1ทิโมธี 1 – TNCV & YCB

Thai New Contemporary Bible

1ทิโมธี 1:1-20

1จดหมายฉบับนี้จากข้าพเจ้าเปาโลผู้เป็นอัครทูตของพระเยซูคริสต์ตามพระบัญชาของพระเจ้าพระผู้ช่วยให้รอดของเรา และของพระเยซูคริสต์ผู้ทรงเป็นความหวังของเรา

2ถึงทิโมธีลูกแท้ของข้าพเจ้าในความเชื่อ

ขอพระคุณ พระเมตตา และสันติสุขจากพระเจ้าพระบิดาและพระเยซูคริสต์องค์พระผู้เป็นเจ้าของเรามีแก่ท่าน

คำเตือนเกี่ยวกับผู้สอนผิด

3ตามที่ข้าพเจ้าได้กำชับท่านเมื่อข้าพเจ้าไปยังแคว้นมาซิโดเนียว่าให้ท่านอยู่ที่เอเฟซัส เพื่อท่านจะได้กำชับบางคนไม่ให้สอนหลักข้อเชื่อผิดๆ อีกต่อไป 4ทั้งไม่ให้หมกมุ่นกับนิยายปรัมปราและลำดับวงศ์ตระกูลอันไม่รู้จบ ซึ่งเป็นการคาดเดาแบบส่งเดชมากกว่าจะส่งเสริมพระราชกิจของพระเจ้าซึ่งเป็นไปโดยความเชื่อ 5เป้าหมายของการกำชับนี้คือความรักอันมาจากใจบริสุทธิ์ จากจิตสำนึกที่ดีและจากความเชื่ออย่างจริงใจ 6บางคนหลงเตลิดไปจากสิ่งเหล่านี้ หันไปพูดจาไร้สาระ 7พวกเขาอยากจะเป็นครูสอนบทบัญญัติทั้งๆ ที่ไม่รู้ว่าตนเองพูดอะไรหรือยืนยันอย่างหนักแน่นถึงเรื่องอะไร

8เรารู้อยู่ว่าบทบัญญัตินั้นดีหากใช้ในทางที่ถูก 9ซึ่งหมายความว่าบทบัญญัติไม่ได้มีขึ้นเพื่อผู้ชอบธรรม แต่มีขึ้นเพื่อคนชอบแหกกฎกับคนกบฏ คนอธรรมกับคนบาป คนไม่บริสุทธิ์กับคนไม่มีศาสนา คนฆ่าพ่อกับคนฆ่าแม่ ฆาตกร 10คนสำส่อนและคนรักร่วมเพศ เพื่อคนค้าทาสกับคนโกหก และคนให้การเท็จ และเพื่อสิ่งอื่นๆ อีกสารพัดที่ขัดกับคำสอนอันมีหลัก 11ซึ่งสอดคล้องกับข่าวประเสริฐอันรุ่งโรจน์ของพระเจ้าผู้ทรงเป็นที่สรรเสริญ คือข่าวประเสริฐที่ทรงมอบหมายให้ข้าพเจ้าประกาศนี้

พระคุณของพระเจ้าต่อเปาโล

12ข้าพเจ้าขอบพระคุณพระเยซูคริสต์องค์พระผู้เป็นเจ้าของเราผู้ทรงประทานกำลังแก่ข้าพเจ้า เพราะพระองค์ทรงเห็นว่าข้าพเจ้าสัตย์ซื่อจึงทรงแต่งตั้งข้าพเจ้าให้รับใช้พระองค์ 13ถึงแม้ว่าครั้งหนึ่งข้าพเจ้าเคยหมิ่นประมาทพระองค์ ข่มเหงผู้เชื่อและก่อความรุนแรง แต่พระองค์ทรงกรุณาข้าพเจ้าเพราะข้าพเจ้าได้ทำไปด้วยความไม่รู้และไม่เชื่อ 14พระคุณขององค์พระผู้เป็นเจ้าของเราได้หลั่งลงมาแก่ข้าพเจ้าอย่างเหลือล้น พร้อมด้วยความเชื่อและความรักซึ่งอยู่ในพระเยซูคริสต์

15ข้อความนี้เป็นความจริงซึ่งสมควรแก่การยอมรับโดยไม่มีข้อกังขา คือพระเยซูคริสต์เสด็จเข้ามาในโลกเพื่อช่วยคนบาปให้รอด และในบรรดาคนบาปข้าพเจ้าเป็นตัวร้ายที่สุด 16แต่เนื่องด้วยเหตุนี้เองจึงทรงกรุณาข้าพเจ้าผู้เป็นตัวร้ายที่สุดในบรรดาคนบาป เพื่อพระเยซูคริสต์จะได้ทรงสำแดงความอดกลั้นพระทัยอันไม่จำกัดให้เป็นตัวอย่างแก่คนทั้งปวงที่จะเชื่อในพระองค์และรับชีวิตนิรันดร์ 17บัดนี้ขอพระเกียรติและพระสิริมีแด่จอมราชันองค์นิรันดร์ผู้ทรงอมตะและเราไม่อาจมองเห็นได้ ผู้ทรงเป็นพระเจ้าแต่ผู้เดียวนั้นตลอดกาลสืบๆ ไปเป็นนิตย์ อาเมน

18ทิโมธีลูกชายของข้าพเจ้า ที่ข้าพเจ้ากำชับท่านเช่นนี้ก็สอดคล้องกับคำเผยพระวจนะที่เคยมีมาเกี่ยวกับท่าน เพื่อเมื่อท่านปฏิบัติตามท่านจะได้ต่อสู้อย่างเข้มแข็ง 19จงยึดมั่นในความเชื่อและจิตสำนึกอันดี บางคนละทิ้งข้อนี้ทำให้ความเชื่อของตนอับปาง 20ในหมู่คนเหล่านี้ได้แก่ฮีเมเนอัสกับอเล็กซานเดอร์ ซึ่งข้าพเจ้ามอบไว้แก่ซาตานเพื่อเขาจะได้เรียนรู้ที่จะไม่หมิ่นประมาทพระเจ้า

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Timotiu 1:1-20

1Paulu, aposteli Kristi Jesu gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Ọlọ́run Olùgbàlà wa, àti Jesu Kristi ìrètí wa,

2Sí Timotiu ọmọ mi nínú ìgbàgbọ́:

Oore-ọ̀fẹ́, àánú àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba àti Jesu Kristi Olúwa wa.

Ìkìlọ̀ lòdì sí olùkọ́ni èké ti òfin

3Bí mo ṣe rọ̀ yìn nígbà tí mò ń lọ sí Makedonia, ẹ dúró ní Efesu, kí ẹ lè dá àwọn ènìyàn kan lẹ́kun láti má ṣe kọ́ ni ní ẹ̀kọ́ èké mọ́ 4kí wọ́n má sì ṣe fiyèsí àwọn ìtàn asán, àti ìtàn ìran aláìlópin. Irú èyí máa ń mú iyàn jíjà wá dípò iṣẹ́ ìríjú Ọlọ́run èyí tí í ṣe ti ìgbàgbọ́. 5Ète àṣẹ náà ni ìfẹ́ ti ń jáde wá láti inú ọkàn mímọ́ àti ẹ̀rí ọkàn rere àti ìgbàgbọ́ àìṣẹ̀tàn. 6Àwọn ẹlòmíràn ti yapa kúrò tí wọ́n sì yà sápá kan sí ọ̀rọ̀ asán. 7Wọ́n ń fẹ́ ṣe olùkọ́ òfin; òye ohun tí wọ́n ń wí kò yé wọn tàbí ti ohun tí wọ́n ń fi ìgboyà tẹnumọ́.

8Ṣùgbọ́n àwa mọ̀ pé òfin dára, bí ènìyàn bá lò ó dáradára. 9Bí a ti mọ̀ pé, a kò ṣe òfin fún olódodo, bí kò ṣe fún àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, fún àwọn aláìmọ́ àti àwọn ẹlẹ́gàn, fún àwọn tí ń pa baba àti àwọn tí ń pa ìyá wọn àti àwọn apànìyàn, 10fún àwọn àgbèrè, fún àwọn aláyídà, fún àwọn onísòwò-ẹrú, fún àwọn èké, fún àwọn abúra èké, àti bí ohun mìíràn bá wà tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro. 11Gẹ́gẹ́ bí ìyìnrere ti ògo Ọlọ́run olùbùkún, tí a fi sí ìtọ́jú mi.

Oore-ọ̀fẹ́ Olúwa sí Paulu

12Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹni tí ó fún mi ní agbára, àní Kristi Jesu Olúwa wa, nítorí tí ó kà mí sí olóòtítọ́ ní yíyànmí sí iṣẹ́ rẹ̀. 13Bí mo tilẹ̀ jẹ́ asọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run rí, àti onínúnibíni àti ìkà ènìyàn, ṣùgbọ́n mo rí àánú gbà, nítorí tí mo ṣe é nínú àìmọ̀ àti àìgbàgbọ́. 14Oore-ọ̀fẹ́ Olúwa wa sì pọ̀ rékọjá pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́, tí ń bẹ nínú Kristi Jesu.

15Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, ó sì yẹ fún ìtẹ́wọ́gbà, pé Jesu Kristi wá sí ayé láti gba ẹlẹ́ṣẹ̀ là; nínú àwọn ẹni tí èmi jẹ́ búburú jùlọ. 16Ṣùgbọ́n nítorí èyí ni mo ṣe rí àánú gbà, pé lára mi, bí olórí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni kí Jesu Kristi fi gbogbo ìpamọ́ra rẹ̀ hàn bí àpẹẹrẹ fún àwọn tí yóò gbà á gbọ́ sí ìyè àìnípẹ̀kun ìkẹyìn. 17Ǹjẹ́ fún ọba ayérayé, àìdíbàjẹ́, àìrí, Ọlọ́run kan ṣoṣo, ni ọlá àti ògo wà fún láéláé. Àmín.

18Àṣẹ yìí ni mo pa fún ọ, Timotiu ọmọ mi, gẹ́gẹ́ bí ìsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí tó ó ti ṣáájú nípa rẹ̀, pé nípasẹ̀ wọ́n kí ìwọ lè máa ja ìjà rere; 19máa ní ìgbàgbọ́ àti ẹ̀rí ọkàn rere. Èyí ti àwọn mìíràn ti mú kúrò lọ́dọ̀ wọn tí wọ́n sì rí ọkàn ìgbàgbọ́ wọn. 20Nínú àwọn ẹni tí Himeneu àti Aleksanderu wà; àwọn tí mo ti fi lé Satani lọ́wọ́, kí a lè kọ́ wọn kí wọ́n má sọ̀rọ̀-òdì mọ́.