New Amharic Standard Version

ዘሌዋውያን 4:1-35

የኀጢአት መሥዋዕት

1እግዚአብሔር (ያህዌ) ሙሴን እንዲህ ሲል ተናገረው፤ 2“ለእስራኤል ሕዝብ እንዲህ በላቸው፤ ‘ማንም ሰው ባለማወቅ ኀጢአት ቢሠራ፣ እግዚአብሔር (ያህዌ) አታድርጉ ብሎ ካዘዛቸውም አንዱን ተላልፎ ቢገኝ፣

3“ ‘የተቀባውም ካህን በሕዝቡ ላይ በደል የሚያስከትል ኀጢአት ቢሠራ፣ ስለ ሠራው ኀጢአት እንከን የሌለበት አንድ ወይፈን ለእግዚአብሔር (ያህዌ) የኀጢአት መሥዋዕት አድርጎ ያቅርብ። 4ወይፈኑን በመገናኛው ድንኳን ደጃፍ በእግዚአብሔር (ያህዌ) ፊት ያቅርብ፤ እጁንም በወይፈኑ ራስ ላይ ይጫን፤ በእግዚአብሔርም (ያህዌ) ፊት ይረደው። 5የተቀባው ካህን ከወይፈኑ ደም ጥቂት ወስዶ ወደ መገናኛው ድንኳን ይግባ፤ 6ጣቱንም በደሙ ውስጥ ነክሮ ከመቅደሱ መጋረጃ ትይዩ፣ በእግዚአብሔር (ያህዌ) ፊት ሰባት ጊዜ ይርጨው። 7ካህኑ ከደሙ ጥቂት ወስዶ በመገናኛው ድንኳን ውስጥ በእግዚአብሔር (ያህዌ) ፊት ያለውንና ሽታው ጣፋጭ የሆነ ዕጣን የሚታጠንበትን መሠዊያ ቀንዶች ይቅባ። የተረፈውን የወይፈኑን ደም ሁሉ በመገናኛው ድንኳን መግቢያ ላይ ባለው በሚቃጠል መሥዋዕት መሠዊያ ግርጌ ያፍሰው፤ 8ለኀጢአት መሥዋዕት ከሚቀርበው ወይፈን ሥቡን ሁሉ ያውጣ፤ ይኸውም፦ የሆድ ዕቃውን የሚሸፍነውን ሥብና ከሆድ ዕቃው ጋር የተያያዘውን ሥብ፣ 9ሁለቱንም ኵላሊቶች፣ በኵላሊቶቹ ላይና በጎድኑ አጠገብ ያለውን ሥብ እንዲሁም የጒበቱን መሸፈኛ ከኵላሊቶቹ ጋር አብሮ አውጥቶ ያቅርብ፤ 10ለኅብረት መሥዋዕት4፥10 በትውፊት የሰላም መሥዋዕት ይባላል፤ እንዲሁም ቍ 26፡31፡35 ይመ። ከሚቀርበው ወይፈን4፥10 የዕብራይስጡ ቃል ተባዕትንና እንስትን ሊያጠቃልል ይችላል። እንዳወጣ ሁሉ ሥቡን ያውጣ፤ ካህኑም የሚቃጠል መሥዋዕት በሚቀርብበት መሠዊያ ላይ ያቃጥለው። 11ነገር ግን የወይፈኑን ቈዳና ሥጋውን ሁሉ፣ ጭንቅላቱንና እግሮቹን፣ ሆድ ዕቃውንና ፈርሱን፣ 12የወይፈኑን ብልት ሁሉ ከሰፈር ውጭ ዐመድ ወደሚፈስበት በአምልኮው ሥርዐት መሠረት ንጹሕ ወደ ሆነው ስፍራ ይውሰደው፤ በተቈለለው ዐመድ ላይ ዕንጨት አንድዶ ያቃጥለው።

13“ ‘መላው የእስራኤል ሕዝብ ባለማወቅ ኀጢአት ቢሠራ፣ አታድርጉ ብሎ እግዚአብሔር (ያህዌ) ካዘዘውም አንዱን ተላልፎ ቢገኝ፣ ይህ ሕዝብ ጥፋቱ ባይታወቀውም በደለኛ ነው። 14የሕዝቡ ጉባኤ ኀጢአት መሥራቱን በተረዳ ጊዜ፣ ለኀጢአት መሥዋዕት የሚሆን አንድ ወይፈን በመገናኛው ድንኳን ፊት ያቅርብ። 15የሕዝቡም ሽማግሌዎች በእግዚአብሔር (ያህዌ) ፊት እጆቻቸውን በወይፈኑ ራስ ላይ ይጫኑ፤ ወይፈኑም በእግዚአብሔር (ያህዌ) ፊት ይታረድ። 16የተቀባውም ካህን ከወይፈኑ ደም ጥቂት ወስዶ ወደ መገናኛው ድንኳን ይግባ። 17ጣቱን በደሙ ውስጥ ነክሮ፣ በመጋረጃው ትይዩ በእግዚአብሔር (ያህዌ) ፊት ሰባት ጊዜ ይርጨው። 18ከደሙ ጥቂት ወስዶ በመገናኛው ድንኳን ውስጥ በእግዚአብሔር (ያህዌ) ፊት ያለውን የመሠዊያ ቀንዶች ይቅባ፤ የተረፈውን ደም ሁሉ በመገናኛው ድንኳን መግቢያ ላይ ባለው በሚቃጠል መሥዋዕት መሠዊያ ግርጌ ያፍሰው። 19ከወይፈኑም ሥቡን ሁሉ ወስዶ በመሠዊያው ላይ ያቃጥል፤ 20ለኀጢአት መሥዋዕት ባቀረበው ወይፈን ላይ እንዳደረገው ሁሉ፣ በዚህኛውም ወይፈን ያድርግ፤ በዚህም መሠረት ካህኑ ስለ ሕዝቡ ያስተሰረያል፤ እነርሱም ይቅር ይባላሉ። 21ወይፈኑንም ከሰፈር ውጭ ያውጣው፤ የመጀመሪያውን ወይፈን እንዳቃጠለው ሁሉ ይህኛውንም ያቃጥል፤ ይህም ስለ ሕዝቡ የሚቀርብ የኀጢአት መሥዋዕት ነው።

22“ ‘አንድ የሕዝብ መሪ ባለማወቅ ኀጢአት ቢሠራ፣ አምላኩም እግዚአብሔር (ኤሎሂም ያህዌ) አታድርጉ ብሎ ከከለከላቸው ትእዛዛት አንዱን ተላልፎ ቢገኝ እርሱ በደለኛ ነው። 23ኀጢአት መሥራቱን በተረዳ ጊዜ እንከን የሌለበትን ተባዕት ፍየል የግሉ መሥዋዕት አድርጎ ያቅርብ። 24እጁንም በፍየሉ ራስ ላይ ይጫን፤ የሚቃጠል መሥዋዕት በሚታረድበትም ስፍራ በእግዚአብሔር (ያህዌ) ፊት ይረደው፤ ይህም የኀጢአት መሥዋዕት ነው። 25ካህኑም ከመሥዋዕቱ ደም በጣቱ ጥቂት ወስዶ የሚቃጠል መሥዋዕት የሚቀርብበትን መሠዊያ ቀንዶች ይቅባ፤ የተረፈውንም ደም ሁሉ በመሠዊያው ግርጌ ያፍሰው። 26የኅብረት መሥዋዕቱን እንዳቃጠለ ሁሉ ሥቡንም በሙሉ በመሠዊያው ላይ ያቃጥል፤ በዚህም መሠረት ካህኑ የሰውየውን ኀጢአት ያስተሰረይለታል፤ ሰውየውም ይቅር ይባላል።

27“ ‘ከሕዝቡ መካከል አንዱ ሰው ባለማወቅ ኀጢአት ቢሠራ፣ እግዚአብሔር (ያህዌ) አታድርጉ ብሎ ከከለከላቸው ትእዛዛት አንዱን ተላልፎ ቢገኝ እርሱ በደለኛ ነው። 28ኀጢአት መሥራቱን በተረዳ ጊዜ፣ እንከን የሌለባትን እንስት ፍየል ስለ ፈጸመው ኀጢአት የግሉ መሥዋዕት አድርጎ ያቅርብ። 29እጁን ለኀጢአት መሥዋዕት በቀረበችው ፍየል ራስ ላይ ይጫን፤ የሚቃጠል መሥዋዕት በሚታረድበት ስፍራም ይረዳት። 30ካህኑ በጣቱ ከደሟ ጥቂት ወስዶ የሚቃጠል መሥዋዕት የሚቀርብበትን መሠዊያ ቀንዶች ይቅባ፤ የተረፈውንም ደም ሁሉ በመሠዊያው ግርጌ ያፍሰው። 31ሥቡን ከኅብረት መሥዋዕት በወጣበት አኳኋን ሥቡን ሁሉ ያውጣ፤ ካህኑም ሽታው እግዚአብሔርን (ያህዌ) ደስ የሚያሰኝ መሥዋዕት አድርጎ በመሠዊያው ላይ ያቃጥለው፤ በዚህም መሠረት ካህኑ የሰውየውን ኀጢአት ያስተሰርይለታል፤ ሰውየውም ይቅር ይባላል።

32“ ‘ስለ ኀጢአት መሥዋዕት የበግ ጠቦት የሚያቀርብ ከሆነ፣ እንከን የሌለባትን እንስት ያቅርብ። 33እጁን በጠቦቷ ራስ ላይ ይጫን፤ የሚቃጠል መሥዋዕት በሚታረድበት ስፍራም የኀጢአት መሥዋዕት አድርጎ ይረዳት። 34ካህኑም ከኀጢአት መሥዋዕቱ ደም በጣቱ ጥቂት ወስዶ የሚቃጠል መሥዋዕት የሚቀርብበትን መሠዊያ ቀንዶች ይቅባ፤ የተረፈውንም ደም ሁሉ በመሠዊያ ግርጌ ያፍሰው። 35ሥቡ ከኅብረት መሥዋዕት ጠቦት በወጣበት አኳኋን ሥቡን ሁሉ ያውጣ፤ ካህኑም በመሠዊያው ላይ ለእግዚአብሔር (ያህዌ) በእሳት በሚቀርበው መሥዋዕት ላይ ያቃጥለው። በዚህ መሠረት ሰውየው የሠራውን ኀጢአት ካህኑ ያስተሰርይለታል፤ ሰውየውም ይቅር ይባላል።

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Lefitiku 4:1-35

Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀

1Olúwa sọ fún Mose pé, 24.2-12: Nu 15.27-29.“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé: ‘Bí ẹnìkan bá ṣẹ̀ láìmọ̀, tí ó ṣe ohun tí kò yẹ kó ṣe sí ọ̀kan nínú àwọn òfin Olúwa.

3“ ‘Bí àlùfáà tí a fi òróró yàn bá ṣẹ̀, tí ó sì mú ẹ̀bi wá sórí àwọn ènìyàn, ó gbọdọ̀ mú ọmọ akọ màlúù tí kò lábùkù wá fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀. 4Kí ó mú ọ̀dọ́ màlúù wá síwájú Olúwa ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. Kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e lórí, kí ó sì pa á níwájú Olúwa. 5Kí àlùfáà tí a fi òróró yàn mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù, kí ó sì gbé e lọ sínú àgọ́ ìpàdé. 6Kí ó ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà kí ó sì wọ́n díẹ̀ nínú rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀méje níwájú Olúwa, níwájú aṣọ títa ibi mímọ́. 7Àlùfáà yóò tún mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ náà sórí ìwo pẹpẹ tùràrí tó wà níwájú Olúwa nínú àgọ́ ìpàdé. Kí ó da gbogbo ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù tókù sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ ẹbọ sísun ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 8Kí ó yọ gbogbo ọ̀rá tí ń bẹ nínú akọ màlúù ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà ọ̀rá tí ó bo nǹkan inú àti gbogbo ohun tó so mọ́ wọn. 9Kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá wọn tí ń bẹ lẹ́bàá ìhà àti ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀, kí ó yọ ọ́ pẹ̀lú kíndìnrín. 10Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ń yọ ọ̀rá kúrò lára màlúù tí a fi rú ẹbọ àlàáfíà; àlùfáà yóò sì sun wọ́n lórí pẹpẹ ẹbọ sísun. 11Ṣùgbọ́n awọ màlúù àti gbogbo ara rẹ̀, àti ẹsẹ̀, gbogbo nǹkan inú àti ìgbẹ́ rẹ̀. 12Èyí túmọ̀ sí pé gbogbo ìyókù akọ màlúù náà ni kí ẹ gbé jáde síta lẹ́yìn ibùdó sí ibi tí a sọ di mímọ́ níbi tí à ń da eérú sí, kí ẹ sì sun wọ́n lórí iná igi, níbi eérú tí a kójọ.

134.13-21: Nu 15.22-26.“ ‘Bí gbogbo àpapọ̀ ènìyàn Israẹli bá ṣèèṣì ṣẹ̀, tí wọ́n sì ṣe ohun tí kò yẹ kí wọ́n ṣe sí ọ̀kan nínú àwọn òfin Olúwa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àpapọ̀ ènìyàn náà kò mọ̀ sí ọ̀rọ̀ náà, wọ́n jẹ̀bi. 14Nígbà tí wọ́n bá mọ̀, gbogbo ìjọ ènìyàn yóò mú akọ màlúù wá sí àgọ́ ìpàdé gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. 15Kí àwọn àgbàgbà ìjọ Israẹli gbé ọwọ́ lórí akọ ọmọ màlúù náà níwájú Olúwa. 16Kí àlùfáà tí a fi òróró yàn sì mú díẹ̀ lára ẹ̀jẹ̀ akọ ọmọ màlúù náà wá sínú àgọ́ ìpàdé. 17Kí ó ti ìka rẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà kí ó sì wọn ní ẹ̀ẹ̀méje níwájú Olúwa níbi aṣọ títa ẹnu-ọ̀nà. 18Kí ó sì mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ náà sórí ìwo pẹpẹ tó wà níwájú Olúwa nínú àgọ́ ìpàdé. Ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà ni kí ó dà sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ ẹbọ sísun ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 19Kí ó yọ gbogbo ọ̀rá kúrò lára rẹ̀, kí ó sì sun ún lórí pẹpẹ. 20Kí ó sì ṣe akọ ọmọ màlúù yìí gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ṣe akọ màlúù tó wà fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ṣe ètùtù fún wọn, á ó sì dáríjì wọ́n. 21Lẹ́yìn náà ni yóò sun màlúù yìí lẹ́yìn ibùdó, yóò sì sun ún gẹ́gẹ́ bó ṣe sun màlúù àkọ́kọ́. Èyí ni ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli.

22“ ‘Bí olórí kan bá ṣèèṣì ṣẹ̀ láìmọ̀ tí ó sì ṣe ohun tí kò yẹ kí ó ṣe sí ọ̀kan nínú àwọn òfin Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, ó jẹ̀bi. 23Nígbà tí a bá sì sọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fún un, ó gbọdọ̀ mú akọ ewúrẹ́ tí kò ní àbùkù wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ rẹ̀. 24Kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lórí ewúrẹ́ náà, kí ó sì pa á níbi tí wọ́n ti ń pa ẹran ẹbọ sísun níwájú Olúwa. Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni. 25Lẹ́yìn èyí, kí àlùfáà ti ìka rẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà, kí ó fi sí orí ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun, kí ó sì da ẹ̀jẹ̀ yòókù sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ 26Kí ó sun gbogbo ọ̀rá rẹ̀ lórí pẹpẹ bí ó ṣe sun ọ̀rá ọrẹ àlàáfíà. Báyìí ní àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin náà, a ó sì dáríjì í.

274.27-31: Nu 15.27,28.“ ‘Bí ènìyàn nínú àwọn ará ìlú bá ṣèèṣì ṣẹ̀ láìmọ̀ tí ó sì ṣe ohun tí kò yẹ sí ọ̀kan nínú àwọn òfin Olúwa, ó jẹ̀bi. 28Nígbà tí a bá sọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fún un, ó gbọdọ̀ mú abo ewúrẹ́ tí kò ní àbùkù wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. 29Kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lórí ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà, kí ó sì pa á níbi ẹbọ sísun. 30Àlùfáà yóò sì ti ìka rẹ̀ bọ́ ẹ̀jẹ̀ náà, yóò fi sí orí ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun, kí ó sì da ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ. 31Kí ó yọ gbogbo ọ̀rá ẹran náà gẹ́gẹ́ bó ṣe yọ ọ̀rá ẹran fún ọrẹ àlàáfíà. Kí àlùfáà sì sun ọ̀rá yìí lórí pẹpẹ bí òórùn dídùn sí Olúwa. Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún ẹni náà, a ó sì dáríjì í.

32“ ‘Bí ó bá mú ọ̀dọ́-àgùntàn wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí ó mú abo tí kò lábùkù. 33Kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e lórí, kí ó sì pa á fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ níbi tí wọ́n ti ń pa ẹran ẹbọ sísun. 34Àlùfáà yóò sì ti ìka rẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà, yóò sì fi sí orí ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun, yóò sì da ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ. 35Kí ó yọ gbogbo ọ̀rá rẹ̀ bó ti yọ ọ̀rá lára ọ̀dọ́-àgùntàn ọrẹ àlàáfíà, àlùfáà yóò sì sun ún ní orí pẹpẹ, lórí ọrẹ tí a fi iná sun sí Olúwa. Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún ẹni náà, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sẹ̀, a ó sì dáríjì í.