Ọ̀rọ̀ ìṣáájú
1Ìfihàn ti Jesu Kristi, tí Ọlọ́run fi fún un, láti fihàn fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ohun tí kò le ṣàìṣẹ ní lọ́ọ́lọ́ọ́; ó sì ránṣẹ́, ó sì fi í hàn láti ọwọ́ angẹli rẹ̀ wá fún Johanu, ìránṣẹ́ rẹ̀, 2ẹni tí ó jẹ́rìí ohun gbogbo tí ó rí, èyí ì ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti ẹ̀rí ti Jesu Kristi. 3Ẹni ìbùkún ni ẹni tí ń kà, àti àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ yìí, tí ó sì ń pa nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí a kọ sínú rẹ̀ mọ́, nítorí ìgbà kù sí dẹ̀dẹ̀.
Ọ̀rọ̀ ìkíni àti ìyìn
41.4: Ek 3.14.Johanu,
Sí àwọn ìjọ méje tí ń bẹ ní Asia:
Oore-ọ̀fẹ́ fún yín, àti àlàáfíà, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ń bẹ, tí ó sì ti wà, tí ó sì ń bọ̀ wá; àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí méje tí ń bẹ níwájú ìtẹ́ rẹ̀; 51.5: Sm 89.27.àti láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi, ẹlẹ́rìí olóòtítọ́, àkọ́bí nínú àwọn òkú, àti aláṣẹ àwọn ọba ayé.
Ẹni tí ó fẹ́ wa, ẹni tí ó gbà wá kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, 61.6: Ek 19.6; Isa 61.6.tí ó sì ti fi wá jẹ ọba àti àlùfáà láti sin Ọlọ́run àti Baba rẹ; tirẹ̀ ni ògo àti ìjọba láé àti láéláé. Àmín.
71.7: Da 7.13; Mt 24.30; Mk 14.62; Sk 12.10.“Kíyèsi i, o ń bọ̀ nínú àwọsánmọ̀,
gbogbo ojú ni yóò sì rí i,
àti àwọn tí ó gún un ní ọ̀kọ̀ pẹ̀lú”;
àti gbogbo orílẹ̀-èdè ayé ni
“yóò sì máa pohùnréré ẹkún nítorí rẹ̀.”
Bẹ́ẹ̀ náà ni! Àmín.
81.8: Ek 3.14. “Èmi ni Alfa àti Omega,” ni Olúwa Ọlọ́run wí, “ẹni tí ó ń bẹ, tí ó ti wà, tí ó sì ń bọ̀ wá, alágbára.”
Ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí Ọmọ Ènìyàn
9Èmi, Johanu, arákùnrin yín àti alábápín pẹ̀lú yín nínú wàhálà àti ìjọba àti sùúrù tí ń bẹ nínú Jesu, wà ní erékúṣù tí a ń pè ní Patmo, nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti nítorí ẹ̀rí Jesu Kristi. 10Mo wà nínú Ẹ̀mí ní ọjọ́ Olúwa, mo sì gbọ́ ohùn ńlá kan lẹ́yìn mi, bí ìró ìpè, 11Ó ń wí pé, “Kọ́ ìwé rẹ̀, ohun tí ìwọ rí, kí ó sí fi ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ méje; sí Efesu, àti sí Smirna, àti sí Pargamu, àti sí Tiatira, àti sí Sardi, àti sí Filadelfia, àti sí Laodikea.”
12Mo sì yí padà láti wo ohùn tí ń bá mi sọ̀rọ̀. Nígbà tí mo yípadà, mo rí ọ̀pá fìtílà wúrà méje, 131.13: Da 7.13; 10.5.àti láàrín àwọn ọ̀pá fìtílà náà, ẹnìkan tí ó dàbí “ọmọ ènìyàn,” tí a wọ̀ ní aṣọ tí ó kanlẹ̀ dé ẹsẹ̀, tí a sì fi àmùrè wúrà dì ní ẹ̀gbẹ́. 14Orí rẹ̀ àti irun rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú, ó funfun bí yìnyín; ojú rẹ̀ sì dàbí, ọwọ́ iná. 151.15: El 1.24.Ẹsẹ̀ rẹ̀ sì dàbí idẹ dáradára, bí ẹni pé a dà á nínú ìléru; ohùn rẹ̀ sì dàbí ìró omi púpọ̀. 161.16: Ek 34.29.Ó sì ní ìràwọ̀ méje ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀; àti láti ẹnu rẹ̀ wá ni idà olójú méjì mímú ti jáde. Ojú rẹ̀ sì dàbí oòrùn tí ó ń fi agbára rẹ̀ hàn.
171.17: Isa 44.2,6.Nígbà tí mo rí i, mo wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ bí ẹni tí ó kú. Ó sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé mi, ó ń wí fún mi pé, “Má ṣe bẹ̀rù. Èmi ni ẹni ìṣáájú àti ẹni ìkẹyìn. 18Èmi ni ẹni tí ó ń bẹ láààyè, tí ó sì ti kú; sì kíyèsi i, èmi sì ń bẹ láààyè sí i títí láé! Mo sì ní kọ́kọ́rọ́ ikú àti ti ipò òkú lọ́wọ́.
19“Kọ̀wé nítorí náà ohun tí ìwọ ti rí, àti ti ohun tí ń bẹ, àti ti ohun tí yóò hù lẹ́yìn èyí; 20ohun ìjìnlẹ̀ tí ìràwọ̀ méje náà tí ìwọ rí ní ọwọ́ ọ̀tún mi, àti ọ̀pá wúrà fìtílà méje náà. Ìràwọ̀ méje ni àwọn angẹli ìjọ méje náà: àti ọ̀pá fìtílà méje náà ní àwọn ìjọ méje.
1以下是上帝賜給耶穌基督的啟示,讓祂把將來要發生的事指示祂的眾奴僕。因此,祂差遣天使告訴祂的奴僕約翰。 2約翰便為自己所看見的一切——上帝的道和耶穌基督做見證。 3那位宣讀這預言的人和那些聽見並遵守其中內容的人有福了,因為日期近了。
問候七教會
4-5我約翰寫信給你們亞細亞的七間教會。願昔在、今在、以後永在的上帝,祂寶座前的七靈1·4-5 「七靈」指的就是聖靈,數字七代表完全,不是說有七個靈。和耶穌基督賜給你們恩典和平安。耶穌基督是忠心的見證人,是首先從死裡復活的,是世上君王的首領。祂愛我們,用自己的血救我們脫離罪惡, 6使我們成為祭司的國度1·6 「成為祭司的國度」或譯「成為國度,做祭司」。來事奉祂的父上帝。願祂得到一切榮耀和權柄,一直到永永遠遠。阿們!
7看啊!祂要駕雲降臨,世人都要看見祂,包括曾經刺祂的人。地上的萬族都必因祂而哀哭。這事必定實現。阿們!
8主上帝說:「我是阿拉法,我是俄梅加1·8 「阿拉法」和「俄梅加」分別是希臘文第一個和最後一個字母,故此句意即「我是始,我是終」。,我是昔在、今在、以後永在的全能者。」
基督的顯現
9我約翰是你們的弟兄,在耶穌裡和你們患難與共、同享國度、一起忍耐。我因傳揚上帝的道、為主耶穌做見證而到了拔摩海島上。 10主日,我被聖靈感動,聽見身後有號角般響亮的聲音說: 11「把你所看見的寫在書上,然後送給以弗所、士每拿、別迦摩、推雅推喇、撒狄、非拉鐵非和老底嘉七間教會。」
12我轉身看究竟是誰在對我說話,我看見七個金燈臺, 13有一位好像人子耶穌的站在這些燈臺中間。祂長袍垂腳,金帶圍胸, 14頭與髮白如羊毛、潔白如雪,眼睛像火焰, 15雙腳像爐中冶煉過的銅一樣光亮,聲音如同洪濤之聲。 16祂右手拿著七顆星,口中吐出一把兩刃的利劍,面貌如烈日放光。
17我一看見祂,便仆倒在祂腳前,像死了一樣。祂把右手按在我身上,說:「不要害怕!我是首先的,我是末後的, 18我是永活者。我曾經死過,但看啊,我永永遠遠活著。我掌握死亡和陰間的鑰匙。 19所以,你要將所看見的一切——現在和將來要發生的事都記錄下來。 20你所看見在我右手中的七顆星和七個金燈臺的奧祕是,七顆星代表七間教會的天使1·20 「天使」或譯「信使」或「使者」,下同,可能指教會的守護天使,或者是教會的領袖。,七個燈臺代表七間教會。