Leviticus 18 – NIV & YCB

New International Version

Leviticus 18:1-30

Unlawful Sexual Relations

1The Lord said to Moses, 2“Speak to the Israelites and say to them: ‘I am the Lord your God. 3You must not do as they do in Egypt, where you used to live, and you must not do as they do in the land of Canaan, where I am bringing you. Do not follow their practices. 4You must obey my laws and be careful to follow my decrees. I am the Lord your God. 5Keep my decrees and laws, for the person who obeys them will live by them. I am the Lord.

6“ ‘No one is to approach any close relative to have sexual relations. I am the Lord.

7“ ‘Do not dishonor your father by having sexual relations with your mother. She is your mother; do not have relations with her.

8“ ‘Do not have sexual relations with your father’s wife; that would dishonor your father.

9“ ‘Do not have sexual relations with your sister, either your father’s daughter or your mother’s daughter, whether she was born in the same home or elsewhere.

10“ ‘Do not have sexual relations with your son’s daughter or your daughter’s daughter; that would dishonor you.

11“ ‘Do not have sexual relations with the daughter of your father’s wife, born to your father; she is your sister.

12“ ‘Do not have sexual relations with your father’s sister; she is your father’s close relative.

13“ ‘Do not have sexual relations with your mother’s sister, because she is your mother’s close relative.

14“ ‘Do not dishonor your father’s brother by approaching his wife to have sexual relations; she is your aunt.

15“ ‘Do not have sexual relations with your daughter-in-law. She is your son’s wife; do not have relations with her.

16“ ‘Do not have sexual relations with your brother’s wife; that would dishonor your brother.

17“ ‘Do not have sexual relations with both a woman and her daughter. Do not have sexual relations with either her son’s daughter or her daughter’s daughter; they are her close relatives. That is wickedness.

18“ ‘Do not take your wife’s sister as a rival wife and have sexual relations with her while your wife is living.

19“ ‘Do not approach a woman to have sexual relations during the uncleanness of her monthly period.

20“ ‘Do not have sexual relations with your neighbor’s wife and defile yourself with her.

21“ ‘Do not give any of your children to be sacrificed to Molek, for you must not profane the name of your God. I am the Lord.

22“ ‘Do not have sexual relations with a man as one does with a woman; that is detestable.

23“ ‘Do not have sexual relations with an animal and defile yourself with it. A woman must not present herself to an animal to have sexual relations with it; that is a perversion.

24“ ‘Do not defile yourselves in any of these ways, because this is how the nations that I am going to drive out before you became defiled. 25Even the land was defiled; so I punished it for its sin, and the land vomited out its inhabitants. 26But you must keep my decrees and my laws. The native-born and the foreigners residing among you must not do any of these detestable things, 27for all these things were done by the people who lived in the land before you, and the land became defiled. 28And if you defile the land, it will vomit you out as it vomited out the nations that were before you.

29“ ‘Everyone who does any of these detestable things—such persons must be cut off from their people. 30Keep my requirements and do not follow any of the detestable customs that were practiced before you came and do not defile yourselves with them. I am the Lord your God.’ ”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Lefitiku 18:1-30

Ìbálòpọ̀ tí kò bá òfin mu

1Olúwa sọ fún Mose pé: 2“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé: ‘Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín. 3Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe bí wọ́n ti ń ṣe ní Ejibiti níbi tí ẹ ti gbé rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe bí wọ́n ti ń ṣe ní ilẹ̀ Kenaani níbi tí èmi ń mú yín lọ. Ẹ kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ìṣe wọn. 4Kí ẹ̀yin kí ó sì máa ṣe òfin mi, kí ẹ̀yin sì máa pa ìlànà mi mọ́, láti máa rìn nínú wọn, Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín. 518.5: Lk 10.28; Ro 10.5; Ga 3.12. Ẹ̀yin ó sì máa pa ìlànà mi mọ́ àti òfin mi; Ẹni tí ó ba ṣe, yóò yè nípa wọn. Èmi ni Olúwa.

6“ ‘Ẹnikẹ́ni nínú yín kò gbọdọ̀ súnmọ́ ìbátan rẹ̀ láti bá a lòpọ̀. Èmí ni Olúwa.

718.7: Le 20.11.“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ tàbùkù baba rẹ nípa bíbá ìyá rẹ lòpọ̀, ìyá rẹ̀ ni, ìwọ kò gbọdọ̀ bá a lòpọ̀.

8“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ tàbùkù baba rẹ nípa bíbá ìyàwó baba rẹ lòpọ̀, nítorí ìhòhò baba rẹ ni.

918.9,11: Le 20.17; De 27.22.“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá arábìnrin rẹ tí ó jẹ́ ọmọ ìyá rẹ lòpọ̀, yálà a bí i nílé yín tàbí lóde.

10“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọbìnrin, ọmọ rẹ ọkùnrin lòpọ̀ tàbí ọmọbìnrin ọmọ rẹ obìnrin lòpọ̀ nítorí pé ìhòhò wọn, ìhòhò ìwọ fúnra rẹ̀ ni.

11“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọbìnrin aya baba rẹ lòpọ̀; èyí tí a bí fún baba rẹ nítorí pé arábìnrin rẹ ni.

1218.12: Le 20.19.“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá arábìnrin baba rẹ lòpọ̀ nítorí pé ìbátan baba rẹ ni.

13“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá arábìnrin màmá rẹ lòpọ̀ nítorí pé ìbátan ìyá rẹ ni.

1418.14: Le 20.20.“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ tàbùkù arákùnrin baba rẹ nípa sísún mọ́ aya rẹ̀ láti bá a lòpọ̀ nítorí pé ìyàwó ẹ̀gbọ́n baba rẹ ni.

1518.15: Le 20.12.“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọ àna obìnrin rẹ lòpọ̀ nítorí pé aya ọmọ rẹ ni. Má ṣe bá a lòpọ̀.

1618.16: Le 20.21.“ ‘Má ṣe bá aya ẹ̀gbọ́n rẹ ọkùnrin lòpọ̀ nítorí pé yóò tàbùkù ẹ̀gbọ́n rẹ.

1718.17: Le 20.14.“ ‘Má ṣe bá ìyá àti ọmọ rẹ obìnrin lòpọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọbìnrin ọmọkùnrin rẹ tàbí ọmọbìnrin ọmọbìnrin rẹ lòpọ̀ nítorí pé ìbátan rẹ tímọ́tímọ́ ni: nítorí àbùkù ni.

18“ ‘Má ṣe fẹ́ àbúrò ìyàwó rẹ obìnrin ní aya gẹ́gẹ́ bí orogún tàbí bá a lòpọ̀, nígbà tí ìyàwó rẹ sì wà láààyè.

1918.19: Le 15.24; 20.18.“ ‘Má ṣe súnmọ́ obìnrin láti bá a lòpọ̀ nígbà tí ó bá ń ṣe nǹkan oṣù, nítorí àkókò àìmọ́ ni.

20“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá aya aládùúgbò rẹ lòpọ̀, kí ìwọ má ba à ba ara rẹ jẹ́ pẹ̀lú rẹ̀.

2118.21: Le 20.2-5.“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fi èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ rẹ rú ẹbọ lórí pẹpẹ sí òrìṣà Moleki, kí o sì tipa bẹ́ẹ̀ ba orúkọ Ọlọ́run rẹ jẹ́. Èmi ni Olúwa.

2218.22: Le 20.13; De 23.18.“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọkùnrin lòpọ̀ bí ìgbà tí ènìyàn ń bá obìnrin lòpọ̀: ìríra ni èyí jẹ́.

2318.23: Ek 22.19; Le 20.15,16; De 27.21.“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ẹranko lòpọ̀ kí ìwọ má ba à ba ara rẹ jẹ́. Obìnrin kò sì gbọdọ̀ jọ̀wọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ẹranko láti bá a lòpọ̀, ohun tó lòdì ni.

24“ ‘Má ṣe fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ba ara rẹ jẹ́, torí pé nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè tí mo lé kúrò níwájú yín ti ba ara wọn jẹ́. 25Nítorí pé ilẹ̀ náà di àìmọ́ nítorí náà mo fi ìyà jẹ ẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ilẹ̀ náà sì pọ àwọn olùgbé ibẹ̀ jáde. 26Ṣùgbọ́n kí ẹ máa pa àṣẹ àti òfin mi mọ́. Onílé tàbí àjèjì tó ń gbé láàrín yín kò gbọdọ̀ ṣe ọ̀kan nínú àwọn ohun ìríra wọ̀nyí. 27Nítorí pé gbogbo ohun ìríra wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn tí wọ́n ti gbé ilẹ̀ náà ṣáájú yín ti ṣe tí ó sì mú kí ilẹ̀ náà di aláìmọ́. 28Bí ẹ bá sọ ilẹ̀ náà di àìmọ́ yóò pọ̀ yín jáde bí ó ti pọ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ti wá ṣáájú yín jáde.

29“ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ohun ìríra wọ̀nyí, kí ẹ gé irú ẹni náà kúrò láàrín àwọn ènìyàn. 30Nítorí náà ẹ gbọdọ̀ ṣe ohun tí mo fẹ́, kí ẹ má sì lọ́wọ́ nínú àṣà ìríra wọ̀nyí, tí wọn ń ṣe kí ẹ tó dé. Ẹ má ṣe fi wọ́n ba ara yín jẹ́. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’ ”