Деяния 7 – NRT & YCB

New Russian Translation

Деяния 7:1-60

Речь Стефана перед Высшим Советом

1Затем первосвященник спросил Стефана:

– Это так?

2Стефан ответил:

– Братья и отцы! Выслушайте меня. Бог славы явился нашему праотцу Аврааму, когда он жил еще в Месопотамии – до того, как он поселился в Харране. 3«Оставь свою страну и своих родственников, – сказал Он ему, – и иди в землю, которую Я тебе укажу»7:3 См. Быт. 12:1. Возможно, что это повеление Бог дал Авраму еще в Уре Халдейском, а позже повторил его уже в Харране.. 4Авраам покинул страну халдеев и поселился в Харране. Оттуда, после смерти его отца, Бог переселил Авраама в страну, в которой вы сейчас живете7:4 См. Быт. 11:31-32; 12:4-5.. 5Он не дал ему здесь никакого наследия, не дал земли даже на ширину ступни7:5 См. Втор. 2:5.. Но Бог обещал дать эту землю во владение ему и его потомкам, хотя в то время у Авраама не было ребенка. 6Бог говорил ему: «Твои потомки будут странниками в чужой земле; они будут обращены в рабство и будут терпеть зло четыреста лет. 7Но Я накажу народ, поработивший их, – сказал Бог, – и тогда они выйдут оттуда и будут служить Мне на этом месте»7:6-7 См. Быт. 15:13-14. См. также Исх. 3:12. Эти слова Бога исполнились, когда Моисей вывел свой народ из Египта (Исх. 14; Деян. 7:17-36).. 8Затем Он дал Аврааму завет обрезания7:8 Об установлении обряда обрезания написано в Быт. 17:9-14.. Авраам стал отцом Исаака и обрезал его на восьмой день после рождения, Исаак же стал отцом Иакова, а Иаков – двенадцати патриархов7:8 Или: «Исаак же обрезал Иакова, а Иаков – двенадцать патриархов»..

9Патриархи из зависти к Иосифу продали его в Египет. Но Бог был с ним 10и избавил его от всех бед. Он дал Иосифу мудрость и помог ему заслужить расположение фараона, царя Египта. Тот сделал Иосифа правителем всего Египта и всего своего дома. 11Затем во всем Египте и в Ханаане начался голод и великое бедствие, и наши праотцы не могли найти пищи. 12Когда Иаков услышал о том, что в Египте есть зерно, он послал туда наших праотцев в первый раз. 13Когда они пришли во второй раз, Иосиф открылся своим братьям, и фараон узнал о родственниках Иосифа. 14После этого Иосиф послал за своим отцом Иаковом и за всеми своими родственниками, которых насчитывалось семьдесят пять человек. 15Иаков пришел в Египет, где умерли и он, и наши праотцы. 16Тела их были перенесены в Шехем и положены в гробницу, которую Авраам купил за серебро у сыновей Хамора в Шехеме7:9-16 История жизни Иосифа записана в Быт. 37; 39–50..

17По мере того как приближалось время исполнения обещаний, данных Богом Аврааму, возрастала численность нашего народа в Египте. 18Так продолжалось, пока в Египте не пришел к власти другой царь, который не знал про Иосифа. 19Он притеснял наших предков, действуя с коварством против нашего народа: он заставлял их выбрасывать новорожденных младенцев, чтобы те умирали.

20В это время родился Моисей, прекрасный перед Богом. Три месяца его вскармливали в отцовском доме, 21а когда вынуждены были расстаться с ним, его подобрала дочь фараона и воспитала, как своего собственного сына. 22Моисей был научен всей египетской мудрости; он был силен и в слове, и в деле7:18-22 См. Исх. 1:1–2:10.. 23Когда ему было сорок лет, он решил навестить своих братьев израильтян. 24Увидев, что одного из них обижает египтянин, он вступился и отомстил, убив обидчика. 25Моисей думал, его братья поймут, что Бог через него дает им избавление, но они не поняли. 26На следующий день Моисей увидел, как двое израильтян дерутся. Он попытался помирить их. «Вы же братья, – говорил он, – зачем вы обижаете друг друга?» 27Тогда обидчик оттолкнул Моисея и сказал: «Кто поставил тебя начальником и судьей над нами? 28Или ты хочешь убить и меня, как вчера убил египтянина?» 29Услышав такие слова, Моисей бежал и поселился в мадианской земле как чужеземец. Там у него родились два сына7:23-29 См. Исх. 2:11-25; 18:2-4..

30Через сорок лет Моисею явился Ангел в пламени горящего тернового куста в пустыне, недалеко от горы Синай. 31Моисей был поражен, когда это увидел. Он подошел ближе, чтобы лучше рассмотреть, и услышал голос Господа: 32«Я Бог твоих отцов, Бог Авраама, Исаака и Иакова». Моисей дрожал от страха и не решался поднять глаз. 33Господь сказал ему: «Сними свою обувь, потому что место, на котором ты стоишь, – святая земля7:33 Это согласуется с древним обычаем, до сих пор распространенным во многих странах Востока, где перед молитвой к Создателю принято разуваться.. 34Я увидел угнетение Моего народа в Египте и услышал их стоны. Я сошел, чтобы освободить их. А теперь иди, Я посылаю тебя в Египет»7:30-34 См. Исх. 3:1-10..

35Того самого Моисея, которого они отвергли и о котором говорили: «Кто поставил тебя начальником и судьей?»7:35 См. Исх. 2:14. – Бог посылал теперь как вождя и избавителя через Ангела, Который явился ему в терновом кусте. 36Моисей вывел их из Египта, совершая чудеса и знамения в Египте, у Красного моря и в пустыне на протяжении сорока лет. 37Этот же самый Моисей сказал израильтянам: «Из ваших же братьев Бог поставит вам Пророка подобного мне»7:37 См. Втор. 18:15.. 38Он, Моисей, – тот самый человек, который был с народом Израиля, собранным в пустыне; он был там с Ангелом, Который говорил с ним на горе Синай, и с нашими отцами. Он принял живые слова, чтобы передать их нам.

39Наши отцы, однако, отказались повиноваться ему, но отвергли его и захотели вернуться в Египет. 40Они сказали Аарону: «Сделай нам богов, которые пойдут перед нами, потому что мы не знаем, что приключилось с этим Моисеем, выведшим нас из Египта»7:40 См. Исх. 32:1, 23.. 41В те дни они сделали золотого тельца, принесли этому идолу жертву и радовались делу своих рук. 42Бог же отвернулся от них и оставил их поклоняться небесным телам, как об этом написано в Книге Пророков:

«Приносили ли вы Мне заклания и жертвы

в течение сорока лет в пустыне, дом Израиля?

43Вы взяли с собой шатер Молоха7:43 Молох – аммонитский бог, в жертвы которому приносились дети. По Закону за поклонение Молоху израильтянам грозила смертная казнь (см. Лев. 18:21; 20:2-5).,

звезду вашего бога Ремфана

и изображения, которые вы сделали для поклонения.

Поэтому Я пошлю вас в плен дальше Вавилона»7:42-43 См. Ам. 5:25-27 со сноской..

44У наших отцов в пустыне была скиния свидетельства, сделанная согласно указаниям, которые Бог дал Моисею, и по образцу, который увидел Моисей. 45Получив эту скинию, наши отцы, под предводительством Иисуса Навина, внесли ее во владения народов, которых Бог изгнал перед ними. И так было до времен царствования Давида, 46который был любим Богом и просил у Него позволения найти жилище для Бога Иакова7:46 В некоторых древних рукописях: «для дома Иакова».. 47Однако дом Ему построил Соломон. 48Но Всевышний не живет в домах, построенных людьми. Пророк говорит об этом:

49«Небеса – престол Мой,

и земля – подножие ног Моих!

Какой вы можете построить Мне дом? –

говорит Господь. –

Где может быть место отдыха для Меня?

50Разве не Моей рукой все это сотворено?»7:49-50 См. Ис. 66:1-2.

51Вы – упрямый народ с необрезанными сердцами и ушами!7:51 Люди с необрезанными сердцами и ушами – это метафора, обозначающая людей непокорных Богу. Вы всегда противитесь Святому Духу, как и ваши отцы! 52Кого из пророков ваши отцы не преследовали? Они убили тех, кто предсказывал пришествие Праведного, предателями и убийцами Которого стали теперь вы! 53Приняв Закон, переданный вам через ангелов, вы не соблюли его.

Убийство Стефана

54Услышав это, они пришли в ярость и начали скрежетать зубами от злости на Стефана. 55Стефан же, исполненный Святого Духа, поднял глаза к небу и увидел славу Божью и Иисуса, стоящего по правую руку от Бога7:55 См. Пс. 109:1..

56– Смотрите, – сказал он, – я вижу открытые небеса и Сына Человеческого, стоящего по правую руку от Бога!

57Тогда они все вместе, заткнув уши, с громким криком бросились на него. 58Они выволокли Стефана за пределы города и стали бросать в него камни. Свидетели обвинения оставили свои плащи у ног молодого человека по имени Савл. 59Когда они бросали в Стефана камни, тот молился:

– Господь Иисус, прими дух мой!

60Потом он пал на колени и громко воскликнул:

– Господи, не наказывай их за этот грех!

С этими словами он умер.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Ìṣe àwọn Aposteli 7:1-60

Ọ̀rọ̀ Stefanu sí àwọn àjọ ìgbìmọ̀

1Nígbà náà ni olórí àlùfáà wí pé, “Òtítọ́ ha ni àwọn ẹ̀sùn tí wọ́ fi kàn ọ́ bí?”

27.2: Sm 29.3; Gẹ 11.31; 15.7.Ní ìdáhùn sí èyí ó wí pé, “Ẹ̀yin arákùnrin àti ẹ̀yin baba, ẹ fetísílẹ̀ sí mi! Ọlọ́run ògo fi ara hàn fún Abrahamu baba wa, nígbà tí ó wà ni Mesopotamia, kí ó to ṣe àtìpó ni Harani. 37.3: Gẹ 12.1.Ọlọ́run wí fún un pé, ‘Jáde kúrò ní orílẹ̀-èdè rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ, lọ sí ilẹ̀ kan tí èmi yóò fihàn ọ́.’

47.4: Gẹ 11.31; 15.7; 12.5.“Nígbà náà ni ó jáde kúrò ní ilẹ̀ àwọn ará Kaldea, ó sì ṣe àtìpó ni Harani. Lẹ́yìn ìgbà tí baba rẹ̀ sì kú, Ọlọ́run mú un sípò padà wá sí ilẹ̀ yìí, níbi tí ẹ̀yin ń gbé báyìí. 57.5: De 2.5; Gẹ 12.7; 17.8.Kò sí fún un ni ìní kan, ànító bi ìwọ̀n ààyè ẹsẹ̀ kan. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ṣe ìlérí fún pé, òun yóò fi ilẹ̀ ìní náà fún un àti fún àwọn irú-ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀, nígbà tí kò tí ì ní ọmọ. 67.6-7: Gẹ 15.13-14.Ọlọ́run sì sọ báyìí pé, ‘Irú-ọmọ rẹ yóò ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì; wọn ó sì sọ wọn di ẹrú, wọn ó sì pọ́n wọn lójú fún irinwó (400) ọdún. 77.7: Ek 3.12.Ọlọ́run wí pé, Orílẹ̀-èdè náà tí wọn yóò máa sìn, ni èmi ó dá lẹ́jọ́; lẹ́yìn náà ni wọn ó sì jáde kúrò, wọn ó sì wá sìn mí níhìn-ín yìí.’ 87.8: Gẹ 17.10-14; 21.2-4; 25.26; 29.31-35; 30.1-24; 35.16-18; 35.23-26.Ó sì fún Abrahamu ni májẹ̀mú ìkọlà. Abrahamu bí Isaaki, ó kọ ọ́ ní ilà ni ọjọ́ kẹjọ tí ó bí i. Isaaki sí bí Jakọbu, Jakọbu sì bí àwọn baba ńlá méjìlá.

97.9: Gẹ 37.11,28; 45.4.7.9-10: Gẹ 39.2-3,21.“Àwọn baba ńlá sí ṣe ìlara Josẹfu, wọ́n sì tà á sí Ejibiti; ṣùgbọ́n Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, 107.10: Gẹ 41.40-46; Sm 105.21.ó sì yọ ọ́ kúrò nínú ìpọ́njú rẹ̀ gbogbo. Ó sì fún Josẹfu ní ọgbọ́n, ó sì mú kí ó rí ojúrere Farao ọba Ejibiti; òun sì fi jẹ baálẹ̀ Ejibiti àti gbogbo ilé rẹ̀.

117.11: Gẹ 41.54-55; 42.5.“Ìyàn kan sì mú ni gbogbo ilẹ̀ Ejibiti àti ni Kenaani, àti ìpọ́njú ńlá, àwọn baba wa kò sì rí oúnjẹ. 127.12: Gẹ 42.2.Ṣùgbọ́n nígbà tí Jakọbu gbọ́ pé alikama ń bẹ ni Ejibiti, ó rán àwọn baba wa lọ lẹ́ẹ̀kínní. 137.13: Gẹ 45.1-4.Nígbà kejì Josẹfu fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn arákùnrin rẹ̀, a sì tún fi wọ́n hàn fún Farao. 147.14: Gẹ 45.9-10.7.14-15: De 10.22.Lẹ́yìn èyí, Josẹfu ránṣẹ́ pe Jakọbu baba rẹ̀, àti àwọn ìbátan rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, gbogbo wọ́n sì tó àrùndínlọ́gọ́rin ọkàn. 15Nígbà náà ni Jakọbu sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti, ní ibi tí òun àti àwọn baba wa kú sí. 167.16: Jo 24.32; Gẹ 50.13.A sì gbé òkú wọn padà wá sí Ṣekemu, a sì tẹ́ wọn sínú ibojì ti Abrahamu rà ni ọwọ́ àwọn ọmọ Amori ní Ṣekemu ní iye owó wúrà kan.

177.17-18: Ek 1.7-8.“Nígbà tí àkókò tí Ọlọ́run yóò mú ìlérí tí ó ṣe fún Abrahamu ṣẹ kù sí dẹ̀dẹ̀, àwọn ènìyàn wa ń gbèrú si gidigidi ní iye ní ilẹ̀ Ejibiti. 18Ṣùgbọ́n ọba tuntun mìíràn tí kò mọ Josẹfu jẹ ní ilẹ̀ Ejibiti. 197.19: Ek 1.10-11; 1.15-22.Òun náà ni ó ṣe àrékérekè sí àwọn ìbátan wa. Wọn sì hùwà búburú sí àwọn baba wa, tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi já àwọn ọmọ ọwọ́ wọn kúrò lọ́wọ́ wọn nítorí kí wọn má ṣe yè.

207.20: Ek 2.2.“Ní àkókò náà ni a bí Mose ọmọ tí ó se iyebíye, tí wọn sí bọ́ lóṣù mẹ́ta ni ilé baba rẹ̀. 217.21: Ek 2.5-6,10.Nígbà tí wọn sí gbe é sọnù, ọmọbìnrin Farao gbé e, ó sì tọ ọ́ dàgbà gẹ́gẹ́ bí ọmọ ara rẹ̀. 22A sì kọ́ Mose ni gbogbo ọgbọ́n ara Ejibiti, ó sì pọ̀ ni ọ̀rọ̀ àti ní ìṣe.

237.23-29: Ek 2.11-15.“Nígbà tí Mose di ọmọ ogójì ọdún, ó sọ sí i lọ́kàn láti lọ bẹ àwọn ọmọ Israẹli ará rẹ̀ wò. 24Nígbà tí ó sì rí ọ̀kan nínú wọ́n tí ará Ejibiti kan ń jẹ́ ní ìyà, ó gbèjà rẹ̀, ó gbẹ̀san ẹni tí wọ́n jẹ ní ìyà nípa lílu ará Ejibiti náà pa. 25Mose rò bí àwọn ará òun mọ̀ pé Ọlọ́run yóò ti ọwọ́ òun gbà wọn; ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀. 26Ní ọjọ́ kejì Mose yọ sí àwọn ọmọ Israẹli méjì bí wọ́n ti ń jà. Òun si fẹ́ parí ìjà fún wọn. Ó wí pé, ‘Ènìyàn mi, ará ni ẹ̀yin; èéṣe tí ẹ̀yin fi ń ṣe ohun tí kò tọ́ sí ara yín?’

27“Ṣùgbọ́n ẹni tí ó fínràn sí ẹnìkejì rẹ̀ ti Mose sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó wí pé, ‘Ta ni ó fi ọ́ jẹ olórí àti onídàájọ́ lórí wa? 28Ṣé ìwọ fẹ́ pa mí bí o ti pa ará Ejibiti lánàá?’ 297.29: Ek 2.22; 18.3-4.Mose sì sá nítorí ọ̀rọ̀ yìí, ó sì wa ṣe àtìpó ni ilẹ̀ Midiani, níbi tí ó gbé bí ọmọ méjì.

307.30-34: Ek 3.1-10.“Nígbà tí ogójì ọdún sì pé, angẹli Olúwa fi ara han Mose ní ijù, ní òkè Sinai, nínú ọ̀wọ́-iná nínú igbó. 31Nígbà tí Mose sì rí i, ẹnu yà á sí ìran náà; nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn láti wò ó fín, ohùn Olúwa kọ sí i, 32wí pé ‘Èmi ni Ọlọ́run àwọn baba rẹ, Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu,’ Mose sì wárìrì pẹ̀lú ìbẹ̀rù, kò sì dáṣà láti wò ó mọ́.

33“Olúwa sì wí fún un pé, ‘Bọ́ bàtà rẹ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ, nítorí ibi tí ìwọ dúró sí i nì ilẹ̀ mímọ́ ni. 34Ní rí rí, mo ti rí ìpọ́njú àwọn ènìyàn mi tí ń bẹ ni Ejibiti, mo sì ti gbọ́ ìkérora wọn, mo sì sọ̀kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n. Wá nísinsin yìí, Èmi ó sì rán ọ lọ sí ilẹ̀ Ejibiti.’

357.35: Ek 2.14.“Mose náà yìí tí wọ́n kọ̀, wí pé, ‘Ta ni ó fi jẹ olórí àti onídàájọ́?’ Òun náà ni Ọlọ́run rán lọ láti ọwọ́ angẹli, tí ó farahàn án ní pápá, láti ṣe olórí àti olùdáǹdè. 367.36: Ek 7.3; 14.21; Nu 14.33.Òun ni ó mú wọn jáde, lẹ́yìn ìgbà tí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ àmì ní ilẹ̀ Ejibiti, àti ni Òkun pupa, àti ni aginjù ní ogójì ọdún.

377.37: De 18.15,18.“Èyí ni Mose náà ti ó wí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ọlọ́run yóò gbé wòlíì kan bí èmi dìde nínú àwọn ènìyàn yín.’ 387.38: Ek 19.Èyí náà ni ẹni tí ó wà nínú ìjọ ní ijù pẹ̀lú angẹli náà tí ó bá a sọ̀rọ̀ ní orí òkè Sinai, àti pẹ̀lú àwọn baba wa; ẹni ti ó gba ọ̀rọ̀ ìyè láti fi fún wa.

397.39: Nu 14.3-4.“Ṣùgbọ́n àwọn baba wa kò fẹ́ gbọ́ tirẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀, àti pé nínú ọkàn wọn, wọn fẹ́ yípadà lọ sí ilẹ̀ Ejibiti. 407.40: Ek 32.1,23.Wọ́n wí fún Aaroni pé, ‘Dá òrìṣà fún wa tí yóò máa tọ́nà ṣáájú wa; nítorí bí ó ṣe ti Mose yìí tí ó mú wa jáde wá láti ilẹ̀ Ejibiti, a kò mọ̀ ohun tí ó ṣe é.’ 417.41: Ek 32.4,6.Wọ́n sì yá ère ẹgbọrọ màlúù ni ọjọ́ wọ̀nyí. Wọ́n sì rú ẹbọ sí ère náà, wọ́n sì ń yọ̀ nínú ohun tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe. 42Ọlọ́run sì padà, ó fi wọn sílẹ̀ láti máa sin ogun ọ̀run: òòrùn, òṣùpá àti ìràwọ̀. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé àwọn wòlíì pé:

“ ‘Ẹ̀yin ha mú ẹran tí a pa àti ẹbọ wa fún mi

ní ogójì ọdún ní ijù bí, ìwọ ilé Israẹli?

43Ẹ̀yin sì tẹ́wọ́gbà àgọ́ Moleki,

àti ìràwọ̀ Refani òrìṣà yín,

àwòrán tí ẹ̀yin ṣe láti máa bọ wọ́n.

Nítorí náà èmi yóò kó yín lọ sí ìgbèkùn rékọjá Babeli.’

447.44: Ek 25.9,40.“Àwọn baba wa ní àgọ́ ẹ̀rí pẹ̀lú wọn ní ijù. Èyí tí a ṣe gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí ó ba Mose sọ̀rọ̀ pé kí ó ṣe é, gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí ó ti rí. 457.45: Jo 3.14-17; De 32.49.Ti àwọn baba wa tí ó tẹ̀lé wọn sí mú bá Joṣua wá sí ilẹ̀ ìní àwọn aláìkọlà, tí Ọlọ́run lè jáde kúrò níwájú àwọn baba wa, títí dí àkókò Dafidi. 467.46: 2Sa 7.8-16; Sm 132.1-5.Ẹni tí ó rí ojúrere níwájú Ọlọ́run, tí ó sì tọrọ láti rí ibùgbé fún Ọlọ́run Jakọbu. 477.47: 1Ọb 6.Ṣùgbọ́n Solomoni ni ó kọ́ ilé fún un.

48“Ṣùgbọ́n Ọ̀gá-ògo kì í gbé ilé ti a fi ọwọ́ kọ́, gẹ́gẹ́ bí wòlíì ti wí pé:

497.49-50: Isa 66.1-2.“ ‘Ọ̀run ni ìtẹ́ mi,

ayé ni àpótí ìtìsẹ̀ mi.

Irú ilé kín ní ẹ̀yin yóò kọ́ fún mi?

ni Olúwa wí.

Tàbí níbo ni yóò jẹ́ ibi ìsinmi mi?

50Ọwọ́ mi kò ha ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí.’

517.51: Ek 33.3,5; Jr 9.26; 6.10; Nu 27.14; Isa 63.10.“Ẹ̀yin ọlọ́rùn líle àti aláìkọlà àyà àti etí! Bí àwọn baba yín gẹ́lẹ́ ni ẹ̀yin rí. Nígbà gbogbo ni ẹ̀yin máa ń dènà Ẹ̀mí Mímọ́! 52Ǹjẹ́ ọ̀kan tilẹ̀ wà nínú àwọn wòlíì tí àwọn baba yín kò ṣe inúnibíni sí? Wọn sì ti pa àwọn ti ó ti ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa wíwá Ẹni Olódodo náà. Nísinsin yìí ẹ̀yin ti dalẹ̀ rẹ̀ ẹ̀yin sí ti pa. 53Ẹ̀yin tí ó gba òfin, gẹ́gẹ́ bí àwọn angẹli ti fi fún ni, tí ẹ kò sì pa á mọ́.”

A sọ Stefanu ní òkúta pa

54Nígbà tí wọn sì gbọ́ nǹkan wọ̀nyí ọkàn wọn gbọgbẹ́ dé inú, wọn sì payínkeke sí i. 55Ṣùgbọ́n Stefanu, ẹni tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó tẹjúmọ́ ọ̀run, ó sì rí ògo Ọlọ́run, àti Jesu dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run. 56Ó sì wí pé, “Wò ó, mo rí ọ̀run ṣí sílẹ̀, Ọmọ Ènìyàn sì dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.”

57Nígbà náà ni wọn kígbe ní ohùn rara, wọn sí di etí wọ́n, gbogbo wọn sì sáré sí i, wọ́n sì rọ́ lù ú, 58wọ́n sì wọ́ ọ sẹ́yìn òde ìlú, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sísọ ọ́ ní òkúta; àwọn ẹlẹ́rìí sì fi aṣọ wọn lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ ọmọkùnrin kan tí a ń pè ní Saulu.

59Bí wọ́n ti ń sọ Stefanu ní òkúta, ó sì ké pe Olúwa wí pé, “Jesu Olúwa, gba ẹ̀mí mi.” 60Nígbà náà ni ó wólẹ̀ lórí eékún rẹ̀, ó kígbe sókè pé, “Olúwa, má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ yìí sí wọn ní ọrùn.” Nígbà ti ó sì wí èyí tán, ó sùn lọ.