2 Thessalonians 1 – NIV & YCB

New International Version

2 Thessalonians 1:1-12

1Paul, Silas1:1 Greek Silvanus, a variant of Silas and Timothy,

To the church of the Thessalonians in God our Father and the Lord Jesus Christ:

2Grace and peace to you from God the Father and the Lord Jesus Christ.

Thanksgiving and Prayer

3We ought always to thank God for you, brothers and sisters,1:3 The Greek word for brothers and sisters (adelphoi) refers here to believers, both men and women, as part of God’s family; also in 2:1, 13, 15; 3:1, 6, 13. and rightly so, because your faith is growing more and more, and the love all of you have for one another is increasing. 4Therefore, among God’s churches we boast about your perseverance and faith in all the persecutions and trials you are enduring.

5All this is evidence that God’s judgment is right, and as a result you will be counted worthy of the kingdom of God, for which you are suffering. 6God is just: He will pay back trouble to those who trouble you 7and give relief to you who are troubled, and to us as well. This will happen when the Lord Jesus is revealed from heaven in blazing fire with his powerful angels. 8He will punish those who do not know God and do not obey the gospel of our Lord Jesus. 9They will be punished with everlasting destruction and shut out from the presence of the Lord and from the glory of his might 10on the day he comes to be glorified in his holy people and to be marveled at among all those who have believed. This includes you, because you believed our testimony to you.

11With this in mind, we constantly pray for you, that our God may make you worthy of his calling, and that by his power he may bring to fruition your every desire for goodness and your every deed prompted by faith. 12We pray this so that the name of our Lord Jesus may be glorified in you, and you in him, according to the grace of our God and the Lord Jesus Christ.1:12 Or God and Lord, Jesus Christ

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Tẹsalonika 1:1-12

11.1: 1Tẹ 1.1; 2Kọ 1.19; Ap 16.1.Paulu, Sila àti Timotiu,

Sí ìjọ Tẹsalonika, nínú Ọlọ́run Baba wa àti Jesu Kristi Olúwa:

21.2: Ro 1.7.Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba àti Jesu Kristi Olúwa.

Ìdúpẹ́ àti àdúrà

31.3: 1Tẹ 1.2.Ó yẹ kí a máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo nítorí yín, ará, àní gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ, nítorí pé ìgbàgbọ́ yín ń dàgbà gidigidi, àti ìfẹ́ olúkúlùkù yín sí ara yín ń di púpọ̀. 4Nítorí náà, àwa tìkára wa ń fi yín ṣògo nínú ìjọ Ọlọ́run, nítorí sùúrù àti ìgbàgbọ́ yín nínú gbogbo inúnibíni àti wàhálà yín tí ẹ̀yin náà ń fi ara dà.

5Àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ẹ̀rí pé òdodo ni ìdájọ́ Ọlọ́run àti pé nítorí èyí ni a ó kà yín yẹ fún ìjọba Ọlọ́run, nítorí èyí tí ẹ̀yin pẹ̀lú ṣe ń jìyà. 6Olódodo ni Ọlọ́run: Òun yóò pọ́n àwọn tí ń pọ́n yín lójú, lójú, 7Òun yóò sì fi ìtura fún ẹ̀yin tí a ti pọ́n lójú àti fún àwa náà pẹ̀lú. Èyí yóò sì ṣe nígbà ìfarahàn Jesu Olúwa láti ọ̀run wá fún wá nínú ọwọ́ iná pẹ̀lú àwọn angẹli alágbára. 81.8: Ga 4.8.Òun yóò fi ìyà jẹ àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí ń ṣe àìgbọ́ràn sí ìyìnrere Jesu Olúwa wa. 9A ó fi ìparun àìnípẹ̀kun jẹ wọ́n ní yà, a ó sì ṣe wọn mọ̀ kúrò níwájú Olúwa àti inú ògo agbára rẹ̀, 10ní ọjọ́ tí yóò jẹ́ ẹni tí a ó yìn lógo nínú àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ àti ẹni àwòyanu ní àárín gbogbo àwọn tí ó ti gbàgbọ́. Èyí kò yọ yín sílẹ̀, nítorí ẹ ti gba ẹ̀rí tí a jẹ́ sí yín gbọ́.

111.11: 1Tẹ 1.3.Nítorí èyí, àwa pẹ̀lú ń gbàdúrà fún un yín nígbà gbogbo, pé kí Ọlọ́run wa kí ó lè kà yín yẹ fún ìpè rẹ̀, àti pé nípa agbára rẹ̀, òun yóò mú gbogbo èrò rere yín ṣẹ àti gbogbo ohun tí ìgbàgbọ́ bá rú jáde. 12Wọ̀nyí ni àdúrà wa, kí orúkọ Jesu Olúwa wa lè di yíyìn lógo nínú yín àti ẹ̀yin nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run àti ti Jesu Kristi Olúwa.