New International Version

Matthew 22:1-46

The Parable of the Wedding Banquet

1Jesus spoke to them again in parables, saying: 2“The kingdom of heaven is like a king who prepared a wedding banquet for his son. 3He sent his servants to those who had been invited to the banquet to tell them to come, but they refused to come.

4“Then he sent some more servants and said, ‘Tell those who have been invited that I have prepared my dinner: My oxen and fattened cattle have been butchered, and everything is ready. Come to the wedding banquet.’

5“But they paid no attention and went off—one to his field, another to his business. 6The rest seized his servants, mistreated them and killed them. 7The king was enraged. He sent his army and destroyed those murderers and burned their city.

8“Then he said to his servants, ‘The wedding banquet is ready, but those I invited did not deserve to come. 9So go to the street corners and invite to the banquet anyone you find.’ 10So the servants went out into the streets and gathered all the people they could find, the bad as well as the good, and the wedding hall was filled with guests.

11“But when the king came in to see the guests, he noticed a man there who was not wearing wedding clothes. 12He asked, ‘How did you get in here without wedding clothes, friend?’ The man was speechless.

13“Then the king told the attendants, ‘Tie him hand and foot, and throw him outside, into the darkness, where there will be weeping and gnashing of teeth.’

14“For many are invited, but few are chosen.”

Paying the Imperial Tax to Caesar

15Then the Pharisees went out and laid plans to trap him in his words. 16They sent their disciples to him along with the Herodians. “Teacher,” they said, “we know that you are a man of integrity and that you teach the way of God in accordance with the truth. You aren’t swayed by others, because you pay no attention to who they are. 17Tell us then, what is your opinion? Is it right to pay the imperial tax22:17 A special tax levied on subject peoples, not on Roman citizens to Caesar or not?”

18But Jesus, knowing their evil intent, said, “You hypocrites, why are you trying to trap me? 19Show me the coin used for paying the tax.” They brought him a denarius, 20and he asked them, “Whose image is this? And whose inscription?”

21“Caesar’s,” they replied.

Then he said to them, “So give back to Caesar what is Caesar’s, and to God what is God’s.”

22When they heard this, they were amazed. So they left him and went away.

Marriage at the Resurrection

23That same day the Sadducees, who say there is no resurrection, came to him with a question. 24“Teacher,” they said, “Moses told us that if a man dies without having children, his brother must marry the widow and raise up offspring for him. 25Now there were seven brothers among us. The first one married and died, and since he had no children, he left his wife to his brother. 26The same thing happened to the second and third brother, right on down to the seventh. 27Finally, the woman died. 28Now then, at the resurrection, whose wife will she be of the seven, since all of them were married to her?”

29Jesus replied, “You are in error because you do not know the Scriptures or the power of God. 30At the resurrection people will neither marry nor be given in marriage; they will be like the angels in heaven. 31But about the resurrection of the dead—have you not read what God said to you, 32‘I am the God of Abraham, the God of Isaac, and the God of Jacob’22:32 Exodus 3:6? He is not the God of the dead but of the living.”

33When the crowds heard this, they were astonished at his teaching.

The Greatest Commandment

34Hearing that Jesus had silenced the Sadducees, the Pharisees got together. 35One of them, an expert in the law, tested him with this question: 36“Teacher, which is the greatest commandment in the Law?”

37Jesus replied: “ ‘Love the Lord your God with all your heart and with all your soul and with all your mind.’22:37 Deut. 6:5 38This is the first and greatest commandment. 39And the second is like it: ‘Love your neighbor as yourself.’22:39 Lev. 19:18 40All the Law and the Prophets hang on these two commandments.”

Whose Son Is the Messiah?

41While the Pharisees were gathered together, Jesus asked them, 42“What do you think about the Messiah? Whose son is he?”

“The son of David,” they replied.

43He said to them, “How is it then that David, speaking by the Spirit, calls him ‘Lord’? For he says,

44“ ‘The Lord said to my Lord:

“Sit at my right hand

until I put your enemies

under your feet.” ’22:44 Psalm 110:1

45If then David calls him ‘Lord,’ how can he be his son?” 46No one could say a word in reply, and from that day on no one dared to ask him any more questions.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Matiu 22:1-46

Òwe àsè ìgbéyàwó

122.1-10: Lk 14.16-24.Jesu tún fi òwe sọ̀rọ̀ fún wọn wí pé: 2“Ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan ti ó múra àsè ìgbéyàwó ńlá fún ọmọ rẹ̀ ọkùnrin. 3Ó rán àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ lọ pe àwọn tí a ti pè tẹ́lẹ̀ sí ibi àsè ìgbéyàwó. Ṣùgbọ́n wọn kò fẹ́ wá.

4“Lẹ́yìn náà ó tún rán àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ mìíràn pé, ‘Ẹ sọ fún àwọn tí mo ti pè wí pé, mo ti ṣe àsè náà tán. A pa màlúù àti ẹran àbọ́pa mi, a ti ṣe ohun gbogbo tán, ẹ wa sí ibi àsè ìgbéyàwó.’

5“Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀n-ọn-nì tí ó ránṣẹ́ lọ pè kò kà á si. Wọ́n ń bá iṣẹ́ wọn lọ, ọ̀kan sí ọ̀nà oko rẹ̀, òmíràn sí ibi òwò rẹ̀.” 6Àwọn ìyókù sì mú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ṣe àbùkù sí wọn, wọ́n lù wọ́n pa. 7Ọba yìí bínú gidigidi, ó sì rán àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, ó sì pa àwọn apànìyàn náà run, ó sì jó ìlú wọn.

8“Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, ‘Àsè ìgbéyàwó ti ṣe tàn, ṣùgbọ́n àwọn tí a pè kò yẹ fún ọlá náà. 9Ẹ lọ sí ìgboro àti òpópónà kí ẹ sì pe ẹnikẹ́ni tí ẹ bá lè rí wá àsè ìgbéyàwó náà.’ 10Nítorí náà, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì jáde lọ sí òpópónà. Wọ́n sì mú oríṣìíríṣìí ènìyàn tí wọ́n lè rí wá, àwọn tí ò dára àti àwọn tí kò dára, ilé àsè ìyàwó sì kún fún àlejò.

11“Ṣùgbọ́n nígbà tí ọba sì wọlé wá láti wo àwọn àlejò tí a pè, ó sì rí ọkùnrin kan nínú wọn tí kò wọ aṣọ ìgbéyàwó. 12Ọba sì bi í pé, ‘Ọ̀rẹ́, báwo ni ìwọ ṣe wà níhìn-ín yìí láìní aṣọ ìgbéyàwó?’ Ṣùgbọ́n ọkùnrin náà kò ní ìdáhùn kankan.

1322.13: Mt 8.12; 13.42,50; 24.51; 25.30; Lk 13.28.“Nígbà náà ni ọba wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ẹ dì í tọwọ́ tẹsẹ̀, kí ẹ sì sọ ọ́ sínú òkùnkùn lóde níbi tí ẹkún àti ìpayínkeke wà.’

14“Nítorí ọ̀pọ̀ ni a pè ṣùgbọ́n díẹ̀ ni a yàn.”

Sísan owó orí fún Kesari

1522.15-22: Mk 12.13-17; Lk 20.20-26.22.15: Mk 3.6; 8.15.Nígbà náà ni àwọn Farisi péjọpọ̀ láti ronú ọ̀nà tì wọn yóò gbà fi ọ̀rọ̀ ẹnu mú un. 16Wọ́n sì rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Herodu lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Olùkọ́, àwa mọ̀ pé olóòtítọ́ ni ìwọ, ìwọ sì ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run ní òtítọ́. Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì í wo ojú ẹnikẹ́ni; nítorí tí ìwọ kì í ṣe ojúsàájú ènìyàn. 17Nísinsin yìí sọ fún wa, kí ni èrò rẹ? Ǹjẹ́ ó tọ́ láti san owó orí fún Kesari tàbí kò tọ́?”

18Ṣùgbọ́n Jesu ti mọ èrò búburú inú wọn, ó wí pé, “Ẹ̀yin àgàbàgebè, èéṣe ti ẹ̀yin fi ń dán mi wò? 19Ẹ fi owó ẹyọ tí a fi ń san owó orí kan hàn mi.” Wọn mú dínárì kan wá fún un, 20ó sì bi wọ́n pé, “Àwòrán ta ni èyí? Àkọlé tà sì ní?”

2122.21: Ro 13.7.Wọ́n sì dáhùn pé, “Ti Kesari ni.”

“Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé,” “Ẹ fi èyí tí í ṣe ti Kesari fún Kesari, ẹ sì fi èyí ti ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”

22Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ẹnu yà wọ́n. Wọ́n fi í sílẹ̀, wọ́n sì bá tiwọn lọ.

Ìgbéyàwó nígbà àjíǹde

2322.23-33: Mk 12.18-27; Lk 20.27-38.22.23: Ap 4.1-2; 23.6-10.Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kan náà, àwọn Sadusi tí wọ́n sọ pé kò si àjíǹde lẹ́yìn ikú tọ Jesu wá láti bi í ní ìbéèrè, 2422.24: De 25.5.Wọ́n wí pé, “Olùkọ́, Mose wí fún wa pé, bí ọkùnrin kan bá kú ní àìlọ́mọ, kí arákùnrin rẹ̀ ṣú aya rẹ̀ lópó, kí ó sì bí ọmọ fún un. 25Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, láàrín wa níhìn-ín yìí, ìdílé kan wà tí ó ní arákùnrin méje. Èyí èkínní nínú wọn gbéyàwó, lẹ́yìn náà ó kú ní àìlọ́mọ. Nítorí náà ìyàwó rẹ̀ di ìyàwó arákùnrin kejì. 26Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ arákùnrin èkejì náà sì tún kú láìlọ́mọ. A sì fi ìyàwó rẹ̀ fún arákùnrin tí ó tún tẹ̀lé e. Bẹ́ẹ̀ sì ni títí tí òun fi di ìyàwó ẹni keje. 27Níkẹyìn obìnrin náà pàápàá sì kú. 28Nítorí tí ó ti ṣe ìyàwó àwọn arákùnrin méjèèje, ìyàwó ta ni yóò jẹ́ ní àjíǹde òkú?”

29Ṣùgbọ́n Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àìmọ̀kan yín ni ó fa irú ìbéèrè báyìí. Nítorí ẹ̀yin kò mọ ìwé Mímọ́ àti agbára Ọlọ́run. 30Nítorí ní àjíǹde kò ní sí ìgbéyàwó, a kò sì ní fi í fún ni ní ìyàwó. Gbogbo ènìyàn yóò sì dàbí àwọn angẹli ní ọ̀run. 31Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nípa ti àjíǹde òkú, tàbí ẹ̀yin kò mọ̀ pé Ọlọ́run ń bá yín sọ̀rọ̀ nígbà ti ó wí pé: 32‘Èmi ni Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu.’ Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run òkú, ṣùgbọ́n tí àwọn alààyè.”

3322.33: Mt 7.28.Nígbà ti àwọn ènìyàn gbọ́ èyí ẹnu yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ.

Òfin tí ó ga jùlọ

3422.34-40: Mk 12.28-34; Lk 20.39-40; 10.25-28.Nígbà ti wọ́n sì gbọ́ pé ó ti pa àwọn Sadusi lẹ́nu mọ́, àwọn Farisi pé ara wọn jọ. 3522.35: Lk 7.30; 11.45; 14.3.Ọ̀kan nínú wọn tí ṣe amòfin dán an wò pẹ̀lú ìbéèrè yìí. 36Ó wí pé, “Olùkọ́ èwo ni ó ga jùlọ nínú àwọn òfin?”

3722.37: De 6.5.Jesu dáhùn pé, “ ‘Fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, gbogbo ẹ̀mí rẹ àti gbogbo inú rẹ.38Èyí ni òfin àkọ́kọ́ àti èyí tí ó tóbi jùlọ. 39Èkejì tí ó tún dàbí rẹ̀ ní pé, ‘Fẹ́ràn ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’ 40Lórí àwọn òfin méjèèjì yìí ni gbogbo òfin àti àwọn wòlíì rọ̀ mọ́.”

Ọmọ ta ni Kristi?

4122.41-46: Mk 12.35-37; Lk 20.41-44.Bí àwọn Farisi ti kó ara wọn jọ, Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, 42“Kí ni ẹ rò nípa Kristi? Ọmọ ta ni òun ń ṣe?”

Wọ́n dáhùn pé, “Ọmọ Dafidi.”

43Ó sì wí fún wọn pé, “Kí lo dé tí Dafidi, tí ẹ̀mí ń darí, pè é ní ‘Olúwa’? Nítorí ó wí pé,

44“ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé,

“Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi

títí tí èmi yóò fi fi àwọn ọ̀tá rẹ

sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ.” ’

45Ǹjẹ́ bí Dafidi bá pè é ni ‘Olúwa,’ báwo ni òun ṣe lè jẹ́ ọmọ rẹ̀?” 4622.46: Mk 12.34; Lk 20.40.Kò sí ẹnìkan tí ó lè sọ ọ̀rọ̀ kan ni ìdáhùn, kò tún sí ẹni tí ó tún bí i léèrè ohun kan mọ́ láti ọjọ́ náà mọ́.