Leviticus 10 – NIV & YCB

New International Version

Leviticus 10:1-20

The Death of Nadab and Abihu

1Aaron’s sons Nadab and Abihu took their censers, put fire in them and added incense; and they offered unauthorized fire before the Lord, contrary to his command. 2So fire came out from the presence of the Lord and consumed them, and they died before the Lord. 3Moses then said to Aaron, “This is what the Lord spoke of when he said:

“ ‘Among those who approach me

I will be proved holy;

in the sight of all the people

I will be honored.’ ”

Aaron remained silent.

4Moses summoned Mishael and Elzaphan, sons of Aaron’s uncle Uzziel, and said to them, “Come here; carry your cousins outside the camp, away from the front of the sanctuary.” 5So they came and carried them, still in their tunics, outside the camp, as Moses ordered.

6Then Moses said to Aaron and his sons Eleazar and Ithamar, “Do not let your hair become unkempt10:6 Or Do not uncover your heads and do not tear your clothes, or you will die and the Lord will be angry with the whole community. But your relatives, all the Israelites, may mourn for those the Lord has destroyed by fire. 7Do not leave the entrance to the tent of meeting or you will die, because the Lord’s anointing oil is on you.” So they did as Moses said.

8Then the Lord said to Aaron, 9“You and your sons are not to drink wine or other fermented drink whenever you go into the tent of meeting, or you will die. This is a lasting ordinance for the generations to come, 10so that you can distinguish between the holy and the common, between the unclean and the clean, 11and so you can teach the Israelites all the decrees the Lord has given them through Moses.”

12Moses said to Aaron and his remaining sons, Eleazar and Ithamar, “Take the grain offering left over from the food offerings prepared without yeast and presented to the Lord and eat it beside the altar, for it is most holy. 13Eat it in the sanctuary area, because it is your share and your sons’ share of the food offerings presented to the Lord; for so I have been commanded. 14But you and your sons and your daughters may eat the breast that was waved and the thigh that was presented. Eat them in a ceremonially clean place; they have been given to you and your children as your share of the Israelites’ fellowship offerings. 15The thigh that was presented and the breast that was waved must be brought with the fat portions of the food offerings, to be waved before the Lord as a wave offering. This will be the perpetual share for you and your children, as the Lord has commanded.”

16When Moses inquired about the goat of the sin offering10:16 Or purification offering; also in verses 17 and 19 and found that it had been burned up, he was angry with Eleazar and Ithamar, Aaron’s remaining sons, and asked, 17“Why didn’t you eat the sin offering in the sanctuary area? It is most holy; it was given to you to take away the guilt of the community by making atonement for them before the Lord. 18Since its blood was not taken into the Holy Place, you should have eaten the goat in the sanctuary area, as I commanded.”

19Aaron replied to Moses, “Today they sacrificed their sin offering and their burnt offering before the Lord, but such things as this have happened to me. Would the Lord have been pleased if I had eaten the sin offering today?” 20When Moses heard this, he was satisfied.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Lefitiku 10:1-20

Ikú Nadabu àti Abihu

1Nadabu àti Abihu tí í ṣe ọmọ Aaroni sì mú àwo tùràrí kọ̀ọ̀kan, wọ́n fi iná àti tùràrí sínú rẹ̀, wọ́n sì rú iná àjèjì níwájú Olúwa, èyí tó lòdì sí àṣẹ Olúwa. 2Torí èyí, iná jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ó sì jó wọn pa, wọ́n sì kú níwájú Olúwa. 3Mose sì sọ fún Aaroni pé, “Ohun tí Olúwa ń sọ nípa rẹ̀ nìyìí nígbà tó wí pé,

“ ‘Ní àárín àwọn tó súnmọ́ mi,

Èmi yóò fi ara mi hàn ní mímọ́

ojú gbogbo ènìyàn

Ní a ó ti bu ọlá fún mi.’ ”

Aaroni sì dákẹ́.

4Mose pe Miṣaeli àti Elsafani ọmọ Usieli tí í ṣe arákùnrin Aaroni, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ wá, kí ẹ sì gbé àwọn arákùnrin yín jáde kúrò níwájú ibi mímọ́ lọ sí ẹ̀yìn ibùdó.” 5Wọ́n sì wá gbé wọn, pẹ̀lú ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọn ní ọrùn wọn lọ sí ẹ̀yìn ibùdó bí Mose ti sọ.

6Mose sọ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù, Eleasari àti Itamari pé, “ẹ má ṣe ṣọ̀fọ̀ nípa ṣíṣe aláìtọ́jú irun yín tàbí kí ẹ ṣí orí yín sílẹ̀, ẹ kò sì gbọdọ̀ ya aṣọ, bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó kùú, Olúwa yóò sì bínú sí gbogbo ìjọ ènìyàn. Ṣùgbọ́n àwọn ẹbí yín, àti gbogbo ilé Israẹli le è ṣọ̀fọ̀ lórí àwọn tí Olúwa fi iná parun. 7Ẹ má ṣe kúrò ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, bí ẹ bá kúrò níbẹ̀, ẹ ó kù ú, nítorí pé òróró ìtasórí Olúwa wà lórí yín.” Wọ́n sì ṣe bí Mose ti wí.

810.8: El 44.21.Olúwa sì sọ fún Aaroni pé. 9“Ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ̀ kò gbọdọ̀ mu ọtí wáìnì tàbí ọtí líle mìíràn nígbàkígbà tí ẹ bá n lọ inú àgọ́ ìpàdé, bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó kù ú, èyí jẹ́ ìlànà títí láé fún un yín láti ìrandíran. 10Ẹ gbọdọ̀ mọ ìyàtọ̀ láàrín mímọ́ àti àìmọ́, láàrín èérí àti àìléèérí. 11Ẹ gbọdọ̀ kọ́ àwọn ara Israẹli ní gbogbo àṣẹ tí Olúwa fún wọn láti ẹnu Mose.”

1210.12,13: Le 6.14-18.Mose sì sọ fún Aaroni, Eleasari àti Itamari àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù pé, “Ẹ mú ẹbọ ohun jíjẹ tó ṣẹ́kù láti inú ẹbọ àfinásun sí Olúwa, kí ẹ jẹ ẹ́ láìní ìwúkàrà nínú, lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ nítorí ó jẹ́ mímọ́ jùlọ. 13Ẹ jẹ́ ní ibi mímọ́, nítorí pé òun ni ìpín rẹ àti ti àwọn ọmọ rẹ nínú ẹbọ tí a finá sun sí Olúwa nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe pa á láṣẹ. 1410.14,15: Le 7.30-34.Ṣùgbọ́n ìwọ àti àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin rẹ le jẹ igẹ̀ ẹran tí a fì níwájú Olúwa àti itan tí wọ́n gbé síwájú Olúwa, kí ẹ jẹ wọ́n ní ibi tí a kà sí mímọ́, èyí ni a ti fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpín yín nínú ẹbọ àlàáfíà àwọn ara Israẹli. 15Itan tí wọ́n mú wá àti igẹ̀ ẹran tí ẹ fì ni ẹ gbọdọ̀ mú wá pẹ̀lú ọ̀rá ẹbọ tí a finá sun láti le è fì wọ́n níwájú Olúwa bí ẹbọ fífì. Èyí yóò sì jẹ́ ìpín tìrẹ àti ti àwọn ọmọ rẹ nígbà gbogbo bí Olúwa ṣe pàṣẹ.”

16Nígbà tí Mose wádìí nípa ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tó sì rí i pé wọ́n ti sun ún, ó bínú sí Eleasari àti Itamari, àwọn ọmọ Aaroni yòókù, ó sì béèrè pé, 1710.17: Le 6.24-26.“Èéṣe tí ẹ kò jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà ní agbègbè ibi mímọ́? Ó jẹ́ mímọ́ jùlọ, a fi fún yín láti lè mú ẹ̀ṣẹ̀ ìjọ ènìyàn kúrò nípa fífi ṣe ètùtù fún wọn níwájú Olúwa. 18Níwọ́n ìgbà tí ẹ kò mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sí Ibi Mímọ́, ẹ̀ bá ti jẹ ewúrẹ́ náà ní agbègbè Ibi Mímọ́ bí mo ṣe pa á láṣẹ.”

19Aaroni sì dá Mose lóhùn pé, “Lónìí tí wọ́n rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ sísun wọn níwájú Olúwa ni irú èyí tún ṣẹlẹ̀ sí mi. Ǹjẹ́ inú Olúwa yóò wá dùn bí mo bá jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ lónìí?” 20Nígbà tí Mose gbọ́ èyí, ọkàn rẹ̀ balẹ̀.