กันดารวิถี 1 – TNCV & YCB

Thai New Contemporary Bible

กันดารวิถี 1:1-54

สำมะโนประชากร

1วันที่หนึ่งเดือนที่สองของปีที่สอง หลังจากชาวอิสราเอลออกจากประเทศอียิปต์ องค์พระผู้เป็นเจ้าตรัสกับโมเสสในเต็นท์นัดพบที่ถิ่นกันดารซีนายว่า 2“จงสำรวจสำมะโนประชากรชุมชนอิสราเอลทั้งหมด แยกเป็นรายตระกูลและครอบครัว ให้ทำบัญชีรายชื่อผู้ชายทุกคน 3เจ้ากับอาโรนจะต้องนับจำนวนผู้ชายในอิสราเอลที่มีอายุยี่สิบปีขึ้นไปซึ่งสามารถทำหน้าที่ในกองทัพได้ โดยแยกพวกเขาออกเป็นหมู่เหล่า 4ผู้นำจากแต่ละเผ่า เผ่าละหนึ่งคนจะเป็นผู้ช่วยของเจ้า 5ต่อไปนี้เป็นรายชื่อของผู้นำที่จะมาช่วยเจ้าได้แก่

จากเผ่ารูเบนคือ เอลีซูร์บุตรเชเดเออร์

6จากเผ่าสิเมโอนคือ เชลูมิเอลบุตรศูริชัดดัย

7จากเผ่ายูดาห์คือ นาห์โชนบุตรอัมมีนาดับ

8จากเผ่าอิสสาคาร์คือ เนธันเอลบุตรศุอาร์

9จากเผ่าเศบูลุนคือ เอลีอับบุตรเฮโลน

10จากบุตรของโยเซฟคือ

จากเผ่าเอฟราอิมคือ เอลีชามาบุตรอัมมีฮูด

จากเผ่ามนัสเสห์คือ กามาลิเอลบุตรเปดาซูร์

11จากเผ่าเบนยามินคือ อาบีดันบุตรกิเดโอนี

12จากเผ่าดานคือ อาหิเยเซอร์บุตรอัมมีชัดดัย

13จากเผ่าอาเชอร์คือ ปากีเอลบุตรโอคราน

14จากเผ่ากาดคือ เอลียาสาฟบุตรเดอูเอล

15จากเผ่านัฟทาลีคือ อาหิราบุตรเอนัน”

16คนเหล่านี้ได้รับการแต่งตั้งจากชุมชนให้เป็นผู้นำเผ่าต่างๆ ตามบรรพบุรุษ พวกเขาเป็นหัวหน้าตระกูลต่างๆ ของอิสราเอล

17โมเสสและอาโรนได้นำชายเหล่านี้ตามบัญชีรายชื่อที่ให้ไว้มา 18และได้เรียกประชุมประชากรทั้งหมดในวันที่หนึ่งเดือนที่สอง ประชาชนได้ระบุบรรพบุรุษของตนตามตระกูลและครอบครัว และได้ขึ้นบัญชีรายชื่อผู้ชายที่มีอายุยี่สิบปีขึ้นไปทีละคน 19ตามที่องค์พระผู้เป็นเจ้าทรงบัญชาโมเสส ดังนั้นเขาจึงนับจำนวนคนเหล่านี้ในถิ่นกันดารซีนาย

20จากวงศ์วานของรูเบนบุตรชายหัวปีของอิสราเอล

ผู้ชายอายุยี่สิบปีขึ้นไปทุกคนที่ออกรบได้ ขึ้นบัญชีรายชื่อทีละคนตามตระกูลและตามครอบครัว 21จำนวนพลจากเผ่ารูเบน 46,500 คน

22จากวงศ์วานของสิเมโอน

ผู้ชายอายุยี่สิบปีขึ้นไปทุกคนที่ออกรบได้ ขึ้นบัญชีรายชื่อทีละคนตามตระกูลและตามครอบครัว 23จำนวนพลจากเผ่าสิเมโอน 59,300 คน

24จากวงศ์วานของกาด

ผู้ชายอายุยี่สิบปีขึ้นไปทุกคนที่ออกรบได้ ขึ้นบัญชีรายชื่อตามตระกูลและตามครอบครัว 25จำนวนพลจากเผ่ากาด 45,650 คน

26จากวงศ์วานของยูดาห์

ผู้ชายอายุยี่สิบปีขึ้นไปทุกคนที่ออกรบได้ ขึ้นบัญชีรายชื่อตามตระกูลและตามครอบครัว 27จำนวนพลจากเผ่ายูดาห์ 74,600 คน

28จากวงศ์วานของอิสสาคาร์

ผู้ชายอายุยี่สิบปีขึ้นไปทุกคนที่ออกรบได้ ขึ้นบัญชีรายชื่อตามตระกูลและตามครอบครัว 29จำนวนพลจากเผ่าอิสสาคาร์ 54,400 คน

30จากวงศ์วานของเศบูลุน

ผู้ชายอายุยี่สิบปีขึ้นไปทุกคนที่ออกรบได้ ขึ้นบัญชีรายชื่อตามตระกูลและตามครอบครัว 31จำนวนพลจากเผ่าเศบูลุน 57,400 คน

32จากวงศ์วานของเอฟราอิมบุตรโยเซฟ

ผู้ชายอายุยี่สิบปีขึ้นไปทุกคนที่ออกรบได้ ขึ้นบัญชีรายชื่อตามตระกูลและตามครอบครัว 33จำนวนพลจากเผ่าเอฟราอิม 40,500 คน

34จากวงศ์วานของมนัสเสห์บุตรโยเซฟ

ผู้ชายอายุยี่สิบปีขึ้นไปทุกคนที่ออกรบได้ ขึ้นบัญชีรายชื่อตามตระกูลและตามครอบครัว 35จำนวนพลจากเผ่ามนัสเสห์ 32,200 คน

36จากวงศ์วานของเบนยามิน

ผู้ชายอายุยี่สิบปีขึ้นไปทุกคนที่ออกรบได้ ขึ้นบัญชีรายชื่อตามตระกูลและตามครอบครัว 37จำนวนพลจากเผ่าเบนยามิน 35,400 คน

38จากวงศ์วานของดาน

ผู้ชายอายุยี่สิบปีขึ้นไปทุกคนที่ออกรบได้ ขึ้นบัญชีรายชื่อตามตระกูลและตามครอบครัว 39จำนวนพลจากเผ่าดาน 62,700 คน

40จากวงศ์วานของอาเชอร์

ผู้ชายอายุยี่สิบปีขึ้นไปทุกคนที่ออกรบได้ ขึ้นบัญชีรายชื่อตามตระกูลและตามครอบครัว 41จำนวนพลจากเผ่าอาเชอร์ 41,500 คน

42จากวงศ์วานของนัฟทาลี

ผู้ชายอายุยี่สิบปีขึ้นไปทุกคนที่ออกรบได้ ขึ้นบัญชีรายชื่อตามตระกูลและตามครอบครัว 43จำนวนพลจากเผ่านัฟทาลี 53,400 คน

44ทั้งหมดนี้คือจำนวนผู้ชายที่โมเสส อาโรนและผู้นำทั้งสิบสองเผ่าของอิสราเอลได้นับไว้ แต่ละคนเป็นตัวแทนครอบครัวของเขา 45คือผู้ชายอิสราเอลอายุยี่สิบปีขึ้นไปทุกคนที่ร่วมทัพได้ ได้ถูกนับไว้ตามครอบครัวของเขา 46รวมทั้งสิ้น 603,550 คน

47แต่จำนวนนี้ไม่รวมคนเผ่าเลวี 48องค์พระผู้เป็นเจ้าได้ตรัสกับโมเสสไว้ว่า 49“ยกเว้นเผ่าเลวี ไม่ต้องลงจำนวนในสำมะโนประชากรของอิสราเอล 50แต่จงตั้งคนเลวีให้รับผิดชอบงานเกี่ยวกับพลับพลาแห่งพันธสัญญา พวกเขาต้องเคลื่อนย้ายพลับพลา ดูแลเครื่องใช้และทุกสิ่งที่อยู่ในพลับพลา พวกเขาต้องตั้งเต็นท์อาศัยอยู่รอบพลับพลา 51เมื่อใดก็ตามที่มีการเคลื่อนย้ายพลับพลา คนเลวีจะเป็นผู้ปลดพลับพลาลงหรือตั้งขึ้นใหม่ ผู้อื่นที่เข้าใกล้พลับพลาจะต้องถูกประหารชีวิต 52ชาวอิสราเอลจะต้องตั้งเต็นท์ของตนเป็นหมู่เหล่า แต่ละคนอยู่ในค่ายของตนภายใต้ธงประจำกอง 53ส่วนคนเลวีจะต้องตั้งเต็นท์รอบพลับพลาแห่งพันธสัญญาเพื่อพระพิโรธของพระเจ้าจะไม่ตกแก่ชุมชนอิสราเอล ให้คนเลวีรับผิดชอบดูแลพลับพลาแห่งพันธสัญญา”

54ประชากรอิสราเอลก็ปฏิบัติตามทุกสิ่งที่องค์พระผู้เป็นเจ้าตรัสสั่งโมเสส

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Numeri 1:1-54

Ìkànìyàn

11.1-46: Nu 26.1-51.Olúwa bá Mose sọ̀rọ̀ ní aginjù Sinai nínú àgọ́ àjọ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kejì ní ọdún kejì tí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, ó wí pé, 2“Ka gbogbo àgbájọ ènìyàn Israẹli nípa ẹbí wọn, àti nípa ìdílé baba wọn, to orúkọ wọn olúkúlùkù ọkùnrin ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. 3Ìwọ àti Aaroni ni kí ẹ kà gbogbo ọmọkùnrin Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn láti ọmọ ogún ọdún sókè, àwọn tí ó tó lọ sójú ogun. 4Kí ẹ mú ọkùnrin kọ̀ọ̀kan láti inú olúkúlùkù ẹ̀yà kí ó sì wá pẹ̀lú yín, kí olúkúlùkù jẹ́ olórí ilé àwọn baba rẹ̀.

5“Orúkọ àwọn ọkùnrin tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ nìyí:

“Láti ọ̀dọ̀ Reubeni, Elisuri ọmọ Ṣedeuri.

6Láti ọ̀dọ̀ Simeoni, Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai.

7Láti ọ̀dọ̀ Juda, Nahiṣoni ọmọ Amminadabu.

8Láti ọ̀dọ̀ Isakari, Netaneli ọmọ Suari.

9Láti ọ̀dọ̀ Sebuluni, Eliabu ọmọ Heloni.

10Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Josẹfu:

láti ọ̀dọ̀ Efraimu, Eliṣama ọmọ Ammihudu.

Láti ọ̀dọ̀ Manase, Gamalieli ọmọ Pedasuri.

11Láti ọ̀dọ̀ Benjamini, Abidani ọmọ Gideoni.

12Láti ọ̀dọ̀ Dani, Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai.

13Láti ọ̀dọ̀ Aṣeri, Pagieli ọmọ Okanri.

14Láti ọ̀dọ̀ Gadi, Eliasafu ọmọ Deueli.

15Láti ọ̀dọ̀ Naftali, Ahira ọmọ Enani.”

16Àwọn wọ̀nyí ni wọ́n yàn nínú àwùjọ ènìyàn, olórí àwọn ẹ̀yà baba wọn. Àwọn ni olórí àwọn ẹbí Israẹli.

17Mose àti Aaroni mú àwọn ènìyàn tí a dárúkọ wọ̀nyí 18wọ́n sì pe gbogbo àwùjọ ènìyàn Israẹli jọ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kejì. Àwọn ènìyàn sì dárúkọ baba ńlá wọn nípa ẹbí àti ìdílé wọn. Wọ́n sì ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn ọmọkùnrin ní ọ̀kọ̀ọ̀kan láti ọmọ ogún ọdún sókè, 19gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe kà wọ́n nínú aginjù Sinai.

20Láti ìran Reubeni tí í ṣe àkọ́bí Israẹli, gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn, lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 21Àwọn tí a kà ní ẹ̀yà Reubeni jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàlélógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (46,500).

22Láti ìran Simeoni, gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n kà, wọ́n sì to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 23Iye àwọn tí á kà nínú ẹ̀yà Simeoni jẹ́ ẹgbàá mọ́kàndínlọ́gbọ̀n ó lé ọ̀ọ́dúnrún (59,300).

24Láti ìran Gadi, gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ẹbí àti ìdílé wọn. 25Iye àwọn tí a kà nínú ẹ̀yà Gadi jẹ́ ẹgbàá méjìlélógún ó lé àádọ́talélẹ́gbẹ̀jọ (45,650).

26Láti ìran Juda, gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n le lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 27Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Juda jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínlógójì ó lé ẹgbẹ̀ta (74,600).

28Láti ìran Isakari, gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n le lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 29Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Isakari jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ó lé irinwó (54,400).

30Láti ìran Sebuluni, gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 31Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Sebuluni jẹ́ ẹgbàá méjìdínlọ́gbọ̀n ó lé egbèje (57,400).

32Láti inú àwọn ọmọ Josẹfu.

Láti ìran Efraimu, gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 33Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Efraimu jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (40,500).

34Láti ìran Manase, gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 35Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Manase jẹ́ ẹgbàá ẹẹ́rìndínlógún ó lé igba (32,200).

36Láti ìran Benjamini, gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 37Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Benjamini jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínlógún ó lé egbèje (35,400).

38Láti ìran Dani, gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 39Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Dani jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélọ́gbọ̀n ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (62,700).

40Láti ìran Aṣeri, gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n le lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 41Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Aṣeri jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (41,500).

42Láti ìran Naftali, gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún ó lé, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 43Iye àwọn tí a kà nínú ẹ̀yà Naftali jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó lé egbèje (53,400).

44Wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn tí Mose àti Aaroni kà, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn olórí méjìlá fún Israẹli, tí ẹnìkọ̀ọ̀kan ṣojú fún ìdílé rẹ̀. 45Gbogbo ọmọkùnrin Israẹli tó jẹ́ ọmọ ogún ọdún sókè, tó sì lè lọ sójú ogun ni wọ́n kà gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn. 46Àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé egbèjìdínlógún dín làádọ́ta (603,550).

471.47: Nu 2.33.A kò ka àwọn ìdílé ẹ̀yà Lefi mọ́ àwọn ìyókù. 48Nítorí Olúwa ti sọ fún Mose pé, 49“Ìwọ kò gbọdọ̀ ka ẹ̀yà Lefi, tàbí kí o kà wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Israẹli. 501.50-53: Nu 3.5-8,21-37; 4.1-33; 8.19; 18.3,4,23.Dípò èyí yan àwọn ọmọ Lefi láti jẹ́ alábojútó àgọ́ ẹ̀rí, lórí gbogbo ohun èlò àti ohun gbogbo tó jẹ́ ti àgọ́ ẹ̀rí. Àwọn ni yóò máa gbé àgọ́ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, wọn ó máa mójútó o, kí wọn ó sì máa pàgọ́ yí i ká. 51Ìgbàkígbà tí àgọ́ yóò bá tẹ̀síwájú, àwọn ọmọ Lefi ni yóò tú palẹ̀, nígbàkígbà tí a bá sì tún pa àgọ́, àwọn ọmọ Lefi náà ni yóò ṣe é. Àlejò tó bá súnmọ́ tòsí ibẹ̀, pípa ni kí ẹ pa á 52kí àwọn ọmọ Israẹli pa àgọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn olúkúlùkù ní ibùdó tirẹ̀ lábẹ́ ọ̀págun tirẹ̀. 53Àwọn ọmọ Lefi yóò jẹ́ alábojútó àti olùtọ́jú àgọ́ ẹ̀rí náà, kí ìbínú má ba à sí lára ìjọ àwọn ọmọ Israẹli; kí àwọn ọmọ Lefi sì máa ṣe ìtọ́jú àgọ́ ẹ̀rí náà.”

54Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.