ኢዮብ 31 – NASV & YCB

New Amharic Standard Version

ኢዮብ 31:1-40

1“ወደ ኰረዳዪቱ ላለመመልከት፣

ከዐይኔ ጋር ቃል ኪዳን ገብቻለሁ።

2ከላይ ከእግዚአብሔር ዘንድ የሰው ዕድል ፈንታው፣

ከአርያም ሁሉን ከሚችል አምላክስ ዘንድ ቅርሱ ምንድን ነው?

3ለኀጢአተኞች ጥፋት፣

ክፉ ለሚያደርጉም መቅሠፍት አይደለምን?

4እርሱ መንገዴን አያይምን?

ርምጃዬንስ ሁሉ አይቈጥርምን?

5“በሐሰት ሄጄ እንደ ሆነ፣

እግሬም ወደ ሽንገላ ቸኵሎ ከሆነ፣

6እግዚአብሔር በእውነተኛ ሚዛን ይመዝነኝ፤

ነውር እንደሌለብኝም ይወቅ።

7አረማመዴ ከመንገድ ወጣ ብሎ፣

ልቤ ዐይኔን ተከትሎ፣

ወይም እጄ ረክሶ ከሆነ፣

8የዘራሁትን ሌላ ይብላው፤

ሰብሌም ተነቅሎ ይጥፋ።

9“ልቤ ሌላዋን ሴት ከጅሎ፣

በባልንጀራዬ ደጅ አድብቼ ከሆነ፣

10ሚስቴ የሌላ ሰው እህል ትፍጭ፤

ሌሎች ሰዎችም ይተኟት፤

11ይህ አሳፋሪ፣

ፍርድም የሚገባው ኀጢአት ነውና።

12ይህ የሚያቃጥልና የሚያጠፋ31፥12 ዕብራይስጡ አባዶን ይላል። እሳት ነው፤

ቡቃያዬንም ባወደመ ነበር።

13“ወንዶችና ሴቶች አገልጋዮቼ አቤቱታ ባቀረቡ ጊዜ፣

ፍርድ አዛብቼ ከሆነ፣

14እግዚአብሔር ሲነሣ ምን አደርጋለሁ?

ሲጠይቀኝስ ምን መልስ እሰጣለሁ?

15እኔን በማሕፀን ውስጥ የፈጠረኝ እነርሱን የፈጠረ አይደለምን?

በሆድ ውስጥ የሠራንስ እርሱ ራሱ አይደለምን?

16“ለድኻ የሚያስፈልገውን ከልክዬ ከሆነ፣

ወይም የመበለቲቱን ዐይን አፍዝዤ ከሆነ፣

17እንጀራዬን ከድኻ ዐደጉ ጋር ሳልካፈል፣

ለብቻዬ በልቼ ከሆነ፣

18ይልቁን ድኻ ዐደጉን ከታናሽነቴ ጀምሮ እንደ አባት አሳደግሁት፤

መበለቲቱንም ከተወለድሁ ጀምሮ መንገድ መራኋት፤

19በልብስ ዕጦት ሰው ሲጠፋ፣

ወይም ዕርቃኑን ያልሸፈነ ድኻ አይቼ፣

20በበጎቼ ጠጕር ስላሞቅሁት፣

ልቡ ባርኮኝ ካልሆነ፣

21በአደባባይ ተሰሚነት አለኝ ብዬ፣

በድኻ ዐደጉ ላይ እጄን አንሥቼ ከሆነ፣

22ትከሻዬ ከመጋጠሚያው ይነቀል፤

ክንዴም ከመታጠፊያው ይሰበር፤

23የእግዚአብሔርን ቍጣ በመፍራቴ፣

እንዲህ ያሉ ነገሮች መፈጸም አልቻልሁም።

24“ወርቅን ተስፋ አድርጌ፣

ወይም ንጹሑን ወርቅ፣ ‘አንተ መታመኛዬ ነህ’ ብዬ ከሆነ፣

25እጄ ባገኘችው ሀብት፣

በባለጠግነቴም ብዛት ደስ ብሎኝ ከሆነ፣

26የፀሓይን ድምቀት አይቼ፣

ወይም የጨረቃን አካሄድ ግርማ ተመልክቼ፣

27ልቤ በስውር ተታልሎ፣

ስለ ክብራቸው አፌ እጄን ስሞ ከሆነ፣

28ለልዑል እግዚአብሔር ታማኝ አለመሆኔ ነውና፣

ይህም ደግሞ የሚያስቀጣኝ በደል በሆነ ነበር።

29“በጠላቴ ውድቀት ደስ ብሎኝ፣

በደረሰበትም መከራ ሐሤት አድርጌ እንደ ሆነ፣

30እኔ ግን በነፍሱ ላይ ክፉ እንዲመጣ በመራገም፣

አንደበቴን ለኀጢአት ከቶ አሳልፌ አልሰጠሁም።

31የቤቴ ሰዎች፣ ‘ከኢዮብ ከብት ሥጋ አስቈርጦ፣

ያልጠገበ ማን ነው?’ ብለው ካልሆነ፣

32ነገር ግን ቤቴ ለመንገደኛው ዘወትር ክፍት ስለ ነበር፣

መጻተኛው በጐዳና ላይ አያድርም ነበር።

33ሰዎች31፥33 ወይም አዳም እንዳደረገው እንደሚያደርጉት በደሌን በልቤ በመሰወር፣

ኀጢአቴን ሸሽጌ ከሆነ፣

34ሕዝቡን በመፍራት፣

የወገኖቼንም ንቀት በመሸሽ፣

ወደ ደጅ ሳልወጣ፣ ዝም ብዬ ቤት ውስጥ አልተቀመጥሁም።

35“ምነው የሚሰማኝ ባገኝ!

የመከላከያ ፊርማዬ እነሆ፤ ሁሉን የሚችል አምላክ ይመልስልኝ፤

ከሳሼም ክሱን በጽሑፍ ያቅርብ።

36በርግጥ ትከሻዬ ላይ በደረብሁት፣

እንደ አክሊልም ራሴ ላይ በደፋሁት ነበር።

37እያንዳንዱን ርምጃዬን በገለጽሁለት፣

እንደ ልዑል እየተንጐራደድሁ በቀረብሁት ነበር።

38“ዕርሻዬ በእኔ ላይ ጮኻ ከሆነ፣

ትልሞቿ ሁሉ በእንባ ርሰው እንደ ሆነ፣

39ፍሬዋን ያለ ዋጋ በልቼ፣

የባለመሬቶቿን ነፍስ አሳዝኜ ከሆነ፣

40በስንዴ ፈንታ እሾኽ፣

በገብስም ምትክ ዐረም ይብቀልብኝ።”

የኢዮብ ቃል ተፈጸመ።

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jobu 31:1-40

Àwíjàre Jobu

1“Mo ti bá ojú mi dá májẹ̀mú,

èmi yó ha ṣe tẹjúmọ́ wúńdíá?

2Nítorí pé kí ni ìpín Ọlọ́run láti ọ̀run wá?

Tàbí kí ni ogún Olódùmarè láti òkè ọ̀run wá.

3Kò ṣe pé àwọn ènìyàn búburú ni ìparun wà fún,

àti àjàkálẹ̀-ààrùn fún àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀?

4Òun kò ha ri ipa ọ̀nà mi,

òun kò ha sì ka gbogbo ìṣísẹ̀ mi?

5“Bí ó bá ṣe pé èmi bá fi àìṣòótọ́ rìn,

tàbí tí ẹsẹ̀ mi sì yára sí ẹ̀tàn,

6(jẹ́ kí Ọlọ́run wọ́n mí nínú ìwọ̀n òdodo,

kí Ọlọ́run le mọ ìdúró ṣinṣin mi.)

7Bí ẹsẹ̀ mí bá yà kúrò lójú ọ̀nà,

tí àyà mí sì tẹ̀lé ipa ojú mi,

tàbí bí àbàwọ́n kan bá sì lẹ̀ mọ́ mi ní ọwọ́,

8ǹjẹ́ kí èmi kí ó gbìn kí ẹlòmíràn kí ó sì mújẹ,

àní kí a fa irú-ọmọ mi tu.

9“Bí àyà mi bá di fífà sí ipasẹ̀ obìnrin kan,

tàbí bí mo bá lọ í ba de ènìyàn ní ẹnu-ọ̀nà ilé aládùúgbò mi,

10kí àyà mi kí ó lọ ọlọ fún ẹlòmíràn,

kí àwọn ẹlòmíràn kí ó tẹ̀ ara wọn ní ara rẹ̀.

11Nítorí pé yóò jẹ́ ohun ìtìjú àní,

ẹ̀ṣẹ̀ tí a ó ṣe onídàájọ́ rẹ̀.

12Nítorí pé iná ní èyí tí ó jó dé ibi ìparun,

tí ìbá sì fa gbòǹgbò ohun ìbísí mi gbogbo tu.

13“Tí mo bá sì ṣe àìka ọ̀ràn ìránṣẹ́kùnrin mi

tàbí ìránṣẹ́bìnrin mi sí,

nígbà tí wọ́n bá ń bá mi jà;

14kí ni èmi ó ha ṣe nígbà tí Ọlọ́run bá dìde?

Nígbà tí ó bá sì ṣe ìbẹ̀wò, ohùn kí ni èmi ó dá?

15Ẹni tí ó dá mi ní inú kọ́ ni ó dá a?

Ẹnìkan náà kí ó mọ wá ní inú ìyá wa?

16“Bí mo bá fa ọwọ́ sẹ́yìn fún ìfẹ́ inú tálákà,

tàbí bí mo bá sì mú kí ojú opó rẹ̀wẹ̀sì,

17tàbí tí mo bá nìkan bu òkèlè mi jẹ,

tí aláìní baba kò jẹ nínú rẹ̀;

18nítorí pé láti ìgbà èwe mi wá ni a ti tọ́ ọ dàgbà pẹ̀lú mi bí ẹni pé baba,

èmi sì ń ṣe ìtọ́jú opó láti inú ìyá mi wá:

19bí èmi bá rí olùpọ́njú láìní aṣọ,

tàbí tálákà kan láìní ìbora;

20bí ọkàn rẹ̀ kò bá súre fún mi,

tàbí bí ara rẹ̀ kò sì gbóná nípasẹ̀ irun àgùntàn mi;

21bí mo bá sì gbé ọwọ́ mi sókè sí aláìní baba,

nítorí pé mo rí ìrànlọ́wọ́ mi ní ẹnu ibodè,

22ǹjẹ́, ní apá mi kí o wọ́n kúrò ní ihò èjìká rẹ̀,

kí apá mi kí ó sì ṣẹ́ láti egungun rẹ̀ wá.

23Nítorí pé ìparun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ni ẹ̀rù ńlá fún mi,

àti nítorí ọláńlá rẹ̀ èmi kò le è dúró.

24“Bí ó bá ṣe pé mo fi wúrà ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé mi,

tàbí tí mo bá wí fún fàdákà dídára pé, ‘Ìwọ ni ààbò mi,’

25bí mo bá yọ̀ nítorí ọrọ̀ mí pọ̀,

àti nítorí ọwọ́ mi dara lọ́pọ̀lọ́pọ̀,

26bí mo bá bojú wo oòrùn nígbà tí ń ràn,

tàbí òṣùpá tí ń ràn nínú ìtànmọ́lẹ̀,

27bí a bá tàn ọkàn mi jẹ

láti fi ẹnu mi kò ọwọ́ mi,

28èyí pẹ̀lú ni ẹ̀ṣẹ̀ ti àwọn onídàájọ́ ní láti bẹ̀wò,

nítorí pé èmí yóò jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run tí ó wà lókè.

29“Bí ó bá ṣe pé mo yọ̀ sì ìparun ẹni tí ó kórìíra mi.

Tàbí bí mo bá sì gbéraga sókè, nígbà tí ibi bá a.

30Bẹ́ẹ̀ èmi kò sì jẹ ki ẹnu mi ki ó ṣẹ̀

nípa fífẹ́ ègún sí ọkàn rẹ̀.

31Bí àwọn ènìyàn inú àgọ́ mi kò bá lè wí pé,

‘Ta ni kò ì tí ì jẹ ẹran rẹ̀ ní àjẹyó?’

32Àlejò kò wọ̀ ni ìgboro rí;

èmí ṣí ìlẹ̀kùn mi sílẹ̀ fún èrò.

33Bí mo bá bò ẹ̀ṣẹ̀ mi mọ́lẹ̀ bí Adamu ni pápá,

ẹ̀bi mi pamọ́ ni àyà mi.

34Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni mo ha bẹ̀rù bí?

Tàbí ẹ̀gàn àwọn ìdílé ní ń bà mí ní ẹ̀rù?

Tí mo fi pa ẹnu mọ́, tí èmí kò sì fi sọ̀rọ̀ jáde?

35(“Ìbá ṣe pé ẹnìkan le gbọ́ ti èmí!

Kíyèsi i, àmì mi, kí Olódùmarè kí ó dá mi lóhùn,

kí èmí kí ó sì rí ìwé náà tí olùfisùn mi ti kọ.

36Nítòótọ́ èmí ìbá gbé le èjìká mi,

èmi ìbá sì dé bí adé mọ́ orí mi.

37Èmi ìbá sì sọ iye ìṣísẹ̀ mi fún un,

bí ọmọ-aládé ni èmi ìbá súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀.)

38“Bí ilẹ̀ mi bá sì ké rara lòdì sí mi

tí a sì fi omijé kún gbogbo poro rẹ̀.

39Bí mo bá jẹ èso oko mi láìsan owó

tàbí tí mo sì mú ọkàn olúwa rẹ̀ fò lọ,

40kí ẹ̀gún òṣùṣú kí ó hù dípò alikama,

àti èpò búburú dípò ọkà barle.”

Ọ̀rọ̀ Jobu parí.