Ìṣe àwọn Aposteli 1 – YCB & CCBT

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Ìṣe àwọn Aposteli 1:1-26

A mú Jesu lọ sí ọ̀run

11.1: Lk 1.1-4.Nínú ìwé mi ìṣáájú, Teofilu, ni mo ti kọ ní ti ohun gbogbo tí Jesu bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àti kọ́ 2títí ó fi di ọjọ́ tí a gbà á lọ sókè ọ̀run, lẹ́yìn tí ó ti ti ipa Ẹ̀mí Mímọ́ pàṣẹ fún àwọn aposteli tí ó yàn. 3Lẹ́yìn ìjìyà rẹ̀, ó fi ara rẹ̀ hàn fún wọn àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí tí ó dájú pé òun wà láààyè. Ó fi ara hàn wọ́n fún ogójì ọjọ́, ó sì sọ̀rọ̀ nípa ìjọba Ọlọ́run. 41.4: Lk 24.49.Ní àkókò kan bí ó sì ti ń jẹun pẹ̀lú wọn, ó pàṣẹ yìí fún wọn, “Ẹ má ṣe kúrò ní Jerusalẹmu, ṣùgbọ́n ẹ dúró de ìlérí tí Baba mi ṣe ìlérí, èyí tí ẹ̀yin tí gbọ́ lẹ́nu mi. 5Nítorí Johanu fi omi bamitiisi yín, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ díẹ̀ sí i, a o fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitiisi yín.”

6Nítorí náà, nígbà tí wọ́n sì péjọpọ̀, wọn bi í léèrè pé, “Olúwa, láti ìgbà yí lọ ìwọ yóò ha mú ìjọba padà fún Israẹli bí?”

7Ó sì wí fún wọn pé, “Kì í ṣe tiyín ni láti mọ àkókò tàbí ìgbà tí Baba ti yàn nípa àṣẹ òun tìkára rẹ̀. 81.8: Lk 24.48-49.Ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò gba agbára, nígbà tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé e yín; ẹ̀yin yóò sì máa ṣe ẹlẹ́rìí mi ni Jerusalẹmu, àti ní gbogbo Judea, àti ní Samaria, àti títí dé òpin ilẹ̀ ayé.”

91.9-12: Lk 24.50-53.Nígbà tí ó sì tí wí nǹkan wọ̀nyí, a gbà á sókè lójú wọn; ìkùùkuu àwọsánmọ̀ sì gbà á kúrò lójú wọn.

10Bí wọ́n sì ti tẹjúmọ́ ojú ọ̀run bí ó ti ń lọ sókè, lójijì, àwọn ọkùnrin méjì tí ó wọ aṣọ funfun dúró létí ọ̀dọ̀ wọn. 11Wọ́n sì wí pé, “Ẹ̀yin ara Galili, èéṣe tí ẹ̀yin fi dúró tí ẹ̀ ń wo ojú ọ̀run? Jesu yìí, tí a gbà sókè ọ̀run kúrò lọ́wọ́ yín, yóò padà bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ ti rí tí ó ń lọ sì ọ̀run.”

A yan Mattia Rọ́pò Judasi

12Lẹ́yìn náà ni wọ́n padà sí Jerusalẹmu láti orí òkè ti a ń pè ni olifi, tí ó tó ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ ìsinmi kan. 131.13: Mt 10.2-4; Mk 3.16-19; Lk 6.14-16.Nígbà tí wọn sì wọlé, wọn lọ sí iyàrá òkè, níbi tí wọ́n ń gbé. Àwọn tó wà níbẹ̀ ni:

Peteru, Jakọbu, Johanu àti Anderu;

Filipi àti Tomasi;

Bartolomeu àti Matiu;

Jakọbu ọmọ Alfeu, Simoni Sealoti, àti Judasi arákùnrin Jakọbu.

14Gbogbo àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn obìnrin àti Maria ìyá Jesu àti àwọn arákùnrin rẹ̀ fi ọkàn kan dúró láti máa gbàdúrà.

15Ní ọjọ́ wọ̀nyí ni Peteru sí dìde dúró láàrín àwọn ọmọ-ẹ̀yìn (iye àwọn ènìyàn wọ̀nyí jẹ́ ọgọ́fà) 161.16-19: Mt 27.3-10.ó wí pé, “Ẹ̀yin ará, ìwé mímọ́ kò lè ṣe kí ó má ṣẹ, èyí tí Ẹ̀mí Mímọ́ ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu Dafidi nípa Judasi, tí ó ṣe atọ́nà fún àwọn tí ó mú Jesu. 17Nítorí ọ̀kan nínú wa ni òun ń ṣe tẹ́lẹ̀, òun sì ní ìpín nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí.”

18(Judasi fi èrè àìṣòótọ́ rẹ̀ ra ilẹ̀ kan; nígbà tí ó sì ṣubú ni ògèdèǹgbé, ó bẹ́ ní agbede-méjì, gbogbo ìfun rẹ̀ sì tú jáde. 19Ó si di mí mọ̀ fún gbogbo àwọn ti ń gbé Jerusalẹmu; nítorí náà ni wọ́n fi ń pè ilẹ̀ náà ni Alkedama ní èdè wọn, èyí sì ni, Ilẹ̀ Ẹ̀jẹ̀.)

201.20: Sm 69.25; 109.8.Peteru sì wí pé, “Nítorí a ti kọ ọ́ nípa rẹ̀ nínú Ìwé Saamu pé,

“ ‘Jẹ́ ki ibùgbé rẹ̀ di ahoro,

kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé inú rẹ̀,’

àti,

“ ‘Ipò rẹ̀ ni kí ẹlòmíràn kí ó gbà.’

21Nítorí náà, ó di dandan láti yan ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ti ń bá wa rìn ni gbogbo àkókò tí Jesu Olúwa ń wọlé, tí ó sì jáde láàrín wa. 22Bẹ́ẹ̀ láti ìgbà bamitiisi Johanu títí ó fi di ọjọ́ náà ti a gbe é lọ sókè kúrò lọ́dọ̀ wa. Ó yẹ kí ọ̀kan nínú àwọn wọ̀nyí ṣe ẹlẹ́rìí àjíǹde rẹ̀ pẹ̀lú wa.”

23Wọn sì yan àwọn méjì, Josẹfu tí a ń pè ní Barsaba (ẹni tí a sọ àpèlé rẹ̀ ni Justu) àti Mattia. 24Wọn sì gbàdúrà, wọn sì wí pé, “Olúwa, ìwọ mọ ọkàn gbogbo ènìyàn, fihàn wá nínú àwọn méjì yìí, èwo ni ìwọ yàn 25kí ó lè gba ipò nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ aposteli yìí, èyí tí Judasi kúrò nínú rẹ̀, ki òun kí ó lè lọ sí ipò ti ara rẹ̀.” 26Wọ́n sì dìbò fún wọn; ìbò sí mú Mattia; a sì kà á mọ́ àwọn aposteli mọ́kànlá.

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

使徒行傳 1:1-26

應許聖靈降臨

1提阿非羅啊,在前一封信中,我從耶穌的生平和教導開始, 2一直談到祂藉著聖靈吩咐了自己選立的使徒,然後被接回天上。 3祂受難後用許多確鑿的證據證實自己活著,在四十天之內屢次向使徒顯現,與他們談論上帝的國。 4有一次,耶穌和他們在一起吃飯的時候,叮囑他們:「你們不要離開耶路撒冷,要在那裡等候我對你們說過的天父的應許。 5因為從前約翰用水給你們施洗,但再過幾天,你們要受聖靈的洗。」

6他們跟耶穌在一起的時候問祂:「主啊,你要在這時候復興以色列國嗎?」 7耶穌回答說:「天父照祂的權柄定下的時間、日期不是你們可以知道的。 8但聖靈降臨在你們身上後,你們必得到能力,在耶路撒冷猶太全境和撒瑪利亞,直到地極,作我的見證人。」

9耶穌說完這番話,就在他們眼前被提升天,被一朵雲彩接去,離開了他們的視線。 10祂上升時,他們都定睛望著天空,忽然有兩個身穿白衣的人站在他們身旁, 11說:「加利利人啊!你們為什麼站在這裡望著天空呢?這位離開你們被接到天上的耶穌,你們看見祂怎樣升天,將來祂還要怎樣回來。」

選立新使徒

12於是,他們從橄欖山回到耶路撒冷。橄欖山距離耶路撒冷不遠,約是安息日允許走的路程1·12 按猶太人的傳統,在安息日只能走約一公里遠。13他們進城後,來到樓上自己住的房間。當時有彼得約翰雅各安得烈腓力多馬巴多羅買馬太亞勒腓的兒子雅各、激進黨人西門雅各的兒子猶大14他們和耶穌的母親瑪麗亞、耶穌的弟弟們及幾個婦女在一起同心合意地恆切禱告。

15那時,約有一百二十人在聚會,彼得站起來說: 16「弟兄們,關於帶人抓耶穌的猶大,聖靈藉著大衛的口早已預言,這經文必須要應驗。 17這人原本是我們中間的一員,與我們同擔使徒的職分。」

18猶大用作惡得來的錢買了一塊田,他頭朝下栽倒在那裡,肚破腸流。 19這消息很快傳遍了耶路撒冷,當地人稱那塊田為「亞革大馬」,就是「血田」的意思。

20彼得繼續說:「詩篇上寫道,『願他的家園一片荒涼,無人居住』,又說,『願別人取代他的職位。』 21-22所以,我們必須另選一個人代替猶大,與我們一同為主耶穌的復活做見證。他必須是從主耶穌接受約翰的洗禮起一直到主升天,始終與我們在一起的人。」

23被提名的有別號巴撒巴又叫猶士都約瑟馬提亞兩個人。 24-25大家便禱告說:「主啊!你洞悉人的內心,求你指明這兩個人中你要揀選哪一個來擔負使徒的職分。猶大丟棄了這職分,去了他該去的地方。」 26然後,他們抽籤,抽中了馬提亞,就把他列入十一使徒中。