Geneza 40 – NTLR & YCB

Nouă Traducere În Limba Română

Geneza 40:1-23

Visele celor doi demnitari ai lui Faraon

1După toate acestea, paharnicul și brutarul regelui Egiptului au păcătuit împotriva stăpânului lor, regele Egiptului. 2Faraon s‑a mâniat pe cei doi demnitari ai săi, pe căpetenia paharnicilor și pe căpetenia brutarilor, 3și i‑a pus sub pază în casa comandantul gărzii3-4 Vezi nota de la 37:36., în temniță, în locul în care era închis și Iosif. 4Comandantul gărzii i‑a dat în grija lui Iosif și el i‑a slujit, iar aceștia au rămas sub pază pentru o vreme.

5Într‑o noapte, amândoi, atât paharnicul, cât și brutarul regelui Egiptului, care erau închiși în temniță, au avut câte un vis, fiecare vis cu semnificația lui. 6Dimineața, când a venit la ei, Iosif s‑a uitat la aceștia și iată că erau tulburați.

7El i‑a întrebat pe demnitarii lui Faraon, care erau sub pază împreună cu el în casa stăpânului său, zicând:

– De ce vă sunt fețele atât de triste astăzi?

8Ei i‑au răspuns:

– Am avut niște vise, dar nu este nimeni care să ni le poată interpreta.

Atunci Iosif le‑a zis:

– Oare nu‑I aparțin lui Dumnezeu interpretările viselor? Istorisiți‑mi‑le mie.

9Căpetenia paharnicilor i‑a istorisit visul său lui Iosif și i‑a zis:

– În visul meu se făcea că înaintea mea era o viță. 10În viță erau trei ramuri. Imediat după ce a înmugurit, i s‑a deschis floarea, iar ciorchinii s‑au făcut struguri copți. 11Cupa lui Faraon era în mâna mea. Am luat strugurii, i‑am stors în cupă și am pus cupa în mâna lui Faraon.

12Iosif i‑a zis:

– Aceasta este interpretarea visului: cele trei ramuri înseamnă trei zile. 13Peste trei zile, Faraon îți va înălța capul și te va repune în slujbă, iar tu vei pune cupa în mâna sa, așa cum făceai înainte, când erai paharnicul lui. 14Dar când îți va merge bine, te rog, adu‑ți aminte de mine și arată‑ți îndurarea față de mine. Amintește‑i lui Faraon de mine și scoate‑mă din această temniță, 15pentru că am fost luat cu forța din țara evreilor. Și nici chiar aici n‑am făcut nimic pentru care să merit să fiu aruncat în temniță15 Același termen ebraic tradus în 37:24 cu puț..

16Când căpetenia brutarilor a văzut că Iosif a dat o interpretare îmbucurătoare, i‑a zis:

– Și eu eram în visul meu și se făcea că pe capul meu se aflau trei coșuri de pâine.16 Sau: coșuri din nuiele. 17În coșul de deasupra erau tot felul de aluaturi coapte pentru Faraon, dar păsările le devorau din coșul de pe capul meu.

18Iosif i‑a răspuns și i‑a zis:

– Aceasta este interpretarea visului: cele trei coșuri înseamnă trei zile. 19Peste trei zile, Faraon îți va „înălța“ capul19 Lit.: îți va înălța capul de pe tine, cu sensul de îți va tăia capul. În ebraică este folosit un joc de cuvinte cu v. 13: îți va înălța capul. Vezi și v. 20. și te va atârna de un copac19 Sau: te va trage în țeapă, un mod de expunere a trupurilor celor executați (și în 40:22; 41:13)., iar păsările îți vor devora carnea.

20A treia zi, Faraon și‑a sărbătorit ziua de naștere și le‑a dat un ospăț tuturor slujitorilor săi. Dintre slujitorii săi, Faraon a înălțat capul căpeteniei paharnicilor și pe al căpeteniei brutarilor. 21El a reașezat în slujba de paharnic pe căpetenia paharnicilor, care a pus din nou cupa în mâna lui Faraon, 22însă pe căpetenia brutarilor a atârnat‑o de un copac, întocmai cum le interpretase Iosif. 23Dar căpetenia paharnicilor nu și‑a mai adus aminte de Iosif, ci l‑a uitat.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 40:1-23

Agbọ́tí àti alásè

1Kò pẹ́ lẹ́yìn èyí, ni agbọ́tí ọba àti alásè rẹ̀ ṣẹ̀ ọba Ejibiti, olúwa wọn. 2Farao sì bínú sí méjì nínú àwọn ìjòyè rẹ̀, olórí agbọ́tí àti olórí alásè, 3Ó sì fi wọ́n sí ìhámọ́ ní ilé olórí ẹ̀ṣọ́, ní inú ẹ̀wọ̀n ibi tí Josẹfu pẹ̀lú wà. 4Olórí ẹ̀ṣọ́ sì yan Josẹfu láti máa ṣe ìránṣẹ́ wọn.

Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti wà ní ìhámọ́ fún ìgbà díẹ̀. 5Ni ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọkùnrin méjèèjì náà—olórí agbọ́tí àti olórí alásè ọba Ejibiti, tí a dè sínú túbú, lá àlá ní òru kan náà, àlá kọ̀ọ̀kan sì ní ìtumọ̀ tirẹ̀.

6Nígbà tí Josẹfu dé ọ̀dọ̀ wọn ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó ṣe àkíyèsí pé, inú wọn kò dùn. 7Ó sì bi àwọn ìjòyè Farao tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìhámọ́, nínú ilé olúwa rẹ̀ léèrè pé, “Èéṣe tí ojú yín fi fàro bẹ́ẹ̀ ní òní, tí inú yín kò sì dùn?”

8Wọ́n wí pé, “Àwa méjèèjì ni a lá àlá, kò sì sí ẹni tí yóò túmọ̀ rẹ̀.”

Josẹfu sì wí fún wọn pé, “Ọlọ́run nìkan ni ó ni ìtumọ̀. Ẹ sọ àwọn àlá yín fún mi.”

9Olórí agbọ́tí sì ṣọ́ àlá rẹ̀ fún Josẹfu, wí pé, “Ní ojú àlá mi, mo rí àjàrà kan (tí wọn ń fi èso rẹ̀ ṣe wáìnì) níwájú mi, 10mo sì rí ẹ̀ka mẹ́ta lórí àjàrà náà, ó yọ ẹ̀ka tuntun, ó sì tanná, láìpẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní í ní èso tí ó ti pọ́n. 11Ife Farao sì wà lọ́wọ́ mi, mo sì mú àwọn èso àjàrà náà, mo sì fún un sínú ife Farao, mo sì gbé ife náà fún Farao.”

12Josẹfu wí fún un pé, “Èyí ni ìtumọ̀ àlá rẹ. Ẹ̀ka mẹ́ta náà dúró fún ọjọ́ mẹ́ta. 13Láàrín ọjọ́ mẹ́ta Farao yóò mú ọ jáde nínú ẹ̀wọ̀n padà sí ipò rẹ, ìwọ yóò sì tún máa gbé ọtí fún un, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ àtẹ̀yìnwá. 14Ṣùgbọ́n nígbà tí ohun gbogbo bá dára fún ọ, rántí mi kí o sì fi àánú hàn sí mi. Dárúkọ mi fún Farao, kí o sì mú mi jáde kúrò ní ìhín. 15Nítorí á jí mi gbé tà kúrò ní ilẹ̀ àwọn Heberu ni, àti pé níhìn-ín èmi kò ṣe ohunkóhun tí ó fi yẹ kí èmi wà ní ìhámọ́ bí mo ti wà yìí.”

16Nígbà tí olórí alásè rí i wí pé ìtumọ̀ tí Josẹfu fún àlá náà dára, ó wí fún Josẹfu pé, “Èmi pẹ̀lú lá àlá, mo ru agbọ̀n oúnjẹ mẹ́ta lórí. 17Nínú agbọ̀n tí ó wà lókè, onírúurú oúnjẹ ló wà níbẹ̀ fún Farao, ṣùgbọ́n àwọn ẹyẹ sì ń ṣà wọ́n jẹ láti inú apẹ̀rẹ̀ náà tí ó wà lórí mi.”

18Josẹfu dáhùn, “Èyí ni ìtumọ̀ àlá rẹ. Agbọ̀n mẹ́ta náà túmọ̀ sí ọjọ́ mẹ́ta. 19Láàrín ọjọ́ mẹ́ta, Farao yóò tú ọ sílẹ̀, yóò sì bẹ́ orí rẹ, yóò sì gbé ara rẹ kọ́ sí orí igi. Àwọn ẹyẹ yóò sì jẹ ara rẹ.”

20Ọjọ́ kẹta sì jẹ́ ọjọ́ ìbí Farao, ó sì ṣe àsè fún gbogbo àwọn ìjòyè e rẹ̀. Ó sì mú olórí agbọ́tí àti olórí alásè jáde kúrò nínú ẹ̀wọ̀n. 21Ó dá olórí agbọ́tí padà sí ipò tí ó wà tẹ́lẹ̀, kí ó ba à le máa fi ago lé Farao ní ọwọ́, 22ṣùgbọ́n, ó so olórí alásè kọ́ sórí igi, gẹ́gẹ́ bí Josẹfu ti sọ fún wọn nínú ìtumọ̀ rẹ̀ sí àlá wọn.

23Ṣùgbọ́n, olórí agbọ́tí kò rántí Josẹfu mọ́, kò tilẹ̀ ronú nípa rẹ̀.