موسی به پیامبری برگزیده میشود
1روزی هنگامی که موسی مشغول چرانیدن گلهٔ پدرزن خود یَترون3:1 پدرزن موسی دو نام داشت: «رِعوئیل» و «یِترون».، کاهن مدیان بود، گله را به آن سوی بیابان، به طرف کوه حوریب، معروف به کوه خدا راند. 2ناگهان فرشتهٔ خداوند از درون بوتهای مشتعل بر او ظاهر شد. موسی دید که بوته شعلهور است، ولی نمیسوزد. 3با خود گفت: «عجیب است! چرا بوته نمیسوزد؟» پس نزدیک رفت تا علّتش را بفهمد.
4وقتی خداوند دید که موسی به بوته نزدیک میشود، از میان بوته ندا داد: «موسی! موسی!»
موسی جواب داد: «بله، میشنوم!»
5خدا فرمود: «بیش از این نزدیک نشو! کفشهایت را درآور، زیرا جایی که بر آن ایستادهای، زمین مقدّس است. 6من هستم خدای اجدادت، خدای ابراهیم، خدای اسحاق و خدای یعقوب.» موسی روی خود را پوشاند، چون ترسید به خدا نگاه کند.
7خداوند فرمود: «من رنج و مصیبت قوم خود را در مصر دیدهام و نالههایشان را برای رهایی از بردگی شنیدهام. بله، من از رنجشان آگاهم. 8اکنون نزول کردهام تا آنها را از چنگ مصریها آزاد کنم و ایشان را از مصر بیرون آورده، به سرزمین خوب و پهناوری که در آن شیر و عسل جاری است ببرم، سرزمینی که اینک قبایل کنعانی، حیتّی، اموری، فرزّی، حوّی و یبوسی در آن زندگی میکنند. 9آری، نالههای بنیاسرائیل به گوش من رسیده است و ظلمی که مصریها به ایشان میکنند، از نظر من پنهان نیست. 10حال، تو را نزد فرعون میفرستم تا قوم من بنیاسرائیل را از مصر بیرون آوری.»
11موسی گفت: «خدایا، من کیستم که نزد فرعون بروم و بنیاسرائیل را از مصر بیرون آورم؟»
12خدا فرمود: «من با تو خواهم بود و وقتی بنیاسرائیل را از مصر بیرون آوردی، در همین کوه مرا عبادت خواهید کرد. این نشانهای خواهد بود که من تو را فرستادهام.»
13موسی عرض کرد: «اگر نزد بنیاسرائیل بروم و به ایشان بگویم که خدای اجدادشان، مرا برای نجات ایشان فرستاده است، و آنها از من بپرسند: ”نام او چیست؟“ به آنها چه جواب دهم؟»
14خدا فرمود: «هستم آنکه هستم! به ایشان بگو ”هستم“ مرا نزد شما فرستاده است.»
15و باز خدا به موسی گفت: «به بنیاسرائیل بگو: ”یهوه3:15 در زبان عبری، کلمهٔ «یهوه» شبیه کلمهٔ «هستم» میباشد و احتمالاً از آن مشتق شده است.، خدای اجداد شما، خدای ابراهیم، خدای اسحاق و خدای یعقوب مرا نزد شما فرستاده است.“
«این نام جاودانهٔ من است و تمام نسلها مرا به این نام خواهند شناخت.
16«حال، برو و تمام مشایخ اسرائیل را جمع کن و به ایشان بگو: ”یهوه، خدای اجداد شما، خدای ابراهیم، اسحاق و یعقوب بر من ظاهر شد و فرمود: من از نزدیک مشاهده کرده و دیدهام چگونه مصریها با شما رفتار کردهاند. 17من وعده دادهام که شما را از سختیهایی که در مصر میکشید، آزاد کنم و به سرزمینی ببرم که در آن شیر و عسل جاری است، سرزمینی که اینک کنعانیها، حیتیها، اموریها، فرزیها، حویها و یبوسیها در آن زندگی میکنند.“
18«مشایخ اسرائیل سخن تو را خواهند پذیرفت. تو همراه آنان به حضور پادشاه مصر برو و به او بگو: ”یهوه، خدای عبرانیها، از ما دیدار کرده است. اجازه بده به فاصلهٔ سه روز راه، به صحرا برویم و در آنجا به یهوه، خدای خود قربانی تقدیم کنیم.“
19«ولی من میدانم که پادشاه مصر اجازه نخواهد داد که بروید، مگر آن که دستی نیرومند او را مجبور سازد. 20پس من دست خود را بلند کرده، مصریها را با انجام همه نوع معجزات در میانشان خواهم زد. پس از آن او شما را رها خواهد کرد. 21من کاری میکنم که مصریها برای شما احترام قائل شوند، به طوری که وقتی آن سرزمین را ترک میگویید، تهیدست نخواهید رفت. 22هر زن اسرائیلی از همسایۀ مصری خود و از بانوی میهمان در خانهاش اجناسی از نقره و طلا و لباس خواهد خواست. شما آنها را بر پسران و دخترانتان خواهید پوشاند. به این ترتیب شما مصریها را غارت خواهید کرد.»
Mose àti igbó tí ń jó
13.1–4.17: Ek 6.2-13.Ní ọjọ́ kan nígbà tí Mose ń ṣọ́ agbo ẹran Jetro baba ìyàwó rẹ̀, àlùfáà Midiani. Ó da agbo ẹran náà lọ sí ọ̀nà jíjìn nínú aginjù. Ó dé Horebu, òkè Ọlọ́run. 23.2: Ap 7.30.Níbẹ̀ ni angẹli Olúwa ti yọ sí i nínú ọ̀wọ́-iná tí ń jó láàrín igbó. Mose rí i pé iná ń jó nínú igbó ṣùgbọ́n igbó kò run 3Nígbà náà ni Mose sọ pé, “Èmi yóò lọ wo ohun ìyanu yìí, ìdí tí iná kò fi jó igbó run.”
4Nígbà tí Olúwa rí i pe Mose ti lọ láti lọ wò ó, Ọlọ́run ké pè é láti àárín igbó náà, “Mose! Mose!”
Mose sì dáhùn ó wí pé, “Èmi nìyìí.”
53.5: Ap 7.33.Olúwa sì wí fún Mose pé, “Má ṣe súnmọ́ ìhín yìí, bọ́ sálúbàtà rẹ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ, nítorí ibi tí ìwọ dúró sí i nì ilẹ̀ mímọ́ ni.” 63.6: Mt 22.32; Mk 12.26; Lk 20.37; Ap 3.13; 7.32.Nígbà náà ní ó wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run baba rẹ, Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki àti Ọlọ́run Jakọbu.” Nítorí ìdí èyí, Mose sì pa ojú rẹ̀ mọ́, nítorí ó bẹ̀rù láti bojú wo Ọlọ́run.
7Ọlọ́run si wí pé, “Èmí ti rí ìpọ́njú àwọn ènìyàn mi ní ilẹ̀ Ejibiti, mo sì ti gbọ́ ohùn igbe wọn nítorí àwọn akóniṣiṣẹ́ wọn. Ìyà tí ń jẹ wọ́n sì kan mi lára. 8Èmi sì ti sọ̀kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Ejibiti, àti láti mú wọn gòkè kúrò ní ilẹ̀ náà lọ sí ilẹ̀ tí ó dára tí ó sì ní ààyè, àní ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin; ibùgbé àwọn ará Kenaani, ará Hiti, Amori, Peresi, Hifi àti Jebusi. 9Ǹjẹ́ nísinsin yìí, wò ó, igbe àwọn ará Israẹli ti dé ọ̀dọ̀ mi, Èmi sì ti rí bí àwọn ará Ejibiti ti ṣe ń gbà ń jẹ wọ́n ní ìyà. 10Ǹjẹ́ nísinsin yìí, lọ, Èmi yóò rán ọ sí Farao láti kó àwọn ènìyàn Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti.”
11Ṣùgbọ́n Mose wí fún Ọlọ́run pé, “Ta ni èmi, tí èmi yóò tọ Farao lọ, ti èmi yóò sì kó àwọn ará Israẹli jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti?”
12Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Mose pé, “Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ. Èyí ni yóò jẹ́ ààmì fún ọ, tí yóò fihàn pé Èmi ni ó rán ọ lọ; Nígbà tí ìwọ bá kó àwọn ènìyàn náà jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, ẹ̀yin yóò sin Ọlọ́run ni orí òkè yìí.”
13Mose sì wí fún Ọlọ́run pé, “Bí mo bá tọ àwọn ará Israẹli lọ tí mo sì sọ fún wọn pé, ‘Ọlọ́run àwọn baba yín ni ó rán mi sí i yín,’ tí wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ mi pé, ‘Kí ni orúkọ rẹ̀?’ Kí ni èmi yóò sọ fún wọn ní ìgbà náà?”
14Ọlọ́run sì sọ fún Mose pé, “èmi ni ti ń jẹ́ èmi ni. Èyí ni ìwọ yóò sọ fún àwọn ará Israẹli: ‘èmi ni ni ó rán mi sí i yín.’ ”
15Ọlọ́run sì wí fún Mose pẹ̀lú pé, “Báyìí ni kí ìwọ sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, ‘Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín; Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki àti Ọlọ́run Jakọbu; ni ó rán mi sí i yín.’
“Èyí ni orúkọ Mi títí ayérayé,
orúkọ ti ẹ ó fi máa rántí Mi
láti ìran dé ìran.
16“Lọ, kó àwọn àgbàgbà Israẹli jọ, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín, Ọlọ́run Abrahamu, ti Isaaki, àti ti Jakọbu; ni ó farahàn mi, ó sì wí pé: Lóòótọ́ èmi ti ń bojú wò yín, èmi sì ti rí ohun tí wọ́n ṣe sí i yín ni ilẹ̀ Ejibiti. 17Èmi sì ti ṣe ìlérí láti mú un yín jáde kúrò nínú ìpọ́njú yín ni ilẹ̀ Ejibiti wá sí ilẹ̀ Kenaani, ará Hiti, Amori, Peresi, Hifi àti Jebusi; ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin.’
18“Àwọn àgbàgbà Israẹli yóò fetísílẹ̀ sí ohùn rẹ. Nígbà náà ni ìwọ, àti àwọn àgbàgbà yóò jọ tọ ọba Ejibiti lọ, ẹ ó sì wí fún un pé, ‘Olúwa, Ọlọ́run àwọn ará Heberu ti pàdé wa. Jẹ́ kí a lọ ni ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sí inú aginjù láti lọ rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run.’ 19Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ pé ọba Ejibiti kò ní jẹ́ kí ẹ lọ bí kò ṣe pé ọwọ́ ńlá Ọlọ́run wà ni ara rẹ̀. 20Nítorí náà, èmi yóò na ọwọ́ mí láti lu àwọn ará Ejibiti pẹ̀lú gbogbo ohun ìyanu tí èmi yóò ṣe ni àárín wọn. Lẹ́yìn náà, òun yóò jẹ́ kí ẹ máa lọ.
21“Èmi yóò sì jẹ́ kí ẹ bá ojúrere àwọn ará Ejibiti pàdé. Tí yóò fi jẹ́ pé ti ẹ̀yin bá ń lọ, ẹ kò ní lọ ní ọwọ́ òfo. 22Gbogbo àwọn obìnrin ni ó ní láti béèrè lọ́wọ́ àwọn aládùúgbò wọn àti gbogbo àwọn obìnrin ti ń gbé nínú ilé rẹ fún ohun fàdákà àti wúrà àti fún aṣọ, èyí ti ẹ̀yin yóò wọ̀ sí ọrùn àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti obìnrin. Báyìí ni ẹ̀yin yóò sì kó ẹrù àwọn ará Ejibiti.”