Jesaja 45 – HTB & YCB

Het Boek

Jesaja 45:1-25

1Zo spreekt Jahweh tot zijn gezalfde, Tot Cyrus, die Hij bij de rechterhand heeft gevat: Om volken voor hem neer te werpen, En vorsten de gordel van de lenden te trekken; Om deuren voor hem los te rukken, Geen poorten blijven gesloten. 2Ik zelf ga voor u uit, En zal de hoogten voor u slechten; Bronzen poorten trap Ik in, Ijzeren grendels sla Ik stuk; 3Verborgen schatten zal Ik u geven, En goed verstopte fortuinen. Opdat ge moogt weten, dat Ik, Jahweh, het ben, Ik, Israëls God, die u riep bij uw naam! 4Terwille van Jakob, mijn dienaar, Van Israël, mijn uitverkorene, Heb Ik u bij uw naam geroepen, U een titel geschonken, zonder dat ge Mij kent. 5Ik ben Jahweh, er is geen ander; Buiten Mij bestaat er geen god. Ik heb u omgord, zonder dat ge Mij kent: 6Opdat men zou weten Van het oosten tot het westen, Dat er geen ander bestaat buiten Mij! Ik ben Jahweh, er is geen ander! 7Ik vormde het licht, En heb het duister geschapen; Het heil verwekt, En het onheil gesticht: Ik, Jahweh, heb dit alles gedaan! 8Hemelen, dauwt uit de hoge, Wolken, laat de gerechtigheid stromen; Aarde open uw schoot, Om vrucht van verlossing te dragen, En gerechtigheid te laten ontspruiten: Ik, Jahweh, heb het gewrocht! 9Wee, die met hun Schepper twisten: De scherven met den pottenbakker! Zegt het leem soms tot hem, die het kneedt: Wat maakt ge? Uw handen staan er niet naar. 10Wee, die tot zijn vader durft zeggen: waarom verwekt ge; Of tot een vrouw: waarom hebt ge barensweeën? 11Zo spreekt Jahweh, Israëls Heilige en Schepper: Durft ge Mij rekenschap vragen van wat gaat gebeuren, Mij bevelen geven over het werk mijner handen? 12Ik heb de aarde gemaakt, en den mens er geschapen, Met eigen hand de hemel gespannen, heel zijn heir er besteld! 13Ik zelf heb hem in mijn goedheid verwekt, En al zijn paden geëffend; Hij is het, die mijn stad zal herbouwen, En mijn ballingen zal laten gaan Zonder losprijs, zonder geschenken: Spreekt Jahweh der heirscharen! 14Zo spreekt Jahweh: Egypte’s slaven en de kooplui van Koesj Met de mannen van Seba, hoog van gestalte, Zullen overgaan in ùw hand, U toebehoren, en achter u aangaan, En in ketens u dienen. Ze zullen voor u ter aarde vallen, En tot u smeken: Alleen bij u is een God, Nergens zijn er andere goden; 15Alleen bij u is een God, die beschermt, De God van Israël is een Verlosser! 16Ze worden allen beschaamd en met schande bedekt, Verlegen druipen ze af, die makers van beelden. 17Israël, gij wordt door Jahweh verlost Met een redding voor eeuwig; Gij zult niet worden beschaamd en te schande gemaakt, In alle eeuwigheid niet! 18Want zo spreekt Jahweh, Die de hemelen schiep, De God, die de aarde boetseerde, Haar maakte en grondde; Die haar niet schiep als een baaierd, Maar vormde, om te worden bewoond. 19Ik ben Jahweh; geen ander! Ik heb niet in het verborgen gesproken, Of in een duistere hoek van de aarde; Tot Jakobs kroost niet gezegd: Zoekt Mij tevergeefs! Neen, Ik ben Jahweh, die rechtuit spreekt, En die de waarheid voorspelt. 20Verzamelt u, komt, treedt allen bijeen Die van de volken zijn overgebleven; Die in onverstand houten afgoden draagt, En bidt tot een god, die niet redt. 21Spreekt op, brengt uw bewijzen naar voren, En beraadt u onder elkander. Wie heeft dit van oudsher verkondigd, En het lang te voren voorspeld? Ben Ik het niet, Jahweh, Buiten wien geen andere god bestaat? Neen, een rechtvaardige en reddende God Is er buiten Mij niet! 22Wendt u tot Mij, dan wordt gij gered, alle grenzen der aarde; Want Ik ben God, er is geen ander! 23Ik zweer bij Mijzelf, uit mijn mond komt de waarheid, Het woord, dat nooit wordt herroepen. Voor Mij moet iedere knie zich buigen, Iedere tong bij Mij zweren. 24Van Mij zal men zeggen: Bij Jahweh alleen is zege en kracht! Tot Hem komen terug, met schaamte bedekt, Allen, die Hem weerstonden; 25Maar in Jahweh zal verwinnen en juichen Heel Israëls geslacht!

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Isaiah 45:1-25

1“Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún ẹni òróró rẹ̀,

sí Kirusi, ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí mo dì mú

láti dojú àwọn orílẹ̀-èdè bolẹ̀ níwájú rẹ̀

àti láti gba ohun ìjà àwọn ọba lọ́wọ́ wọn,

láti ṣí àwọn ìlẹ̀kùn níwájú rẹ̀

tí ó fi jẹ́ pé a kì yóò ti àwọn ẹnu-ọ̀nà.

2Èmi yóò lọ síwájú rẹ,

Èmi ó sì tẹ́ àwọn òkè ńlá pẹrẹsẹ

Èmi yóò fọ gbogbo ẹnu-ọ̀nà idẹ

èmi ó sì gé ọ̀pá irin.

3Èmi yóò sì fún ọ ní àwọn ọrọ̀ ibi òkùnkùn,

ọrọ̀ tí a kó pamọ́ sí àwọn ibi tí ó fi ara sin,

tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ yóò fi mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa,

Ọlọ́run Israẹli, ẹni tí ó pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ.

4Nítorí Jakọbu ìránṣẹ́ mi

àti Israẹli ẹni tí mo yàn,

Mo pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ,

mo sì gbé oyè kan kà ọ́ lórí

bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kò gbà mí.

5Èmi ni Olúwa, àti pé kò sí ẹlòmíràn;

yàtọ̀ sí èmi kò sí ọlọ́run kan,

Èmi yóò fún ọ ní okun,

bí o kò tilẹ̀ tí ì gbà mí,

6tí o fi jẹ́ pé láti ìlà-oòrùn

títí dé ibi ìwọ̀ rẹ̀

kí ènìyàn le mọ̀, kò sí ẹnìkan lẹ́yìn mi.

Èmi ni Olúwa, lẹ́yìn mi kò sí ẹlòmíràn mọ́.

7Mo dá ìmọ́lẹ̀, mo sì dá òkùnkùn,

Mo mú àlàáfíà wá, Mo sì dá àjálù;

Èmi Olúwa ni ó ṣe nǹkan wọ̀nyí.

8“Ìwọ ọ̀run lókè rọ òjò òdodo sílẹ̀;

jẹ́ kí àwọsánmọ̀ kí ó rọ̀ ọ́ sílẹ̀.

Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó yanu gbagada,

jẹ́ kí ìgbàlà kí ó dìde sókè,

jẹ́ kí òdodo kí ó dàgbà pẹ̀lú rẹ̀;

Èmi Olúwa ni ó ti dá a.

945.9: Isa 29.16; Ro 9.20.“Ègbé ni fún ènìyàn tí ó ń bá Ẹlẹ́dàá rẹ̀ jà,

ẹni tí òun jẹ́ àpáàdì kan láàrín àwọn àpáàdì tí ó wà lórí ilẹ̀.

Ǹjẹ́ amọ̀ lè sọ fún amọ̀kòkò, pé:

‘Kí ni ohun tí ò ń ṣe?’

Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ lè sọ pé,

‘Òun kò ní ọwọ́?’

10Ègbé ni fún ẹni tí ó sọ fún baba rẹ̀ pé,

‘Kí ni o bí?’

tàbí sí ìyá rẹ̀,

‘Kí ni ìwọ ti bí?’

11“Ohun tí Olúwa wí nìyìí,

Ẹni Mímọ́ Israẹli, àti Ẹlẹ́dàá rẹ̀.

Nípa ohun tí ó ń bọ̀,

ǹjẹ́ o ń bi mí léèrè nípa àwọn ọmọ mi,

tàbí kí o pàṣẹ fún mi nípa iṣẹ́ ọwọ́ mi bí?

12Èmi ni ẹni tí ó dá ilẹ̀ ayé

tí ó sì da ọmọ ènìyàn sórí i rẹ̀.

Ọwọ́ mi ni ó ti ta àwọn ọ̀run;

mo sì kó àwọn àgbájọ ìràwọ̀ rẹ̀ síta.

13Èmi yóò gbé Kirusi sókè nínú òdodo mi.

Èmi yóò mú kí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.

Òun yóò tún ìlú mi kọ́

yóò sì tú àwọn àtìpó mi sílẹ̀,

ṣùgbọ́n kì í ṣe fún owó tàbí ẹ̀bùn kan,

ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”

1445.14: 1Kọ 14.25.Ohun tí Olúwa wí nìyìí:

“Àwọn èròjà ilẹ̀ Ejibiti àti àwọn ọjà ilẹ̀ Kuṣi,

àti àwọn Sabeani—

wọn yóò wá sọ́dọ̀ rẹ

wọn yóò sì jẹ́ tìrẹ;

wọn yóò máa wọ́ tẹ̀lé ọ lẹ́yìn,

wọn yóò máa wá lọ́wọ̀ọ̀wọ́.

Wọn yóò máa foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀,

wọn yóò sì máa bẹ̀bẹ̀ níwájú rẹ pé,

‘Nítòótọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ kò sì ṣí ẹlòmíràn;

kò sí ọlọ́run mìíràn.’ ”

15Nítòótọ́ ìwọ jẹ́ Ọlọ́run tí ó fi ara rẹ̀ pamọ́,

Ìwọ Ọlọ́run àti Olùgbàlà Israẹli,

16Gbogbo àwọn tí ó ń gbẹ́ ère ni ojú yóò tì

wọn yóò sì kan àbùkù;

gbogbo wọn ni yóò bọ́ sínú àbùkù papọ̀.

1745.17: Hb 5.9.Ṣùgbọ́n Israẹli ni a ó gbàlà láti ọwọ́ Olúwa

pẹ̀lú ìgbàlà ayérayé;

a kì yóò kàn yín lábùkù tàbí kí a dójútì yín,

títí ayé àìnípẹ̀kun.

18Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí,

ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run,

Òun ni Ọlọ́run;

ẹni tí ó mọ tí ó sì dá ayé,

Òun ló ṣe é;

Òun kò dá a láti wà lófo,

ṣùgbọ́n ó ṣe é kí a lè máa gbé ibẹ̀,

Òun wí pé:

“Èmi ni Olúwa,

kò sì ṣí ẹlòmíràn.

19Èmi kò sọ̀rọ̀ níbi tí ó fi ara sin,

láti ibìkan ní ilẹ̀ òkùnkùn,

Èmi kò tí ì sọ fún àwọn ìran Jakọbu pé,

‘Ẹ wá mi lórí asán.’

Èmi Olúwa sọ òtítọ́,

Mo sì sọ èyí tí ó tọ̀nà.

20“Ẹ kó ara yín jọ kí ẹ sì wá;

ẹ kórajọ, ẹ̀yin ìsáǹsá láti àwọn orílẹ̀-èdè wá.

Aláìmọ̀kan ni àwọn tí ó ń ru ère igi káàkiri,

tí wọ́n gbàdúrà sí àwọn òrìṣà tí kò le gba ni.

2145.21: Ap 15.18.Jẹ́ kí a mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀, fihàn wá,

jẹ́ kí wọn jọ dámọ̀ràn papọ̀.

Ta ló ti sọ èyí lọ́jọ́ tí o ti pẹ́,

ta ló ti wí èyí láti àtètèkọ́ṣe?

Kì í ha á ṣe Èmi, Olúwa?

Àti pé kò sí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi,

Ọlọ́run olódodo àti olùgbàlà;

kò sí ẹlòmíràn àfi èmi.

22“Yípadà sí mi kí a sì gbà ọ́ là,

ẹ̀yin ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé;

nítorí Èmi ni Ọlọ́run kò sì ṣí ẹlòmíràn.

2345.23: Ro 14.11; Fp 2.10-11.Nípa èmi tìkára mi ni mo ti búra,

ẹnu mi ni ó ti sọ ọ́ pẹ̀lú gbogbo ipá mi,

ọ̀rọ̀ náà tí a kì yóò lè parẹ́.

Níwájú mi ni gbogbo orúnkún yóò wólẹ̀;

nípa mi ni gbogbo ahọ́n yóò búra.

24Wọn yóò sọ ní ti èmi, ‘Nínú Olúwa nìkan ni

òdodo àti agbára wà.’ ”

Gbogbo àwọn tí ó ti bínú sí;

yóò wá sọ́dọ̀ rẹ̀ a ó sì dójútì wọn.

25Ṣùgbọ́n nínú Olúwa gbogbo àwọn ìran Israẹli

ni a ó rí ní òdodo, a o sì gbé wọn ga.