Yohana 1 – NEN & YCB

Kiswahili Contemporary Version (Neno: Bibilia Takatifu)

Yohana 1:1-51

Neno Alifanyika Mwili

11:1 1Yn 1:2; Yn 17:5; Flp 2:6; Isa 55:11Hapo mwanzo alikuwako Neno, huyo Neno alikuwa pamoja na Mungu, naye Neno alikuwa Mungu. 21:2 Ufu 1:8; Mwa 1:1Tangu mwanzo huyo Neno alikuwa pamoja na Mungu.

31:3 Kol 1:16; Ebr 1:2Vitu vyote viliumbwa kwa yeye, wala pasipo yeye hakuna chochote kilichoumbwa ambacho kimeumbwa. 41:4 1Yn 5:20; Ufu 1:8; Yn 12:46Ndani yake ndimo ulimokuwa uzima na huo uzima ulikuwa nuru ya watu. 51:5 Yn 3:19Nuru hungʼaa gizani nalo giza halikuishinda.

61:6 Mt 3:1Alikuja mtu mmoja aliyetumwa kutoka kwa Mungu, jina lake Yohana. 71:7 Yn 3:26; 5:33; 3:15Alikuja kama shahidi apate kuishuhudia hiyo nuru, ili kwa kupitia kwake watu wote waweze kuamini. 81:8 Yn 1:20Yeye mwenyewe hakuwa ile nuru, bali alikuja kuishuhudia hiyo nuru. 91:9 1Yn 2:8; Isa 49:6Kwamba nuru halisi, imwangaziayo kila mtu ilikuwa inakuja ulimwenguni.

101:10 Yn 1:3; Ebr 1:2; 11; 3Huyo Neno alikuwako ulimwenguni na ingawa ulimwengu uliumbwa kupitia kwake, haukumtambua. 111:11 Lk 19:14; Mdo 3:26; 13:46Alikuja kwa walio wake, lakini wao hawakumpokea. 121:12 Isa 56:5; Rum 8:15; Gal 3:26; 2Pet 1:4; 1Yn 3:1Bali wote waliompokea, aliwapa uwezo wa kufanyika watoto wa Mungu, ndio wale waliaminio jina lake. 131:13 Tit 3:5; Yak 1:18Hawa ndio wasiozaliwa kwa damu, wala kwa mapenzi ya mwili au kwa mapenzi ya mtu, bali kwa mapenzi ya Mungu.

141:14 1Yn 1:1-2; 4:2; Yn 14:6Neno alifanyika mwili, akakaa miongoni mwetu, nasi tukauona utukufu wake, utukufu kama wa Mwana pekee atokaye kwa Baba, amejaa neema na kweli.

151:15 Yn 1:32; 3:32; 5:33; Mt 3:11; Mk 1:7; Lk 3:16; Yn 1:27, 30; 3:31; 8:58; Kol 1:17Yohana alishuhudia habari zake, akapaza sauti, akisema, “Huyu ndiye yule niliyewaambia kwamba, ‘Yeye ajaye baada yangu ni mkuu kuniliko mimi, kwa kuwa alikuwepo kabla yangu.’ ” 161:16 Kol 1:19; 2:9Kutokana na ukamilifu wake, sisi sote tumepokea neema juu ya neema. 171:17 Kum 32:46Kwa kuwa sheria ilitolewa kwa mkono wa Mose, lakini neema na kweli imekuja kupitia Yesu Kristo. 18Hakuna mtu yeyote aliyemwona Mungu wakati wowote, ila ni Mungu Mwana pekee, aliye kifuani mwa Baba ndiye ambaye amemdhihirisha.

Ushuhuda Wa Yohana Mbatizaji

(Mathayo 3:1-12; Marko 1:1-8; Luka 3:1-18)

191:19 Yn 7:1; 10:24Huu ndio ushuhuda wa Yohana wakati Wayahudi walipowatuma makuhani na Walawi kutoka Yerusalemu kumuuliza, “Wewe ni nani?” 201:20 Yn 3:28; Lk 3:15-16Yohana alikiri waziwazi pasipo kuficha akasema, “Mimi si Kristo.”1:20 Kristo maana yake ni Masiya, yaani Aliyetiwa mafuta.

211:21 Kum 18:15; Mt 11:4Wakamuuliza, “Wewe ni nani basi? Je, wewe ni Eliya?”

Yeye akajibu, “Hapana, mimi siye.”

“Je, wewe ni yule Nabii?”

Akajibu, “Hapana.”

22Ndipo wakasema, “Basi tuambie wewe ni nani ili tupate jibu la kuwapelekea wale waliotutuma. Wewe wasemaje juu yako mwenyewe?”

231:23 Mt 3:1; Isa 40:3Akawajibu kwa maneno ya nabii Isaya, akisema, “Mimi ni sauti ya mtu aliaye nyikani, ‘Yanyoosheni mapito ya Bwana.’ ”

24Basi walikuwa wametumwa watu kutoka kwa Mafarisayo 251:25 Mt 21:25wakamuuliza, “Kama wewe si Kristo, wala si Eliya na wala si yule Nabii, kwa nini basi unabatiza?”

261:26 Mt 3:11; Mk 1:7, 8Yohana akawajibu, “Mimi ninabatiza kwa maji,1:26 Hapa tafsiri zingine zinasema ndani ya maji. lakini katikati yenu yupo mtu msiyemjua. 271:27 Yn 3:26; Mdo 13:25Yeye ajaye baada yangu, sistahili hata kufungua kamba za viatu vyake.”

281:28 Yn 3:26; 10:40Mambo haya yote yalitukia huko Bethania, ngʼambo ya Mto Yordani, mahali Yohana alipokuwa akibatiza.

Yesu Mwana-Kondoo Wa Mungu

291:29 Mwa 22:8; Ufu 5:6Siku iliyofuata, Yohana alimwona Yesu akimjia akasema, “Tazama, Mwana-Kondoo wa Mungu aichukuaye dhambi ya ulimwengu! 301:30 Yn 15:27Huyu ndiye yule niliyewaambia kwamba, ‘Mtu anakuja baada yangu ambaye ni mkuu kuniliko mimi, kwa kuwa alikuwepo kabla yangu.’ 311:31 Mal 3:1; Mt 3:6; Lk 1:17, 76, 77; 3:3, 4Mimi mwenyewe sikumfahamu, lakini sababu ya kuja nikibatiza kwa maji ni ili yeye apate kufunuliwa kwa Israeli.”

321:32 Mt 3:16; Mk 1:10Kisha Yohana akatoa ushuhuda huu: “Nilimwona Roho akishuka kutoka mbinguni kama hua, akakaa juu yake. 331:33 Mk 1:4; Mt 3:11Mimi nisingemtambua, lakini yeye aliyenituma nibatize kwa maji alikuwa ameniambia, ‘Yule mtu utakayemwona Roho akimshukia na kukaa juu yake, huyo ndiye atakayebatiza kwa Roho Mtakatifu.’ 341:34 Mt 4:3Mimi mwenyewe nimeona jambo hili na ninashuhudia kuwa huyu ndiye Mwana wa Mungu.”

Wanafunzi Wa Kwanza Wa Yesu

351:35 Mt 3:1Siku iliyofuata, Yohana alikuwa huko tena pamoja na wanafunzi wake wawili. 361:36 Yn 1:29Alipomwona Yesu akipita, akasema, “Tazama, Mwana-Kondoo wa Mungu!”

37Wale wanafunzi wawili walipomsikia Yohana akisema haya, wakamfuata Yesu. 381:38 Mt 23:7Yesu akageuka, akawaona wakimfuata akawauliza, “Mnataka nini?”

Wakamwambia, “Rabi,” (maana yake Mwalimu), “Unaishi wapi?”

39Yesu akawajibu, “Njooni, nanyi mtapaona!”

Hivyo wakaenda na kupaona mahali alipokuwa anaishi, wakakaa naye siku ile, kwa kuwa ilikuwa yapata saa kumi.

401:40 Mt 4:18-22Andrea nduguye Simoni Petro, alikuwa mmoja wa wale wawili waliosikia yale Yohana aliyokuwa amesema, naye ndiye alimfuata Yesu. 411:41 Yn 4:25Kitu cha kwanza Andrea alichofanya ni kumtafuta Simoni nduguye na kumwambia, “Tumemwona Masiya” (yaani, Kristo). 421:42 Mwa 32:28; Mt 16:18Naye akamleta kwa Yesu.

Yesu akamwangalia na kusema, “Wewe ni Simoni mwana wa Yohana. Utaitwa Kefa” (ambalo limetafsiriwa Petro1:42 Petro kwa Kiyunani au Kefa kwa Kiaramu; maana yake ni Kipande cha mwamba.).

Yesu Awaita Filipo Na Nathanaeli

431:43 Mt 10:3; Yn 14:8-9; Mt 4:9Siku iliyofuata Yesu aliamua kwenda Galilaya. Akamkuta Filipo, akamwambia, “Nifuate.”

441:44 Yn 12:21Basi Filipo alikuwa mwenyeji wa Bethsaida, mji alikotoka Andrea na Petro. 451:45 Yn 21:2; Lk 24:27; Mt 2:23; Lk 3:23Filipo naye akamkuta Nathanaeli na kumwambia, “Tumemwona yeye ambaye Mose aliandika habari zake katika Sheria na ambaye pia manabii waliandika kumhusu, yaani, Yesu wa Nazareti, mwana wa Yosefu.”

461:46 Yn 7:41-42, 52Nathanaeli akauliza, “Nazareti! Je, kitu chochote chema chaweza kutoka Nazareti?” Filipo akamwambia, “Njoo uone.”

471:47 Za 32:2; Rum 9:4-6Yesu alipomwona Nathanaeli anakaribia, akanena habari zake akasema, “Tazama huyu ni Mwisraeli kweli kweli; hana hila ndani yake.”

48Nathanaeli akamuuliza, “Umenifahamuje?”

Yesu akamjibu, “Nilikuona ulipokuwa bado uko chini ya mtini, kabla hata Filipo hajakuita.”

491:49 Mt 23:7; 4:3; 2; 2; 27:42Nathanaeli akamwambia, “Rabi, wewe ni Mwana wa Mungu! Wewe ni Mfalme wa Israeli!”

50Yesu akamwambia, “Unaamini kwa kuwa nilikuambia nilikuona ulipokuwa bado uko chini ya mtini? Basi utaona mambo makuu zaidi kuliko hilo.” 511:51 Mt 3:16; 8:20; Mwa 28:12Ndipo akawaambia, “Amin, amin nawaambia, ninyi mtaona mbingu ikifunguka na malaika wa Mungu wakipanda na kushuka juu ya Mwana wa Adamu.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Johanu 1:1-51

Ọ̀rọ̀ di ẹran-ara

11.1: Gẹ 1.1; 1Jh 1.1; If 19.13; Jh 17.5.Ní àtètèkọ́ṣe ni Ọ̀rọ̀ wà, Ọ̀rọ̀ sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run, Ọlọ́run sì ni Ọ̀rọ̀ náà. 2Òun ni ó sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run ní àtètèkọ́ṣe. 31.3: Kl 1.16; 1Kọ 8.6; Hb 1.2.Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá ohun gbogbo; lẹ́yìn rẹ̀ a kò sì dá ohun kan nínú ohun tí a ti dá. 41.4: Jh 5.26; 11.25; 14.6.Nínú rẹ̀ ni ìyè wà, ìyè yìí náà sì ni ìmọ́lẹ̀ aráyé, 51.5: Jh 9.5; 12.46.ìmọ́lẹ̀ náà sì ń mọ́lẹ̀ nínú òkùnkùn, òkùnkùn kò sì borí rẹ̀.

61.6: Mk 1.4; Mt 3.1; Lk 3.3; Jh 1.19-23.Ọkùnrin kan wà tí a rán láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá; orúkọ ẹni tí ń jẹ́ Johanu. 7Òun ni a sì rán fún ẹ̀rí, kí ó lè ṣe ẹlẹ́rìí fún ìmọ́lẹ̀ náà, kí gbogbo ènìyàn kí ó lè gbàgbọ́ nípasẹ̀ rẹ̀. 8Òun fúnra rẹ̀ kì í ṣe ìmọ́lẹ̀ náà, ṣùgbọ́n a rán an wá láti ṣe ẹlẹ́rìí fún ìmọ́lẹ̀ náà.

91.9: 1Jh 2.8.Ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ ń bẹ tí ń tan ìmọ́lẹ̀ fún olúkúlùkù ènìyàn tí ó wá sí ayé. 10Òun sì wà ní ayé, àti pé, nípasẹ̀ rẹ̀ ni a sì ti dá ayé, ṣùgbọ́n ayé kò sì mọ̀ ọ́n. 11Ó tọ àwọn tirẹ̀ wá, àwọn tirẹ̀ kò sì gbà á. 121.12: Ga 3.26; Jh 3.18; 1Jh 5.13.Ṣùgbọ́n iye àwọn tí ó gbà á, àní àwọn náà tí ó gbà orúkọ rẹ̀ gbọ́, àwọn ni ó fi ẹ̀tọ́ fún láti di ọmọ Ọlọ́run. 131.13: Jn 3.5; 1Pt 1.23; Jk 1.18; 1Jh 3.9.Àwọn ọmọ tí kì í ṣe nípa ẹ̀jẹ̀, tàbí nípa ti ìfẹ́ ara, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nípa ìfẹ́ ti ènìyàn, bí kò ṣe láti ọwọ́ Ọlọ́run.

141.14: Ro 1.3; Ga 4.4; Fp 2.7; 1Tm 3.16; Hb 2.14; 1Jh 4.2.Ọ̀rọ̀ náà sì di ara, òun sì ń bá wa gbé. Àwa sì ti rí ògo rẹ̀, àní ògo ọmọ rẹ kan ṣoṣo, tí ó ti ọ̀dọ̀ Baba wá, ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́.

151.15: Jh 1.30.Johanu sì jẹ́rìí nípa rẹ̀, ó kígbe, ó sì wí pé, “Èyí ni ẹni tí mo sọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, ‘Ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi pọ̀jù mí lọ, nítorí òun ti wà ṣáájú mi.’ ” 161.16: Kl 1.19; 2.9; Ef 1.23; Ro 5.21.Nítorí láti inú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ ni gbogbo wa sì ti gba ìbùkún kún ìbùkún. 171.17: Jh 7.19.Nítorí pé nípasẹ̀ Mose ni a ti fi òfin fún ni ṣùgbọ́n òun; oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́ láti ipasẹ̀ Jesu Kristi wá. 181.18: El 33.20; Jh 6.26; 1Jh 4.12; Jh 3.11.Kò sí ẹni tí ó rí Ọlọ́run rí, bí kò ṣe òun nìkan, àní ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo, ẹni tí òun pàápàá jẹ́ Ọlọ́run, tí ó sì wà ní ìbáṣepọ̀ tí ó súnmọ́ jùlọ pẹ̀lú baba, òun náà ni ó sì fi í hàn.

Johanu sọ pé òun kì í ṣe Kristi

191.19: Jh 1.6.Èyí sì ni ẹ̀rí Johanu, nígbà tí àwọn Júù rán àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi láti Jerusalẹmu wá láti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ ẹni tí òun ń ṣe. 201.20: Jh 3.28.Òun kò sì kùnà láti jẹ́wọ́, ṣùgbọ́n òun jẹ́wọ́ wọ́ọ́rọ́wọ́ pé, “Èmi kì í ṣe Kristi náà.”

211.21: Mt 11.14; 16.14; Mk 9.13; Mt 17.13; De 18.15,18.Wọ́n sì bi í léèrè pé, “Ta ha ni ìwọ? Elijah ni ìwọ bí?”

Ó sì wí pé, “Èmi kọ́.”

“Ìwọ ni wòlíì náà bí?”

Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́.”

22Ní ìparí wọ́n wí fún un pé, “Ta ni ìwọ í ṣe? Fún wa ní ìdáhùn kí àwa kí ó lè mú èsì padà tọ àwọn tí ó rán wa wá lọ. Kí ni ìwọ wí nípa ti ara rẹ?”

231.23: Isa 40.3; Mk 1.3; Mt 3.3; Lk 3.4.Johanu sì fi ọ̀rọ̀ wòlíì Isaiah fún wọn ní èsì pé, “Èmi ni ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù, ‘Ẹ ṣe ọ̀nà Olúwa ní títọ́.’ ”

24Ọ̀kan nínú àwọn Farisi tí a rán 25bi í léèrè pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń bamitiisi nígbà náà, bí ìwọ kì í bá ṣe Kristi, tàbí Elijah, tàbí wòlíì náà?”

261.26-27: Mk 1.7-8; Mt 3.11; Lk 3.16.Johanu dá wọn lóhùn, wí pé, “Èmi ń fi omi bamitiisi, ẹnìkan dúró láàrín yín, ẹni tí ẹ̀yin kò mọ̀, 27Òun náà ni ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi, okùn bàtà ẹni tí èmi kò tó láti tú.”

28Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó ṣẹlẹ̀ ní Betani ní òdìkejì odò Jordani, níbi tí Johanu ti ń fi omi bamitiisi.

Jesu jẹ́ Ọ̀dọ́-Àgùntàn Ọlọ́run

291.29: Jh 1.36; Isa 53.7; Ap 8.32; 1Pt 1.19; If 5.6; 1Jh 3.5.Ní ọjọ́ kejì, Johanu rí Jesu tí ó ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Wò ó, Ọ̀dọ́-àgùntàn Ọlọ́run, ẹni tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ! 30Èyí ni ẹni tí mo ń sọ nígbà tí mo wí pé, ‘Ọkùnrin kan tí ń bọ̀ wá lẹ́yìn mi, tí ó pọ̀jù mí lọ, nítorí tí ó ti wà ṣáájú mi.’ 31Èmi gan an kò sì mọ̀ ọ́n, ṣùgbọ́n ìdí tí mo fi wá ń fi omi ṣe ìtẹ̀bọmi ni kí a lè fi í hàn fún Israẹli.”

321.32: Mk 1.10; Mt 3.16; Lk 3.22.Nígbà náà ni Johanu jẹ́rìí sí i pé, “Mo rí Ẹ̀mí sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá bí àdàbà, tí ó sì bà lé e. 33Èmi kì bá tí mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe pé ẹni tí ó rán mi láti fi omi bamitiisi sọ fún mi pé, ‘Ọkùnrin tí ìwọ rí tí Ẹ̀mí sọ̀kalẹ̀ tí ó bà lé lórí ni ẹni tí yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitiisi.’ 34Èmi ti rí i, mo sì jẹ́rìí pé, èyí ni Ọmọ Ọlọ́run.”

Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu àkọ́kọ́

351.35: Lk 7.18.Ní ọjọ́ kejì, Johanu dúró pẹ̀lú méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. 36Nígbà tí ó sì rí Jesu bí ó ti ń kọjá lọ, ó wí pé, “Wò ó Ọ̀dọ́-àgùntàn Ọlọ́run!”

37Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì náà sì gbọ́ ohun tí ó wí yìí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sì í tọ Jesu lẹ́yìn. 38Nígbà náà ni Jesu yípadà, ó rí i pé wọ́n ń tọ òun lẹ́yìn, ó sì béèrè pé, “Kí ni ẹ̀yin ń wá?”

Wọ́n wí fún un pé, “Rabbi” (ìtumọ̀ èyí tí í ṣe Olùkọ́ni), “Níbo ni ìwọ ń gbé?”

39Ó wí fún wọn pé, “Ẹ wá wò ó, ẹ̀yin yóò sì rí i.”

Wọ́n sì wá, wọ́n sì rí ibi tí ó ń gbé, wọ́n sì wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ náà. Ó jẹ́ ìwọ̀n wákàtí kẹwàá ọjọ́.

401.40-42: Mt 4.18-22; Mk 1.16-20; Lk 5.2-11.Anderu arákùnrin Simoni Peteru jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn méjì tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Johanu, tí ó sì tọ Jesu lẹ́yìn. 411.41: Da 9.25; Jh 4.25.Ohun àkọ́kọ́ tí Anderu ṣe ni láti wá Simoni arákùnrin rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Àwa ti rí Messia” (ẹni tí ṣe Kristi). 421.42: Jh 21.15-17; 1Kọ 15.5; Mt 16.18.Ó sì mú un wá sọ́dọ̀ Jesu.

Jesu sì wò ó, ó wí pé, “Ìwọ ni Simoni ọmọ Jona: Kefa ni a ó sì máa pè ọ” (ìtumọ̀ èyí tí ṣe Peteru).

Jesu pe Filipi àti Natanaeli

431.43: Mt 10.3; Jh 6.5; 12.21; 14.8.Ní ọjọ́ kejì Jesu ń fẹ́ jáde lọ sí Galili, ó sì rí Filipi, ó sì wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”

44Filipi gẹ́gẹ́ bí i Anderu àti Peteru, jẹ́ ará ìlú Betisaida. 451.45: Lk 24.27.Filipi rí Natanaeli, ó sì wí fún un pé, “Àwa ti rí ẹni náà tí Mose kọ nípa rẹ̀ nínú òfin àti ẹni tí àwọn wòlíì ti kọ̀wé rẹ̀, Jesu ti Nasareti, ọmọ Josẹfu.”

461.46: Jh 7.41; Mk 6.2.Natanaeli béèrè pé, “Nasareti? Ohun rere kan ha lè ti ibẹ̀ jáde?”

Filipi wí fún un pé, “Wá wò ó.”

47Jesu rí Natanaeli ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí nípa rẹ̀ pé, “Èyí ni ọmọ Israẹli tòótọ́, nínú ẹni tí ẹ̀tàn kò sí.”

48Natanaeli béèrè pé, “Báwo ni ìwọ ti ṣe mọ̀ mí?”

Jesu sì dáhùn pé, “Èmi rí ọ nígbà tí ìwọ wà lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ kí Filipi tó pè ọ́.”

491.49: Sm 2.7; Mk 15.32; Jh 12.13.Nígbà náà ni Natanaeli sọ ọ́ gbangba pé, “Rabbi, ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run; Ìwọ ni ọba Israẹli.”

50Jesu sì wí fún un pé, “Ìwọ gbàgbọ́ nítorí mo wí fún ọ pé mo rí ọ lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́. Ìwọ ó rí ohun tí ó pọ̀jù ìwọ̀nyí lọ.” 511.51: Lk 3.21; Gẹ 28.12.Nígbà náà ni ó fi kún un pé, “Èmi wí fún yín nítòótọ́, ẹ̀yin yóò rí ọ̀run ṣí sílẹ̀, àwọn angẹli Ọlọ́run yóò sì máa gòkè, wọ́n ó sì máa sọ̀kalẹ̀ sórí Ọmọ Ènìyàn.”