Geneza 46 – NTLR & YCB

Nouă Traducere În Limba Română

Geneza 46:1-34

Iacov și familia sa merg în Egipt

1Israel a pornit în călătorie cu tot ce avea, iar când a ajuns la Beer-Șeba, a adus jertfe Dumnezeului tatălui său Isaac.

2Dumnezeu i‑a vorbit lui Israel în vedenii de noapte și i‑a zis:

– Iacov, Iacov!

El a răspuns:

– Iată‑mă!

3Dumnezeu a zis:

– Eu sunt Dumnezeu, Dumnezeul tatălui tău. Nu te teme să te cobori în Egipt, căci acolo te voi face un neam mare. 4Eu Însumi Mă voi coborî cu tine în Egipt și tot Eu te voi aduce cu siguranță înapoi, iar Iosif îți va închide ochii.

5Apoi Iacov a plecat din Beer-Șeba. Fiii lui Israel i‑au dus pe tatăl lor, Iacov, pe copiii și pe soțiile lor în carele pe care Faraon le trimisese să‑i aducă. 6Iacov și toată sămânța lui și‑au luat turmele și bunurile, pe care le strânseseră în țara Canaan, și au venit în Egipt. 7El i‑a adus cu el în Egipt pe fiii săi, pe nepoții săi, pe fiicele sale și pe nepoatele sale, adică toată sămânța sa.

8Acestea sunt numele fiilor lui Israel (Iacov și urmașii săi) care au venit în Egipt:

Ruben, întâiul născut al lui Iacov,

9și fiii lui Ruben:

Hanoh, Palu, Hețron și Carmi.

10Fiii lui Simeon:

Iemuel, Iamin, Ohad, Iachin, Țohar și Saul, fiul unei canaanite.

11Fiii lui Levi:

Gherșon, Chehat și Merari.

12Fiii lui Iuda:

Er, Onan, Șela, Pereț și Zerah; dar Er și Onan au murit în țara Canaan.

Fiii lui Pereț au fost Hețron și Hamul.

13Fiii lui Isahar:

Tola, Puva, Iov și Șimron.

14Fiii lui Zabulon:

Sered, Elon și Iahleel.

15Aceștia au fost fiii Leei, pe care ea i‑a născut lui Iacov în Padan-Aram. Ea îi mai născuse și o fiică, pe nume Dina. Toți fiii și fiicele sale au fost în număr de treizeci și trei.

16Fiii lui Gad:

Țifion, Haghi, Șuni, Ețbon, Eri, Arodi și Areli.

17Fiii lui Așer:

Imna, Ișva, Ișvi și Beria.

Sora lor a fost Serah.

Fiii lui Beria:

Heber și Malchiel.

18Aceștia au fost copiii Zilpei, pe care Laban i‑a dat‑o fiicei sale Lea. Pe aceștia i‑a născut ea lui Iacov, fiind în total șaisprezece suflete.

19Fiii Rahelei, soția lui Iacov:

Iosif și Beniamin. 20În țara Egiptului, lui Iosif i s‑au născut Manase și Efraim pe care i i‑a născut Asnat, fiica lui Poti-Fera, preotul din On20 Vezi nota la 41:45..

21Fiii lui Beniamin:

Bela, Becher, Așbel, Ghera, Naaman, Ehi, Roș, Mupim, Hupim și Ard.

22Aceștia au fost fiii Rahelei, care i s‑au născut lui Iacov, fiind în total paisprezece persoane.

23Fiul lui Dan:

Hușim.

24Fiii lui Neftali:

Iahțeel, Guni, Iețer și Șilem.

25Aceștia au fost copiii Bilhei, pe care Laban i‑a dat‑o fiicei sale Rahela; pe aceștia i‑a născut ea lui Iacov, fiind în total șapte persoane.

26Toți cei care au mers cu Iacov în Egipt, care ieșiseră din coapsele lui, în afară de soțiile fiilor săi, erau în total șaizeci și șase de persoane. 27Lui Iosif i s‑au născut doi fii în Egipt. Astfel, toți cei din familia lui Iacov, care au venit în Egipt, erau șaptezeci.

Iacov se așază în Goșen

28Iacov l‑a trimis pe Iuda înainte la Iosif pentru a afla drumul spre Goșen. Când au ajuns în ținutul Goșen, 29Iosif și‑a pregătit carul și s‑a suit să‑l întâlnească pe Israel, tatăl său, în Goșen. Când a ajuns la el, l‑a îmbrățișat și a plâns pe umărul lui multă vreme. 30Apoi Israel i‑a zis lui Iosif: „Acum, după ce ți‑am văzut fața, pot să mor, căci ești încă în viață.“ 31Iosif le‑a zis fraților săi și familiei tatălui său: „Mă voi sui la Faraon și‑i voi istorisi: «Frații mei și familia tatălui meu, care erau în țara Canaan, au venit la mine. 32Oamenii aceștia sunt păstori, deoarece cresc vite. Ei și‑au adus turmele, cirezile și tot ceea ce au.» 33Când Faraon vă va chema și vă va întreba: «Ce ocupație aveți?», 34voi să‑i răspundeți: «Robii tăi sunt crescători de vite, din tinerețea noastră și până acum, atât noi, cât și părinții noștri.» Astfel, veți putea locui în ținutul Goșen, căci oricine paște turmele este o urâciune înaintea egiptenilor.“

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 46:1-34

Jakọbu lọ sí Ejibiti

1Báyìí ni Israẹli mú ìrìnàjò rẹ̀ pọ̀n pẹ̀lú ohun gbogbo tí ó ní, nígbà tí ó sì dé Beerṣeba, ó rú ẹbọ sí Ọlọ́run Isaaki baba rẹ̀.

2Ọlọ́run sì bá Israẹli sọ̀rọ̀ ní ojú ìran ní òru pé, “Jakọbu! Jakọbu!”

Ó sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”

3Ọlọ́run sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run, Ọlọ́run baba rẹ, má ṣe bẹ̀rù láti sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Ejibiti nítorí, èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá níbẹ̀. 4Èmi yóò sì sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú rẹ lọ sí Ejibiti, èmi yóò sì tún mú ọ padà wá. Ọwọ́ Josẹfu fúnra rẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí.”

5Nígbà náà ni Jakọbu kúrò ní Beerṣeba, àwọn ọmọ Israẹli sì mú Jakọbu baba wọn àti àwọn aya wọn àti àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì kó wọn sí inú kẹ̀kẹ́ ẹrù tí Farao fi ránṣẹ́ fún ìrìnàjò rẹ̀. 646.6: Ap 7.14,15.Wọ́n tún kó àwọn ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo ohun ìní tí wọ́n ti ní láti ilẹ̀ Kenaani, Jakọbu àti gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti. 7Ó kó àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin pẹ̀lú àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin pẹ̀lú àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ obìnrin, gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ lọ sí Ejibiti.

846.8-27: Ek 1.1-4; Nu 26.4-50.Èyí ni orúkọ àwọn ọmọ Israẹli (Jakọbu àti ìran rẹ̀) tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ Ejibiti:

Reubeni àkọ́bí Jakọbu.

9Àwọn ọmọkùnrin Reubeni:

Hanoku, Pallu, Hesroni àti Karmi.

10Àwọn ọmọkùnrin Simeoni:

Jemueli, Jamini, Ohadi, Jakini, Sohari àti Saulu, tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọbìnrin ará Kenaani.

11Àwọn ọmọkùnrin Lefi:

Gerṣoni, Kohati àti Merari.

12Àwọn ọmọkùnrin Juda:

Eri, Onani, Ṣela, Peresi àti Sera (ṣùgbọ́n Ẹri àti Onani ti kú ní ilẹ̀ Kenaani).

Àwọn ọmọ Peresi:

Hesroni àti Hamulu.

13Àwọn ọmọkùnrin: Isakari!

Tola, Pua, Jaṣibu àti Ṣimroni.

14Àwọn ọmọkùnrin Sebuluni:

Seredi, Eloni àti Jahaleli.

15Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Lea tí ó bí fún Jakọbu ní Padani-Aramu yàtọ̀ fún Dina ọmọbìnrin rẹ̀. Àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti ọmọbìnrin rẹ̀ wọ̀nyí jẹ́ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) lápapọ̀.

16Àwọn ọmọkùnrin Gadi:

Sefoni, Haggi, Ṣuni, Esboni, Eri, Arodi, àti Areli.

17Àwọn ọmọkùnrin Aṣeri:

Imina, Iṣifa, Iṣfi àti Beriah. Arábìnrin wọn ni Sera.

Àwọn ọmọkùnrin Beriah:

Heberi àti Malkieli.

18Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ tí Jakọbu bí nípasẹ̀ Silipa, ẹni tí Labani fi fún Lea ọmọbìnrin rẹ̀. Gbogbo wọn jẹ́ mẹ́rìndínlógún lápapọ̀.

19Àwọn ọmọkùnrin Rakeli aya Jakọbu:

Josẹfu àti Benjamini.

20Ní Ejibiti, Asenati ọmọbìnrin Potifẹra, alábojútó àti àlùfáà Oni, bí Manase àti Efraimu fún Josẹfu.

21Àwọn ọmọ Benjamini:

Bela, Bekeri, Aṣbeli, Gera, Naamani, Ehi, Roṣi, Mupimu, Huppimu àti Ardi.

22Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin tí Rakeli bí fún Jakọbu. Wọ́n jẹ́ mẹ́rìnlá lápapọ̀.

23Àwọn ọmọ Dani:

Huṣimu.

24Àwọn ọmọ Naftali:

Jasieli, Guni, Jeseri, àti Ṣillemu.

25Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ tí Biliha ẹni tí Labani fi fún Rakeli ọmọ rẹ̀ bí fún Jakọbu. Wọ́n jẹ́ méje lápapọ̀.

26Gbogbo àwọn tí ó lọ pẹ̀lú Jakọbu sí Ejibiti, àwọn tí ó jẹ́ ìran rẹ̀ tààrà láìka àwọn aya ọmọ rẹ̀, jẹ́ ènìyàn mẹ́rìndínláàádọ́rin. 2746.27: Ap 7.14.Pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin méjì tí a bí fún Josẹfu ní Ejibiti àwọn ará ilé Jakọbu tí ó lọ sí Ejibiti jẹ́ àádọ́rin lápapọ̀.

28Jakọbu sì rán Juda ṣáájú rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Josẹfu, kí wọn bá à le mọ ọ̀nà Goṣeni. Nígbà tí wọ́n dé agbègbè Goṣeni, 29Josẹfu tọ́jú kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀ ó sì lọ sí Goṣeni láti pàdé Israẹli baba rẹ̀. Bí Josẹfu ti dé iwájú baba rẹ̀, ó dì mọ́ baba rẹ̀ ó sì sọkún fún ìgbà pípẹ́.

30Israẹli wí fún Josẹfu pé, “Wàyí o, mo le kú, níwọ̀n bí mo ti rí i fún ara mi pé, o wà láààyè síbẹ̀.”

31Nígbà náà ni Josẹfu wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ àti fún àwọn ará ilé baba rẹ̀ pé, “Èmi yóò gòkè lọ, èmi yóò sì bá Farao sọ̀rọ̀, èmi yóò sì wí fún un pé, ‘Àwọn arákùnrin mi àti ìdílé baba mi tí ń gbé ní Kenaani ti tọ̀ mí wá. 32Darandaran ni àwọn ènìyàn náà, wọ́n ń tọ́jú ẹran ọ̀sìn, wọ́n sì kó agbo ẹran wọn àti agbo màlúù wọn àti gbogbo ohun tí wọ́n ní pẹ̀lú wá.’ 33Nígbà tí Farao bá pè yín wọlé tí ó sí béèrè irú iṣẹ́ tí ẹ ń ṣe, 34ẹ fún un lésì pé, ‘Àwọn ìránṣẹ́ rẹ ń tọ́jú ẹran ọ̀sìn ni láti ìgbà èwe wa wá gẹ́gẹ́ bí a ṣe ba a lọ́wọ́ àwọn baba wa.’ Nígbà náà ni wọn yóò fún un yín láààyè láti tẹ̀dó sí ilẹ̀ Goṣeni, nítorí pé àwọn ará Ejibiti kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ darandaran.”