1 Chronicles 5 – NIVUK & YCB

New International Version – UK

1 Chronicles 5:1-26

Reuben

1The sons of Reuben the firstborn of Israel (he was the firstborn, but when he defiled his father’s marriage bed, his rights as firstborn were given to the sons of Joseph son of Israel; so he could not be listed in the genealogical record in accordance with his birthright, 2and though Judah was the strongest of his brothers and a ruler came from him, the rights of the firstborn belonged to Joseph) – 3the sons of Reuben the firstborn of Israel:

Hanok, Pallu, Hezron and Karmi.

4The descendants of Joel:

Shemaiah his son, Gog his son,

Shimei his son, 5Micah his son,

Reaiah his son, Baal his son,

6and Beerah his son, whom Tiglath-Pileser5:6 Hebrew Tilgath-Pilneser, a variant of Tiglath-Pileser; also in verse 26 king of Assyria took into exile. Beerah was a leader of the Reubenites.

7Their relatives by clans, listed according to their genealogical records:

Jeiel the chief, Zechariah, 8and Bela son of Azaz, the son of Shema, the son of Joel.

They settled in the area from Aroer to Nebo and Baal Meon. 9To the east they occupied the land up to the edge of the desert that extends to the River Euphrates, because their livestock had increased in Gilead.

10During Saul’s reign they waged war against the Hagrites, who were defeated at their hands; they occupied the dwellings of the Hagrites throughout the entire region east of Gilead.

Gad

11The Gadites lived next to them in Bashan, as far as Salekah:

12Joel was the chief, Shapham the second, then Janai and Shaphat, in Bashan.

13Their relatives, by families, were:

Michael, Meshullam, Sheba, Jorai, Jakan, Zia and Eber – seven in all.

14These were the sons of Abihail son of Huri, the son of Jaroah, the son of Gilead, the son of Michael, the son of Jeshishai, the son of Jahdo, the son of Buz.

15Ahi son of Abdiel, the son of Guni, was head of their family.

16The Gadites lived in Gilead, in Bashan and its outlying villages, and on all the pasture-lands of Sharon as far as they extended.

17All these were entered in the genealogical records during the reigns of Jotham king of Judah and Jeroboam king of Israel.

18The Reubenites, the Gadites and the half-tribe of Manasseh had 44,760 men ready for military service – able-bodied men who could handle shield and sword, who could use a bow, and who were trained for battle. 19They waged war against the Hagrites, Jetur, Naphish and Nodab. 20They were helped in fighting them, and God delivered the Hagrites and all their allies into their hands, because they cried out to him during the battle. He answered their prayers, because they trusted in him. 21They seized the livestock of the Hagrites – fifty thousand camels, two hundred and fifty thousand sheep and two thousand donkeys. They also took one hundred thousand people captive, 22and many others fell slain, because the battle was God’s. And they occupied the land until the exile.

The half-tribe of Manasseh

23The people of the half-tribe of Manasseh were numerous; they settled in the land from Bashan to Baal Hermon, that is, to Senir (Mount Hermon).

24These were the heads of their families: Epher, Ishi, Eliel, Azriel, Jeremiah, Hodaviah and Jahdiel. They were brave warriors, famous men, and heads of their families. 25But they were unfaithful to the God of their ancestors and prostituted themselves to the gods of the peoples of the land, whom God had destroyed before them. 26So the God of Israel stirred up the spirit of Pul king of Assyria (that is, Tiglath-Pileser king of Assyria), who took the Reubenites, the Gadites and the half-tribe of Manasseh into exile. He took them to Halah, Habor, Hara and the river of Gozan, where they are to this day.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Kronika 5:1-26

Rubeni

15.1-26: Gẹ 46.9; Nu 26.5,6.Ǹjẹ́ àwọn ọmọ Reubeni, àkọ́bí Israẹli. (Nítorí òun ni àkọ́bí; ṣùgbọ́n, bí ó ti ṣe pé ó ba ibùsùn baba rẹ̀ jẹ́, a fi ogún ìbí rẹ̀ fún àwọn ọmọ Josẹfu ọmọ Israẹli: a kì yóò sì ka ìtàn ìdílé náà gẹ́gẹ́ bí ipò ìbí. 2Nítorí Juda borí àwọn arákùnrin rẹ̀, àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni aláṣẹ ti ń jáde wá; ṣùgbọ́n ogún ìbí jẹ́ ti Josẹfu), 3àwọn ọmọ Reubeni àkọ́bí Israẹli ni:

Hanoku àti Pallu, Hesroni àti Karmi.

4Àwọn ọmọ Joẹli:

Ṣemaiah ọmọ rẹ̀, Gogu ọmọ rẹ̀,

Ṣimei ọmọ rẹ̀. 5Mika ọmọ rẹ̀,

Reaiah ọmọ rẹ̀, Baali ọmọ rẹ̀.

6Beera ọmọ rẹ̀, tí Tiglat-Pileseri ọba Asiria kó ní ìgbèkùn lọ. Ìjòyè àwọn ọmọ Reubeni ni Beera jẹ́.

7Àti àwọn arákùnrin rẹ̀ nípa ìdílé wọn, nígbà tí a ń ka ìtàn ìdílé ìran wọn:

Jeieli àti Sekariah ni olórí, 8àti Bela ọmọ Asasi ọmọ Ṣema, ọmọ Joẹli.

Wọ́n tí ń gbé Aroeri àní títí dé Nebo àti Baali-Meoni. 9Àti níhà àríwá, o tẹ̀dó lọ títí dé àtiwọ aginjù láti odò Eufurate; nítorí tí ẹran ọ̀sìn wọn pọ̀ sí i ní ilẹ̀ Gileadi.

10Àti ní ọjọ́ Saulu, wọ́n bá àwọn ọmọ Hagari jagun, ẹni tí ó ṣubú nípa ọwọ́ wọn; wọ́n sì ń gbé inú àgọ́ wọn ní gbogbo ilẹ̀ àríwá Gileadi.

Ìdílé Gadi

11Àti àwọn ọmọ Gadi ń gbé lékè wọn, ní ilẹ̀ Baṣani títí dé Saleka:

12Joẹli jẹ́ olórí, Ṣafamu ìran ọmọ Janai, àti Ṣafati ni Baṣani.

13Àti àwọn arákùnrin wọn ti ilẹ̀ àwọn baba wọn ní:

Mikaeli, Meṣullamu Ṣeba, Jorai, Jaka, Sia àti Eberi méje.

14Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Abihaili, ọmọ Huri, ọmọ Jeroa, ọmọ Gileadi, ọmọ Mikaeli, ọmọ Jeṣiṣai, ọmọ Jado, ọmọ Busi.

15Ahi, ọmọ Adbeeli, ọmọ Guni, olórí ilé àwọn baba wọn.

16Wọ́n sì ń gbé Gileadi ní Baṣani àti nínú àwọn ìlú rẹ̀, àti nínú gbogbo ìgbèríko Ṣaroni, ní agbègbè wọn.

17Gbogbo wọ̀nyí ni a kà nípa ìtàn ìdílé, ní ọjọ́ Jotamu ọba Juda, àti ní ọjọ́ Jeroboamu ọba Israẹli.

18Àwọn ọmọ Reubeni, àti àwọn ọmọ Gadi, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase, nínú àwọn ọkùnrin alágbára tí wọ́n ń gbé asà àti idà, tí wọ́n sì ń fi ọrun tafà, tí wọ́n sì mòye ogun, jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹgbẹ̀rìnlélógún dín ogójì (47,760) ènìyàn, tí ó jáde lọ sí ogún náà. 19Wọ́n sì bá àwọn ọmọ Hagari jagun, pẹ̀lú Jeturi, àti Nafiṣi àti Nadabu. 20Nígbà tí wọ́n sì rí ìrànlọ́wọ́ gbà si, a sì fi àwọn ọmọ Hagari lé wọn lọ́wọ́, àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn; nítorí tiwọn ké pe Ọlọ́run ní ogun náà, òun sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn; nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lé e. 21Wọ́n sì kó ẹran ọ̀sìn wọn lọ; ìbákasẹ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (50,000) àti àgùntàn ọ̀kẹ́ méjìlá ó lé ẹgbàárùn-ún (250,000), àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì (2,000), àti ènìyàn ọ̀kẹ́ márùn-ún (100,000). 22Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ṣubú tí a pa, nítorí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ogun náà, wọ́n sì jókòó ní ipò wọn títí di ìgbà ìkólọ sí ìgbèkùn.

Ààbọ̀ Ẹ̀yà Manase

23Àwọn ọmọkùnrin ààbọ̀ ẹ̀yà Manase ń gbé ní ilẹ̀ náà: wọ́n bí sí i láti Baṣani títí dé Baali-Hermoni, àti Seniri àti títí dé òkè Hermoni.

24Wọ̀nyí sì ni àwọn olórí ilé àwọn baba wọn. Eferi, Iṣi, Elieli, Asrieli, Jeremiah, Hodafiah àti Jahdieli àwọn alágbára akọni ọkùnrin, ọkùnrin olókìkí, àti olórí ilé àwọn baba wọn. 25Wọ́n sì ṣẹ̀ sí Ọlọ́run àwọn baba wọn, wọ́n sì ṣe àgbèrè tọ àwọn ọlọ́run ènìyàn ilẹ̀ náà lẹ́yìn, tí Ọlọ́run ti parun ní iwájú wọn. 26Nítorí náà Ọlọ́run Israẹli ru ẹ̀mí Pulu ọba Asiria sókè (èyí ni Tiglat-Pileseri ọba Asiria), ó si kó wọn lọ, àní àwọn ọmọ Reubeni àti àwọn ọmọ Gadi, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase lọ sí ìgbèkùn. Ó sì kó wọn wá sí Hala, àti Habori, àti Harani, àti sí etí odò Gosani; títí dí òní yìí.