwọn ẹni búburú, àti bí ìwọ sì ti dán àwọn tí ń pe ara wọn ní aposteli, tí wọ́n kì í sì í ṣe bẹ́ẹ̀ wo, tí ìwọ sì rí pé èké ni wọ́n, 3tí ìwọ sì faradà ìyà, àti nítorí orúkọ mi tí ó sì rọ́jú, tí àárẹ̀ kò sì mú ọ.

4Síbẹ̀ èyí ni mo rí wí sí ọ, pé, ìwọ ti fi ìfẹ́ ìṣáájú rẹ sílẹ̀. 5Rántí ibi tí ìwọ ti gbé ṣubú! Ronúpìwàdà, kí ó sì ṣe iṣẹ́ ìṣáájú; bí kò sì ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó sì tọ̀ ọ́ wá, èmi ó sì ṣí ọ̀pá fìtílà rẹ̀ kúrò ní ipò rẹ̀, bí kò ṣe bí ìwọ bá ronúpìwàdà. 6Ṣùgbọ́n èyí ni ìwọ ní, pé ìwọ kórìíra ìṣe àwọn Nikolatani, èyí tí èmi pẹ̀lú sì kórìíra.

72.7: Gẹ 2.9.Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò fi èso igi ìyè nì fún jẹ, tí ń bẹ láàrín Paradise Ọlọ́run.

Sí Ìjọ ní Smirna

82.8: Isa 44.6.“Àti sí angẹli ìjọ ní Smirna kọ̀wé.

Nǹkan wọ̀nyí ni ẹni tí í ṣe ẹni ìṣáájú àti ẹni ìkẹyìn wí, ẹni tí ó ti kú, tí ó sì tún yè.

9Èmi mọ iṣẹ́ rẹ, àti ìpọ́njú, àti àìní rẹ—ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ ni ọ́, èmi sì mọ ọ̀rọ̀-òdì tí àwọn tí ń wí pé, Júù ni àwọn tìkára wọn, tí wọn kì sì í ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọ́n jẹ́ Sinagọgu ti Satani. 102.10: Da 1.12.Má ṣe bẹ̀rù ohunkóhun tí ìwọ ń bọ wá jìyà rẹ̀. Kíyèsi i, èṣù yóò gbé nínú yín jù sínú túbú, kí a lè dán yin wò; ẹ̀yin ó sì ní ìpọ́njú ní ọjọ́ mẹ́wàá, ìwọ ṣa ṣe olóòtítọ́ dé ojú ikú, èmi ó sì fi adé ìyè fún ọ.

11Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun kì yóò fi ara pa nínú ikú kejì.

Sí ìjọ ní Pargamu

12“Àti sì angẹli ìjọ ni Pargamu kọ̀wé.

Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ó ní idà mímú olójú méjì.

13Èmí mọ̀ ibi tí ìwọ ń gbé, àní ibi tí ìtẹ́ Satani wà. Síbẹ̀ ìwọ di orúkọ mi mú ṣinṣin. Ìwọ kò sì sẹ́ ìgbàgbọ́ nínú mi, pàápàá jùlọ ni ọjọ́ Antipa ẹlẹ́rìí mi, olóòtítọ́ ènìyàn, ẹni tí wọn pa láàrín yín, níbi tí Satani ń gbé.

142.14: Nu 31.16; 25.1-2.Ṣùgbọ́n mo ni nǹkan díẹ̀ wí sí ọ; nítorí tí ìwọ ní àwọn kan tí ó di ẹ̀kọ́ Balaamu mú síbẹ̀, ẹni tí ó kọ́ Balaki láti mú ohun ìkọ̀sẹ̀ wá síwájú àwọn ọmọ Israẹli, láti máa jẹ ohun tí a pa rú ẹbọ sí òrìṣà, àti láti máa ṣe àgbèrè. 15Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ sì ní àwọn tí ó gbá ẹ̀kọ́ àwọn Nikolatani pẹ̀lú, ohun tí mo kórìíra. 16Nítorí náà, ronúpìwàdà; bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó tọ̀ ọ́ wá nísinsin yìí, èmí o sì fi idà ẹnu mi bá wọn jà.

172.17: Sm 78.24; Isa 62.2.Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. Ẹni tí o bá ṣẹ́gun ni èmi o fi manna tí ó pamọ́ fún, èmi ó sì fún un ni òkúta funfun kan, àti sára òkúta náà ni a kọ orúkọ tuntun kan, tí ẹnìkan kò mọ̀ bí kò ṣe ẹni tí ó gbà á.

Sí ìjọ ni Tiatira

182.18: Da 10.6.“Àti sí angẹli ìjọ ní Tiatira kọ̀wé.

Nǹkan wọ̀nyí ni Ọmọ Ọlọ́run wí, ẹni tí ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́-iná, tí ẹsẹ̀ rẹ̀ sì dàbí idẹ dáradára.

19Èmi mọ̀ iṣẹ́, ìfẹ́, àti ìgbàgbọ́ àti ìsìn àti sùúrù rẹ̀; àti pé iṣẹ́ rẹ̀ ìkẹyìn ju tí ìṣáájú lọ.

202.20: 1Ọb 16.31; 2Ọb 9.22,30; Nu 25.1.Ṣùgbọ́n èyí ni mo rí wí sí ọ, nítorí tí ìwọ fi ààyè sílẹ̀ fún obìnrin Jesebeli tí ó ń pe ara rẹ̀ ní wòlíì. Nípasẹ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó sì ń kọ́ àwọn ìránṣẹ́ mi, ó sì ń tàn wọ́n láti máa ṣe àgbèrè, àti láti máa jẹ ohun tí a pa rú ẹbọ sì òrìṣà. 21Èmi fi àkókò fún un, láti ronúpìwàdà; ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ ronúpìwàdà àgbèrè rẹ̀. 22Nítorí náà, èmi ó gbé e sọ sí orí àkéte ìpọ́njú, àti àwọn tí ń bá a ṣe panṣágà ni èmi ó fi sínú ìpọ́njú ńlá, bí kò ṣe bí wọ́n bá ronúpìwàdà iṣẹ́ wọn. 232.23: Jr 17.10; Sm 62.12.Èmi o pa àwọn ọmọ rẹ̀ run; gbogbo ìjọ ni yóò sì mọ̀ pé, èmi ni ẹni tí ń wádìí inú àti ọkàn, èmi ó sì fi fún olúkúlùkù yín gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.

24Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni mò ń sọ fún, ẹ̀yin ìyókù tí ń bẹ ní Tiatira, gbogbo ẹ̀yin tí kò ni ẹ̀kọ́ yìí, ti kò ì tí ì mọ̀ ohun tí wọn pè ni ohun ìjìnlẹ̀ Satani, èmi kò di ẹrù mìíràn rù yín, 25ṣùgbọ́n èyí tí ẹ̀yin ní, ẹ di mú ṣinṣin títí èmi ó fi dé.

262.26: Sm 2.8-9.Ẹni tí ó bá sì ṣẹ́gun, àti tí ó sì ṣe ìfẹ́ mi títí dé òpin, èmi ó fún un láṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè: 27‘Òun ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn; gẹ́gẹ́ bí a ti ń fọ́ ohun èlò amọ̀kòkò ni a ó fọ́ wọn túútúú,’ gẹ́gẹ́ bí èmi pẹ̀lú tí gbà àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Baba mi. 28Èmi yóò sì fi ìràwọ̀ òwúrọ̀ fún un. 29Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.

Tagalog Contemporary Bible

Pahayag 2:1-29

Ang Sulat para sa Iglesya sa Efeso

1“Isulat mo ito para sa anghel na nagbabantay sa iglesya sa Efeso:

“Ito ang mensahe ng may hawak ng pitong bituin sa kanang kamay at lumalakad sa gitna ng pitong ilawang ginto: 2Alam ko ang mga ginagawa ninyo pati ang inyong mga pagsisikap at pagtitiyaga. Alam ko rin na hindi ninyo kinukunsinti ang masasamang tao. Siniyasat ninyo ang mga nagpapanggap na apostol, at napatunayan ninyong mga sinungaling sila. 3Tiniis ninyo ang mga kahirapan dahil sa pananampalataya ninyo sa akin, at hindi kayo nanghina. 4Ngunit ito ang ayaw ko sa inyo: ang inyong pag-ibig sa akin ngayon ay hindi na tulad ng dati. 5Alalahanin ninyo kung gaano kayo nanamlay sa pananampalataya. Magsisi kayo sa mga kasalanan ninyo at gawing muli ang dati ninyong ginagawa. Kung hindi, pupuntahan ko kayo at kukunin ang inyong ilawan. 6Ngunit ito ang gusto ko sa inyo: kinasusuklaman ninyo ang mga ginagawa ng mga Nicolaita,2:6 Nicolaita: Tingnan sa Talaan ng mga Salita sa likod. na kinasusuklaman ko rin.

7“Kayong nakikinig, pag-isipan ninyong mabuti ang sinasabi ng Banal na Espiritu sa mga iglesya.

“Ang magtatagumpay ay papayagan kong kumain ng bunga ng punongkahoy na nagbibigay ng buhay. Ang punong ito ay nasa paraiso ng Dios.”

Ang Sulat para sa Iglesya sa Smirna

8“Isulat mo ito para sa anghel na nagbabantay sa iglesya sa Smirna:

“Ito ang mensahe niya na siyang simula at katapusan ng lahat, na namatay ngunit muling nabuhay: 9Alam ko ang inyong pagtitiis. Alam ko ring mahirap kayo, ngunit mayaman sa espiritwal na mga bagay. Alam kong hinahamak kayo ng mga taong nagsasabing mga Judio sila, ngunit ang totooʼy mga kampon sila ni Satanas. 10Huwag kayong matakot sa mga paghihirap na malapit na ninyong danasin. Tandaan ninyo: Ipapabilanggo ni Satanas ang ilan sa inyo upang subukan kayo. Daranas kayo ng pang-uusig sa loob ng sampung araw. Manatili kayong tapat hanggang kamatayan, at gagantimpalaan ko kayo ng buhay na walang hanggan.

11“Kayong nakikinig, pag-isipan ninyong mabuti ang sinasabi ng Banal na Espiritu sa mga iglesya.

“Ang magtatagumpay ay hindi makakaranas ng ikalawang kamatayan.”

Ang Sulat para sa Iglesya sa Pergamum

12“Isulat mo ito para sa anghel na nagbabantay sa iglesya sa Pergamum:

“Ito ang mensahe ng may hawak ng matalas na espada na dalawa ang talim: 13Alam ko na kahit nakatira kayo sa lugar na hawak ni Satanas ay nananatili pa rin kayong tapat sa akin. Sapagkat hindi kayo tumalikod sa pananampalataya ninyo sa akin, kahit noong patayin si Antipas na tapat kong saksi riyan sa lugar ninyo na tirahan ni Satanas. 14Ngunit ito ang ayaw ko sa inyo: May ilan sa inyo na sumusunod sa mga aral ni Balaam. Si Balaam ang nagturo kay Balak kung paano udyukan ang mga Israelita na magkasala sa pamamagitan ng pagkain ng mga inihandog sa mga dios-diosan at sa pamamagitan ng paggawa ng sekswal na imoralidad. 15At may ilan din sa inyo na sumusunod sa mga aral ng mga Nicolaita. 16Kaya magsisi kayo sa mga kasalanan ninyo! Sapagkat kung hindi, pupunta ako riyan sa lalong madaling panahon at kakalabanin ko ang mga taong iyan na sumusunod sa mga maling aral sa pamamagitan ng espada na lumalabas sa aking bibig.

17“Kayong nakikinig, pag-isipan ninyong mabuti ang sinasabi ng Banal na Espiritu sa mga iglesya.

“Ang magtatagumpay ay bibigyan ko ng pagkain na inilaan ko sa langit. Bibigyan ko rin ang bawat isa sa kanila ng puting bato na may nakasulat na bagong pangalan na walang ibang nakakaalam kundi ang makakatanggap nito.”

Ang Sulat para sa Iglesya sa Tiatira

18“Isulat mo ito para sa anghel na nagbabantay sa iglesya sa Tiatira:

“Ito ang mensahe ng Anak ng Dios, na ang mga mataʼy nagliliyab na parang apoy at ang mga paaʼy nagniningning na parang pinakintab na tanso: 19Alam ko ang mga ginagawa ninyo. Alam ko na mapagmahal kayo, matapat, masigasig maglingkod at matiyaga. Alam ko rin na higit pa ang ginagawa ninyo ngayon kaysa sa noong una. 20Ngunit ito ang ayaw ko sa inyo: Hinahayaan ninyo lang na magturo ang babaeng si Jezebel na nagpapanggap na propeta. Nililinlang niya ang mga taong naglilingkod sa akin at hinihikayat na gumawa ng sekswal na imoralidad at kumain ng mga inihandog sa mga dios-diosan. 21Binigyan ko siya ng panahon upang magsisi sa kanyang imoralidad, ngunit ayaw niya. 22Makinig kayo! Bibigyan ko siya ng karamdaman hanggang sa hindi na siya makabangon sa higaan. Parurusahan ko siya nang matindi pati ang mga nakipagrelasyon sa kanya, kung hindi sila magsisisi sa kanilang kasamaan. 23Papatayin ko ang mga tagasunod niya upang malaman ng lahat ng iglesya na alam ko ang iniisip at hinahangad ng tao. Gagantihan ko ang bawat isa sa inyo ayon sa mga ginawa ninyo.

24“Pero ang iba sa inyo riyan sa Tiatira ay hindi sumusunod sa mga turo ni Jezebel. Hindi kayo natuto ng tinatawag nilang ‘malalalim na mga turo ni Satanas.’ Kaya wala na akong idadagdag pang tuntunin na dapat ninyong sundin. 25Ipagpatuloy na lang ninyo ang inyong katapatan sa akin hanggang sa pagdating ko. 26-27Sapagkat ang mga magtatagumpay at patuloy na sumusunod sa kalooban ko hanggang sa wakas ay bibigyan ko ng kapangyarihang mamahala sa mga bansa, tulad ng kapangyarihang ibinigay sa akin ng aking Ama. Mamamahala sila sa pamamagitan ng kamay na bakal at dudurugin nila ang mga bansa gaya ng pagdurog sa palayok.2:26-27 Tingnan ang Salmo 2:8-9. 28At ibibigay ko rin sa kanila ang tala sa umaga.2:28 tala sa umaga: sa Ingles, “morning star.”

29“Kayong nakikinig, pag-isipan ninyong mabuti ang sinasabi ng Banal na Espiritu sa mga iglesya.”