ปฐมกาล 20 – TNCV & YCB

Thai New Contemporary Bible

ปฐมกาล 20:1-18

อับราฮัมและอาบีเมเลค

(ปฐก.12:10-20; 26:1-11)

1อับราฮัมเดินทางจากที่นั่นเข้าไปในเขตเนเกบและตั้งถิ่นฐานอยู่ระหว่างเมืองคาเดชกับเมืองชูร์ เขาพักที่เมืองเกราร์ชั่วระยะหนึ่ง 2ที่นั่น อับราฮัมบอกใครต่อใครเกี่ยวกับซาราห์ภรรยาของเขาว่า “นางคือน้องสาวของข้าพเจ้า” กษัตริย์อาบีเมเลคแห่งเกราร์จึงส่งคนมารับนางไป

3แต่ในคืนหนึ่ง พระเจ้าเสด็จมาหาอาบีเมเลคในความฝันและตรัสกับเขาว่า “เจ้าจะต้องตายแน่! เพราะหญิงคนนั้นซึ่งเจ้าพามามีสามีแล้ว”

4แต่อาบีเมเลคยังไม่ได้เข้าหานางเลย เขาจึงทูลว่า “ข้าแต่องค์พระผู้เป็นเจ้า พระองค์จะทรงทำลายชนชาติที่ไม่ผิดหรือ? 5เขาไม่ได้บอกข้าพระองค์หรอกหรือว่า ‘นางเป็นน้องสาวของข้าพเจ้า’ และนางเองก็ไม่ได้พูดด้วยหรอกหรือว่า ‘เขาเป็นพี่ชายของข้าพเจ้า’? ข้าพระองค์ทำไปด้วยใจซื่อมือสะอาด”

6พระเจ้าตรัสกับเขาในความฝันว่า “ถูกแล้ว เรารู้ว่าเจ้าทำไปด้วยใจซื่อ เหตุนี้แหละเราจึงปกป้องเจ้าไว้ไม่ให้ทำบาปต่อเรา นี่เป็นเหตุที่เราไม่ปล่อยให้เจ้าแตะต้องตัวนาง 7บัดนี้จงคืนภรรยาของชายผู้นั้นกลับไป เพราะเขาเป็นผู้เผยพระวจนะ แล้วเขาจะอธิษฐานเผื่อเจ้า แล้วเจ้าจะรอดชีวิต แต่ถ้าเจ้าไม่ยอมคืนนาง เจ้าก็แน่ใจได้เลยว่าเจ้ากับคนของเจ้าทั้งหมดจะต้องตาย”

8เช้าตรู่วันรุ่งขึ้นอาบีเมเลคเรียกประชุมข้าราชสำนักทั้งหมดและแจ้งพวกเขาให้ทราบถึงเหตุการณ์ที่เกิดขึ้น คนทั้งปวงก็กลัวยิ่งนัก 9อาบีเมเลคจึงเรียกอับราฮัมมาถามว่า “ทำไมท่านทำกับเราอย่างนี้? เราทำผิดอะไรต่อท่านหรือ? ท่านจึงนำความผิดใหญ่หลวงมาตกกับเราและอาณาจักรของเรา? ท่านไม่ควรทำกับเราเช่นนี้เลย” 10อาบีเมเลคถามอับราฮัมว่า “เหตุใดท่านจึงทำเช่นนี้?”

11อับราฮัมตอบว่า “ข้าพเจ้าบอกตัวเองว่า ‘ผู้คนที่นี่ไม่เกรงกลัวพระเจ้าแน่ๆ พวกเขาจะฆ่าเราเพราะอยากได้ภรรยาของเรา’ 12นอกจากนี้นางก็เป็นน้องสาวของข้าพเจ้าจริงๆ นางเป็นน้องต่างมารดาของข้าพเจ้า และนางได้มาเป็นภรรยาของข้าพเจ้า 13เมื่อพระเจ้าให้ข้าพเจ้ารอนแรมออกจากครัวเรือนของบิดา ข้าพเจ้าบอกนางว่า ‘ถ้าเจ้ารักเรา ไม่ว่าไปที่ไหนขอให้เจ้าบอกว่า “เขาเป็นพี่ชายของฉัน” ’ ”

14อาบีเมเลคจึงยกฝูงแกะ ฝูงวัว และข้าทาสชายหญิงให้แก่อับราฮัม และคืนนางซาราห์ผู้เป็นภรรยาให้แก่เขา 15อาบีเมเลคกล่าวว่า “ดินแดนของเราอยู่ตรงหน้าท่าน จะอาศัยอยู่ที่ไหนก็ได้ตามใจชอบ”

16แล้วเขากล่าวกับซาราห์ว่า “เราขอมอบเงินหนึ่งพันเชเขล20:16 1 เชเขล คือเงินหนักประมาณ 11. 5 กรัม มีค่าเท่ากับค่าแรงสองเดือนแก่พี่ชายของเจ้า เป็นค่าทำขวัญต่อหน้าทุกคนที่อยู่กับเจ้า เจ้าไม่มีมลทินใดๆ เลย”

17จากนั้นอับราฮัมก็อธิษฐานต่อพระเจ้า และพระเจ้าก็ทรงรักษาอาบีเมเลค ชายา และทาสหญิงของเขา ให้พวกเขาสามารถมีบุตรได้อีกครั้งหนึ่ง 18เพราะองค์พระผู้เป็นเจ้าทรงให้ผู้หญิงทุกคนในครัวเรือนของอาบีเมเลคเป็นหมัน ด้วยเหตุจากนางซาราห์ภรรยาของอับราฮัม

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 20:1-18

Abrahamu àti Abimeleki

1Abrahamu sì kó kúrò níbẹ̀ lọ sí ìhà gúúsù ó sì ń gbé ní agbede-méjì Kadeṣi àti Ṣuri; ó sì gbé ní ìlú Gerari fún ìgbà díẹ̀. 220.2: Gẹ 12.13; 26.7.Abrahamu sì sọ ní ti Sara aya rẹ̀ níbẹ̀ pé, “Arábìnrin mi ni.” Abimeleki ọba Gerari sì ránṣẹ́ mú Sara wá sí ààfin rẹ̀.

3Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tọ Abimeleki wá ní ojú àlá lọ́jọ́ kan, ó sì wí fún un pé, “Kíyèsi, kò sí ohun tí o fi sàn ju òkú lọ, nítorí obìnrin tí ìwọ mú sọ́dọ̀ n nì, aya ẹni kan ní íṣe.”

4Ṣùgbọ́n Abimeleki kò tí ìbá obìnrin náà lòpọ̀, nítorí náà ó wí pé, “Olúwa ìwọ yóò run orílẹ̀-èdè aláìlẹ́bi bí? 5Ǹjẹ́ òun kò sọ fún mi pé, ‘Arábìnrin mi ni,’ obìnrin náà pẹ̀lú sì sọ pé, ‘Arákùnrin mí ni’? Ní òtítọ́ pẹ̀lú ọkàn mímọ́ àti ọwọ́ mímọ́, ni mo ṣe èyí.”

6Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún un nínú àlá náà pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ pé pẹ̀lú òtítọ́ inú ni ìwọ ṣe èyí, èyí ni mo fi pa ọ́ mọ́ tí ń kò jẹ́ kí o ṣẹ̀ sí mi. Ìdí nìyí tí n kò fi jẹ́ kí o ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin náà. 7Nísinsin yìí, dá aya ọkùnrin náà padà, nítorí pé wòlíì ni, yóò sì gbàdúrà fún ọ, ìwọ yóò sì yè. Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá dá a padà, mọ̀ dájú pé ìwọ àti gbogbo ẹni tí í ṣe tìrẹ yóò kú.”

8Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ kejì, Abimeleki pe gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀. Nígbà tí ó sì sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún wọn, ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi. 9Nígbà náà ni Abimeleki pe Abrahamu ó sì wí fún un pé, “Èwo ni èyí tí ìwọ ṣe sí wa yìí? Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ ọ́ tí ìwọ fi mú ìdálẹ́bi ńlá wá sí orí èmi àti ìjọba mi? Kò yẹ kí ìwọ hu irú ìwà yìí sí mi.” 10Abimeleki sì bi Abrahamu pé, “Kín ló dé tí ìwọ fi ṣe èyí?”

11Abrahamu sì dáhùn pé, “Mo ṣe èyí nítorí mo rò nínú ara mi pé, ẹ̀yin tí ẹ wà níhìn-ín, ẹ kò bẹ̀rù Ọlọ́run, pé, ẹ sì le pa mí nítorí aya mi. 12Yàtọ̀ fún ìyẹn, òtítọ́ ni pé arábìnrin mi ni. Ọmọ baba kan ni wá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a kì í ṣe ọmọ ìyá kan. Mo sì fẹ́ ẹ ní aya. 13Nígbà tí Ọlọ́run sì mú mi rìn kiri kúrò ní ilé baba mi, mo wí fún un pé, ‘Èyí ni ọ̀nà tí ó lè gbà fihàn pé ó fẹ́ràn mi. Gbogbo ibi tí a bá dé máa sọ pé, “Arákùnrin rẹ ni mí.” ’ ”

14Nígbà náà ni Abimeleki mú àgùntàn àti màlúù wá, àti ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin, ó sì kó wọn fún Abrahamu, ó sì dá Sara aya rẹ̀ padà fún un. 15Abimeleki sì tún wí fún un pé, “Gbogbo ilẹ̀ mí nìyí níwájú rẹ, máa gbé ní ibikíbi tí o fẹ́ níbẹ̀.”

16Abimeleki sì wí fún Sara pé, “Mo fi ẹgbẹ̀rún (1,000) owó ẹyọ fàdákà fún arákùnrin rẹ. Èyí ni owó ìtánràn ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọ níwájú gbogbo ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ àti pé, a dá ọ láre pátápátá.”

17Nígbà náà, Abrahamu gbàdúrà sí Ọlọ́run, Ọlọ́run sì wo Abimeleki àti aya rẹ̀ àti àwọn ẹrúbìnrin rẹ̀ sàn. Wọ́n sì tún ń bímọ, 18nítorí Olúwa ti sé gbogbo ará ilé Abimeleki nínú nítorí Sara aya Abrahamu.