ปฐมกาล 15 – TNCV & YCB

Thai New Contemporary Bible

ปฐมกาล 15:1-21

พระเจ้าทรงทำพันธสัญญากับอับราม

1ต่อมาองค์พระผู้เป็นเจ้ามีพระดำรัสมาถึงอับรามทางนิมิตว่า

“อย่ากลัวเลย อับรามเอ๋ย

เราเป็นโล่ของเจ้า15:1 หรือเราเป็นผู้ครอบครองเหนือเจ้า

เป็นบำเหน็จยิ่งใหญ่ของเจ้า15:1 หรือบำเหน็จของเจ้าจะยิ่งใหญ่

2แต่อับรามทูลว่า “ข้าแต่พระยาห์เวห์องค์เจ้าชีวิต พระองค์จะประทานบำเหน็จให้แก่ข้าพระองค์ไปทำไมในเมื่อข้าพระองค์ยังไม่มีลูกเลย และผู้ที่จะรับมรดกของข้าพระองค์15:2 ในภาษาฮีบรูวลีนี้มีความหมายไม่ชัดเจนก็คือเอลีเยเซอร์แห่งดามัสกัส?” 3และอับรามทูลว่า “พระองค์ไม่ได้ประทานลูกให้ข้าพระองค์เลย ฉะนั้นคนรับใช้ในครัวเรือนจะเป็นผู้รับมรดกของข้าพระองค์”

4แล้วองค์พระผู้เป็นเจ้ามีพระดำรัสมาถึงอับรามว่า “ชายผู้นี้จะไม่ได้เป็นผู้รับมรดกของเจ้า แต่ลูกที่เกิดจากตัวเจ้าเองจะเป็นผู้รับมรดกของเจ้า” 5พระองค์ทรงนำเขาออกมาข้างนอกและตรัสว่า “จงเงยหน้าขึ้นดูฟ้าแล้วนับดวงดาว หากเจ้าสามารถนับได้” แล้วพระองค์ตรัสกับเขาว่า “เผ่าพันธุ์15:5 หรือเมล็ดพันธุ์ของเจ้าจะเป็นเช่นนั้นแหละ”

6อับรามเชื่อองค์พระผู้เป็นเจ้าและพระองค์ทรงนับว่าเขาเป็นคนชอบธรรมเพราะความเชื่อนี้

7พระองค์ตรัสกับเขาด้วยว่า “เราคือพระยาห์เวห์องค์พระผู้เป็นเจ้าผู้นำเจ้าออกจากเมืองเออร์ของชาวเคลเดีย เพื่อจะยกดินแดนนี้ให้เป็นกรรมสิทธิ์ของเจ้า”

8แต่อับรามทูลว่า “ข้าแต่พระยาห์เวห์องค์เจ้าชีวิต ข้าพระองค์จะรู้ได้อย่างไรว่าดินแดนนี้จะเป็นกรรมสิทธิ์ของข้าพระองค์?”

9ดังนั้นพระยาห์เวห์ จึงตรัสกับเขาว่า “จงนำวัวตัวเมีย แพะ และแกะผู้ ซึ่งแต่ละอย่างมีอายุสามปี พร้อมกับนกเขาและนกพิราบรุ่นอย่างละตัวมาให้เรา”

10อับรามนำสัตว์เหล่านี้มาถวาย โดยผ่าเป็นสองซีก แต่ละซีกวางไว้ตรงข้ามกัน ส่วนนกนั้นเขาไม่ได้ผ่า 11แล้วฝูงเหยี่ยวโฉบมาที่ซากสัตว์เหล่านั้น แต่อับรามไล่มันไปเสีย

12ขณะดวงอาทิตย์กำลังลับขอบฟ้า อับรามหลับสนิท ความมืดทึบอันน่าหวาดกลัวแผ่ปกคลุมเขา 13แล้วองค์พระผู้เป็นเจ้าตรัสกับอับรามว่า “จงรู้แน่เถิดว่า ลูกหลานของเจ้าจะเป็นคนต่างด้าวในต่างแดน และจะตกเป็นทาสถูกกดขี่ข่มเหงสี่ร้อยปี 14แต่เราจะลงโทษชนชาติที่เขาเป็นทาสรับใช้ และหลังจากนั้นเขาจะออกมาพร้อมด้วยทรัพย์สมบัติมากมาย 15ส่วนเจ้าจะตามบรรพบุรุษไปอย่างสงบสุขและถูกฝังเมื่อชรามากแล้ว 16ในชั่วอายุที่สี่ ลูกหลานของเจ้าจะกลับมาที่นี่ เพราะขณะนี้บาปของชาวอาโมไรต์ยังไม่ถึงที่สุดที่เราจะลงโทษพวกเขา”

17เมื่อดวงอาทิตย์ลับไปและความมืดเข้ามาปกคลุม ก็มีกระถางไฟควันโขมงและคบเพลิงที่ลุกโชติช่วงปรากฏขึ้น และเคลื่อนผ่านสัตว์เหล่านั้น 18ในวันนั้นองค์พระผู้เป็นเจ้าทรงทำพันธสัญญากับอับรามว่า “เราจะมอบดินแดนนี้แก่ลูกหลานของเจ้า ตั้งแต่ลำน้ำแห่งอียิปต์จดแม่น้ำใหญ่คือยูเฟรติส 19คือดินแดนของชาวเคไนต์ ชาวเคนัส ชาวคัดโมไนต์ 20ชาวฮิตไทต์ ชาวเปริสซี ชาวเรฟาอิม 21ชาวอาโมไรต์ ชาวคานาอัน ชาวเกอร์กาชี และชาวเยบุส”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 15:1-21

Májẹ̀mú Ọlọ́run pẹ̀lú Abramu

1Lẹ́yìn èyí, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Abramu wá lójú ìran pé,

“Abramu má ṣe bẹ̀rù.

Èmi ni ààbò rẹ,

Èmi sì ni èrè ńlá rẹ.”

2Ṣùgbọ́n Abramu wí pé, “Olúwa Olódùmarè, kí ni ìwọ yóò fi fún mi níwọ̀n ìgbà tí èmi kò bímọ, Elieseri ará Damasku ni yóò sì jogún mi,” 3Abramu sì tún tẹ̀síwájú pé, “Ìwọ kò fún mi ní ọmọ, nítorí náà ẹrú nínú ilé mi sì ni yóò jẹ́ àrólé mi.”

415.4: Gẹ 17.16,21; 18.10; 21.2.Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tún tọ̀ ọ́ wá pé, “Ọkùnrin yìí kọ́ ni yóò jẹ́ àrólé rẹ bí kò ṣe ọmọ tí ìwọ bí fúnra rẹ̀ ni yóò jẹ́ àrólé rẹ.” 515.5: Ro 4.18; Hb 11.12.Olúwa sì mú Abramu jáde sí ìta ó sì wí fún un pé, “Gbé ojú sókè sí ọ̀run kí o sì ka àwọn ìràwọ̀ bí ó bá ṣe pé ìwọ le è kà wọ́n.” Ó sì wí fun un pé, “Nítorí náà, báyìí ni irú-ọmọ rẹ yóò rí.”

615.6: Ro 4.3; Ga 3.6; Jk 2.23.Abramu gba Olúwa gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un.

7Ó sì tún wí fún un pé, “Èmi ni Olúwa tí ó mú ọ jáde láti Uri ti Kaldea láti fún ọ ní ilẹ̀ yìí láti jogún.”

8Ṣùgbọ́n Abramu wí pé, “Olúwa Olódùmarè, báwo ni mo ṣe lè mọ̀ pé ilẹ̀ náà yóò jẹ́ ohun ìní mi?”

9Nítorí náà, Olúwa wí fún un pé, “Mú abo màlúù, ewúrẹ́ àti àgbò ọlọ́dún mẹ́ta mẹ́ta wá, àti àdàbà kan àti ọmọ ẹyẹlé kan.”

10Abramu sì mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí wá, ó sì là wọ́n sí méjì méjì, ó sì fi ẹ̀là èkínní kọjú sí èkejì, ṣùgbọ́n kò la àwọn ẹyẹ ní tiwọn. 11Àwọn ẹyẹ igún sì ń wá sórí òkú ẹran náà, Abramu sì ń lé wọn.

1215.12: Jb 4.13,14.Bí oòrùn ti ń wọ̀, Abramu sùn lọ fọnfọn, òkùnkùn biribiri tí ó kún fún ẹ̀rù sì bò ó. 1315.13: Ek 1.1-14; Ap 7.6.15.13-14: Ek 12.40,41; Ap 7.7.Nígbà náà ni Olúwa wí fún Abramu pé, “Mọ èyí dájú pé, irú-ọmọ rẹ yóò ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì, wọn ó sì sọ wọn di ẹrú, wọn ó sì pọ́n wọn lójú fún irinwó (400) ọdún. 14Ṣùgbọ́n orílẹ̀-èdè náà tí wọn yóò máa sìn, ni èmi ó dá lẹ́jọ́, lẹ́yìn náà ni wọn ó sì jáde pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀. 15Ṣùgbọ́n ìwọ yóò tọ àwọn baba rẹ lọ ni àlàáfíà, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò sì di arúgbó kí a tó gbé ọ sin. 16Ní ìran kẹrin àwọn ìran rẹ yóò padà wá sí ibi. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ará Amori kò ì tí ì kún òsùwọ̀n.”

17Nígbà tí oòrùn wọ̀ tí ilẹ̀ sì ṣú, ìkòkò iná tí ń ṣèéfín àti ọwọ́ iná sì ń kọjá láàrín ẹ̀là ẹran náà. 1815.18: Gẹ 17.2,7,9-14,21.Ní ọjọ́ náà gan an ni Olúwa dá májẹ̀mú pẹ̀lú Abramu, ó sì wí pé, “Àwọn ìran rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún, láti odò Ejibiti dé odò ńlá Eufurate: 19ilẹ̀ àwọn ará Keni, àti ti ará Kenissiti, àti ará Kadmoni, 20àti ti ará Hiti, àti ti ará Peresi, àti ti ará Refaimu. 21Àti ti ará Amori, àti ti ará Kenaani, àti ti ará Girgaṣi àti ti ará Jebusi.”