Revelation 20 – NIVUK & YCB

New International Version – UK

Revelation 20:1-15

The thousand years

1And I saw an angel coming down out of heaven, having the key to the Abyss and holding in his hand a great chain. 2He seized the dragon, that ancient snake, who is the devil, or Satan, and bound him for a thousand years. 3He threw him into the Abyss, and locked and sealed it over him, to keep him from deceiving the nations anymore until the thousand years were ended. After that, he must be set free for a short time.

4I saw thrones on which were seated those who had been given authority to judge. And I saw the souls of those who had been beheaded because of their testimony about Jesus and because of the word of God. They20:4 Or God; I also saw those who had not worshipped the beast or its image and had not received its mark on their foreheads or their hands. They came to life and reigned with Christ for a thousand years. 5(The rest of the dead did not come to life until the thousand years were ended.) This is the first resurrection. 6Blessed and holy are those who share in the first resurrection. The second death has no power over them, but they will be priests of God and of Christ and will reign with him for a thousand years.

The judgment of Satan

7When the thousand years are over, Satan will be released from his prison 8and will go out to deceive the nations in the four corners of the earth – Gog and Magog – and to gather them for battle. In number they are like the sand on the seashore. 9They marched across the breadth of the earth and surrounded the camp of God’s people, the city he loves. But fire came down from heaven and devoured them. 10And the devil, who deceived them, was thrown into the lake of burning sulphur, where the beast and the false prophet had been thrown. They will be tormented day and night for ever and ever.

The judgment of the dead

11Then I saw a great white throne and him who was seated on it. The earth and the heavens fled from his presence, and there was no place for them. 12And I saw the dead, great and small, standing before the throne, and books were opened. Another book was opened, which is the book of life. The dead were judged according to what they had done as recorded in the books. 13The sea gave up the dead that were in it, and death and Hades gave up the dead that were in them, and each person was judged according to what they had done. 14Then death and Hades were thrown into the lake of fire. The lake of fire is the second death. 15Anyone whose name was not found written in the book of life was thrown into the lake of fire.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Ìfihàn 20:1-15

Ìjọba ẹgbẹ̀rún ọdún

1Mo sì rí angẹli kan ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, ti òun ti kọ́kọ́rọ́ ọ̀gbun, àti ẹ̀wọ̀n ńlá kan ní ọwọ́ rẹ̀. 2O sì di dragoni náà mú, ejò àtijọ́ nì, tí í ṣe èṣù, àti Satani, ó sì dè é ní ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún. 3Ó sì gbé e sọ sínú ọ̀gbun náà, ó sì tì í, ó sì fi èdìdì dì í lórí rẹ̀, kí ó má ba à tan àwọn orílẹ̀-èdè jẹ mọ́ títí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún náà yóò fi pé. Lẹ́yìn èyí, a kò le ṣàì tú u sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀.

420.4: Da 7.9,22,27.Mo sì rí àwọn ìtẹ́, wọ́n sì jókòó lórí wọn, a sì fi ìdájọ́ fún wọ́n, mo sì rí ọkàn àwọn tí a ti bẹ́ lórí nítorí ẹ̀rí Jesu, àti nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti àwọn tí kò sì foríbalẹ̀ fún ẹranko náà, àti fún àwòrán rẹ̀, tàbí tí kò sì gbà àmì rẹ̀ ní iwájú wọn àti ní ọwọ́ wọn; wọ́n sì wà láààyè, wọ́n sì jẹ ọba pẹ̀lú Kristi ní ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún. 5(Àwọn òkú ìyókù kò wà láààyè mọ́ títí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún náà yóò fi pé). Èyí ni àjíǹde èkínní. 6Ẹni ìbùkún àti mímọ́ ni ẹni tí ó ní ipa nínú àjíǹde èkínní náà. Lórí àwọn wọ̀nyí ikú ẹ̀ẹ̀kejì kò ní agbára, ṣùgbọ́n wọn ó jẹ́ àlùfáà Ọlọ́run àti ti Kristi, wọn ó sì máa jẹ ọba pẹ̀lú rẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún.

Ìparun Satani

7Nígbà tí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún náà bá sì pé, a ó tú Satani sílẹ̀ kúrò nínú túbú rẹ̀. 820.8: El 38.2,9,15.Yóò sì jáde lọ láti máa tan àwọn orílẹ̀-èdè tí ń bẹ ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé jẹ, Gogu àti Magogu, láti gbá wọn jọ sí ogun: àwọn tí iyè wọn dàbí iyanrìn Òkun. 920.9: 2Ọb 1.10-12.Wọ́n sì gòkè lọ la ibú ayé já, wọ́n sì yí ibùdó àwọn ènìyàn mímọ́ ká àti ìlú àyànfẹ́ náà: iná sì ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, ó sì jó wọn run. 10A sì wọ́ Èṣù tí ó tàn wọ́n jẹ lọ sínú adágún iná àti sulfuru, níbi tí ẹranko àti wòlíì èké nì gbé wà, a ó sì máa dá wọn lóró tọ̀sán tòru láé àti láéláé.

Àwọn òkú gba ìdájọ́

1120.11-12: Da 7.9-10.Mo sì rí ìtẹ́ funfun ńlá kan, àti ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀, níwájú ẹni tí ayé àti ọ̀run fò lọ; a kò sì rí ààyè fún wọn mọ́. 12Mo sì rí àwọn òkú, àti èwe àti àgbà, wọn dúró níwájú ìtẹ́; a sì ṣí àwọn ìwé sílẹ̀; a sì ṣí àwọn ìwé mìíràn kan sílẹ̀ tí í ṣe ìwé ìyè: a sì ṣe ìdájọ́ fún àwọn òkú láti inú ohun tí a ti kọ sínú àwọn ìwé náà, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn. 13Òkun sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú rẹ̀ lọ́wọ́; àti òkú àti ipò òkú sì jọ̀wọ́ òkú tí ó wà nínú wọn pẹ̀lú: a sì ṣe ìdájọ́ wọn, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn. 14Àti ikú àti ipò òkú ni a sì sọ sínú adágún iná. Èyí ni ikú kejì. 1520.15: If 3.5.Bí a bá sì rí ẹnikẹ́ni tí a kò kọ orúkọ rẹ̀ sínú ìwé ìyè, a ó sọ ọ́ sínú adágún iná.