Warumi 3 – NEN & YCB

Kiswahili Contemporary Version (Neno: Bibilia Takatifu)

Warumi 3:1-31

Uaminifu Wa Mungu

1Basi kuna faida gani kuwa Myahudi? Au kuna thamani gani katika tohara? 23:2 Za 147:19; Mdo 7:38Kuna faida kubwa kwa kila namna! Kwanza kabisa, Wayahudi wamekabidhiwa lile Neno halisi la Mungu. 33:3 Rum 10:16; Ebr 4:2; 2Tim 2:13Ingekuwaje kama wengine hawakuwa na imani? Je, kutokuamini kwao kungebatilisha uaminifu wa Mungu? 43:4 Yn 3:33; Za 116:11La hasha! Mungu na aonekane mwenye haki, na kila mwanadamu kuwa mwongo, kama ilivyoandikwa:

“Ili uthibitike kuwa wa kweli unaponena,

na ukashinde utoapo hukumu.”

53:5 Rum 6:19; Gal 3:15Ikiwa uovu wetu unathibitisha haki ya Mungu waziwazi, tuseme nini basi? Je, Mungu kuileta ghadhabu yake juu yetu ni kwamba yeye si mwenye haki? (Nanena kibinadamu.) 63:6 Mwa 18:25; Rum 2:16La hasha! Kama hivyo ndivyo ilivyo, Mungu angehukumuje ulimwengu? 73:7 Rum 3:4; 9:19Mtu aweza kuuliza, “Kama uongo wangu unasaidia kuonyesha kweli ya Mungu na kuzidisha utukufu wake, kwa nini basi mimi nahukumiwa kuwa mwenye dhambi?” 83:8 Rum 6:1; Mdo 5:20; 6:1; 15Nasi kwa nini tusiseme, kama wengine wanavyotusingizia kuwa tunasema, “Tutende maovu ili mema yapate kuja?” Wao wanastahili hukumu yao.

Wote Wametenda Dhambi

93:9 1Fal 8:46; Gal 3:22Tusemeje basi? Je, sisi ni bora kuwaliko wao? La hasha! Kwa maana tumekwisha kuhakikisha kwa vyovyote kwamba Wayahudi na watu wa Mataifa wote wako chini ya nguvu ya dhambi. 103:10 Za 14:1, 3; 53:1Kama ilivyoandikwa:

“Hakuna mwenye haki, hakuna hata mmoja.

11Hakuna hata mmoja mwenye ufahamu,

hakuna hata mmoja amtafutaye Mungu.

123:12 Za 53:1-3; Mhu 7:20Wote wamepotoka,

wote wameoza pamoja;

hakuna atendaye mema,

naam, hakuna hata mmoja.”

133:13 Za 5:9; 140:3“Makoo yao ni makaburi wazi;

kwa ndimi zao wao hufanya udanganyifu.”

“Sumu ya nyoka iko midomoni mwao.”

143:14 Za 10:7“Vinywa vyao vimejaa laana na uchungu.”

153:15 Isa 59:7, 8; Mit 1:16“Miguu yao ina haraka kumwaga damu;

16maangamizi na taabu viko katika njia zao,

173:17 Isa 59:7, 9wala njia ya amani hawaijui.”

183:18 Za 36:1“Hakuna hofu ya Mungu machoni pao.”

193:19 Yn 10:34; Rum 2:12Basi tunajua ya kwamba chochote sheria inachosema, inawaambia wale walio chini ya sheria ili kila kinywa kinyamazishwe na ulimwengu wote uwajibike kwa Mungu. 203:20 Mdo 13:39; Gal 2:16; Rum 4:15; 7:7Kwa hiyo hakuna binadamu hata mmoja atakayehesabiwa haki mbele za Mungu kwa matendo ya sheria, kwa maana sheria hutufanya tuitambue dhambi.

Haki Kwa Njia Ya Imani

213:21 Isa 46:13; Rum 9:30; Mdo 10:43; Rum 1:2Lakini sasa, haki itokayo kwa Mungu imedhihirishwa pasipo sheria, ambayo Sheria na Manabii wanaishuhudia. 223:22 Rum 9:30; Gal 3:28; Kol 3:11Haki hii itokayo kwa Mungu hupatikana kwa Yesu Kristo kwa wote wamwaminio. Kwa maana hapo hakuna tofauti, 233:23 Rum 9:19; 5:2; 3:9; Gal 3:22kwa kuwa wote wametenda dhambi na kupungukiwa na utukufu wa Mungu, 243:24 2Kor 12:9; Tit 2:11; Za 130:7; Gal 4:5wanahesabiwa haki bure kwa neema yake kwa njia ya ukombozi ulio katika Kristo Yesu. 253:25 Za 65:3; Ebr 9:28; 1Pet 1:19; Ufu 1:5; Mdo 14:16; 17:30Yeye ambaye Mungu alimtoa awe dhabihu ya upatanisho kwa njia ya imani katika damu yake. Alifanya hivi ili kuonyesha haki yake, kwa sababu kwa ustahimili wake aliziachilia zile dhambi zilizotangulia kufanywa. 26Alifanya hivyo ili kuonyesha haki yake wakati huu, ili yeye awe mwenye haki na mwenye kumhesabia haki yule anayemwamini Yesu.

Umuhimu Wa Kuwa Na Imani

273:27 1Kor 1:29-31; Efe 2:9Basi, kujivuna kuko wapi? Kumewekwa mbali. Kwa sheria gani? Je, ni kwa ile ya matendo? La hasha, bali kwa ile sheria ya imani. 283:28 Gal 3:11; Yn 2:19Kwa maana twaona kwamba mwanadamu huhesabiwa haki kwa njia ya imani wala si kwa matendo ya sheria. 293:29 Mdo 10:34, 35Je, Mungu ni Mungu wa Wayahudi peke yao? Je, yeye si Mungu wa watu wa Mataifa pia? Naam, yeye ni Mungu wa watu wa Mataifa pia. 303:30 Rum 4:11, 12; Gal 3:8Basi kwa kuwa tuna Mungu mmoja tu, atawahesabia haki wale waliotahiriwa kwa imani na wale wasiotahiriwa kwa imani iyo hiyo. 31Je, basi ni kwamba tunaibatilisha sheria kwa imani hii? La, hasha! Badala yake tunaithibitisha sheria.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Romu 3:1-31

Ìṣòtítọ́ Ọlọ́run

1Ǹjẹ́ àǹfààní wo ní Júù ní? Tàbí kín ni èrè ilà kíkọ? 23.2: Sm 147.19; Ro 9.4.Púpọ̀ lọ́nà gbogbo; pàtàkì jùlọ ni pé àwọn ni a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lé lọ́wọ́.

3Ǹjẹ́ kí ha ni bí àwọn kan jẹ́ aláìgbàgbọ́? Àìgbàgbọ́ wọn yóò ha sọ òtítọ́ Ọlọ́run di asán bí? 43.4: Sm 51.4.Kí a má rí! Kí Ọlọ́run jẹ́ olóòtítọ́, àti olúkúlùkù ènìyàn jẹ́ èké; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:

“Kí a lè dá ọ láre nínú ọ̀rọ̀ rẹ,

ṣùgbọ́n kí ìwọ lè borí nígbà tí ìwọ bá wá sí ìdájọ́.”

53.5: Ro 5.9; 6.19; 1Kọ 9.8; Ga 3.15.Ṣùgbọ́n bí àìṣòdodo wa bá fi òdodo Ọlọ́run hàn, kín ni àwa ó wí? Ọlọ́run ha jẹ́ àìṣòdodo bí, nígbà tí ó bá ń fi ìbínú rẹ̀ hàn? (Mo fi ṣe àkàwé bí ènìyàn.) 6Kí a má rí i. Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, Ọlọ́run yóò ha ṣe lè dájọ́ aráyé? 7Nítorí bí òtítọ́ Ọlọ́run bá di púpọ̀ sí ìyìn rẹ̀ nítorí èké mi, èéṣe tí a fi ń dá mi lẹ́jọ́ bí ẹlẹ́ṣẹ̀? 83.8: Ro 6.1,15.Èéṣe tí a kò fi ṣe búburú kí rere lè jáde wá? Bí àwọn kan tí ń fi ẹnu àtẹ́ sọ wí pé a ń sọ bẹ́ẹ̀; ti àwọn kan sì ń tẹnumọ́ ọn pé a sọ; àwọn ẹni tí ìdálẹ́bi wọn tọ́.

Kò sí olóòtítọ́ kan

93.9: Ro 1.18-32; 2.1-29; 11.32; 3.23.Ǹjẹ́ kí ha ni? Àwa ha sàn ju wọn lọ bí? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá, nítorí a fihàn ṣáájú pé àti àwọn Júù àti àwọn Giriki, gbogbo wọn ni ó wà lábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. 103.10-12: Sm 14.1-3; 53.1-3.Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé,

“Kò sí ẹni tí í ṣe olódodo, kò sí ẹnìkan,

11kò sí ẹni tí òye yé,

kò sí ẹni tí ó ń wá Ọlọ́run.

12Gbogbo wọn ni ó ti yapa,

wọ́n jùmọ̀ di aláìlérè;

kò sí ẹni tí ń ṣe rere,

kò tilẹ̀ sí ẹnìkan.”

133.13: Sm 5.9; 140.3.“Ibojì tí ó ṣí sílẹ̀ ní ọ̀fun wọn:

ahọ́n wọn n sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.”

“Oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ lábẹ́ ètè wọn.”

143.14: Sm 10.7.“Ẹnu ẹni tí ó kún fún èpè àti fún oró kíkorò.”

153.15-17: Isa 59.7-8.“Ẹsẹ̀ wọn yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀,

16ìparun àti ìpọ́njú wà lọ́nà wọn.

17Ọ̀nà àlàáfíà ni wọn kò sì mọ̀,”

183.18: Sm 36.1.“Ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò sí níwájú wọn.”

193.19: Ro 2.12.Àwa sì mọ̀ pé ohunkóhun tí òfin bá wí, ó ń wí fún àwọn tí ó wà lábẹ́ òfin: kí gbogbo ẹnu bá à lè dákẹ́ àti kí a lè mú gbogbo aráyé wá sábẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run. 203.20: Sm 143.2; Ap 13.39; Ga 2.16; 3.11; Ro 7.7.Nítorí pé nípa iṣẹ́ òfin, a kì yóò dá ẹnikẹ́ni láre níwájú rẹ̀: nítorí nípa òfin ni ìmọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ti wá.

Ìṣòdodo nípa ìgbàgbọ́

213.21: Ro 1.17; Fp 3.9; 2Pt 1.1.Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, a ti fi òdodo Ọlọ́run hàn láìsí òfin, tí a ti ń jẹ́rìí sí nípa òfin àti nípa àwọn wòlíì, 223.22: Ro 4.5; 9.30; 10.12; Ga 2.16.àní òdodo Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi, sí gbogbo ènìyàn àti gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́, nítorí tí kò sí ìyàtọ̀ láàrín Júù àti Helleni. 233.23: Ro 3.9.Gbogbo ènìyàn ni ó ṣá ti ṣẹ̀, tí wọ́n sì kùnà ògo Ọlọ́run, 243.24: Ro 4.16; 5.9; Ef 2.8; Tt 3.7; Ef 1.7; Kl 1.14; Hb 9.15.àwọn ẹni tí a ń dá láre lọ́fẹ̀ẹ́ nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, nípa ìdáǹdè tí ó wà nínú Kristi Jesu. 25Ẹni tí Ọlọ́run ti gbé kalẹ̀ láti jẹ́ ètùtù nípa ìgbàgbọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, láti fi òdodo rẹ̀ hàn nítorí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti kọjá, nínú ìpamọ́ra Ọlọ́run, 263.26: 1Jh 2.2; Kl 1.20.láti fi òdodo rẹ̀ hàn ní ìgbà ìsinsin yìí: kí ó lè jẹ́ olódodo àti olùdáláre ẹni tí ó gba Jesu gbọ́.

27Ọ̀nà ìṣògo dà? A ti mú un kúrò. Nípa òfin wo? Nípa iṣẹ́? Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n nípa òfin ìgbàgbọ́. 283.28: Ap 13.39; Ro 5.1; Ef 2.9.Nítorí náà, a parí rẹ̀ sí pé nípa ìgbàgbọ́ ni a ń dá ènìyàn láre láìsí iṣẹ́ òfin. 293.29: Ro 9.24; Ap 10.34-35.Ọlọ́run àwọn Júù nìkan ha ni bí? Kì í ha ṣe ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú? Bẹ́ẹ̀ ni, ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú. 303.30: Ro 4.11-12,16.Bí ó ti jẹ́ pé Ọlọ́run kan ni, yóò dá àwọn akọlà láre nípa ìgbàgbọ́ àti àwọn aláìkọlà nípa ìgbàgbọ́ wọn. 313.31: Ro 8.4; Mt 5.17.Àwa ha ń sọ òfin dasán nípa ìgbàgbọ́ bí? Kí a má rí i, ṣùgbọ́n a ń fi òfin múlẹ̀.