New International Version

Romans 12:1-21

A Living Sacrifice

1Therefore, I urge you, brothers and sisters, in view of God’s mercy, to offer your bodies as a living sacrifice, holy and pleasing to God—this is your true and proper worship. 2Do not conform to the pattern of this world, but be transformed by the renewing of your mind. Then you will be able to test and approve what God’s will is—his good, pleasing and perfect will.

Humble Service in the Body of Christ

3For by the grace given me I say to every one of you: Do not think of yourself more highly than you ought, but rather think of yourself with sober judgment, in accordance with the faith God has distributed to each of you. 4For just as each of us has one body with many members, and these members do not all have the same function, 5so in Christ we, though many, form one body, and each member belongs to all the others. 6We have different gifts, according to the grace given to each of us. If your gift is prophesying, then prophesy in accordance with your12:6 Or the faith; 7if it is serving, then serve; if it is teaching, then teach; 8if it is to encourage, then give encouragement; if it is giving, then give generously; if it is to lead,12:8 Or to provide for others do it diligently; if it is to show mercy, do it cheerfully.

Love in Action

9Love must be sincere. Hate what is evil; cling to what is good. 10Be devoted to one another in love. Honor one another above yourselves. 11Never be lacking in zeal, but keep your spiritual fervor, serving the Lord. 12Be joyful in hope, patient in affliction, faithful in prayer. 13Share with the Lord’s people who are in need. Practice hospitality.

14Bless those who persecute you; bless and do not curse. 15Rejoice with those who rejoice; mourn with those who mourn. 16Live in harmony with one another. Do not be proud, but be willing to associate with people of low position.12:16 Or willing to do menial work Do not be conceited.

17Do not repay anyone evil for evil. Be careful to do what is right in the eyes of everyone. 18If it is possible, as far as it depends on you, live at peace with everyone. 19Do not take revenge, my dear friends, but leave room for God’s wrath, for it is written: “It is mine to avenge; I will repay,”12:19 Deut. 32:35 says the Lord. 20On the contrary:

“If your enemy is hungry, feed him;

if he is thirsty, give him something to drink.

In doing this, you will heap burning coals on his head.”12:20 Prov. 25:21,22

21Do not be overcome by evil, but overcome evil with good.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Romu 12:1-21

Ẹbọ ààyè mímọ́

112.1: Ro 6.13,16,19; 1Pt 2.5.Nítorí náà mo fi ìyọ́nú Ọlọ́run bẹ̀ yín ará, kí ẹ̀yin kí ó fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè mímọ́, ìtẹ́wọ́gbà, èyí ni iṣẹ́ ìsìn yín tí ó tọ̀nà. 212.2: 1Jh 2.15; Ef 4.23; 5.10.Kí ẹ má sì da ara yín pọ̀ mọ́ ayé yìí; ṣùgbọ́n kí ẹ paradà láti di tuntun ní èrò inú yín, kí ẹ̀yin kí ó lè rí ìdí ìfẹ́ Ọlọ́run, tí ó dára, tí ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà, ti ó sì pé.

Ìsìn ìrẹ̀lẹ̀ nínú Kristi

3Ǹjẹ́ mo wí fún olúkúlùkù ènìyàn tí ó wà nínú yín, nípa oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún mi, kí ó má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ; ṣùgbọ́n kí ó le rò níwọ́ntún-wọ́nsì, bí Ọlọ́run ti fi ìwọ̀n ìgbàgbọ́ fún olúkúlùkù. 412.4: 1Kọ 12.12-14; Ef 4.4,16.Nítorí gẹ́gẹ́ bí àwa ti ní ẹ̀yà púpọ̀ nínú ara kan, tí gbogbo ẹ̀yà kò sì ní iṣẹ́ kan náà: 512.5: 1Kọ 10.17; 12.20,27; Ef 4.25.Bẹ́ẹ̀ ni àwa, tí a jẹ́ púpọ̀, a jẹ́ ara kan nínú Kristi, àti olúkúlùkù ẹ̀yà ara ọmọnìkejì rẹ̀. 612.6-8: 1Kọ 7.7; 12.4-11; 1Pt 4.10-11.Ǹjẹ́ bí àwa sì ti ń rí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ẹ̀bùn gbà gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún wa, bí ó ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ ni, kí a máa sọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ìgbàgbọ́; 7Tàbí iṣẹ́ ìránṣẹ́, kí a kọjú sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa tàbí ẹni tí ń kọ́ni, kí ó kọjú sí kíkọ́. 8Tàbí ẹni tí ó ń gbani níyànjú, sí ìgbìyànjú; ẹni tí ń fi fún ni kí ó máa fi inú kan ṣe é; ẹni tí ń ṣe olórí, kí ó máa ṣe é ní ojú méjèèjì; ẹni tí ń ṣàánú, kí ó máa fi inú dídùn ṣe é.

Ẹ̀kọ́ nípa ìfẹ́

9Kí ìfẹ́ kí ó wà ní àìṣẹ̀tàn. Ẹ máa takété sí ohun tí í ṣe búburú; ẹ fi ara mọ́ ohun tí í ṣe rere. 10Ní ti ìfẹ́ ará, ẹ máa fi ìyọ́nú fẹ́ràn ara yín; ní ti ọlá, ẹ máa fi ẹnìkejì yín ṣáájú. 11Ní ti iṣẹ́ ṣíṣe, ẹ má ṣe ọ̀lẹ; ẹ máa ní ìgbóná ọkàn; ẹ máa sìn Olúwa. 1212.12: Ap 1.14; Ro 5.2; 1Tẹ 5.17.Ẹ máa yọ̀ ni ìrètí; ẹ máa mú sùúrù nínú ìpọ́njú; ẹ máa dúró gbọingbọin nínú àdúrà. 13Ẹ máa pèsè fún àìní àwọn ènìyàn mímọ́; ẹ fi ara yín fún àlejò ṣíṣe.

1412.14: Mt 5.44; Lk 6.28.Ẹ máa súre fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín; ẹ máa súre, ẹ má sì ṣépè. 15Àwọn tí ń yọ̀, ẹ máa bá wọn yọ̀, àwọn tí ń sọkún, ẹ máa bá wọn sọkún. 1612.16: Ro 11.25; 15.5; 1Kọ 1.10; 2Kọ 13.11; Fp 2.2; 4.2; Òw 3.7; 26.12.Ẹ máa wà ní inú kan náà sí ara yín. Ẹ má ṣe gbéraga, ṣùgbọ́n ẹ má tẹ̀lé àwọn onírẹ̀lẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ojú ara yín.

1712.17: Òw 20.22; 2Kọ 8.21; 1Tẹ 5.15.Ẹ má ṣe fi búburú san búburú fún ẹnikẹ́ni. Ẹ má pèsè ohun tí ó tọ́ níwájú gbogbo ènìyàn. 1812.18: Mk 9.50; Ro 14.19.Bí ó bá sé é ṣe, bí ó ti wà ní ipa tiyín, ẹ má wà ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn. 1912.19: Le 19.18; De 32.35; Hb 10.30.Olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n, ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ṣùgbọ́n ẹ fi ààyè sílẹ̀ fún ìbínú Ọlọ́run; nítorí a ti kọ ọ́ pé, Olúwa wí pé, “Tèmi ni ẹ̀san, èmi ó gbẹ̀san.” 2012.20: Òw 25.21-22; Mt 5.44; Lk 6.27.Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀,

“Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ;

bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mu.

Ní ṣíṣe èyí, ìwọ ó kó ẹ̀yín iná lé e ní orí.”

21Má ṣe jẹ́ kí búburú ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n fi rere ṣẹ́gun búburú.