پيدايش 5 – PCB & YCB

Persian Contemporary Bible

پيدايش 5:1-32

از آدم تا نوح

(اول تواريخ 1‏:1‏-4)

1اين است شرح پيدايش آدم و نسل او. هنگامی كه خدا خواست انسان را بيافريند، او را شبيه خود آفريد. 2او انسان را مرد و زن خلق فرموده، آنها را بركت داد و از همان آغاز خلقت، ايشان را «آدم» ناميد.

3‏-5آدم: وقتی آدم ۱۳۰ ساله بود، پسرش5‏:3‏-5 در اين شجره نامه «پسر» می‌تواند به معنی «نوه» يا «نبيره» نيز باشد.‏ شيث به دنيا آمد. او شبيه پدرش آدم بود. بعد از تولد شيث، آدم ۸۰۰ سال ديگر عمر كرد و صاحب پسران و دختران شد. آدم در سن ۹۳۰ سالگی مرد.

6‏-8شيث: وقتی شيث ۱۰۵ ساله بود، پسرش انوش به دنيا آمد. بعد از تولد انوش، شيث ۸۰۷ سال ديگر عمر كرد و صاحب پسران و دختران شد. شيث در سن ۹۱۲ سالگی مرد.

9‏-11انوش: وقتی انوش نود ساله بود، پسرش قينان به دنيا آمد. بعد از تولد قينان، انوش ۸۱۵ سال ديگر عمر كرد و صاحب پسران و دختران شد. انوش در سن ۹۰۵ سالگی مرد.

12‏-14قينان: وقتی قينان هفتاد ساله بود، پسرش مهلل‌ئيل به دنيا آمد. بعد از تولد مهلل‌ئيل، قينان ۸۴۰ سال ديگر عمر كرد و صاحب پسران و دختران شد. او در سن ۹۱۰ سالگی مرد.

15‏-17مهلل‌ئيل: وقتی مهلل‌ئيل شصت و پنج ساله بود، پسرش يارد به دنيا آمد. پس از تولد يارد، مهلل‌ئيل ۸۳۰ سال ديگر عمر كرد و صاحب پسران و دختران شد. او در سن ۸۹۵ سالگی مرد.

18‏-20يارد: وقتی يارد ۱۶۲ ساله بود، پسرش خنوخ به دنيا آمد. بعد از تولد خنوخ، يارد ۸۰۰ سال ديگر عمر كرد و صاحب پسران و دختران شد. يارد در سن ۹۶۲ سالگی مرد.

21‏-24خنوخ: وقتی خنوخ شصت و پنج ساله بود، پسرش متوشالح به دنيا آمد. بعد از تولد متوشالح، خنوخ ۳۰۰ سال ديگر با خدا زيست. او صاحب پسران و دخترانی شد و ۳۶۵ سال زندگی كرد. خنوخ با خدا می‌زيست و خدا او را به حضور خود به بالا برد و ديگر كسی او را نديد.

25‏-27متوشالح: وقتی متوشالح ۱۸۷ ساله بود، پسرش لمک به دنيا آمد. بعد از تولد لمک، متوشالح ۷۸۲ سال ديگر زندگی كرد و صاحب پسران و دختران شد. متوشالح در سن ۹۶۹ سالگی مرد.

28‏-31لمک: وقتی لمک ۱۸۲ ساله بود، پسرش نوح به دنيا آمد. لمک گفت: «اين پسر، ما را از كار سختِ زراعت كه در اثر لعنت خداوند بر زمين، دامنگير ما شده، آسوده خواهد كرد.» پس لمک اسم او را نوح (يعنی «آسودگی») گذاشت. بعد از تولد نوح، لمک ۵۹۵ سال ديگر عمر كرد و صاحب پسران و دختران شد. او در سن ۷۷۷ سالگی مرد.

32نوح: نوح در سن ۵۰۰ سالگی صاحب سه پسر به نامهای سام، حام و يافث بود.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 5:1-32

Ìran Adamu títí dé ìran Noa

15.1,2: Gẹ 1.27,28; Mt 19.4; Mk 10.6.Èyí ni àkọsílẹ̀ ìran Adamu.

Nígbà tí Ọlọ́run dá ènìyàn, ní àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a. 2Àti akọ àti abo ni Ó dá wọn, ó sì súre fún wọn, ó sì pe orúkọ wọ́n ní Adamu ní ọjọ́ tí ó dá wọn.

3Nígbà tí Adamu di ẹni àádóje ọdún, ó bí ọmọkùnrin kan tí ó jọ ọ́, tí ó jẹ́ àwòrán ara rẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Seti. 4Ọjọ́ Adamu, lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Seti, jẹ́ ẹgbẹ̀rin (800) ọdún, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 5Àpapọ̀ ọdún tí Adamu gbé ní orí ilẹ̀ jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé ọgbọ̀n (930), ó sì kú.

6Nígbà tí Seti pé àrùnlélọ́gọ́rùn-ún ọdún, ó bí Enoṣi. 7Lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Enoṣi, Seti sì gbé fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó lé méje (807), ó sì bí àwọn; ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 8Àpapọ̀ ọdún Seti sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé méjìlá (912), ó sì kú.

9Nígbà tí Enoṣi di ẹni àádọ́rùn-ún ọdún ni ó bí Kenani. 10Lẹ́yìn tí ó bí Kenani, Enoṣi sì wà láààyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (815), ó sì bí àwọn ọkùnrin àti obìnrin. 11Àpapọ̀ ọdún Enoṣi jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé márùn-ún (905), ó sì kú.

12Nígbà tí Kenani di àádọ́rin ọdún ni ó bí Mahalaleli. 13Lẹ́yìn tí ó bí Mahalaleli, Kenani wà láààyè fún òjìlélẹ́gbẹ̀rin ọdún (840), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 14Àpapọ̀ ọjọ́ Kenani jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé mẹ́wàá (910), ó sì kú.

15Nígbà tí Mahalaleli pé ọmọ àrùnlélọ́gọ́ta ọdún ni ó bí Jaredi. 16Mahalaleli sì gbé fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó lé ọgbọ̀n (830) lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Jaredi, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 17Àpapọ̀ iye ọdún Mahalaleli jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó dín márùn-ún (895), ó sì kú.

18Nígbà tí Jaredi pé ọmọ ọgọ́jọ ọdún ó lé méjì ni ó bí Enoku. 19Lẹ́yìn èyí, Jaredi wà láààyè fún ẹgbẹ̀rin (800) ọdún Enoku sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 20Àpapọ̀ ọdún Jaredi sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún dín méjìdínlógójì (962), ó sì kú.

21Nígbà tí Enoku pé ọmọ ọgọ́ta ọdún ó lé márùn ni ó bí Metusela. 22Lẹ́yìn tí ó bí Metusela, Enoku sì bá Ọlọ́run rìn ní ọ̀ọ́dúnrún (300) ọdún, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 23Àpapọ̀ ọjọ́ Enoku sì jẹ́ irinwó ọdún dín márùndínlógójì (365). 245.24: Hb 11.5; Jd 14.Enoku bá Ọlọ́run rìn; a kò sì rí i mọ́ nítorí Ọlọ́run mú un lọ.

25Nígbà tí Metusela pé igba ọdún dín mẹ́tàlá ní o bí Lameki. 26Lẹ́yìn èyí Metusela wà láààyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún dín méjìdínlógún (782), lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Lameki, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 27Àpapọ̀ ọdún Metusela jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún dín mọ́kànlélọ́gbọ̀n (969), ó sì kú.

28Nígbà tí Lameki pé ọdún méjìlélọ́gọ́sàn án ni ó bí ọmọkùnrin kan. 29Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Noa, ó sì wí pé, “Eléyìí ni yóò tù wá nínú ni iṣẹ́ àti làálàá ọwọ́ wa, nítorí ilẹ̀ tí Olúwa ti fi gégùn ún.” 30Lẹ́yìn tí ó bí Noa, Lameki gbé fún ẹgbẹ̀ta ọdún dín márùn-ún (595), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 31Àpapọ̀ ọdún Lameki sì jẹ́ ẹgbẹ̀rin ọdún dín mẹ́tàlélógún (777), ó sì kú.

32Lẹ́yìn tí Noa pé ọmọ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ọdún ni ó bí Ṣemu, Hamu àti Jafeti.