Hebreos 10 – NVI & YCB

Nueva Versión Internacional

Hebreos 10:1-39

El sacrificio de Cristo, ofrecido una vez y para siempre

1Dios nos dio la Ley como una manera de mostrarnos todo lo bueno que pensaba darnos luego. No era eso lo que en verdad pensaba darnos. Es por eso por lo que la Ley nunca puede hacer perfectos a los que se acercan a Dios. Siguiendo la Ley, los sacerdotes ofrecían los mismos sacrificios sin cesar año tras año, pero no pudieron hacer a nadie perfecto. 2Si pudieran hacerlo, la gente que ofrece esos sacrificios ya habría dejado de hacerlo. Pues, una vez limpios de pecado, ya no se sentirían culpables. 3Pero esos sacrificios solo sirven para recordarnos nuestros pecados todos los años. 4Pues es imposible que la sangre de los toros y de los chivos quite los pecados.

5Por eso, al venir a este mundo, Cristo le dijo a Dios:

«No has querido sacrificios ni ofrendas,

sino que me has preparado un cuerpo.

6No te agradaron ni ofrendas quemadas

ni sacrificios por el pecado.

7Por eso dije: “Aquí me tienes, oh Dios:

He venido a hacer tu voluntad,

tal como dicen las Escrituras de mí”».

8Primero dijo: «Sacrificios y ofrendas, ofrendas quemadas y sacrificios por el pecado no te gustaron ni fueron de tu agrado». Sin embargo, esto es lo que la Ley exigía que se ofreciera. 9Luego añadió: «Aquí me tienes: He venido a hacer tu voluntad». Así quitó esos sacrificios para establecer uno nuevo. 10Por esa obediencia somos declarados santos por Dios, por medio del sacrificio del cuerpo de Jesucristo. Este sacrificio fue ofrecido una sola vez y para siempre.

11Todo sacerdote celebra el culto día tras día. Una y otra vez ofrece los mismos sacrificios, los cuales nunca pueden quitar los pecados. 12Pero Jesucristo, como sacerdote, ofreció por los pecados un solo sacrificio para siempre. Después se sentó a la derecha de Dios. 13Allí está en espera de que sus enemigos sean puestos debajo de sus pies. 14Porque con un solo sacrificio ha hecho perfectos para siempre a los que han sido elegidos por Dios.

15También el Espíritu Santo nos asegura que esto es cierto. Primero dice:

16«Este es el pacto que haré con ellos

después de aquel tiempo —dice el Señor—:

Pondré mis leyes en su corazón

y las escribiré en su mente».

17Después añade:

«Y nunca más me acordaré de sus pecados y maldades».

18Y, cuando los pecados han sido perdonados, ya no hace falta otro sacrificio por el pecado.

Llamado a continuar creyendo

19Así que, hermanos en la fe, tenemos plena libertad para entrar en el Lugar Santísimo. Esto es posible por medio de la sangre que Jesús derramó en la cruz. 20Al morir de esa manera nos abrió el paso a través de la cortina que nos separaba de la presencia de Dios. Él es ahora un camino nuevo y vivo hacia Dios. 21Así que tenemos un gran sacerdote que está al frente de la casa de Dios. 22Acerquémonos entonces a Dios con corazón sincero y con la completa seguridad que da la fe. Cristo nos ha limpiado de pecado, como quien es bañado con agua pura. Por eso, acerquémonos con una conciencia tranquila. 23Mantengamos firme, y sin dudar, la confianza que tenemos en nuestra salvación, porque Dios es fiel para cumplir lo que prometió. 24Preocupémonos los unos por los otros, para animarnos a amar a los demás y hacer lo bueno. 25No dejemos de reunirnos, como acostumbran hacerlo algunos. Al contrario, animémonos unos a otros, y con mayor razón ahora que vemos que se acerca el día del regreso del Señor.

26Si después de conocer la verdad pecamos tercamente, ya no hay sacrificio que perdone nuestros pecados. 27Solo nos queda una terrible espera de juicio. Es decir, el fuego ardiente que ha de devorar a los adversarios de Dios. 28Cualquiera que rechazaba la Ley de Moisés moría sin compasión si dos o tres testigos declaraban que había desobedecido. 29¿Cuánto mayor castigo piensan ustedes que merece el que ha despreciado al Hijo de Dios? ¿Qué castigo recibirá el que ha rechazado la sangre de Cristo? Pues esa sangre es la del pacto por medio del cual había sido elegido por Dios. Quien así actúa ha insultado al Espíritu de Dios, quien nos ama, aunque no lo merezcamos. 30Pues sabemos bien que Dios dijo: «Mía es la venganza; yo castigaré»; y también: «El Señor juzgará a su pueblo». 31¡Terrible cosa es ser castigado en las manos del Dios vivo!

32Recuerden aquellos días pasados cuando ustedes sostuvieron una dura lucha y soportaron mucho sufrimiento. Eso fue cuando ustedes apenas acababan de recibir el mensaje de Dios como una luz en la oscuridad. 33Unas veces se vieron insultados públicamente y fueron perseguidos; otras veces sufrieron juntamente con los que eran tratados de igual manera. 34También sintieron compasión de los que estaban en la cárcel. Y, cuando a ustedes les quitaron sus bienes, lo aceptaron con alegría, seguros de que tenían una riqueza mejor y más permanente.

35Así que no pierdan la confianza, porque esta será grandemente recompensada. 36Ustedes necesitan seguir confiando para que, después de haber cumplido la voluntad de Dios, reciban lo que él ha prometido. 37Pues dentro de muy poco tiempo,

«el que ha de venir vendrá, y no tardará.

38Pero al que él declare justo vivirá para siempre, gracias a la fe.

Y, si deja de creer,

no será de mi agrado».

39Pero nosotros no somos de los que dejan de creer y acaban por perderse. Somos de los que tienen fe y salvan su vida.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Heberu 10:1-39

Ìrúbọ Kristi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo fún gbogbo ènìyàn

1Nítorí tí òfin jẹ́ òjìji àwọn ohun rere ti ń bọ̀ tí kì í ṣe àwòrán tòótọ́ fún àwọn òtítọ́ náà, wọn kò lè fi ẹbọ kan náà tí wọn ń rú nígbà gbogbo lọ́dọọdún mu àwọn tí ń wá jọ́sìn di pípé. 2Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, a kì ìbá tí dẹ́kun àti máa rú wọn, nítorí àwọn ti ń sìn ki ìbá tí ní ìmọ̀ ẹ̀ṣẹ̀, nígbà tí a bá ti wẹ̀ wọ́n mọ́ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. 3Ṣùgbọ́n nínú ẹbọ wọ̀nyí ni a ń ṣe ìrántí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́dọọdún. 4Nítorí ko ṣe é ṣe fún ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù àti ti ewúrẹ́ láti mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò.

510.5-9: Sm 40.6-8.Nítorí náà nígbà tí Kristi wá sí ayé, ó wí pé,

“Ìwọ kò fẹ́ ẹbọ àti ọrẹ,

ṣùgbọ́n ara ni ìwọ ti pèsè fún mi,

6ẹbọ sísun àti ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ ni

ìwọ kò ní inú dídùn sí.

7Nígbà náà ni mo wí pé, ‘Kíyèsi i (nínú ìwé kíká ni a gbé kọ ọ́ nípa ti èmi)

mo dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run.’ ”

8Nígbà tí o wí ni ìṣáájú pé, “Ìwọ kò fẹ́ ẹbọ àti ọrẹ àti ẹbọ sísun, àti ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò ni inú dídùn si wọn” (àwọn èyí tí a ń rú gẹ́gẹ́ bí òfin). 9Nígbà náà ni ó wí pé, “Kíyèsi i, mo de láti ṣe ìfẹ́ rẹ Ọlọ́run.” Ó mú ti ìṣáájú kúrò, kí a lè fi ìdí èkejì múlẹ̀. 10Nípa ìfẹ́ náà ni a ti sọ wá di mímọ́ nípa ẹbọ ti Jesu Kristi fi ara rẹ̀ rú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.

11Àti olúkúlùkù àlùfáà sì ń dúró lójoojúmọ́ láti ṣiṣẹ́ ìsìn, ó sì ń ṣe ẹbọ kan náà nígbàkígbà, tí kò lè mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò láé. 1210.12-13: Sm 110.1.Ṣùgbọ́n òun, lẹ́yìn ìgbà tí o ti rú ẹbọ kan fún ẹ̀ṣẹ̀ títí láé, o jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run; 13láti ìgbà náà, ó retí títí a o fi àwọn ọ̀tá rẹ̀ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀. 14Nítorí nípa ẹbọ kan a ti mú àwọn tí a sọ di mímọ́ pé títí láé.

15Ẹ̀mí Mímọ́ sì ń jẹ́rìí fún wa pẹ̀lú, nítorí lẹ́yìn tí ó wí pé,

1610.16-17: Jr 31.33-34.“Èyí ni májẹ̀mú ti èmi o ba wọn dá

lẹ́hìn àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, ni Olúwa wí.

Èmi o fi òfin mi sí wọn ní ọkàn,

inú wọn pẹ̀lú ni èmi o sì kọ wọn sí.”

17Ó tún sọ wí pé:

“Ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti àìṣedéédéé wọn

lèmi kì yóò sì rántí mọ́.”

18Ṣùgbọ́n níbi tí ìmúkúrò ìwọ̀nyí bá gbé wà, ìrúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ kò sí mọ́.

Ìpè sí ìforítì

19Ará, ǹjẹ́ bí a ti ní ìgboyà láti wọ inú Ibi Mímọ́ Jùlọ nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Jesu, 20nípa ọ̀nà títún àti ààyè, tí o yà sí mímọ́ fún wa, àti láti kọjá aṣọ ìkélé èyí yìí ní, ara rẹ̀; 21àti bí a ti ni àlùfáà gíga lórí ilé Ọlọ́run; 22ẹ jẹ́ kí a fi òtítọ́ ọkàn súnmọ́ tòsí ni ẹ̀kún ìgbàgbọ́, kí a sì wẹ ọkàn wa mọ́ kúrò nínú ẹ̀rí ọkàn búburú, kí a sì fi omi mímọ́ wẹ ara wa nù. 23Ẹ jẹ́ kí a di ìjẹ́wọ́ ìrètí wa mu ṣinṣin ni àìṣiyèméjì, nítorí pé olóòtítọ́ ní ẹni tí o ṣe ìlérí. 24Ẹ jẹ́ kí a yẹ ara wa wò láti ru ara wa sí ìfẹ́ àti sí iṣẹ́ rere, 25kí a ma máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bi àṣà àwọn ẹlòmíràn; ṣùgbọ́n kí a máa gba ara ẹni níyànjú pẹ̀lúpẹ̀lú bí ẹ̀yin ti rí i pé ọjọ́ náà ń súnmọ́ etílé.

26Nítorí bí àwa ba mọ̀ ọ́n mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí àwa bá ti gba ìmọ̀ òtítọ́ kò tún sí ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. 2710.27: Isa 26.11.Bí kò ṣe ìrètí ìdájọ́ tí ó ba ni lẹ́rù, àti ti ìbínú ti o múná, tí yóò pa àwọn ọ̀tá run. 2810.28: De 17.2-6.Ẹnikẹ́ni tí ó ba gan òfin Mose, ó kú láìsí àánú nípa ẹ̀rí ẹni méjì tàbí mẹ́ta. 2910.29: El 24.8.Mélòó mélòó ni ẹ rò pé a o jẹ ẹni náà ní ìyà kíkan, ẹni tí o tẹ Ọmọ Ọlọ́run mọ́lẹ̀ tí ó sì ti ka ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú ti a fi sọ ọ́ di mímọ́ si ohun àìmọ́, tí ó sì ti kẹ́gàn ẹ̀mí oore-ọ̀fẹ́. 3010.30: De 32.35-36.Nítorí àwa mọ ẹni tí o wí pé, Ẹ̀san ni ti èmi, Olúwa wí pé, “Èmi ó gbẹ̀san.” Àti pẹ̀lú, “Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀.” 31Ohun ẹ̀rù ni láti ṣubú sí ọwọ́ Ọlọ́run alààyè.

32Ṣùgbọ́n ẹ rántí ọjọ́ ìṣáájú nínú èyí tí, nígbà tí a ti sí yin lójú, ẹ fi ara da wàhálà ńlá ti ìjìyà; 33lápákan, nígbà tí a sọ yín di ìran wíwò nípa ẹ̀gàn àti ìpọ́njú; àti lápákan, nígbà tí ẹ̀yin di ẹgbẹ́ àwọn tí a ṣe bẹ́ẹ̀ si. 34Nítorí ẹ̀yin bá àwọn tí ó wà nínú ìdè kẹ́dùn, ẹ sì fi ayọ̀ gba ìkólọ ẹrù yin, nítorí ẹ̀yin mọ nínú ara yin pé, ẹ ni ọrọ̀ tí ó wà títí, tí ó sì dára jù bẹ́ẹ̀ lọ. 35Nítorí náà ẹ má ṣe gbé ìgboyà yín sọnù, èyí ti o ni èrè ńlá.

36Nítorí ẹ̀yin kò le ṣe aláìní sùúrù, nítorí ìgbà tí ẹ̀yin bá ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tan kí ẹ̀yin le gba ìlérí náà. 3710.37: Isa 26.20; Hk 2.3-4.Nítorí,

“Ni ìwọ̀n ìgbà díẹ̀ sí i,

ẹni náà ti ń bọ̀ yóò dé,

kí yóò sì jáfara.

38Ṣùgbọ́n,

“Olódodo ni yóò yè nípa ìgbàgbọ́.

Ṣùgbọ́n bí o ba fàsẹ́yìn,

ọkàn mi kò ní inú dídùn sí i.”

39Ṣùgbọ́n àwa kò sí nínú àwọn tí ń fàsẹ́yìn sínú ègbé; bí kò ṣe nínú àwọn tí o gbàgbọ́ sí ìgbàlà ọkàn.