Revelation 15 – NIVUK & YCB

New International Version – UK

Revelation 15:1-8

Seven angels with seven plagues

1I saw in heaven another great and marvellous sign: seven angels with the seven last plagues – last, because with them God’s wrath is completed. 2And I saw what looked like a sea of glass glowing with fire and, standing beside the sea, those who had been victorious over the beast and its image and over the number of its name. They held harps given them by God 3and sang the song of God’s servant Moses and of the Lamb:

‘Great and marvellous are your deeds,

Lord God Almighty.

Just and true are your ways,

King of the nations.15:3 Some manuscripts ages

4Who will not fear you, Lord,

and bring glory to your name?

For you alone are holy.

All nations will come

and worship before you,

for your righteous acts have been revealed.’15:3,4 Phrases in this song are drawn from Psalm 111:2,3; Deut. 32:4; Jer. 10:7; Psalms 86:9; 98:2.

5After this I looked, and I saw in heaven the temple – that is, the tabernacle of the covenant law – and it was opened. 6Out of the temple came the seven angels with the seven plagues. They were dressed in clean, shining linen and wore golden sashes round their chests. 7Then one of the four living creatures gave to the seven angels seven golden bowls filled with the wrath of God, who lives for ever and ever. 8And the temple was filled with smoke from the glory of God and from his power, and no-one could enter the temple until the seven plagues of the seven angels were completed.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Ìfihàn 15:1-8

Angẹli méje pẹ̀lú ìyọnu méje

115.1: Le 26.21.Mo sì rí àmì mìíràn ní ọ̀run tí ó tóbi tí ó sì ya ni lẹ́nu, àwọn angẹli méje tí ó ni àwọn ìyọnu méje ìkẹyìn, nítorí nínú wọn ni ìbínú Ọlọ́run dé òpin. 2Mo sì rí bí ẹni pé, Òkun dígí tí o dàpọ̀ pẹ̀lú iná: àwọn tí ó sì dúró lórí Òkun dígí yìí jẹ́ àwọn ti wọ́n ṣẹ́gun ẹranko náà, àti àwòrán rẹ̀, àti àmì rẹ̀ àti nọ́mbà orúkọ rẹ̀, wọn ní ohun èlò orin Ọlọ́run. 315.3: Ek 15.1; Sm 145.17.Wọ́n sì ń kọ orin ti Mose, ìránṣẹ́ Ọlọ́run, àti orin ti Ọ̀dọ́-Àgùntàn, wí pé:

“Títóbi àti ìyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ,

Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè;

òdodo àti òtítọ́ ni ọ̀nà rẹ̀,

ìwọ ọba àwọn orílẹ̀-èdè.

415.4: Jr 10.7; Sm 86.9-10.Ta ni kì yóò bẹ̀rù, Olúwa,

tí kì yóò sì fi ògo fún orúkọ rẹ̀?

Nítorí ìwọ nìkan ṣoṣo ni mímọ́.

Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni yóò sì wá,

ti yóò sì foríbalẹ̀ níwájú rẹ,

nítorí a ti fi ìdájọ́ rẹ hàn.”

515.5: Ek 40.34.Lẹ́yìn náà mo sì wo, sì kíyèsi i, a ṣí tẹmpili àgọ́ ẹ̀rí ní ọ̀run sílẹ̀; 6àwọn angẹli méje náà sì ti inú tẹmpili jáde wá, wọ́n ni ìyọnu méje náà, a wọ̀ wọ́n ní aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun ti ń dán, a sì fi àmùrè wúrà dìwọ́n ni oókan àyà. 7Àti ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà fi ìgò wúrà méje fún àwọn angẹli méje náà, tí ó kún fún ìbínú Ọlọ́run, ẹni tí ń bẹ láààyè láé àti láéláé. 8Tẹmpili náà sì kún fún èéfín láti inú ògo Ọlọ́run àti agbára rẹ̀ wá; ẹnikẹ́ni kò sì lè wọ inú tẹmpili náà lọ títí a fi mú ìyọnu méjèèje àwọn angẹli méje náà ṣẹ.