La Parola è Vita

Matteo 16:1-28

«Vogliamo un miracolo»

1Un giorno i Farisei e i Sadducei vennero per verificare ciò che Gesù sosteneva, cioè di essere il Messia, chiedendogli di mostrar loro un segno dal cielo.

2-3Gesù rispose: «Voi siete in grado di prevedere il tempo dal cielo. Il cielo rosso stasera indica che domani il tempo sarà buono; se invece è rosso di mattina vuol dire che sarà brutto tempo per tutto il giorno. Ebbene, sapete interpretare lʼaspetto del cielo, eppure non siete capaci di capire i segni ben comprensibili dei tempi! 4Questo popolo malvagio e incredulo mi sta chiedendo un segno straordinario nel cielo, ma non gli sarà dato nessun altro segno, eccetto il segno di Giona!» E Gesù si allontanò da loro.

5Giunti al di là del lago, i discepoli si accorsero di aver dimenticato di portare del cibo.

6«Fate attenzione!» li mise in guardia Gesù, «diffidate del lievito dei Farisei e dei Sadducei!»

7I discepoli pensavano che stesse riferendosi al fatto che avevano dimenticato di portare il pane.

8Gesù sapeva ciò che stavano pensando e disse loro: «Uomini di poca fede! Perché vi preoccupate tanto di non aver cibo? 9Ma non capirete mai?! Non vi ricordate più delle cinquemila persone che ho sfamato con cinque pani e dei canestri che ne avanzarono? 10Avete dimenticato le altre quattromila persone che ho sfamato con sette pani e tutto ciò che ne avanzò? 11Come avete potuto pensare che stessi parlando di cibo? Ma ripeto: diffidate del lievito dei Farisei e dei Sadducei!»

12Soltanto allora capirono che per «lievito» Gesù intendeva glʼinsegnamenti sbagliati dei Farisei e dei Sadducei.

«Chi pensi che io sia?»

13Quando Gesù arrivò nel territorio di Cesarea di Filippo, chiese ai suoi discepoli: «Chi dicono che io sia?»

14«Beh», risposero, «certi dicono che sei Giovanni Battista, altri Elia, altri ancora Geremia o qualcun altro dei profeti».

15Allora Gesù chiese loro: «E voi, chi pensate che io sia?»

16Rispose Simon Pietro: «Tu sei il Cristo, il Messia, il Figlio del Dio vivente!»

17Allora Gesù gli disse: «Dio ti ha benedetto, Simone, figlio di Giona, perché non hai scoperto questa verità con forze umane, ma è stato mio Padre che è in cielo a rivelartela. 18Tu sei Pietro e su questa pietra costruirò la mia Chiesa; e tutte le potenze dellʼinferno non potranno vincerla mai. 19Io ti darò le chiavi del Regno dei Cieli; qualsiasi porta chiuderai in terra, sarà chiusa anche in cielo e qualsiasi porta aprirai in terra, sarà aperta in cielo!»

20Poi Gesù proibì ai discepoli di dire ad altri che era lui il Messia.

21Da allora in poi Gesù cominciò a spiegare ai discepoli che sarebbe andato a Gerusalemme, informandoli di ciò che gli sarebbe accaduto in quella città: che avrebbe sofferto nelle mani dei capi giudei, che sarebbe stato ucciso e tre giorni dopo sarebbe resuscitato di nuovo.

22Ma Pietro lo prese in disparte per protestare: «Voglia il cielo, Signore», gli disse, «che questo non ti capiti mai!»

23Ma Gesù si voltò verso di lui e disse: «Vattene da me, Satana! Per me tu sei un ostacolo, perché stai ragionando da un punto di vista umano, non da quello di Dio!»

24Poi Gesù disse ai suoi discepoli: «Se qualcuno vuole seguirmi, smetta di pensare a se stesso, prenda la sua croce e mi segua. 25Perché chi pensa a salvare la propria vita, la perderà; chi invece è pronto a dare la sua vita per me, la ritroverà.

26Che vantaggio ne avrete, se guadagnate tutto il mondo e perdete la vita eterna? Che cosa può essere paragonato al valore della vita eterna? 27Perché io, il Figlio dellʼUomo, verrò con i miei angeli nella gloria di mio Padre e giudicherò ogni persona, secondo le sue azioni. 28E alcuni di voi, qui presenti in questo momento, non moriranno finché non mi avranno visto venire nel mio Regno».

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Matiu 16:1-28

Bíbéèrè Fún Ààmì

116.1-4: Mk 8.11-12; Lk 11.16,29; 12.54-56; Mt 12.38-39; Jh 2.18; 6.30.Àwọn Farisi àti àwọn Sadusi wá láti dán Jesu wò. Wọ́n ní kí ó fi ààmì ńlá kan hàn àwọn ní ojú ọ̀run.

2Ó dá wọn lóhùn pé, “Nígbà tí ó bá di àṣálẹ́, ẹ ó sọ pé, ‘Ìbá dára kí ojú ọ̀run pọ́n.’ 3Ní òwúrọ̀, ‘Ẹ̀yin yóò wí pé ọjọ́ kì yóò dára lónìí, nítorí ti ojú ọ̀run pọ́n, ó sì ṣú dẹ̀dẹ̀,’ ẹ̀yin àgàbàgebè, ẹ̀yin le sọ ààmì ojú ọ̀run, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò le mọ ààmì àwọn àkókò wọ̀nyí. 4Ìran búburú aláìgbàgbọ́ yìí ń béèrè ààmì àjèjì mélòó kàn ni ojú sánmọ̀, ṣùgbọ́n a kí yóò fún ẹnìkankan ní ààmì bí kò ṣe ààmì Jona.” Nígbà náà ni Jesu fi wọ́n sílẹ̀, ó sì bá tirẹ̀ lọ.

Ìwúkàrà Farisi àti Sadusi

516.5-12: Mk 8.13-21.Nígbà tí wọ́n dé apá kejì adágún, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ṣàkíyèsí pé wọ́n ti gbàgbé láti mú àkàrà kankan lọ́wọ́. 616.6: Lk 12.1.Jesu sì kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ kíyèsára, ẹ sì ṣọ́ra, ní ti ìwúkàrà àwọn Farisi àti àwọn Sadusi.”

7Wọ́n ń sọ eléyìí ni àárín ara wọn wí pé, “Nítorí tí àwa kò mú àkàrà lọ́wọ́ ni.”

816.8: Mt 6.30; 8.26; 14.31.Nígbà tí ó gbọ́ ohun ti wọ́n ń sọ, Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré, èéṣe tí ẹ̀yin ń dààmú ara yín pé ẹ̀yin kò mú oúnjẹ lọ́wọ́? 9Tàbí ọ̀rọ̀ kò yé yín di ìsinsin yìí? Ẹ̀yin kò rántí pé mo bọ́ ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (5,000) ènìyàn pẹ̀lú ìṣù àkàrà márùn-ún àti iye agbọ̀n tí ẹ kójọ bí àjẹkù? 10Ẹ kò sì tún rántí ìṣù méje tí mo fi bọ́ ẹgbàajì (4,000) ènìyàn àti iye agbọ̀n tí ẹ̀yín kójọ? 11Èéha ṣe tí kò fi yé yín pé èmi kò sọ̀rọ̀ nípa ti àkàrà? Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo wí fún yín, ẹ ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisi àti ti Sadusi.” 12Nígbà náà ni ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wáyé wọn pé, kì í ṣe nípa ti ìwúkàrà ní ó sọ wí pé kí wọ́n kíyèsára, bí kò ṣe tí ẹ̀kọ́ àwọn Farisi àti Sadusi.

Peteru jẹ́wọ́ Kristi

1316.13-16: Mk 8.27-30; Lk 9.18-21.Nígbà tí Jesu sì dé Kesarea-Filipi, ó bi àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ta ni àwọn ènìyàn ń fi Ọmọ ènìyàn pè?”

1416.14: Mt 14.2; Mk 6.15; Lk 9.7-18; Jh 1.21.Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwọn kan ni Johanu onítẹ̀bọmi ni, àwọn mìíràn wí pé, Elijah ni, àwọn mìíràn wí pé, Jeremiah ni, tàbí ọ̀kan nínú àwọn wòlíì.”

15“Ṣùgbọ́n ẹyin ń kọ?” Ó bi í léèrè pé, “Ta ni ẹ̀yin ń fi mi pè?”

1616.16: Mt 1.16; Jh 11.27; 1.49.Simoni Peteru dáhùn pé, “Ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè.”

1716.17: 1Kọ 15.50; Ga 1.16; Ef 6.12; Hb 2.14.Jesu sì wí fún un pé, “Alábùkún fún ni ìwọ Simoni ọmọ Jona, nítorí ẹran-ara àti ẹ̀jẹ̀ kọ́ ló fi èyí hàn bí kò ṣe Baba mi tí ó ń bẹ ní ọ̀run. 18Èmi wí fún ọ, ìwọ ni Peteru àti pé orí àpáta yìí ni èmi yóò kọ́ ìjọ mi lé, àti ẹnu-ọ̀nà ipò òkú kì yóò lè borí rẹ̀. 19Èmi yóò fún ní àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjọba Ọ̀run; Ohun tí ìwọ bá dè ní ayé, òun ni a ó dè ní ọ̀run. Ohunkóhun tí ìwọ bá sì tú ní ayé yìí, a ó sì tú ní ọ̀run.” 2016.20: Mt 8.4; Mk 3.12; 5.43; 7.36; 9.9.Nígbà náà ó kìlọ̀ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni pé Òun ni Kristi náà.

Jesu sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ikú ara rẹ̀

2116.21-28: Mk 8.31–9.1; Lk 9.22-27.16.21: Mt 17.22-23; 20.17-19; Lk 17.25; Mt 17.12; 26.2.Láti ìgbà yìí lọ, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí ṣàlàyé fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kedere nípa lílọ sí Jerusalẹmu láti jẹ ọ̀pọ̀ ìyà lọ́wọ́ àwọn àgbàgbà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé, kí a sì pa òun, àti ní ọjọ́ kẹta, kí ó sì jíǹde.

22Peteru mú Jesu sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí í bá a wí pé, “Kí a má rí i Olúwa! Èyí kì yóò ṣẹlẹ̀ sí Ọ!”

2316.23: Mt 4.10.Jesu pa ojú dà, ó sì wí fún Peteru pé, “Kúrò lẹ́yìn mi, Satani! Ohun ìkọ̀sẹ̀ ni ìwọ jẹ́ fún mi; ìwọ kò ro ohun tí i ṣe ti Ọlọ́run, bí kò ṣe èyí ti ṣe ti ènìyàn.”

2416.24-26: Mt 10.38-39; Lk 14.27; 17.33; Jh 12.25.Nígbà náà ni Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí ó sì gbé àgbélébùú rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn. 25Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ là, yóò sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù nítorí mi, yóò rí i. 26Èrè kí ni ó jẹ́ fún ènìyàn bí ó bá jèrè gbogbo ayé yìí, tí ó sì sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù? Tàbí kí ni ènìyàn yóò fi dípò ẹ̀mí rẹ̀? 27Nítorí Ọmọ ènìyàn yóò wá nínú ògo baba rẹ pẹ̀lú àwọn angẹli rẹ̀, nígbà náà ni yóò sì san án fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.

28“Lóòótọ́ ni mo wí fún yín. Ẹlòmíràn wà nínú àwọn tí ó wà níhìn-ín yìí, tí kì yóò ri ikú títí wọn ó fi rí Ọmọ ènìyàn tí yóò máa bọ̀ ní ìjọba rẹ̀.”